Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents
ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORI KỌKANLA—AWỌN IJOYE FI ẸHONU HAN

    Ọkan lara ijẹri to ṣe pataki julọ ti a ṣe fun iṣẹ Atunṣe ni ifẹhonu han ti awọn ijoye ti n ṣe ẹsin Kristẹni ni ilẹ Germany fihan ninu igbimọ ti Spires ni 1529. Igboya, igbagbọ, ati iduroṣinṣin awọn eniyan Ọlọrun wọnyi gba ominira fun ero inu ati eri ọkan fun awọn iran ti o tẹle. Ifẹhonu han wọn ni o fun ijọ ti a fọ mọ ni orukọ Protestant; awọn agbekalẹ rẹ ni “ipilẹ fun ẹsin Protestant.”ANN 86.1

    Igba okunkun to lẹru de fun iṣẹ Atunṣe. Yato si aṣẹ Worms ti o yọ Luther kuro labẹ aabo ofin, ti o si tako awọn ikọni tabi igbagbọ rẹ, ifarada ẹsin ti n gbilẹ ninu ijọba naa. Agbara Ọlọrun da awọn agbara ti n tako otitọ duro. Charles V n fẹ lati pa iṣẹ Atunṣe run, ṣugbọn nigbakugba ti o ba gbe ọwọ rẹ soke, o maa n di dandan fun lati yi ọwọ rẹ pada. Latigbadegba ni o dabi ẹnipe iparun kiakia yoo kọlu gbogbo awọn ti wọn gboya lati tako Romu; ṣugbọn ni akoko ti o nira julọ, awọn ọmọ ogun Turk yọ lati iha ila oorun wa, ṣugbọn ọba France, ati popu funra rẹ ko ogun ja a nitori ti wọn jowu wipe agbara ọba naa n tubọ n pọ si; nitori eyi, laarin ija ati rogbodiyan awọn orilẹ ede, a fi iṣẹ Atunṣe silẹ lati dagba ati lati tan kalẹ.ANN 86.2

    Amọ lẹyin-ọrẹyin, awọn ilẹ ti n ṣe atilẹyin popu pari ija wọn ki wọn baa le jumọ pọ ṣe atako awọn Alatunṣe. Igbimọ Spires ni 1526 ti fun ipinlẹ kọọkan ni ominira ninu ọrọ ti o ba ni i ṣe pẹlu ẹsin titi a yoo fi pe ipade apapọ; ṣugbọn kopẹ pupọ nigba ti ewu ti o fa ipinu yii kọja, ti ọba pe igbimọ keji lati pade ni Spires, lati le pa ẹkọ odi run. Bi o ba ṣe e ṣe a yoo fi ọna alaafia fa oju awọn ijoye mọra lati le tako iṣẹ Atunṣe; ṣugbọn bi eyi ba baku, Charles ṣetan lati lo idà.ANN 86.3

    Inu awọn atẹle popu dun. Awọn tó wa si Spires ninu wọn pọ jọjọ, wọn si fi ikorira wọn han si awọn Alatunṣe ati awọn ti wọn ṣe ti wọn ni ojutaye. Melancthon sọ wipe: “Awa ni ohun ifibu ati idọti aye; ṣugbọn Kristi yoo boju wo awọn otoṣi eniyan rẹ, yoo si pa wọn mọ.” A ko gba awọn ijoye inu igbimọ naa ti wọn gbagbọ ninu iyinrere laaye lati waasu iyinrere ninu ibugbe wọn. Ṣugbọn awọn ara Spires n poungbẹ fun ọrọ Ọlọrun, pẹlu gbogbo awọn ofin ti wọn ṣe, ọpọ awọn eniyan ni wọn lọ si ibi isin ti a ṣe ninu ile ijọsin afọbajẹ ti Saxony.ANN 86.4

    Eyi tete mu wahala wá kankan. A ka iṣẹ iranṣẹ ọba ninu igbimọ naa wipe bi a ti fun ni ni ominira ti ẹri ọkan ti fa rukerudo nla, ọba si fẹ ki a fagile. Aṣẹ ti ko si idi fun yii fa ibinu ati ibẹru laarin awọn Kristẹni ti wọn gbagbọ ninu iyinrere. Ọkan sọ wipe: “Kristi titun ṣubu si ọwọ Kaifa ati Pilatu.” Iwa ipa awọn ẹlesin Romu tubọ n pọ si. Onitara alaimoye atẹle popu kan sọ wipe: “Awọn ara Turks san ju awọn atẹle Luther lọ; nitori ti awọn ara Turks ni ọjọ ti wọn n gbawẹ, ṣugbọn awọn atẹle Luther ki i ṣe bẹẹ. Bi a ba nilati yan laarin Iwe Mimọ Ọlọrun ati awọn aṣiṣe ti wọn ti pẹ ninu ijọ, a nilati kọ ọrọ Ọlọrun silẹ.” Melancthon sọ wipe: “Faber n sọ okuta tuntun si awa ti o gbagbọ ninu iyinrere lojoojumọ, laarin awọn eniyan inu apero.”ANN 86.5

    A ti gbe ifarada ẹsin kalẹ ni ọna ti o ba ofin mu, awọn ipinlẹ ti wọn gbagbọ ninu iyinrere si pinu lati tako titapa si ẹtọ wọn. Luther, ko le lọ si Spires nitori ti o si wa labẹ ihamọ ti Aṣẹ Worms fi si; ṣugbọn awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ, ati awọn ijoye ti Ọlọrun gbe dide lati gbeja iṣẹ Rẹ ni akoko pajawiri yii rọpọ rẹ. Frederick, ẹni pataki, ẹni ti o n daabo bo Luther tẹlẹ ti ku; ṣugbọn Duke John, arakunrin rẹ, ati ẹni ti o rọpo rẹ fi tayọtayọ gba iṣẹ Atunṣe, o fẹran alaafia, ṣugbọn o fi agbara ati igboya han ninu ohun gbogbo ti o ba ni i ṣe pẹlu igbagbọ.ANN 86.6

    Awọn alufa beere wipe ki awọn ipinlẹ ti wọn gba iṣẹ Atunṣe o gba aṣẹ Romu laisi ibeere. Awọn Alatunṣe, ni ọna keji, n beere fun ominira ti a ti kọkọ fifun ni. Wọn ko le fi ọwọ si ki Romu tun da awọn ipinlẹ ti wọn ti fi ayọ nla gba ọrọ Ọlọrun pada si abẹ akoso rẹ.ANN 86.7

    Lati le ni alaafia, ẹnikan sọ wipe nibi ti iṣẹ Atunṣe ko ba ti fi ẹsẹ mulẹ, ki a fi agbara nla fun Aṣẹ Worms lokun nibẹ; ati pe, “nibi ti awọn eniyan ba ti yapa kuro ninu rẹ, bi a ba ni ki wọn wa ni ibamu pẹlu rẹ ti o le fa rogbodiyan, ki wọn maṣe atunṣe tuntun, ki wọn ma sọrọ lori ohunkohun ti o le fa ede aiyede, wọn ko gbodo tako gbigba mass, wọn ko si gbọdọ gba ki awọn ẹlẹsin Katoliki ti Romu o darapọ mọ ẹsin Luther.” A gbe aba yii kalẹ niwaju igbimọ, o si tẹ awọn alufa ati biṣọbu popu lọrun daradara.ANN 87.1

    Bi a ba fi ọwọ si aṣẹ yii, “Iṣẹ Atunṣe ko nile tan kalẹ . . . de ibi ti a ko ti mọ ọ, bẹẹ si ni a ko nile fi ẹsẹ rẹ mulẹ lori ipilẹ ti o lagbara . . . ni awọn ibi ti o wa.” Ko ni si ominira lati sọrọ. Ko ni si aaye fun ijere ọkan. A si fẹ ki awọn ọrẹ iṣẹ Atunṣe o faramọ idilọwọ ati ìfòfindè yii. O dabi ẹnipe ireti aye ti fẹ wọ omi. “Fifi idi aṣẹ Romu mulẹ pada . . . yoo da awọn aṣeju atijọ pada laiyẹsẹ;” ààyè yoo si wa daradara lati “pari iparun” iṣẹ ti “iyapa ati erokero ẹsin ti mì jìgìjigi.”ANN 87.2

    Bi awọn ẹgbẹ ti wọn gbagbọ ninu iyinrere ti pade fun ijiroro, wọn wo ara wọn pẹlu ifoya. Wọn n beere lọwọ ara wọn wipe: “Kini ki a ṣe?” Awọn ọrọ nla ti o kan gbogbo aye ni o wa nilẹ. “Ṣe ki awọn adari iṣẹ Atunṣe o tẹriba, ki wọn si gba aṣẹ naa ni? Bawo ni o ṣe rọrun to fun awọn Alatunṣe lati ṣe aroye titi ti wọn a fi ṣe ohun ti ko tọ ni akoko wahala yii, bi o tilẹ jẹ wipe o tobi nitootọ! Awọn idi ti ko tọna ṣugbọn ti wọn dara loju ti pọ to fun wọn lati gba a! A fun awọn ijoye ti wọn jẹ atẹle Luther ni anfani lati ṣe ẹsin wọn laisi idiwọ. A fun gbogbo awọn ọmọ ijọba wọn ti wọn ti gba igbagbọ yii ṣaaju ki a to ṣe ofin yii ni iru anfani kan naa. Ṣe ko yẹ ki eyi o to wọn bi? Ọpọlọpọ idamu ti gbigba aṣẹ yii i ba dena ti pọ to! Iru ewu ati wahala ti wọn ko mọ wo ni ṣiṣe atako yoo sọ wọn si! Tani o mọ awọn anfani ti ọjọ ọla yoo mu wa? Ẹ jẹ ki a gba alaafia laaye; ẹ jẹ ki a gba ipe alaafia ti Romu n mu wa, ki a si wo ọgbẹ ilẹ Germany san. Awọn Alatunṣe le fi iru awọn ọrọ bawọnyii da ara wọn lare lati gba àbá ti i ba bi iṣẹ wọn ṣubu laipẹ jọjọ.ANN 87.3

    “Wọn fi tayọtayọ wo ipilẹ ti àbá yii duro le lori, wọn si wuwa pẹlu igbagbọ. Kini ipilẹ naa? Ohun ni ẹtọ Romu lati ṣe akoso ẹri ọkan eniyan ati lati maṣe fi aaye gba iwadi. Ṣebi awọn ati awọn ọmọ ilu wọn yoo jẹgbadun ominira ẹsin? Bẹẹni, ṣugbọn aba yii fun wọn gẹgẹ bi ojurere ni, ki i ṣe gẹgẹ bi ẹtọ. Ilana nla fun aṣẹ yii ni yoo ṣe akoso fun gbogbo awọn ti ko si labẹ agbekalẹ yii; ko si ohun ti n jẹ ẹri ọkan; Romu ni adajọ ti ko le baku, a si nilati ṣe igbọran si i. Gbigba aba yii yoo tumọ si wipe wọn fi ọwọ si ki ominira ẹsin o maṣe kọja Saxony ti a ti fọmọ; ninu awọn ilẹ ti n ṣe ẹsin Kristẹni yoku, bibeere ibeere pẹlu ominira ati gbigba igbagbọ ti a fọ mọ yoo jẹ iwa ọdaran, ti a si nilati ṣe idajọ rẹ pẹlu tubu tabi idanasunni. Ṣe wọn yoo gba lati ni agbegbe ti yoo maa ni ominira ẹsin? ki a sọ wipe iṣẹ Atunṣe ti ṣe ijere ọkan rẹ ti o kẹyin? o ti gba ilẹ rẹ ti o kẹyin? ati nibikibi ti Romu ba ti n ṣe akoso lọwọlọwọ, ijọba rẹ yoo wa titi lae? Ṣe awọn Alatunṣe le gba wipe wọn jẹ alailẹṣẹ fun ẹjẹ ọpọ awọn eniyan ti wọn ti padanu ẹmi wọn ninu awọn ilẹ ti n ṣe ẹsin popu nitori wipe wọn fẹ gba ilana yii? Eyi yoo tumọ si wipe, ni akoko ti o ga julọ, wọn kọ iṣẹ iyinrere ati ominira ẹsin Kristẹni silẹ.” Ṣugbọn dipo bẹẹ, wọn yan lati “padanu ohun gbogbo, ani ipinlẹ wọn, ade wọn, ati ẹmi wọn.”ANN 87.4

    Awọn ijoye sọ wipe, “ẹ jẹ ki a tako aṣẹ yii.” “Lori ọrọ ẹri ọkan, ọpọ eniyan ko ni agbara.” Awọn ijoye sọ wipe: “Aṣẹ 1526 ni o jẹ ki a ri alaafia ti ijọba yii n jẹgbadun rẹ; bi a ba mu kuro, yoo jẹ ki wahala ati iyapa o kun ilẹ Germany. Igbimọ yii ko ni agbara ju lati daabo bo ominira ẹsin lọ titi ti igbimọ ijọ yoo fi pade.” Ojuṣe ilu ni lati daabo bo ominira ẹri ọkan, eyi si ni opin aṣẹ rẹ lori ọrọ ẹsin. Gbogbo ijọba aye ti o ba ṣe ofin tabi ṣe akoso lori iṣẹ ẹsin pẹlu aṣẹ ilu sọ igbagbọ ti awọn Kristẹni ti wọn gbagbọ ninu iyinrere fi gbogbo agbara ja fun nu.ANN 87.5

    Awọn atẹle popu pinu lati sẹ ohun ti wọn pe ni “agidi ailẹru” yii rọ. Wọn bẹrẹ nipa dida iyapa silẹ laarin awọn alatilẹyin iṣẹ Atunṣe, ati lati ṣẹru ba awọn ti wọn koi tii ṣe atilẹyin rẹ ni gbangba. Lẹyin-ọrẹyin, a pe awọn aṣoju awọn ilu ti wọn ti gba ominira wa siwaju igbimọ a si beere boya wọn yoo gba aba ti wọn mu wa. Wọn bẹbẹ fun akoko diẹ, ṣugbọn a ko fi aaye gba wọn. Nigba ti a beere ni ọwọ wọn, awọn ti wọn duro ti awọn Alatunṣe fẹrẹ to idaji iye wọn. Awọn ti wọn kọ lati kọ ominira ẹri ọkan ati ẹtọ olukuluku lati ṣe ipinu ara rẹ silẹ mọ wipe ipinu wọn ti yà wọn sọtọ fun ẹgan, ibawi, ati inunibini. Ọkan ninu awọn aṣoju naa sọ wipe: “A nilati sẹ ọrọ Ọlọrun tabi—ki a sun wa nina.”ANN 87.6

    Ọba Ferdinad, aṣoju ọba ninu igbimọ naa ri wipe aṣẹ naa yoo fa iyapa nla ayafi bi a ba le rọ awọn ijoye lati gba a ki wọn si ti i lẹyin. Nitori naa, o wa n rọ wọn, nitori ti o mọ daju wipe fifi ipa mu awọn eniyan wọnyi yoo tubọ jẹ ki wọn lo agidi si ni. O “bẹ awọn ijoye lati gba aṣẹ naa, o fi da wọn loju wipe inu ọba yoo dun si wọn jọjọ.” Ṣugbọn awọn olootọ eniyan wọnyi mọ aṣẹ kan ti o ga ju awọn alaṣe aye lọ, wọn fi tọwọtọwọ dahun wipe: “A yoo ṣe igbọran si ọba ninu ohun gbogbo ti yoo mu alaafia wa, ti yoo si fi ọwọ fun Ọlọrun.”ANN 88.1

    Niwaju igbimọ naa, ọba kede fun afọbajẹ ati awọn ọrẹ rẹ wipe “a ti fẹ kọ aba naa bi aṣẹ ọba,” ati wipe “ohun ti o ku fun wọn lati ṣe ni lati gba ipinu ọpọ eniyan.” Nigba ti o sọrọ bayii tan, o kuro ninu apero naa ko si fun awọn Alatunṣe ni anfani lati ṣe ijiroro, tabi lati fesi. “Wọn ran aṣoju lati lọ bẹ ọba lati pada wa, ṣugbọn pabo ni o jasi.” Èsì ti o fọ fun gbogbo arọwa ti wọn pa si ni wipe: “A ti ṣe ipinu lori ọrọ naa; ohun ti o ku ni ki a ṣe igbọran si.”ANN 88.2

    Awọn ti wọn ṣe ti ọba mọ daju wipe awọn ijoye ti wọn jẹ Kristẹni yoo tẹle Iwe Mimọ gẹgẹ bi aṣẹ ti o ga ju ikọni ati ilana eniyan lọ; wọn si mọ wipe, nibikibi ti a ba ti gba ikọni yii, ilana popu yoo ṣubu ni dandan. Ṣugbọn, bi ọpọlọpọ lati akoko yẹn wa, wọn n wo “awọn ohun ti a ri” wọn n dun ara wọn ninu wipe iṣẹ ọba ati ti popu lagbara, titi awọn Alatunṣe si jẹ alailera. Bi o ba jẹ wipe agbara eniyan nikan ni awọn Alatunṣe gbẹkẹle ni, wọn i ba jẹ alailagbara bi awọn atẹle popu ti ro. Ṣugbọn bi o tilẹ jẹ wipe wọn kere niye, ti wọn ko si ba Romu fi ohun ṣọkan, wọn ni okun wọn. Wọn pe ẹjọ kotẹmilọrun “lati ọdọ iroyin igbimọ lọ si ọdọ ọrọ Ọlọrun, ati lati ọdọ ọba Charles lọ si ọdọ Jesu Kristi Ọba awọn ọba ati Oluwa awọn oluwa.”ANN 88.3

    Bi Ferdinand ti kọ lati bọwọ fun ohun ti wọn fi tọkantọkan gbagbọ, awọn ijoye naa pinu lati maṣe naani aisinile rẹ, ṣugbọn wọn mu Ifẹhonu han wọn wa siwaju igbimọ orilẹ ede laidẹsẹduro. Wọn ṣe awọn akọsilẹ pataki kan ti wọn mu wa siwaju igbimọ:ANN 88.4

    “Awa ti a wa nibi fi èhonu wa han niwaju Ọlọrun, Ẹlẹda, Oludaabobo, Olurapada, ati Olugbala wa kan ṣoṣo, ati Ẹni ti yoo jẹ Adajọ wa ni ọjọ kan, ati niwaju gbogbo eniyan ati gbogbo ẹda, fun awa ati fun awọn eniyan wa, wipe a ko fi ọwọ si tabi faramọ aṣẹ ti a fẹ gbe kalẹ lọnakọna, ninu ohunkohun ti o ba tako Ọlọrun, ọrọ mimọ Rẹ, ẹtọ wa si ẹri ọkan wa, ati si igbala ọkan wa.”ANN 88.5

    “Kini! A fi ohun si aṣẹ yii! A sọ wipe nigba ti Ọlọrun Alagbara ba pe eniyan wa sinu imọ Rẹ, ẹni naa ko le gba imọ Ọlọrun!” “Ko si ikọni ti o daju ayafi eyi ti o ba ọrọ Ọlọrun mu. . . . Oluwa ko fi ọwọ si kikọ ikọni miran. . . . Awọn ẹsẹ miran ti wọn fi ara han kedere ni o yẹ ki wọn ṣe alaye Iwe Mimọ; . . . Kristẹni nilo Iwe Mimọ yii ninu ohun gbogbo, o rọrun lati yeni, a si fun ni lati le fọn okunkun ká. A ti pinu pẹlu oore ọfẹ Ọlọrun lati ṣe atilẹyin wiwaasu ọrọ Rẹ nikanṣoṣo ninu iwa mimọ rẹ, gẹgẹ bi o ti wa ninu Majẹmu Laelae ati Tuntun, laifi ohun kankan ti o le tako o kun. Ọrọ yii ni otitọ kan ṣoṣo; ohun ni odiwọn ti o daju fun gbogbo ikọni ati igbe aye ti ko le baku, ti ko si le tan wa jẹ. Ẹnikẹni ti o ba kọle le ori ipilẹ yii yoo duro lati doju kọ gbogbo agbara ipo oku, nigba ti gbogbo asan eniyan ti wọn doju kọ ọ yoo ṣubu niwaju Ọlọrun.”ANN 88.6

    “Nitori idi eyi a kọ ajaga ti wọn gbe si ọrun wa silẹ.” Bakan naa, a n reti ki ọba alayeluwa o ṣe si wa gẹgẹ bi ijoye Kristẹni ti o fẹran Ọlọrun ju ohun gbogbo lọ; a tun sọ wipe a ṣetan lati fun, ati ẹyin oluwa oloore ọfẹ pẹlu, gbogbo ifẹ ati igbọran ti i ṣe ojuṣe wa ti o tọna ti o si ba ofin mu.”ANN 88.7

    O fi ọwọ ba awọn ọmọ igbimọ lọkan gan an ni. Ọpọ awọn ti wọn wa nibẹ kun fun iyalẹnu ati ibẹru nitori igboya awọn ti n fi ẹhonu han yii. Ọjọ iwaju ko daju, o si ṣokunkun. O dabi ẹnipe iyapa, ija, ati itajẹsilẹ de tan. Ṣugbọn awọn Alatunṣe ni idaniloju wipe iṣe wọn jẹ otitọ, wọn gbẹkẹle ọwọ Alagbara julọ, wọn si “kun fun igboya ati iduro ṣinṣin.”ANN 89.1

    “Awọn ẹkọ to wa ninu Ifẹhonu han olokiki yii . . . ni i ṣe ipilẹ ẹsin Protestant. Ifẹhonu han yii tako aṣeju meji lori ọrọ igbagbọ: akọkọ ni ayọjuran awọn alaṣe ilu, ekeji si ni agbara ijọ ti a ko gbọdọ wo loju. Dipo awọn aṣeju wọnyi, ẹsin Protestant gbe agbara ẹri ọkan ga ju awọn alaṣẹ ilu lọ, ati aṣẹ ọrọ Ọlọrun ga ju ijọ lọ. Ni akọkọ, o tako agbara oṣelu ninu ohun ti i ṣe ti ẹmi, o sọ pẹlu awọn woli ati apostoli wipe, ‘A nilati gbọ ti Ọlọrun ju ti eniyan lọ.’ Niwaju ade Charles Karun, o gbe ade Jesu Kristi ga. Ṣugbọn o ṣe ju eyi lọ; o fi ikọni yii lelẹ wipe gbogbo ikọni eniyan nilati tẹriba fun ọrọ Ọlọrun. Awọn afẹhonuhan tun kede ẹtọ wọn lati sọ nipa igbagbọ wọn nipa otitọ laisi idiwọ. Ki i ṣe wipe wọn a gbagbọ, ti wọn a tun ṣe igbọran nikan, ṣugbọn wọn a tun kọni ni ohun ti ọrọ Ọlọrun sọ, wọn tun tako ẹtọ awọn alufa ati awọn alaṣẹ ilu lati ṣe idiwọ. Ifẹhonuhan ti Spires jẹ ijẹri ti o lagbara ni atako si ainifarada lori ọrọ ẹsin, ti o tun fi idi ẹtọ gbogbo eniyan mulẹ lati jọsin Ọlọrun gẹgẹ bi ẹri ọkan wọn ba ti ṣe sọ.ANN 89.2

    A ti ṣe ikede naa. A kọ ọ si inu ọkan ọpọlọpọ awọn eniyan ati si inu iwe ọrun nibi ti agbara eniyan kan ko ti le paarẹ. Gbogbo awọn eniyan ilẹ Germany ti wọn gbagbọ ninu iyinrere gba Ifẹhonuhan yii gẹgẹ bi afihan igbagbọ wọn. Awọn eniyan ri ileri fun igba ọtun ti o dara ninu akọsile yii nibi gbogbo. Ọkan lara awọn ijoye sọ fun awọn Afẹhonuhan ti Spires wipe: “Ki Ọlọrun Alagbara ti O ti fun yin ni oore ọfẹ lati fi gbogbo agbara ṣe ijẹwọ, laisi idiwọ, ati laibẹru o payin mọ ninu iduroṣinṣin Kristẹni naa titi di ọjọ ailopin.”ANN 89.3

    Bi o ba ṣe wipe lẹyin igba ti o ṣe aṣeyọri diẹ, iṣẹ Atunṣe gba lati wa ojurere aye ni, i ba jẹ alaiṣootọ si Ọlọrun ati si ara rẹ, i ba si pa ara rẹ run. Iriri awọn Alatunṣe pataki wọnyi jẹ ẹkọ fun gbogbo awọn eniyan ti n bọ. Bi Satani ti n ṣiṣẹ lati tako Ọlọrun ati ọrọ Rẹ koi tii yipada; o si tako ki a fi ọrọ Ọlọrun ṣe odiwọn igbesi aye gẹgẹ bi o ti ṣe ni ọrundun kẹrindinlogun. Nisinsinyii, awọn eniyan ti yapa kuro ninu ikọni ati ilana rẹ, a si nilo lati pada si ipilẹ ẹkọ nla ti awọn Protestant — Bibeli, ani Bibeli nikan, gẹgẹ bi odiwọn fun igbagbọ ati iṣe. Satani si n ṣiṣẹ nipasẹ ohun gbogbo ti o le lo lati pa ominira ẹsin run. Agbara ti o tako ẹsin Kristẹni, eyi ti awọn afẹhonu han ti Spires tako wa n ṣiṣẹ nisinsinyii pẹlu agbara tuntun lati fi idi iṣakoso ti o sọnu mulẹ pada. Titẹle ọrọ Ọlọrun laiyẹsẹ ti a fihan ni akoko wahala fun iṣẹ Atunṣe naa ni ireti fun atunṣe lonii.ANN 89.4

    Ami ewu fi ara han fun awọn Protestant; awọn ami tun fi ara han pẹlu wipe Ọlọrun na ọwọ Rẹ lati daabo bo awọn olootọ. Laarin akoko yii ni “Melancthon yara mu ọrẹ rẹ, Simon Grynaeus, la aarin ilu Spires kọja lọ si odò Rhine, o n sọ fun ki o re odo naa kọja. Ẹnu ya Simon, o wa beere idi ti o fi wuwa bẹẹ. Melancthon sọ wipe, ‘Ọkunrin agbalagba kan ti o duro tọwọtọwọ, ṣugbọn ti emi ko mọ fi ara han fun mi, o si sọ wipe laarin iṣẹju diẹ si, Fardinand yoo ran awọn oniṣẹ idajọ lati wa fi aṣẹ ọba mu Grynaeus.’”ANN 89.5

    Ni ọjọ naa, Faber, ọga ninu awọn ọmọwe ti i ṣe atẹle popu, ti ba Grynaeus lorukọ jẹ ninu iwaasu rẹ; nigba ti o pari, o ba jiroro lori bi o ti ṣe n gbeja “awọn aṣiṣe onirira kan.” “Faber fi ibinu rẹ pamọ, ṣugbọn lọgan ti o de ọdọ ọba, o gba aṣẹ lati mu ọjọgbọn oniwahala ti Heidelberg. Melancthon ko ṣe iyemeji wipe Ọlọrun gba ọrẹ rẹ silẹ nipa riran ọkan ninu awọn angẹli mimọ Rẹ lati wa ki i nilọ.ANN 89.6

    “Laimira ni eti bebe odo Rhine, o duro titi ti odo naa fi gba Grynaeus silẹ kuro lọwọ awọn ti n ṣe inunibini si. Nigba ti Melancthon ri i ni odikeji odo, o kigbe wipe, ‘Eh eh, a gba a kuro ni ẹnu awọn ti n poungbẹ fun ẹjẹ alaiṣẹ.’ Nigba ti o pada de ile rẹ, a sọ fun Melancthon wipe nigba ti awọn iranṣẹ ọba n wa Grynaeus, wọn tu gbogbo inu ile naa yẹbẹyẹbẹ lati oke de isalẹ.”ANN 89.7

    Iṣẹ Atunṣe yoo lokiki si nipa gbigbe wa si iwaju awọn ẹni nla aye. Ọba Ferdinand kọ lati gbọ ti awọn ijoye ti wọn gba iyinrere gbọ; ṣugbọn a yoo fun wọn ni anfani lati ko ẹjọ wọn wa siwaju ọba ati awọn eniyan pataki ninu ijọ ati laarin ilu. Lati le dawọ rogbodiyan ti n yọ ijọba naa lẹnu duro, Charles V, ni ọdun keji lẹyin ifẹhonuhan ni Spires pe igbimọ kan ni Augsburg, o si sọ wipe oun ni yoo dari igbimọ naa. A pe awọn adari Protestant wa sibẹ.ANN 90.1

    Awọn ewu nla n dún mọ iṣẹ Atunṣe; ṣugbọn awọn ti n kede rẹ si fi iṣẹ wọn le Ọlọrun lọwọ, wọn pinu lati duro ṣinṣin pẹlu iyinrere. Awọn olubadamọran afọbajẹ ti Saxony rọ ọ ki o maṣe fi ara han ninu igbimọ naa. Wọn sọ wipe, ọba fẹ ki awọn ijoye o wa ki o baa le fa wọn sinu panpẹ ni. “N jẹ ki i ṣe fifi ohun gbogbo wewu ni lati lọ de ara ẹni mọ inu ogiri ilu kan pẹlu ọta alagbara?” Ṣugbọn awọn miran fi igboya dahun pe, “Ẹ jẹ ki awọn ijoye o wuwa pẹlu igboya, a yoo si gba iṣẹ Ọlọrun kuro ninu ewu.” Luther sọ wipe, “Ọlọrun jẹ olootọ; ko ni kọ wa silẹ.” Afọbajẹ pẹlu awọn ẹmẹwa rẹ jade, wọn n lọ si Augsburg. Gbogbo wọn ni wọn mọ iru ewu ti o le wu wọn, ọpọlọpọ si n lọ pẹlu oju kikoro ati ọkan wuwo. Ṣugbọn Luther, ẹni ti o sin wọn de Coburg, sọ igbagbọ wọn ti n rì jí nipa kikọ ọrin ti o kọ silẹ ninu irin ajo naa, “Ile iṣọ alagbara ni Ọlọrun wa.” Ọpọ ipaya ni o bọ kuro ninu ọkan wọn, ọpọ ọkan wuwo ni wọn di fifuyẹ, nigba ti wọn gbọ awọn ọrọ amoriya ti o wa ninu rẹ.ANN 90.2

    Awọn ijoye ti wọn gba igbagbọ ti a tunṣe pinu lati kọ ero wọn silẹ ni ọna ti o han kedere, pẹlu ẹri lati inu Iwe Mimọ wa, ti wọn yoo si gbe kalẹ niwaju igbimọ. Luther, Melancthon ati awọn akẹgbẹ wọn ni a gbe iṣẹ naa fun. Awọn Protestant gba Ijẹwọ yii gẹgẹ bi alaye lori igbagbọ wọn, wọn si parapọ lati kọ orukọ wọn si ara iwe pataki naa. O jẹ akoko ọlọwọ, ati akoko idanwo. Awọn Alatunṣe n ṣe aajo wipe ki a maṣe da iṣẹ wọn papọ mọ ọrọ oṣelu; wọn ro wipe iṣẹ Atunṣe ko gbọdọ lo agbara kankan ayafi eyi ti o ba jade wa lati inu ọrọ Ọlọrun. Nigba ti awọn ijoye Kristẹni n jade wa lati wa kọ orukọ wọn si ara Ijẹwọ yii, Melancthon da wọn duro, o sọ pe: “Iṣẹ awọn olukọni nipa Ọlọrun ati awọn ojiṣẹ Ọlọrun ni lati dàba awọn nnkan wọnyi; ẹ jẹ ki a fi awọn ohun toku silẹ fun aṣẹ awọn alagbara aye.” John ara Saxony fesi wipe, “Ọlọrun majẹ, ki o yọmi silẹ. Mo ti pinu lati ṣe ohun ti o tọna, lai damu ara mi nipa ade mi. Mo fẹ lati ṣe ijẹwọ Oluwa. Fila afọbajẹ ati aṣọ igunwa mi ko ṣe iyebiye ni oju mi bii agbelebu Jesu Kristi.” Nigba ti o sọrọ bayii tan, o kọ orukọ rẹ silẹ. Omiran ninu awọn ijoye naa sọ, bi o ti mu ohun ikọwe wipe: “Bi ọla Jesu Kristi Oluwa mi ba fẹ bẹẹ, mo ṣetan . . . lati fi ẹrù ati ẹmi mi silẹ.” O fikun wipe, “Mo yan lati fi awọn eniyan ilu mi ati ipinlẹ mi silẹ, ani ki n fi orilẹ ede baba mi silẹ pẹlu ọpa ni ọwọ, ju ki n gba ikọni miran ju eyi ti o wa ninu ijẹwọ yii lọ.” Bi igbagbọ ati igboya awọn eniyan Ọlọrun wọnyi ti ri niyii.ANN 90.3

    Akoko to lati fi ara han niwaju ọba. Charles V joko lori itẹ rẹ, awọn afọbajẹ, ati awọn ijoye si joko yii ka, o n tẹti si awọn Protestant Alatunṣe. A ka ijẹwọ igbagbọ wọn. Ninu apero pataki yii, a gbe otitọ iyinrere kalẹ ni ọna ti o han kedere, a si fi awọn aṣiṣe ijọ padi han. I ba dara bi a ba pe ọjọ naa ni “ọjọ ti o tobi julọ fun iṣẹ Atunṣe, ati ọkan ninu awọn ti wọn logo julọ ninu itan ẹsin Kristẹni ati ti gbogbo eniyan.”ANN 90.4

    Ṣugbọn ọdun diẹ ni o kọja lati igba ti ajẹjẹ ẹsin ti Wittenberg danikan duro niwaju igbimọ orilẹ ede ni Worms. Ṣugbọn awọn ijoye alagbara ti wọn lokiki julọ ninu ijọba naa ni wọn duro ni ipo rẹ. A ko fi aaye gba Luther lati fi ara han ni Augsburg, ṣugbọn o wa nibẹ pẹlu ọrọ ati adura rẹ. O kọwe wipe, “Inu mi dun pupọpupọ nitori pe mo wa laaye titi di akoko yii, nigba ti awọn olujẹwọ olokiki wọnyi gbe Kristi ga nigbangba, ninu iru apero ologo yii.” Bayi ni Iwe Mimọ ṣe wa si imuṣẹ wipe: “Ẹmi yoo sọ nipa awọn ijẹri Rẹ . . . niwaju awọn ọba.” O. Dafidi 119:46.ANN 90.5

    Ni igba aye Pọlu a mu iyinrere ti a titori rẹ fi sinu tubu wa siwaju awọn ijoye ati ẹni giga ilu alagbara naa. Nitori naa ni akoko yii, ohun ti ọba ti sọ wipe a ko gbọdọ waasu rẹ lori pẹpẹ, a wa n kede rẹ ni aafin ọba; ohun ti ọpọlọpọ ro wipe ko yẹ ki awọn iranṣẹ o tẹti si, ohun ni awọn adari ati oluwa ijọba n tẹti si tiyanutiyanu. Awọn ọba ati awọn eniyan nla ni wọn n gbọ, awọn ijoye alade ni wọn n waasu rẹ, otitọ pataki Ọlọrun si ni iwaasu naa. Onkọwe kan sọ wipe, “Lati akoko awọn apostoli wa, koi tii si iṣẹ ti o tobi ju eyi lọ tabi ijẹwọ ti niyin ju.”ANN 90.6

    Biṣọbu ijọ padi kan sọ wipe, “Ohun gbogbo ti awọn atẹle Luther sọ ni o jẹ ootọ; a ko le sẹ. Omiran beere lọwọ Dr Eck wipe, “Njẹ a le fi imọ ti o ye kooro tako ijẹwọ ti afọbajẹ ati awọn alatilẹyin rẹ ṣe yii bi?” “Pẹlu akọsilẹ awọn apostoli ati awọn woli— rara!” ni o fi dahun; “ṣugbọn pẹlu akọsilẹ awọn Baba ijọ ati ti igbimọ—bẹẹni!” Ẹni ti n beere ibeere wa dahun wipe, “O yemi. Awọn atẹle Luther, gẹgẹ bi o ti sọ wa ninu Iwe Mimọ, nigba ti awa wa ni ita rẹ.”ANN 91.1

    A jeere diẹ lara awọn ijoye Germany sinu igbagbọ ti a fọmọ. Ọba funra rẹ sọ wipe ootọ ni ohun ti awọn Protestant n sọ. A ṣe itumọ Ijẹwọ yii si oriṣiriṣi ede a si pin kaakiri gbogbo Europe, ọpọlọpọ awọn eniyan ni wọn si n gba a ni awọn akoko ti o tẹle gẹgẹ bi ohun ti wọn gbagbọ.ANN 91.2

    Awọn ojiṣẹ Ọlọrun tootọ ko danikan ṣiṣẹ. Nigba ti awọn ijoye ati agbara ati ẹmi buburu ni ibi giga n parapọ lati tako wọn, Oluwa ko fi awọn eniyan Rẹ silẹ. Bi o ba ṣe wipe a ṣi wọn ni oju ni, wọn i ba ri ami iduroti ati iranlọwọ Ọlọrun bi a ti fifun awọn woli ni igba atijọ. Nigba ti iranṣẹ Eliṣa fi awọn ẹgbẹgun ti o yi wọn ka, ti ko si fun wọn ni aaye lati salọ, han Eliṣa, woli naa gbadura: “Oluwa, mo bẹ Ọ, ṣi oju rẹ, ki o le riran.” 2 Awọn Ọba 6:17. Si kiyesii, ori oke naa kun fun kẹkẹ ati ẹṣin ina, ẹgbẹgun ọrun ti a kó sibẹ lati daabo bo eniyan Ọlọrun. Bẹẹ gẹgẹ ni awọn angẹli ṣe daabo bo awọn oṣiṣẹ ninu iṣẹ Atunṣe.ANN 91.3

    Ọkan lara awọn ikọni ti Luther di mu ṣinṣin ni pe a ko gbọdọ lo agbara ijọba lati ran iṣẹ Atunṣe lọwọ, a ko si ni lo ohun ija lati gbeja rẹ. Inu rẹ dun wipe awọn ijoye inu ijọba naa jẹwọ iyinrere; ṣugbọn nigba ti wọn sọ wipe wọn fẹ darapọ lati daabo bo o, o sọ wipe “Ọlọrun nikan ṣoṣo ni o yẹ ki o daabo bo ẹkọ iyinrere. . . . Bi ipa ti eniyan ba ko ninu rẹ ba ti kere to, bẹẹ ni iṣẹ Ọlọrun nitori rẹ yoo ti pọ to. O ri gbogbo aba iṣọraṣe oṣelu ti wọn n ṣe gẹgẹ bi ibẹru ti ko yẹ ati ainigbẹkẹle ti o ni ẹṣẹ ninu.”ANN 91.4

    Nigba ti awọn ọta alagbara parapọ lati doju igbagbọ ti a fọmọ bolẹ, ti o dabi ẹnipe a ti fẹ yọ ọpọlọpọ idà ti i, Luther kọwe wipe: “Satani n fi ibinu rẹ han; awọn alufa alaiwabiọlọrun n ditẹ; ogun si dó tì wa. Ẹ rọ awọn eniyan lati fi igboya jagun niwaju itẹ Ọlọrun, pẹlu igbagbọ ati adura, ki awọn ọta wa le fi agidi duro ni alaafia nigba ti Ẹmi Ọlọrun ba ṣẹgun wọn. Ohun ti a nilo julọ, iṣẹ wa ti o ga julọ ni adura; ẹ jẹ ki awọn eniyan o mọ wipe ida doju kọ wọn, ibinu Satani si n ru si wọn, ẹ si jẹ ki wọn gbadura.”ANN 91.5

    Nigba ti o n sọ nipa adehun ti awọn ijoye ti wọn gba igbagbọ ti a tunṣe fẹ ṣe ni ọjọsi, Luther sọ wipe ohun ija kan ṣoṣo ti o yẹ ki a lo ninu ija yii ni “ida Ẹmi.” O kọwe si afọbajẹ ti Saxony wipe: “A kole fi ọwọ si ibaṣepọ ti wọn gbero naa nitori ẹri ọkan wa. A yan lati ku ni igba mẹwa ju ki a ri ki a ta ẹjẹ kan silẹ nitori iyinrere wa lọ. Ipa tiwa ni lati dabi ọdọ aguntan ti a fẹ pa. A nilati gbe agbelebu Kristi. Maṣe jẹ ki ẹru o ba alayeluwa rẹ. Adura wa yoo ṣiṣẹ ju gbogbo ohun ti awọn ọta wa yoo ṣe pẹlu ifọnu wọn. Ẹ maṣe jẹ ki ẹjẹ awọn arakunrin yin o wa ni ọwọ yin. Bi ọba ba fẹ fi wa le igbimọ igbẹjọ rẹ lọwọ, a ṣetan lati fi ara han. O o le gbeja igbagbọ wa: olukuluku ni yoo gbagbọ pẹlu ewu ati wahala fun ara rẹ.”ANN 91.6

    Lati ibi ikọkọ adura ni agbara ti o mi aye ninu iṣẹ Atunṣe Nla ti jade wa. Nibẹ, pẹlu idakẹjẹ mimọ, awọn iranṣẹ Ọlọrun fi ẹsẹ wọn le ori apata awọn ileri Rẹ. Ni akoko wahala ni Augsburg, Luther “ko jẹ ki ọjọ kan o kọja laiṣe wipe o fi wakati mẹta, o kere tan, ninu awọn akoko ti wọn dun un kawe julọ gbadura.” Ninu yara rẹ, a gbọ ti o n tu ọkan rẹ jade niwaju Ọlọrun pẹlu awọn ọrọ “ti wọn kun fun iyin, ibẹru, ati ireti, bi igba ti eniyan ba n ba ọrẹ rẹ sọrọ.” O sọ wipe, “Mo mọ wipe Iwọ ni Baba ati Ọlọrun wa, Iwọ yoo si fọn awọn ti n ṣe inunibini si awọn ọmọ Rẹ ka; nitori ti ewu n wu Ọ pẹlu wa. Tirẹ ni gbogbo ọrọ naa, nipasẹ agbara Rẹ si ni a fi fi ọwọ wa si. Nitori naa, daabo bo wa o Baba!”ANN 91.7

    O kọwe si Melancthon ti ibẹru ati ipaya bo mọlẹ bayii pe: “Oore ọfẹ ati alaafia ninu Kristi—ninu Kristi ni mo sọ ki i ṣe ninu aye. Amin. Mo ni ikorira ti o pọ jọjọ si awọn aniyan ti wọn n bo ọ mọlẹ. Bi iṣẹ naa ki i ba n ṣe ti ododo fi silẹ; bi o ba n ṣe ti ododo, kilode ti ko yẹ ki a fi gbagbọ ninu awọn ileri Ẹni ti o paṣẹ fun wa lati sun lai bẹru? . . . A kò lè wá Kristi tì ninu iṣẹ otitọ ati ododo. O wa laaye. O n jọba; iru ibẹru wo ni o wa yẹ ki a ni?”ANN 91.8

    Ọlọrun gbọ igbe awọn iranṣẹ Rẹ. O fun awọn ijoye ati alufa ni igboya ati oore ọfẹ lati di otitọ mu ni atako si awọn alaṣẹ ibi okunkun aye yii. Oluwa sọ wipe: “Kiyesii, Mo gbe okuta igun ile kan lelẹ ni Sioni, eyi ti a yan ti o si ṣe iyebiye: ẹni ti o ba gbagbọ ninu Rẹ, oju ki yoo ti i.” I Peteru 2:6. Awọn Protestant Alatunṣe ti kọle le ori Kristi, ilẹkun ipo oku ko si le bori wọn.ANN 92.1

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents