Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents
ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORI KEJIDINLOGOJI—IKILỌ IKẸYIN

    “Mo ri angẹli miran n sọkalẹ wa lati ọrun, ti o ni agbara nla; ilẹ aye si mọlẹ nitori ogo rẹ. O si kigbe ni ohùn rara pẹlu ohun agbara wipe, Babiloni nla ṣubu, o ṣubu, o si ti di ibugbe awọn ẹmi eṣu, ati ile fun gbogbo ẹmi aimọ, ati ààgò fun gbogbo ẹyẹ alaimọ ati eye buburu.” “Mo si gbọ ohun miran lati ọrun n wipe, Ẹ jade kuro ninu rẹ ẹyin eniyan Mi, ki ẹ ma baa ṣe alabapin ẹṣẹ rẹ, ki ẹ ma baa ṣiṣe gba arun rẹ.” Ifihan 18:1, 2, 4.ANN 268.1

    Iwe Mimọ tọka si akoko ti a o ṣe atunsọ ipolongo iṣubu Babiloni bi angẹli keji inu Ifihan 14 (ẹsẹ 8) ti sọ ọ, pẹlu sisọ, ni afikun, awọn iwa ibajẹ ti wọn ti n wọ inu oriṣiriṣi awọn ẹgbẹ ti wọn ko ara wọn jọ pọ di Babiloni, lati akoko ti a ti funni ni iṣẹ iranṣẹ akọkọ, ni igba ẹrun 1844. Ipo ẹsin inu aye ti o banilẹru ni a ṣe alaye rẹ nibi. Ni gbogbo igba ti wọn ba kọ otitọ sile, iyè awọn eniyan a maa ṣokunkun si ni, ọkan wọn a tubọ ni agidi si, titi ti wọn a fi fi ẹsẹ mulẹ ninu orikunkun alaigbagbọ. Ni kikọ ikilọ ti Ọlọrun fifunni silẹ, wọn a tẹsiwaju lati maa tẹ ọkan ninu awọn Ofin Mẹwa loju, titi ti wọn a fi ṣe inunibini si awọn ti wọn ri wipe o jẹ mimọ. A ṣaata Kristi ninu ẹgan ti a ṣe si ọrọ ati awọn eniyan Rẹ. Bi awọn ijọ ti n gba ikọni ibẹmilo, a o mu ikora-ẹni-nijanu ti a fi si ori ọkan ti ko yipada kuro, ijẹwọ ẹsin yoo wa di aṣọ lati bo ẹṣẹ ti o buru julọ mọlẹ. Igbagbọ ninu ifarahan ẹmi ṣilẹkun silẹ fun ẹmi atannijẹ ati ikọni ẹmi eṣu, nipa eyi a o ri agbara awọn angẹli buburu ninu awọn ijọ.ANN 268.2

    A sọ nipa Babiloni ni akoko ti a ṣe afihan rẹ ninu asọtẹlẹ yii pe: “Ẹṣẹ rẹ ti ga de ọrun, Ọlọrun si ti ranti awọn aiṣedeede rẹ.” Ifihan 18:5. O ti kun ago ẹbi rẹ, iparun si ti fẹ bọ sori rẹ. Ṣugbọn Ọlọrun si ni awọn eniyan Rẹ ni Babiloni, ki O to ṣe ibẹwo idajọ Rẹ, a nilati pe awọn olootọ wọnyi sita, ki wọn ma baa ṣe alabapin ẹṣẹ rẹ, ki wọn “ma baa si gba ijiya rẹ.” Nitori naa ni a fi ni ẹgbẹ ti a fi angẹli ti o sọkalẹ lati ọrun wa ṣe akajuwe, eyi ti ilẹ aye mọlẹ pẹlu ogo rẹ, ti o n fi ohun rara kigbe nla, ti o n kede awọn ẹṣẹ Babiloni. Ni ifarakora pẹlu iṣẹ iranṣẹ rẹ, a gbọ wipe: “Jade kuro ninu rẹ, ẹyin eniyan Mi.” Awọn ikede wọnyi, ní iṣọkan pẹlu iṣẹ iranṣẹ angẹli kẹta, parapọ di ikilọ ti o kẹyin ti a o fun awọn olugbe aye.ANN 268.3

    Aye yoo wọ inu iṣẹlẹ ti o lẹru. Awọn agbara aye, ni iṣọkan lati ba aṣẹ Ọlọrun jagun yoo paṣẹ ki “gbogbo eniyan, ati kekere ati nla, ọlọrọ ati otoṣi, ominira ati onde” (Ifihan 13:16), o tẹle aṣa ijọ nipa pipa ọjọ isinmi eke mọ. A o jẹ gbogbo awọn ti wọn kọ lati ṣe igbọran niya, nikẹyin a o sọ wipe iku ni o tọ si wọn. Ni idakeji, ofin Ọlọrun ti o paṣẹ ọjọ Isinmi Ẹlẹda funni n beere fun igbọran o si n ṣe ikilọ ibinu Rẹ si gbogbo ẹni ti o ba ru awọn ilana rẹ.ANN 268.4

    Pẹlu alaye yekeyeke niwaju eniyan, ẹnikẹni ti yoo ba tẹ ofin Ọlọrun loju lati ṣe igbọran si aṣẹ eniyan a gba ami ẹranko naa; ó gba ami igbọran si agbara ti ó yan lati ṣe igbọran si ju Ọlọrun lọ. Ikilọ lati ọrun ni wipe: “Bi ẹnikẹni ba jọsin ẹranko naa ati aworan rẹ, ti o gba ami rẹ siwaju ori rẹ tabi ni ọwọ ọtun rẹ, oun pẹlu yoo mu ninu waini ibinu Ọlọrun ti a tu jade ni aini abula sinu aago ibinu Rẹ.” Ifihan 14:9, 10.ANN 268.5

    Ṣugbọn ko si ẹni ti yoo jiya ibinu Ọlọrun titi ti a o fi tẹ otitọ naa mọ wọn niye ati lọkan, ti wọn yoo si kọ ọ silẹ. Ọpọ wa ti wọn koi ti i ni anfani lati gbọ otitọ pataki fun akoko yii ri. A koi ti i ṣe alaye ojuṣe wọn si ofin kẹrin fun wọn ni bi o ti jẹ gan an. Ẹni ti n wo gbogbo ọkan ti O si n dan gbogbo ero ọkan wo ko ni fi ẹnikẹni ti o ba fẹ lati ni imọ otitọ silẹ, ki a wa tan an jẹ lori ọrọ ijakadi naa. A ko ni pa aṣẹ naa fun awọn eniyan laimọ. Gbogbo eniyan ni yoo ni imọlẹ ti o to lati le fi oye ṣe ipinu rẹ.ANN 268.6

    Ọjọ Isinmi ni yoo jẹ ohun idanwo nla fun igbọran, nitori ohun ni koko otitọ ti a n jiyan le lori. Nigba ti idanwo ikẹyin yii ba wa si ori eniyan, nigba naa ni a o fa ila idanimọ si aarin awọn ti n sin Ọlọrun ati awọn ti ko sin In. Nigba ti pipa ọjọ isinmi eke mọ yoo wa ni ibamu pẹlu ofin ilu, ni atako si ofin kẹrin yoo jẹ ṣiṣe igbọran si agbara ti o ṣodi si Ọlọrun, pipa ọjọ Isinmi tooto mọ, ni igbọran si ofin Ọlọrun jẹ ẹri igbọran si Ẹlẹda. Nigba ti ẹgbẹ kan, nipa gbigba ami itẹriba fun agbara aye, gba ami ẹranko naa, ikeji nipa yiyan ami igbọran si aṣẹ Ọlọrun gba edidi Ọlọrun.ANN 268.7

    Titi di akoko yii, a saba maa n ri awọn ti n waasu otitọ iṣẹ iranṣẹ angẹli kẹta gẹgẹ bi awọn ti n ru ibẹru soke lasan. Asọtẹlẹ wọn wipe ainifarada ẹsin yoo gba akoso ni United States, wipe ijọ ati ilu yoo parapọ lati ṣe inunibini si awọn ti wọn pa ofin Ọlọrun mọ ni a ri gẹgẹ bi eyi ti ko bojumu ti ko si lẹsẹ nilẹ. A ti fi igboya sọ wipe ilẹ yii ko le yatọ si ohun ti o ti n jẹ—oludaabo bo ominira ẹsin. Ṣugbọn bi nipa fifi aṣẹ muni pa ọjọ Sọnde mọ ti n ru soke kaakiri, iṣẹlẹ ti a ṣe iyemeji nipa rẹ fun igba pipẹ ti a ko si gbagbọ ni a n ri ti o n bọ wa, ti iṣẹ iranṣẹ angẹli kẹta yoo si ni ipa ti ko le ni tẹlẹ.ANN 269.1

    Ni akoko gbogbo Ọlọrun n ran awọn iranṣẹ Rẹ lati ba ẹṣẹ wi ninu aye ati ninu ijọ. Ṣugbọn awọn eniyan fẹran ki a sọrọ didun fun wọn, ko si si aye fun otitọ ailabawọn ti a ko pọn. Ọpọ awọn alatunṣe, ni ibẹrẹ iṣẹ wọn pinu lati rọra ṣe ni biba ẹṣẹ ijọ ati ti orilẹ ede wi. Wọn n reti lati dari awọn eniyan pada si ikọni Bibeli pẹlu apẹẹrẹ igbe aye mimọ Kristẹni. Ṣugbọn Ẹmi Ọlọrun ba le wọn gẹgẹ bi O ti wá sori Elija, ti O mi si lati ba ẹṣẹ ọba buburu ati ti Isreali apẹyinda wi; wọn ko le ṣiwọ wiwaasu ọrọ ailabawọn ti Bibeli—ikọni ti wọn kọkọ lọra lati waasu. A mu wọn fi itara ṣe ikede otitọ ati ewu ti n wu awọn ọkan. Ọrọ ti Ọlọrun fun wọn ni wọn n sọ laibẹru ohun ti yoo ti ẹyin rẹ wa, a si fi ipa mu awọn eniyan lati gbọ ikilọ.ANN 269.2

    Bayi ni a o ṣe waasu iṣẹ iransẹ angẹli kẹta. Nigba ti akoko ba to lati fifunni pẹlu agbara nla Oluwa a ṣiṣẹ nipasẹ awọn iranṣẹ onirẹlẹ Rẹ, yoo dari oye awọn ti wọn fi ara wọn jin fun iṣẹ Rẹ. Oṣiṣẹ naa a kun oju oṣuwọn, ki i ṣe pẹlu ẹkọ lati ile ẹkọ giga bikoṣe pẹlu agbara Ẹmi Rẹ. A o rọ awọn eniyan ti wọn kun fun igbagbọ ati adura lati jade lọ pẹlu itara mimọ lati kede ọrọ ti Ọlọrun fifun wọn. A o ṣi ẹṣẹ Babiloni sita kedere. Abayọri ẹlẹru ti fifi aṣẹ ijọba muni pa ilana ijọ mọ, aṣa ibẹmilo ti n wọle bi agbara ijọ padi ti n dagba kiakia ni bonkẹlẹ—gbogbo rẹ ni a o ṣi aṣọ loju wọn. Nipasẹ awọn iṣẹ iranṣẹ ẹlẹru wọnyi awọn eniyan a taji. Ọpọlọpọ awọn eniyan ti koi ti i gbọ iru awọn ọrọ bawọnyi ri ni yoo gbọ. Pẹlu iyanu wọn a gbọ wipe ijọ ni Babiloni naa ti o ṣubu nitori aṣiṣe ati ẹṣẹ rẹ nitori bi o ti ṣe kọ otitọ ti a ran si lati ọrun wa silẹ. Bi awọn eniyan ba ti n lọ si ọdọ awọn olukọ wọn tẹlẹ pẹlu ibeere onitara pe, Ṣe awọn nnkan wọnyi ri bẹẹ? awọn oniwaasu a gbe itan arosọ kalẹ, wọn a sọ asọtẹlẹ ọrọ didun, lati le mu ibẹru wọn kuro ati lati pa ẹri ọkan wọn ti o ji lẹnu mọ. Ṣugbọn nigba ti ọpọlọpọ kọ lati jẹ ki aṣẹ eniyan lasan o tẹ wọn lọrun wọn si beere fun “Bayi ni Oluwa wi,” awọn iṣẹ iranṣẹ ti o lokiki, bi i ti awọn Farisi aye igbaani, ti wọn kun fun ibinu nitori ti a ko gba aṣẹ wọn laibeere ibeere, yoo si sọ wipe iṣẹ iranṣẹ Satani ni wọn a si ru awọn eniyan ti wọn fẹran ẹṣẹ soke lati kẹgan ati lati ṣe inunibini si awọn ti n waasu rẹ.ANN 269.3

    Bi ariyanjiyan naa ti n wọ awọn ilẹ miran ti a si n dari iye awọn eniyan si ofin Ọlọrun ti a n ru, Satani a ta giri. Agbara ti n tẹle iṣẹ iranṣẹ naa a tubọ mu ki inu o bi awọn ti n tako o si ni. Awọn alufa a lo agbara ti o fẹrẹ kọja ti eniyan lati ti ilẹkun mọ imọlẹ naa ki o ma baa tan si ori agbo wọn. Pẹlu ohun gbogbo ti o wa ni ikawọ wọn, wọn a ṣe akitiyan lati tẹ ijiroro lori awọn koko ọrọ pataki wọnyi ri. Ijọ a pe ọwọ agbara nla ijọba ninu iṣẹ yii, awọn atẹle popu ati awọn Protestant a wa ni iṣọkan. Bi ẹgbẹ ti n ṣiṣẹ lati fi ipa muni pa ọjọ Sọnde mọ ti n lo agidi ti wọn si n nigboya si, a yoo ṣe ofin lati tako awọn ti n pa ofin mọ. A o fi sisan owo itanran ati itimọle dẹruba wọn, a o fi ipo agbara lọ awọn miran, a o si fi ẹbun ati anfani lọ awọn miran gẹgẹ bi ituloju lati kọ igbagbọ wọn silẹ. Ṣugbọn idahun iduroṣinṣin wọn ni pe: “Ẹ fi aṣiṣe wa han wa lati inu ọrọ Ọlọrun”—iru ibeere kan naa ti Luther beere labẹ iru iṣẹlẹ kan naa.ANN 269.4

    Awọn ti a pe lẹjọ si ile ẹjọ a sọrọ alagbara lati jẹri si otitọ, ti awọn ti o gbọ a si pinu lati pa gbogbo ofin Ọlọrun mọ. Bayi ni a o ṣe tan imọlẹ naa si ọpọlọpọ ti i bama mọ ohun kan nipa awọn otitọ wọnyi.ANN 269.5

    A o ṣesi ṣiṣe igbọran tọkantọkan si ọrọ Ọlọrun bi iṣọtẹ. Awọn ti Satani ti fọ loju, obi a wuwa lile ati iwa onroro si ọmọ rẹ ti o jẹ onigbagbọ, ọga lọkunrin ati lobinrin a fiyajẹ ọmọ ọdọ wọn ti n pa ofin mọ. A o dawọ ifẹ duro, a o kọ awọn ọmọ silẹ a o si le wọn kuro nile. Ọrọ Pọlu a wa si imuṣẹ ni bi o ti ṣe kọ ọ: “Gbogbo awọn ti yoo gbe igbesi aye iwabiọlọrun ninu Kristi Jesu yoo jiya inunibini. 2 Timoti 3:12. Bi awọn olugbeja otitọ ti kọ lati bọwọ fun isinmi ọjọ Sọnde, a o ju diẹ lara wọn sinu ọgba ẹwọn, a o le awọn miran kuro ni ilu, a o ṣe awọn miran bi ẹru. Ọgbọn eniyan nisinsinyii ri gbogbo iwọnyi gẹgẹ bi ohun ti ko le ṣẹlẹ, ṣugbọn bi a ba ti n mu ikoninijanu Ẹmi Ọlọrun kuro ni ọdọ awọn eniyan, ti wọn a si wa labẹ iṣakoso Satani, ẹni ti o korira ofin Ọlọrun, awọn iṣẹlẹ ti ko yeni a bẹrẹ. Ọkan le kun fun iwa ika nigba ti a ba mu ifẹ ati ibẹru Ọlọrun kuro.ANN 269.6

    Bi iji naa ti n bọ, ẹgbẹ nla kan ti wọn jẹwọ igbagbọ ninu iṣẹ iranṣẹ angẹli kẹta, ṣugbọn ti ko ni iyasimimọ nipasẹ igbọran si otitọ, a fi ipo wọn silẹ, wọn a si darapọ mọ awọn ẹgbẹ alatako. Nipa didarapọ mọ aye ati kikopa ninu ẹmi rẹ, wọn n woye ọrọ ninu imọlẹ kan naa, nigba ti idanwo ba si de, wọn ṣetan lati ya si ibi ti o rọrun ti o tun lokiki. Awọn eniyan ti wọn ni ẹbun ti wọn n sọrọ didun, ti wọn fi igba kan ri yọ ninu otitọ, lo agbara wọn lati tan awọn ọkan jẹ ati lati ṣi wọn lọna. Wọn di ọta kikoro si awọn arakunrin wọn tẹlẹ ri. Nigba ti a ba mu awọn ti n pa ọjọ Isinmi mọ wa si ile ẹjọ lati dahun fun igbagbọ wọn, awọn apẹyinda wọnyi a jẹ aṣoju Satani to wulo julọ lati fi wọn han ni ọna ti ko tọ ati lati fẹsun kan wọn, pẹlu iroyin eke ati ẹtan wọn a ru ọkan awọn alaṣe soke lati tako wọn.ANN 270.1

    Ni akoko inunibini yii a o dan igbagbọ awọn iranṣẹ Oluwa wo. Wọn ti ṣe ikilọ funni pẹlu otitọ, ni wiwo Ọlọrun ati ọrọ Rẹ nikan ṣoṣo. Ẹmi Ọlọrun mi si wọn lọkan, o si fun wọn lokun lati sọrọ. Pẹlu itara mimọ ati imisi Ọlọrun ti o lagbara lori wọn, wọn bẹrẹ iṣẹ wọn laiṣeṣiro ohun ti yoo jẹ atubọtan sisọrọ ti Ọlọrun fifun wọn lati fun awọn eniyan. Wọn ko wo ere aye, bẹẹ ni wọn ko wa lati da orukọ tabi ẹmi wọn si. Sibẹ nigba ti iji atako ati ẹgan ba rọ lu wọn, diẹ ti wọn kun fun ibẹru a ṣetan lati sọ wipe: “Bi o ba jẹ wipe a mọ ibi ti ọrọ wa yoo yọri si ni, a kii bati sọrọ.” Wahala yi wọn ka. Satani si n fi idanwo nla kọlu wọn. O dabi ẹnipe iṣẹ ti wọn bẹrẹ pọ ju agbara wọn lọ. Iparun dẹru ba wọn. Imoriya to n fun wọn lokun ko si mọ, sibẹ wọn ko le pẹyinda. Nigba ti wọn ba mọ ipo ainiranlọwọ wọn, wọn a salọ si ọdọ Ẹni Alagbara fun okun. Wọn ranti pe ọrọ ti wọn sọ ki i ṣe ti wọn bikoṣe ti Ẹni ti o sọ fun wọn lati ṣe ikilọ. Ọlọrun fi otitọ sinu ọkan wọn, wọn ko sile ṣe lati ma kede rẹ.ANN 270.2

    Iru iriri kan naa ni awọn eniyan Ọlọrun ni latẹyinwa. Wycliffe, Huss, Luther, Tyndale, Baxter, Wesley kọni wipe a nilati fi Bibeli dan gbogbo ikọni wo, wọn si sọ wipe ki a kọ gbogbo ohun ti o ba da lẹbi silẹ. Inunibini dide si awọn eniyan wọnyi pẹlu ibinu ti ko duro, sibẹ wọn ko ṣiwọ lati kede otitọ. Oriṣiriṣi akoko ninu itan ijọ ni wọn ni otitọ pataki ti o wa fun iwulo awọn eniyan Ọlọrun ni akoko naa. Gbogbo otitọ tuntun ni wọn duro tako ikorira ati atako, awọn ti a fi imọlẹ bukun fun ri idanwo ati idamu. Oluwa fun awọn eniyan ni otitọ pataki ni akoko pajawiri. Tani o jẹ kọ lati kede rẹ? O paṣẹ fun awọn iranṣẹ Rẹ lati kede ipe aanu ti o kẹyin fun araye. Wọn ko le dakẹ, laiṣe wipe wọn fẹ iparun ọkan wọn. Awọn aṣoju Kristi ko ni ohun kankan ṣe pẹlu ayọrisi. Wọn nilati ṣiṣẹ wọn ki wọn si fi ayọrisi rẹ silẹ pẹlu Ọlọrun.ANN 270.3

    Bi atako ti n gbona si, iporuuru ọkan tun de ba awọn iranṣẹ Ọlọrun, nitori wọn ri bi ẹnipe awọn ni wọn mu wahala wa. Ṣugbọn ẹri ọkan ati ọrọ Ọlọrun fi da wọn loju wipe wọn n ṣe ohun ti o tọ, bi o tilẹ jẹ wipe idanwo naa tẹsiwaju, a fun wọn ni okun lati farada a. Wahala naa n sunmọ wọn si, o si n lagbara si, ṣugbọn igbagbọ ati igboya wọn a dọgba pẹlu akoko pajawiri naa. Ẹri wọn ni: “A ko gbọdọ tọwọ bọ ọrọ Ọlọrun ni ọna ti ko yẹ, ni pinpin ofin Rẹ si meji, ni pipe abala kan ni eyi ti o ṣe pataki ati abala keji wipe ko ṣe pataki, lati le ri oju rere aye. Oluwa wa ti awa n sin le gba wa. Kristi ti ṣẹgun agbara aye ṣe o wa yẹ ki a bẹru aye ti a ti ṣẹgun naa bi?”ANN 270.4

    Inunibini ní oriṣiriṣi ọna jẹ idagbasoke ti yoo wa niwọn igba ti Satani ba si wa, ti ẹsin Kristẹni ba si ni agbara ti o wa laaye. Ko si ẹni ti o le sin Ọlọrun laipe atako ẹgbẹ ogun okunkun si ara rẹ. Awọn angẹli buburu yoo doju kọ ọ pẹlu ibẹru wipe ipa rẹ n mu awọn ti wọn mu ni igbekun kuro lọwọ wọn. Awọn ẹni ibi ti apẹẹrẹ rẹ jẹ ibawi fun a darapọ mọ wọn lati pin niya pẹlu Ọlọrun nipasẹ idanwo to n fanimọra. Nigba ti awọn wọnyi ko ba ṣe aṣeyọri a a wa lo agbara ipa lati dari ẹri ọkan.ANN 270.5

    Ṣugbọn niwọn igba ti Jesu ba ṣi jẹ alagbawi eniyan ninu ibi mimọ loke, awọn alaṣẹ ati eniyan a ṣi ni imọlara agbara ikoninijanu Ẹmi Mimọ. O ṣi n ṣe akoso ofin ilẹ naa diẹdiẹ. Bi ki i ba n ṣe nitori awọn ofin wọnyi ni, ipo aye i ba buru ju bi o ti wa nisinsinyii lọ. Nigba ti ọpọ awọn alaṣẹ wa jẹ aṣoju ti n ṣe akikanju fun Satani, Ọlọrun pẹlu ni awọn aṣoju Rẹ laarin awọn adari orilẹ ede. Ọta n mi si awọn iranṣẹ rẹ lati ṣe ofin ti yoo di iṣẹ Ọlọrun lọwọ jọjọ, ṣugbọn awọn angẹli mimọ a mi si awọn adari ilu ti wọn bẹru Oluwa lati tako iru ofin bẹẹ pẹlu ọrọ ti wọn ko ni le fesi si. Awọn eniyan perete ni yoo da ìṣàn iwa buburu nla duro. A o da atako awọn ọta otitọ duro ki iṣẹ iranṣẹ angẹli kẹta baa le ṣe iṣẹ rẹ. Nigba ti a ba ṣe ikilọ ti o kẹyin funni, awọn adari ti Oluwa n tipasẹ wọn ṣiṣẹ bayi a fiye si, diẹ lara wọn a si gba a, wọn a si duro pẹlu awọn eniyan Ọlọrun ni akoko idamu.ANN 271.1

    Angẹli ti o darapọ mọ ikede iṣẹ iranṣẹ angẹli kẹta yoo tan imọlẹ si gbogbo aye pẹlu ogo rẹ. Iṣẹ ti yoo tan kaakiri gbogbo aye ati agbara ti a ko riri ni a n sọtẹlẹ nibi. Ẹgbẹ onireti ti 1840—44 jẹ ifarahan agbara Ọlọrun lọna ti o logo, a gbe iṣẹ iranṣẹ angẹli akọkọ de gbogbo ibudo ajiyinrere ninu aye, ati ni awọn orilẹ ede miran, a ri ifẹ si ọrọ ẹsin ti a ri keyin lati igba iṣẹ Atunṣe ni ọrundun kẹrindinlogun; ṣugbọn ẹgbẹ alagbara yii a ju awọn wọnyi lọ labẹ ikilọ ti o kẹyin ti angẹli kẹta.ANN 271.2

    Iṣẹ naa yoo fi ara jọ ti ọjọ Pẹntikọsti. Bi a ti funni ni “ojo akọrọ,” ni titu Ẹmi Mimọ sita ni ibẹrẹ iyinrere lati le jẹ ki eso ti o ṣeyebiye o wu, bẹẹ gẹgẹ ni a o funni ni “ojo arọkuro” ni opin rẹ lati le mu ki ikore o pọn. “Nigba naa ni a o mọ, bi a ba tẹsiwaju lati mọ Oluwa: a ti pèsè ijade lọ Rẹ bi aarọ; yoo si wa si ọdọ wa bi ojo, bi ojo arọkuro ati ojo akọrọ sori ilẹ aye.” Hosea 6:3. “Nitori naa ẹ yọ, ẹyin ọmọ Sioni, ki ẹ si ni inu didun ninu Oluwa yin: nitori ti O ti fun yin ni ojo akọrọ ni bi o ti yẹ, yoo si jẹ ki ojo o rọ sori yin, ojo akọrọ ati ojo arọkuro.” Joẹli 2:23. “Ni ọjọ ikẹyin ni Ọlọrun wi, Emi yoo tu Ẹmi Mi si ori gbogbo ẹran ara.” “Yoo si ṣe, ẹnikẹni ti o ba kepe orukọ Oluwa ni a o gbala.” Iṣe 2:17, 21.ANN 271.3

    Iṣẹ nla iyinrere ki yoo pari laisi ifarahan agbara Ọlọrun bi eyi ti o farahan ni ibẹrẹ rẹ. Awọn asọtẹlẹ ti wọn wa si imuṣẹ ninu itujade ojo akọrọ ni ibẹrẹ iyinrere yoo wa si imuṣẹ lẹẹkansi ninu ojo arọkuro ni igba opin rẹ. Akoko yii ni “akoko itura” eyi ti apostoli Peteru wo ọjọ iwaju fun nigba ti o sọ wipe: “Ẹ ronupiwada nitori naa, ki ẹ si yipada, ki a le mu ẹṣẹ yin kuro, nigba ti akoko itura yoo de lati iwaju Oluwa; yoo si ran Jesu wa.” Iṣe 3:19, 20.ANN 271.4

    Awọn iranṣẹ Ọlọrun, pẹlu oju wọn ti o mọlẹ ti o si n tan pẹlu iyasọtọ mimọ yoo yara kankan lati ibikan lọ si ekeji lati kede iṣẹ iranṣẹ lati ọrun. Pẹlu ọpọlọpọ ohùn kaakiri ilẹ aye, a o funni ni ikilọ naa. A o ṣe iṣẹ iyanu, a o mu awọn alaisan larada, iṣẹ ami ati iṣẹ iyanu yoo tẹle awọn onigbagbọ. Satani pẹlu a ṣiṣẹ pẹlu iṣẹ iyanu eke, ani yoo mu ina sọkalẹ lati ọrun wa niwaju eniyan. Ifihan 13:13. Nipa eyi, a o mu ki awọn olugbe aye o ṣe ipinu wọn.ANN 271.5

    A yoo jiyin iṣẹ iranṣẹ naa, ki i ṣe pẹlu ọrọ eniyan bikoṣe pẹlu igbagbọ jijinlẹ ti Ẹmi Ọlọrun. A ti ṣe alaye ọrọ naa. A ti funrungbin eso naa, bayii yoo wu, yoo si so eso. Iwe atẹjade ti awọn ajiyinrere pin kaakiri ni ipa ti wọn, sibẹ ọpọlọpọ ti a fọwọba lọkan ni a ko gba laaye lati ni oye otitọ naa ni kikun tabi lati ṣe igbọran si. Nisinsinyii, itansan imọlẹ n tan si ibi gbogbo, a si n ri otitọ bi o ti n fi ara han ketekete, awọn ọmọ Ọlọrun ti wọn jẹ olootọ ọkan si n ja ide ti o de wọn. Ibaṣepọ ti idile, ibaṣepọ ti ijọ ko lagbara lati da wọn duro mọ. Otitọ ṣeyebiye ju ohun gbogbo lọ. Laika awọn agbara ti wọn parapọ tako otitọ si, ọpọlọpọ ni wọn duro si ọdọ Ọlọrun.ANN 271.6

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents