Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents
ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORI KEJE—ÌYAPA LUTHER KÚRÒ NI ROMU

    Martin Luther ṣe pataki julọ laarin awọn ti a pe lati dari ijọ kuro ninu okunkun ẹsin popu wa si inu imọlẹ igbagbọ mimọ. Onitara, ti o ni ifẹ ọkan, ati olufọkansin, ti ko mọ ibẹru kankan ayafi ibẹru Ọlọrun, ti ko si mọ ipilẹ kankan fun igbagbọ ẹsin ayafi Iwe Mimọ, Luther ni ẹni ti o yẹ fun akoko rẹ; Ọlọrun ṣe iṣẹ nla fun atunṣe ijọ ati ilalọyẹ araye nipasẹ rẹ.ANN 52.1

    Bii awọn ti wọn kọkọ kede iyinrere, Luther jẹ talaka eniyan. Ile agbẹ aroko ara Germany kan ni o ti lo ibẹrẹ igbesi aye rẹ. Nipa iṣẹ ojumọ gẹgẹ bi awakuṣa ni baba rẹ fi ri owo ẹkọ rẹ san. O fẹ ki o di agbẹjọro; ṣugbọn Ọlọrun fẹ lati fi ṣe onkọle ninu tẹmpili nla ti o rọra n ga soke lati ọdun pupọ sẹyin wa. Wahala, aini ati ikora-ẹni-nijanu ni ọna ti o lagbara ni ile ẹkọ ti Ọlọrun pese silẹ fun Luther fun iṣẹ ti o ṣe pataki ninu igbesi aye rẹ.ANN 52.2

    Baba Luther jẹ ọlọpọlọ pipe ti iyè rẹ ja fafa, o ni okun iwa, ki i yẹ kuro ninu ipinu rẹ, o jẹ olootọ, onipinu, ati oninukan. O jẹ olootọ si ohun ti o ba gbà wipe o jẹ ojuṣe rẹ laika ohun ti yoo ba ti ẹyin rẹ wa si. Iṣọwọ ronu rẹ ti o peye mu ki o fi oju ti ko tọ wo ilana ìdéra ẹni mọ inu ile ẹsin. Inu rẹ bajẹ pupọpupọ nigba ti Luther wọ inu ile ẹsin laiṣe wipe o fi ọwọ si; lẹyin ọdun meji ni o to ba ọmọ rẹ laja, ṣugbọn eyi ko yi ero rẹ pada.ANN 52.3

    Awọn obi Luther mu ẹkọ ati itọsọna awọn ọmọ wọn ni ọkunkundun. Wọn ṣe akitiyan lati kọ wọn ni imọ Ọlọrun ati iwuwasi Kristẹni. Baba saba maa n gbadura ni etigbọ ọmọ rẹ, ki ọmọ naa le ranti orukọ Oluwa, ati ni ọjọ kan ki o le ṣe iranwọ ninu titan otitọ Rẹ kalẹ. Gbogbo anfani fun idagbasoke ti iwa wiwu, ati ti ọpọlọ wọn, ti igbesi aye wahala wọn gba wọn laaye lati ní ni awọn obi wọnyi lo daradara. Wọn fi tọkantọkan tẹramọ pipese awọn ọmọ wọn silẹ fun igbesi aye onifọkansin ati eyi ti o wulo. Ninu iduroṣinṣin ati okun ìwà wọn, wọn maa n rorò mọ awọn ọmọ wọn ni igba miran; ṣugbọn nigba ti Alatunṣe naa ri wipe wọn ṣe aṣiṣe ni awọn ọna miran, eyi ti o fi ọwọ si ninu itọni wọn pọ ju eyi ti ko fi ọwọ si lọ.ANN 52.4

    Ni ile ẹkọ ti a ran lọ nigba ti o wa ni ọmọde, a fi iya jẹ, a tun wu iwa ipa si nigba miran. Aini awọn obi rẹ pọ debi pe nigba ti o ba n lọ si ile ẹkọ rẹ ni ilu keji, fun igba diẹ, o maa n kọ orin lati ile de ile ki o to le ri ounjẹ rẹ; ọpọ igba si ni ebi maa n paa.ANN 52.5

    Awọn ero èké nipa ẹsin ti wọn n bani lọkanjẹ ni akoko rẹ maa n dẹru ba a. Yoo dubule ni aṣalẹ pẹlu ọkan ibanujẹ, yoo maa fi ipaya wo ọjọ iwaju, o maa n wa ni ibẹru nigba gbogbo pẹlu ero wipe Ọlọrun jẹ onroro, onidajọ ti o buru, ti kii sii dari ji ni, dipo ki o ri bi Baba ọrun alaanu.ANN 52.6

    Sibẹ pẹlu gbogbo awọn irẹwẹsi nla yii, Luther fi tọkantọkan tẹsiwaju ninu ìpele giga iwuwasi ati imọ ti o fa mọ ọkan rẹ. O poungbẹ fun imọ, iwa ifọkansin rẹ ati ifẹ rẹ lati kọ nipa ohun ti o ṣe e ṣe, mu ki o nifẹ ohun ti o nipọn ti o si wulo, dipo ohun ti o wa fun aṣehan ti ko si jinlẹ.ANN 52.7

    Nigba ti o pe ọmọ ọdun meji-din-logun, o wọ ile ẹkọ giga ti Erfurt, ipo ti o wa nibẹ dara, ọjọ iwaju rẹ si dara nibẹ ju ti ti atẹyinwa lọ. Nipasẹ ìkówójọ ati iṣẹ ṣiṣe, awọn obi rẹ ni agbara lati fun ni ohun gbogbo ti o nilo. Ipa awọn ọrẹ rẹ ti wọn jẹ ọlọgbọn mu ki ibanujẹ ọkan tí ẹkọ rẹ lati ibẹrẹ wa kó ba, o dinku. O kọ nipa awọn onkọwe ti wọn dara julọ, o n fi tọkantọkan ko awọn ero ijinlẹ wọn jọ, o si n fi ọgbọn awọn ọlọgbọn ṣe ti ara rẹ. Labẹ inira awọn olukọ rẹ akọkọ o fi ami titayọ han, pẹlu awọn ayika ti wọn ṣe iranwọ fun ọkan rẹ, iṣọwọronu rẹ dagbasoke ni kiakia. Ẹmi iranti, ironu ti o ja fafa, iṣọwọronu ti o lókun, ati afiyesi laisimi, awọn nnkan wọnyi gbe soke tente laarin awọn ẹlẹgbẹ rẹ. Ilana ẹkọ jẹ ki iye rẹ o muna si, o jẹ ki awọn ero kan o maa lọ ninu ọpọlọ rẹ, o si fun ni afiyesi ti o mu bi abẹ; wọn n pese rẹ silẹ fun awọn wahala aye rẹ.ANN 52.8

    Ibẹru Ọlọrun n gbe ninu ọkan Luther, eyi ran lọwọ lati ni iduroṣinṣin, o si jẹ ki o ni ẹmi irẹlẹ niwaju Ọlọrun. O ni imọlara igbẹkẹle rẹ ninu iranlọwọ Ọlọrun, ko si baku lati bẹrẹ ọjọ kọọkan pẹlu adura, ọkan rẹ si n bẹbẹ fun itọsọna ati iranlọwọ nigba gbogbo. O saba maa n sọ wipe, “Gbigbadura daradara ni aabọ eyi ti o dara julọ ninu ẹkọ.”ANN 53.1

    Ni ọjọ kan nigba ti o n yẹ awọn iwe wo ninu ile ikowe-pamọsi, Luther ri Bibeli ni ede Latin. Koi ti i ri iru iwe yii ri. Ko tilẹ mọ wipe iru rẹ wa. O gbọ nipa awọn abala Iyinrere ati Episteli ti a maa n ka si awọn eniyan nigba isin gbogboogbo, o si ro wipe eyi ni gbogbo Bibeli. Bayi, fun igba akọkọ, o boju wo ọrọ Ọlọrun. O si awọn awẹ mimọ rẹ wo pẹlu ibẹru ati iyalẹnu; pẹlu ọkan rẹ ti o n mi gulegule, o ka awọn ọrọ iye wo funra rẹ, o si n danu duro loorekoore lati sọ wipe: “Bi Ọlọrun ba le fun mi ni iru iwe yii fun ara mi!” Awọn angẹli ọrun wa lẹgbẹ rẹ, itansan imọlẹ lati ọrun si fi ohun iṣura otitọ han si iye rẹ. O maa n bẹru lati ṣe si Ọlọrun, ṣugbọn nisisinyii, idaniloju nipa ipo rẹ gẹgẹ bi ẹlẹṣẹ mu lọkan ju ti tẹlẹ lọ.ANN 53.2

    Ifẹ atọkanwa lati ni ominira kuro lọwọ ẹṣẹ ati lati ri alaafia pẹlu Ọlọrun dari rẹ nikẹyin lati gbe igbesi aye ajẹjẹ ẹsin, o si jọwọ ara rẹ fun iṣesi awọn ajẹjẹ ẹsin. Nibi o nilo lati ṣe awọn iṣẹ ti wọn yẹpẹrẹ ẹni, o n tọrọ bárà lati ile de ile. O wà ni asiko ti eniyan maa n wọna fun ibọwọfun ati imọyi-ẹni, nitori naa, awọn iṣẹ pẹpẹẹpẹ wọnyi ko ba a lara mu rara; ṣugbọn o fi suuru fi ara da irẹnisilẹ rẹ, pẹlu igbagbọ wipe wọn ṣe pataki nitori ẹṣẹ rẹ.ANN 53.3

    Gbogbo akoko ti o ba yọ silẹ ninu iṣẹ ojumọ rẹ ni o maa n lo lati kẹkọ, o maa n fi orun dun ara rẹ, o si n ṣe aroye nitori akoko ti o n lo lati jẹ ounjẹ perete rẹ. Ju ohun gbogbo lọ o fẹran lati maa kọ ẹkọ ọrọ Ọlọrun. O ti ri Bibeli kan ti a fi ẹwọn de mọ ogiri ile ẹsin, nibẹ si ni o saba maa n lọ. Bi idalẹbi ẹṣẹ rẹ ti n jinlẹ si, o wa ọna lati ri alaafia ati idariji nipasẹ iṣẹ ọwọ ara rẹ. O gbe igbesi aye ti o nini lara julọ, o n ro lati tẹri awọn iwa buburu rẹ ba pẹlu awẹ, iṣọ oru, ati ifiyajẹ ara ẹni, awọn iwa ti igbesi aye ajẹjẹ ẹsin ko mu kuro. Ko yẹra kuro ninu ifiyajẹ ara ẹni nipasẹ eyi ti yoo fi ri ọkan mimọ ti yoo jẹ ki o le duro pẹlu idalare niwaju Ọlọrun. Nigba ti o ya, o sọ wipe, “Nitootọ, mo jẹ alufa onifọkansin, mo si tẹle awọn ilana ẹgbẹ mi pẹlu ofin tótó ju bi mo ti le sọ lọ. Bi iṣe awọn alufa ba le mu awọn alufa de ọrun, o ye ki n le debẹ laiṣe aniani. . . . Bi mo ba tẹsiwaju diẹ si ni, n ba gbe ifiyajẹra-ẹni mi de oju iku.” Nitori ifiyajẹra-ẹni yii agbara rẹ dinku, giri si maa n mu, ipa rẹ ko si kuro lara rẹ patapata. Ṣugbọn pẹlu gbogbo akitiyan rẹ, ọkan wuwo rẹ ko ri alaafia. Lẹyin-ọrẹyin o fere sọ ireti nu.ANN 53.4

    Nigbati o dabi ẹnipe ko si ireti mo fun Luther, Ọlọrun gbe ọrẹ ati oluranlọwọ dide fun. Staupitz ti o jẹ olufọkansin ṣe alaye ọrọ Ọlọrun fun Luther o si rọ ọ ki o maṣe wo ara rẹ mọ, ki o dawọ rironu lori ijiya ainipẹkun nitori riru ofin Ọlọrun duro, ki o si wo Jesu Olugbala rẹ ti n dari ẹṣẹ ji ni. “Dipo ki o maa fi iya jẹ ara rẹ nitori awọn ẹṣẹ rẹ, sọ ara rẹ si ọwọ Olurapada. Ni igbẹkẹle ninu Rẹ, ninu ododo igbesi aye Rẹ, ninu iku iwẹnumọ Rẹ. . . . Fi eti silẹ si Ọmọ Ọlọrun. O di eniyan ki O le fun ọ ni idaniloju ojurere Ọlọrun.” “Fẹran Ẹni ti o kọkọ fẹ ọ.” Bi oniṣẹ-iranṣẹ aanu ṣe sọrọ niyi. Awọn ọrọ rẹ mu Luther lọkan gan an ni. Lẹyin ọpọlọpọ ijakadi pẹlu awọn aṣiṣe ti o ti gba fun igba pipẹ, o ni oye otitọ, alaafia si wa si ọkan rẹ to n damu.ANN 53.5

    A gbe ọwọ le Luther lori gẹgẹ bi alufa, a si pe e lati ile awọn ajẹjẹ ẹsin lati wa jẹ ọjọgbọn ni ile ẹkọ giga ni Wittenberg. Nibi o kọ ẹkọ ọrọ Ọlọrun ni ede ti a fi kọ gan an. O bẹrẹ si ni i kọni ni ẹkọ lori Bibeli; o si n ṣi O. Dafidi, awọn Iyinrere, ati awọn Episteli paya si oye awọn ọpọ eniyan ti inu wọn dun lati gbọ. Staupitz, ọrẹ ati ọga rẹ, rọ ọ lati gun ori pẹpẹ iwaasu, ki o si waasu ọrọ Ọlọrun. Luther lọra, o ro wipe ohun ko to lati ba awọn eniyan sọrọ ni ipo Kristi. Lẹyin ironu ọlọjọ gbọọrọ, o tẹti si ipe awọn ọrẹ rẹ. O ti jẹ alagbara ninu Iwe Mimọ na, oore ọfẹ Ọlọrun si wa ni ori rẹ. Ijageere ọrọ rẹ fa awọn olugbọ rẹ lọkan, bi o ti n sọ otitọ ni ọna ti o ye kooro, ati pẹlu agbara jẹ ki otitọ o ye won, itara rẹ si fi ọwọ ba wọn lọkan.ANN 53.6

    Luther si jẹ ọmọ ijọ paadi nitootọ, ko si ni ero wipe oun le jẹ ohun miran. Ninu idari Ọlọrun, o bẹ Romu wò. Ẹsẹ ni o fi rin irin ajo rẹ, o n duro ni awọn ile awọn ajẹjẹ ẹsin ti wọn wa ni oju ọna. Ninu ile ẹsin kan ni Italy, ẹnu ya a nitori ọrọ, ògo ati igbadun ti o ri. Nitori ti wọn n ri owo gọbọi, awọn alufa ibẹ n gbe inu ile ọlọla, wọn n wọ aṣọ olowo iyebiye, wọn si n jẹ onjẹ aladidun. Pẹlu ẹdun ọkan, Luther ṣe afiwe iṣẹlẹ yii pẹlu isẹra-ẹni ati ijiya igbesi aye rẹ. Ọkan rẹ bẹrẹ si ni poruuru.ANN 54.1

    Nikẹyin, o ri ilu ti o wa ni ori oke meje naa ni òkè réré. Pẹlu ìrò ọkan ti o jinlẹ, o nà gbalaja si ori ilẹ, o wipe: “Romu mimọ, mo ki ọ.” O wọ inu ilu naa, o bẹ awọn ile ijọsin wo, o fi eti si awọn oriṣiriṣi itan agbayanu ti awọn alufa n sọ, o si ṣe ohun gbogbo ti o yẹ ni ṣiṣe. Ni ibi gbogbo, o ri awọn iṣẹlẹ ti wọn ya a lẹnu ti wọn si ja láyà. O ri wipe aiṣedeede wọpọ ni aarin awọn alufa. O gbọ awọn ẹfẹ ti ko boju mu lati ọdọ awọn agba alufa, ẹru ba a nitori awọn iwa aimọ wọnyi, ani ti wọn n wu nigba ti wọn ba n gba mass. Bi o ti dara pọ mọ awọn alufa ati awọn ọmọ ilu, o ri iwa faaji ati aikora-ẹni-nijanu. Nibikibi ti o ba gboju si, dipo ki o ri iwa mimọ, iwa aimọ ni o ri. O kọwe wipe: “Ko si ẹni ti o le rò wipe wọn n wu iru iwa ẹṣẹ ati iwa ibajẹ yii ni Romu; eniyan ni lati ri wọn ki o si gbọ wọn ki o to le gbagbọ. Idi niyi ti wọn fi ni iwa lati maa sọ wipe, ‘Bi ọrun apadi ba wà, ori rẹ ni a kọ Romu le: ohun ni ọgbun nla nibi ti iruuru ẹṣẹ gbogbo ti n jade wa.”ANN 54.2

    Ninu ofin ti o ṣẹṣẹ jade, popu ṣe ileri idariji fun ẹnikẹni ti yoo ba gun “akasọ Pilatu” pẹlu eekun rẹ, eyi ni a sọ wipe Olugbala wa sọkalẹ lati ori rẹ nigba ti O n kuro ni gbọngan idajọ awọn Romu, ti a si gbe wa si Romu lati Jerusalẹmu ni ọna iyanu. Luther n fi tọkantọkan gun akasọ yii ni ọjọ kan nigba ti o gbọ ohùn kan bi ìró àrá ti o sọ fun wipe: “Olododo yoo wa nipa igbagbọ.” Romu 1:17. O dide duro lori ẹsẹ rẹ, o si yara kankan kuro nibẹ pẹlu itiju ati ibẹru. Agbara ẹsẹ yii ko kuro ni ọkan rẹ. Lati akoko yii lọ o ri ni kedere ju ti atẹyinwa lọ bi gbigbẹkẹle iṣẹ eniyan fun igbala ti jẹ ẹtan to, ati bi igbagbọ nigba gbogbo ninu iṣẹ Kristi ti ṣe pataki to. Oju rẹ ṣi silẹ si awọn itanjẹ ijọ paadi, ko sile padé mọ. Nigba ti o yi oju rẹ kuro ni Romu, ọkan rẹ yi kuro pẹlu, lati akoko yii lọ, iyapa naa n fẹ si, titi ti ko fi ni ibaṣepọ kankan mọ pẹlu ijọ paadi.ANN 54.3

    Lẹyin ti o pada de lati Romu, Luther gba oye dokita ninu ẹkọ nipa Ọlọrun ni ile ẹkọ giga ni Wittenberg. Bayii o ni anfani ju ti tẹlẹ lọ lati fi ara rẹ jin fun Iwe Mimọ ti o fẹran. O ti jẹ ẹjẹ ọlọwọ lati fi pẹlẹkutu kọ ẹkọ ọrọ Ọlọrun, ki o si fi otitọ waasu rẹ, ki i si ṣe awọn ọrọ ati ikọni popu, ni gbogbo ọjọ aye rẹ. Ki i ṣe alufa ajẹjẹ ẹsin tabi ọjọgbọn lasan mọ, ṣugbọn ẹni ti a fi aṣẹ fun lati kede Bibeli. A ti pe e gẹgẹ bi oluṣọ aguntan lati bọ agbo Ọlọrun ti wọn n pebi ti wọn si n poungbe fun otitọ. O fi igboya sọ wipe awọn Kristẹni ko gbọdọ gba ikọni kankan ayafi eyi ti o ba duro lori aṣẹ Iwe Mimọ. Awọn ọrọ wọnyi ṣe akọlu si ipilẹ agbara ijọ paadi. Wọn ni awọn koko ọrọ to ṣe pataki fun iṣẹ Atunṣe.ANN 54.4

    Luther ri ewu ti o wa ninu gbigbe ọrọ eniyan ga ju ọrọ Ọlọrun lọ. O fi igboya tako ero aigbagbọ awọn ọmọwe, o si tako ero eniyan ati awọn ẹkọ nipa Ọlọrun ti wọn ti ni ipa lori awọn eniyan fun igba pipẹ. O ta iru awọn ẹkọ wọnyi nu bi eyi ti ko nitumọ, ti o tun lewu, o si wa ọna lati dari ọkan awọn olugbọ rẹ kuro ninu ọgbọn ẹwẹ awọn elero ijinlẹ ati awọn ti n kọni nipa Ọlọrun, ki o si yi si awọn otitọ ti awọn woli ati awọn apostoli fi kọni.ANN 54.5

    Awọn iṣẹ iranṣẹ ti wọn ṣe iyebiye ni o fi fun awọn ọpọ ero ti wọn n tẹti si ọrọ rẹ. Wọn koi ti i gbọ iru awọn ikọni yii ri. Iroyin ayọ ifẹ Olugbala, idaniloju idariji ati alaafia nipasẹ ẹjẹ iwẹnumọ Rẹ, mu inu wọn dun, o si sọ ireti ainipẹkun ji ninu wọn. A tan ina kan ni Wittenberg, eyi ti itansan rẹ yoo tan de opin aye, ti yoo si maa mọlẹ si titi di opin akoko.ANN 54.6

    Ṣugbọn imọlẹ ati okunkun ko le jumọ wa papọ. Ijakadi ti ko le farasin wa laarin otitọ ati èké. Lati di ọkan mu ati lati gbeja rẹ tumọ si wipe a yoo tako ekeji, a yoo si bi i subu. Olugbala wa funra Rẹ sọ wipe: “Emi ko wa lati ran alaafia, bikoṣe ida.” Matiu 10:34. Lẹyin ọdun diẹ ti iṣẹ Atunṣe bẹrẹ, Luther sọ wipe: “Ki i ṣe wipe Ọlọrun n dari mi, ṣugbọn O n ti mi siwaju. O n gbe mi lọ. Emi ki i ṣe ọga ara mi. Mo fẹ lati wa ni alaafia; ṣugbọn a sọ mi si aarin rukerudo ati ijakadi.” Bayi, a ṣe fa a sinu wahala naa.ANN 55.1

    Ijọ Romu ti sọ oore ọfẹ Ọlọrun di okoowo. A gbe tabili awọn ti n pa owo da (Matiu 21:12) si ẹba pẹpẹ rẹ, ayika si kun fun igbe awọn ti n ṣe katakara. Nitori ati ko owo jọ fun kikọ ile ijọsin Peteru mimọ ni Romu, popu gbe idariji ẹṣẹ sita fun tita ni gbangba. A yoo kọ tẹmpili kan fun ijọsin Ọlọrun pẹlu owo ẹṣẹ—a yoo gbe okuta igun rẹ ro pẹlu èrè aiṣedeede! Ṣugbọn ọna kan naa gan ti Romu lo lati ko ọrọ jọ ni o ṣe ikọlu ti o lagbara julọ si agbara ati titobi rẹ. Eyi ni o ta eyi ti o lagidi julọ ti o si ṣe aṣeyọri julọ ninu awọn ọta ẹsin ijọ paadi ji, ti o si yọri si ogun ti o mi itẹ popu, ti o si ja ade onipele mẹta bọ kuro ni ori rẹ.ANN 55.2

    Tetzel, ẹni ti a ran lati wa ta idariji ẹṣẹ ni Germany ti jẹbi awọn ẹṣẹ nla si ilu ati si ofin Ọlọrun, ṣugbọn nitori pe o bọyọ kuro ninu awọn ijiya ti o yẹ fun awọn ẹṣẹ rẹ, a yan an lati ṣe iṣẹ ojukokoro, ati iṣẹ oniwaibajẹ fun popu. Pẹlu ainitiju nla, o n pa awọn irọ ti wọn han kedere, o si n sọ awọn itan ti o yanilẹnu lati tan awọn eniyan alaimọkan, ti wọn le gba ohunkohun gbọ jẹ. Bi o ba ṣe wipe wọn ni ọrọ Ọlọrun ni, a ki bati ṣe bẹyẹn tan wọn jẹ. Ki a baa le fi wọn si abẹ akoso ijọ padi, lati le fi kun agbara ati ọrọ awọn adari olojukokoro rẹ, ni a ṣe fi Bibeli pamọ kuro ni ọdọ wọn.ANN 55.3

    Bi Tetzel ti n wọ inu ilu kan, iranṣẹ kan n lọ niwaju rẹ, ti n kigbe wipe: “Oore ọfẹ Ọlọrun ati ti baba mimọ wa si ẹnu ọna yin.” Awọn eniyan si tẹwọgba opurọ asọrọ-odi naa afi bi ẹnipe òhun ni Ọlọrun funra Rẹ ti o sọkalẹ wa lati ọrun wa si ọdọ wọn. A gbe okoowo ẹlẹgan yii kalẹ sinu ile ijọsin, Tetzel si gun ori pẹpẹ iwaasu, o n bu iyin fun idariji ẹṣẹ yii gẹgẹ bi ẹbun Ọlọrun ti o dara julọ. O sọ wipe nipa agbara iwe aṣẹ idariji rẹ, gbogbo ẹṣẹ ti ẹni ti o ba ra a ba ṣẹ lẹyin eyi ni a o dari rẹ ji, ati wipe ironupiwada ko ṣe pataki.” Ju eyi lọ, o fi da awọn olugbọ rẹ loju wipe ki i ṣe wipe iwe aṣẹ idariji yii ni agbara lati gba alaaye là nikan, ṣugbọn o le gba awọn oku la pẹlu; wipe lọgan ti owó naa ba ti balẹ ninu apoti ikowopamọ si, ọkan ẹni ti a tori rẹ san owo naa yoo kuro ninu ibi ifiyajẹni, lọ si ọrun.ANN 55.4

    Nigba ti Simon Magus fẹ ra agbara lati ṣe iṣẹ iyanu lọwọ awọn apostoli, Peteru da lohun wipe: “Ki owo rẹ o ṣegbe pelu rẹ, nitori ti iwọ ro wipe a le fi owo ra ẹbun Ọlọrun.” Iṣe 8:20. Ṣugbọn ọpọ awọn eniyan ni wọn n du ọja Tetzel. Wura ati fadaka n san wọ inu apo iṣura rẹ. O rọrun lati ni igbala ti a le fi owo rà ju eyi ti o nilo ironupiwada, igbagbọ, ati iṣẹ afọkanṣe lati tako, ati lati bori ẹṣẹ lọ.ANN 55.5

    Awọn ọmọwe ati olufọkansin ninu Ijọ Romu ti tako ikọni rira idariji ẹṣẹ, ọpọlọpọ si wa ti wọn ko ni igbagbọ ninu irọ ti o tako ironu ati ifihan yii. Ko si awọn agba alufa ti o gboya lati sọ ọrọ tako okoowo ẹṣẹ yii; ṣugbọn ọkan awọn eniyan ko balẹ mọ, o si ti bẹrẹ si ni i poruuru, ti ọpọ n fi tọkantọkan beere boya Ọlọrun ko ni ṣiṣẹ nipasẹ ohun èlò kan lati fọ ijọ Rẹ mọ.ANN 55.6

    Bi o tilẹ jẹ wipe Luther si jẹ ọmọ ijọ paadi tọkantọkan, o korira ọrọ awọn asọrọ odi ti n ta idariji ẹṣẹ yii. Ọpọ awọn ọmọ ijọ rẹ ni wọn ti ra iwe aṣẹ idariji ẹṣẹ, wọn wa bẹrẹ si ni wa si ọdọ alufa wọn, wọn n jẹwọ awọn ẹṣẹ wọn loriṣiriṣi, wọn si n reti ki a dari ji wọn, ki i ṣe nitori pe wọn ronupiwada, ti wọn si fẹ ṣe atunṣe, ṣugbọn nitori pe wọn ti ra iwe fun idariji ẹṣẹ. Luther kọ lati dari ji wọn, o si kilọ fun wọn wipe, ayafi bi wọn ba ronupiwada ki wọn si yi igbesi aye wọn pada, wọn yoo ṣegbe ninu ẹṣẹ wọn. Ninu iporuuru ọkan wọn pada si ọdọ Tetzel lati ṣe aroye wipe ẹni ti wọn jẹwọ ẹṣẹ wọn fun ko gba iwe aṣẹ wọn; awọn kan tun fi igboya sọ wipe ki a da owo wọn pada. Inu bi alufa oníbárà yii. O ṣẹ èpè ti o buru jai, o mu ki a da ina si aarin ilu, o si sọ wipe: “oun ti gba aṣẹ lati ọdọ popu lati dana sun gbogbo ẹlẹkọ odi ti yoo ba gbero lati tako iwe idariji ẹṣẹ rẹ ti o jẹ mimọ julọ.”ANN 55.7

    Luther wa fi igboya bẹrẹ iṣẹ rẹ gẹgẹ bi olugbeja otitọ. A gbọ ohùn rẹ lati ori pẹpẹ, o n ṣe ikilọ ẹlẹru kikankikan. O fi bi ẹṣẹ ti buru to han awọn eniyan, o si kọ wọn wipe ko le ṣe e ṣe fun eniyan, pẹlu iṣẹ ọwọ rẹ, lati din ẹbi ẹṣẹ rẹ ku, tabi lati bọ kuro ninu ijiya rẹ. Ko si ohun kan ti o le gba ẹlẹṣẹ la ayafi ironupiwada si ọdọ Ọlọrun ati igbagbọ ninu Kristi. A ko le fi owó ra oore ọfẹ Kristi; ẹbun ọfẹ ni. O gba awọn eniyan niyanju lati maṣe ra idariji ẹṣẹ, ṣugbọn ki wọn fi igbagbọ wo Olurapada ti a kan mọ igi. O ṣe alaye iriri kikoro ara rẹ nigba ti o n ṣiṣẹ lasan nipa iyẹpẹrẹ ara ẹni, ati ifiya-jẹ-ara ẹni lati le ri igbala, o si fi da awọn olugbọ rẹ loju wipe nipa gbigbe oju kuro ni ara oun, ati gbigbagbọ ninu Kristi ni oun fi ri alaafia ati ayọ.ANN 56.1

    Bi Tetzel ti n tẹsiwaju ninu ọja rẹ ati awọn ọrọ alaiwabi-ọlọrun rẹ, Luther pinu lati lo ọna ti o lagbara si lati tako awọn iṣekuṣe wọnyi. O ri ọna kan laipẹ. Ọpọlọpọ ère wa ni ile ijọsin Wittenberg, eyi ti a maa n fi han awọn eniyan ni awọn ọjọ mimọ kan, a si n ṣe idariji ẹṣẹ ni kikun fun gbogbo awọn ti wọn ba bẹ ile ijọsin wò ti wọn si ṣe ijẹwọ ẹṣẹ ni akoko naa. Ni awọn ọjọ wọnyi, awọn eniyan pupọ ni wọn maa n wa sibẹ. Eyi ti o ṣe pataki julọ ninu awọn ọjọ wọnyi, ajọdun gbogbo awọn eniyan mimọ, n bọ lọna. Nigba ti o ku ọla, Luther darapọ mọ awọn eniyan ti wọn n lọ si ile ijọsin, o si lẹ iwe kan ti o fi kókó ọrọ marun-din-lọgọrun tako ikọni nipa tita idariji ẹṣẹ mọ ilẹkun rẹ. O kede ifẹ rẹ lati ṣe awijare si gbogbo awọn koko wọnyi ni ọjọ keji ninu ile ẹkọ giga, fun ẹnikẹni ti o ba fẹ ṣe atako wọn.ANN 56.2

    Gbogbo eniyan ni wọn fiyesi awọn akiyesi rẹ. A ka a ni akatunka, a tun ṣe atunsọ rẹ ni ibi gbogbo. Irọkẹkẹ nla bẹ silẹ ninu ile ẹkọ giga, ati ni gbogbo ilu naa. O fihan pẹlu awọn afiyesi wọnyi wipe a ko fun popu tabi ẹnikẹni ni agbara lati dari ẹṣẹ jini. Irọ patapata gbaa ni gbogbo ilana naa,—ète lati gba owó nipa titan awọn eniyan alaimọkan jẹ lasan ni,—ète Satani lati pa gbogbo ọkan awọn ti wọn ba gbẹkẹle irọ rẹ run ni. A tun fihan kedere wipe iyinrere Kristi ni ohun ẹṣọ ti o ṣe iyebiye julọ ti ijọ ni, ati wipe lọfẹ ni a fi oore ọfẹ Ọlọrun ti a fihan ninu rẹ fun gbogbo ẹni ti o ba wa pẹlu ironupiwada ati igbagbọ.ANN 56.3

    Awọn afiyesi Luther fa ijiroro; ṣugbọn ko si ẹni ti o ni igboya lati pe wọn nija. Awọn ohun ti o kọ silẹ ti tan kalẹ de gbogbo Germany laipẹ ọjọ, lẹyin ọsẹ diẹ, o ti de gbogbo ilẹ ti a ti n ṣe ẹsin Kristẹni. Ọpọlọpọ awọn atẹle ẹsin Romu ti wọn jẹ onifọkansin, ti wọn ri ti wọn si n kaanu nitori awọn iwa ibajẹ ti won n gbilẹ kan ninu ijọ, ṣugbọn ti wọn ko mọ bi wọn yoo ti da duro, ka awọn afiyesi wọnyi pẹlu ayọ nla, wọn si ri ohùn Ọlọrun ninu wọn. Wọn ri wipe Oluwa ninu oore ọfẹ Rẹ na ọwọ Rẹ lati da iwa ibajẹ ti o n yara kankan gbilẹ si ti o n ti Romu jade wa yii duro. Awọn ijoye ati awọn alaṣe ilu n yọ labẹnu wipe a dá agbara onigberaga ti a ko le yẹ ipinu rẹ wò yii duro.ANN 56.4

    Ṣugbọn ọpọ ero ti wọn fẹran ẹṣẹ, ti wọn si jẹ alaimọkan bẹru nitori pe a ti gbá awọn ẹtan ti wọn pa ibẹru wọn lẹnumọ kuro. Awọn alufa ẹlẹtan ti a da duro ninu iṣẹ gbigbe iwa ibajẹ larugẹ ri wipe wahala ti de ba ọna ati ri owó wọn, wọn binu, wọn si parapọ lati fi idi ẹtan wọn mulẹ. Alatunṣe naa yoo pade awọn olufisun kikoro. Awọn kan fi ẹsun kan an wipe o wuwa laironu pẹlu igbonara. Awọn miran fi ẹsun kan an wipe ti inu ara rẹ ni o ṣe, wipe ki i ṣe Ọlọrun ni o n dari rẹ, ṣugbọn igberaga ati ìyájú ni o n tì í. O dahun wipe, “Tani ko mọ wipe ko si ẹni ti o n gbe ero tuntun sita ti ko ni dabi ẹnipe o n gberaga, ti a ko si ni fi ẹsun kan wipe o n da wahala silẹ? . . . Kini idi ti a fi pa Kristi ati gbogbo awọn ajẹriku? Nitori ti o dabi ẹnipe wọn fi igberaga kẹgan ọgbọn akoko wọn ni, ati wipe wọn n fi imọ tuntun kọni laikọkọ fi irẹlẹ gba imọran ero awọn agba.”ANN 56.5

    O tun sọ wipe: “A yoo ṣe ohunkohun ti mo ba ṣe, ki i ṣe pẹlu ọgbọn eniyan, bikoṣe pẹlu imọran Ọlọrun. Bi iṣẹ naa ba i ṣe ti Ọlọrun, tani yoo le da duro? ti ki i ba ṣe bẹẹ, tani o le mu ki o tẹsiwaju? Ki i ṣe ifẹ mi, ki i ṣe ti wọn, ki i ṣe tiwa; bikoṣe ifẹ Rẹ, Baba mimọ ti n bẹ ni ọrun.”ANN 56.6

    Bi o tilẹ jẹ wipe Ẹmi Ọlọrun ni O mi si Luther lati ṣe iṣẹ rẹ, yoo ri ijakadi kikan. Ẹgan awọn ọta rẹ, ṣiṣe afihan ero rẹ ni ọna ti ko tọ, ati bi wọn ti ronu lori iwa rẹ ati erongba rẹ ni ọna aitọ ati ni ọna ika, kọlu u bi igbi omi; wọn si ṣe iṣẹ wọn. Ọkan rẹ ti balẹ wipe awọn adari awọn eniyan ninu ijọ ati ninu ile ẹkọ yoo fi tayọtayọ darapọ mọ oun lati ṣe atunṣe. Ọrọ iwuri lati ọdọ awọn ti wọn wa ni ipo giga fun ni ayọ ati ireti. O ti n wọna fun igba ọtun ti n yọ fun ijọ. Ṣugbọn ọrọ iwuri ti yipada di ẹgan ati ibawi. Ọpọ awọn oloye ninu ijọ ati ni ilu ni wọn mọ wipe otitọ ni awọn afiyesi rẹ; ṣugbọn laipẹ jọjọ, wọn ri wipe awọn ayipada nla ni yoo ṣẹlẹ bi wọn ba gba awọn otitọ wọnyi. Títún awọn eniyan ṣe, ki a si la wọn lọyẹ yoo din agbara Romu ku, yoo dawọ ọpọ owo ti n san sinu ile iṣura rẹ duro, yoo si din ọla ati igbadun awọn adari ijọ paadi ku jọjọ. Siwaju si, kikọ awọn eniyan lati ronu, ki wọn si wuwa gẹgẹ bi ẹni ti yoo jiyin iṣẹ rẹ, lati wo Kristi nikan ṣoṣo fun igbala, yoo bi itẹ popu wo, yoo si pa aṣẹ wọn run nikẹyin. Nitori idi eyi wọn kọ imọ ti Ọlọrun fifun wọn silẹ, wọn si doju ija kọ Kristi ati otitọ nipa titako ẹni ti O ran lati ṣi wọn niye.ANN 56.7

    Luther wariri bi o ti n wo ara rẹ—ẹnikan ṣoṣo ti o doju kọ agbara ti o ga julọ ni aye. Nigba miran, o ṣe iyemeji boya lootọ ni Ọlọrun dari oun lati tako aṣẹ ijọ. O kọwe wipe: “Tani mi ti n o fi tako ọlanla popu, ẹni ti . . . awọn ọba aye ati gbogbo aye n wariri niwaju rẹ? . . . Ko si ẹni ti o le mọ iya ti ọkan mi jẹ laarin awọn ọdun meji akọkọ wọnyi, ati iru iporuuru ọkan ati ainireti ti mo jin si.” Ṣugbọn a ko fi i silẹ ki ọkan rẹ o bajẹ tan patapata. Nigba ti iranlọwọ eniyan pin, ó wo Ọlọrun nikan ṣoṣo, o si kẹkọ wipe oun le sinmi le ọwọ alagbara julọ ni, ki oun si wa ni alaafia.ANN 57.1

    Luther kọwe si ọrẹ iṣẹ Atunṣe kan wipe: “A ko le ni oye Iwe Mimọ nipa ẹkọ tabi iwoye. Ojuṣe rẹ akọkọ ni ki o bẹrẹ pẹlu adura. Gba adura ki Oluwa, ninu aanu nla Rẹ, o fun ọ ni oye tootọ nipa ọrọ Rẹ. Ko si olutumo ọrọ Ọlọrun miran ju Ẹni ti o kọ ọ lọ, gẹgẹ bi Oun funra Rẹ ti wi, ‘Ọlọrun yoo kọ gbogbo wọn.’ Maṣe reti ohunkohun lati inu iṣẹ rẹ, tabi lati inu oye rẹ: gbẹkẹle Ọlọrun, ati agbara Ẹmi Rẹ patapata. Gba eyi gbọ lati ọdọ ẹni ti o ti ni iriri.”ANN 57.2

    Ẹkọ ti o ṣe pataki niyi fun awọn ti wọn ro wipe Ọlọrun ti pe wọn lati ṣe alaye awọn otitọ ti ìwòyí fun awọn miran. Awọn otitọ wọnyi yoo ru ikorira Satani ati ti awọn ti wọn fẹran ẹtan ti o gbe kalẹ soke. Ninu ijakadi pẹlu iwa buburu, ohun ti a nilo ju agbara ọgbọn ati ironu eniyan lọ.ANN 57.3

    Nigba ti awọn ọta ba n lo aṣa ati ẹkọ eniyan, tabi ti wọn n lo ọrọ ati aṣe popu, Luther pade wọn pẹlu Bibeli àni Bibeli nikan ṣoṣo. Ọrọ ti wọn kò lè fèsì sí wa nibẹ; nitori idi eyi ni awọn ti wọn ti di ẹru si aṣa ati ẹtan ṣe n kigbe fun ẹjẹ, bi awọn Ju ti kigbe fun ẹjẹ Kristi. Awọn onitara fun Romu n kigbe wipe, “Ẹlẹkọ odi ni.” “Iṣọtẹ nla ni si ijọ bi a ba jẹ ki ẹlẹkọ odi buburu yii o wa laaye fun wakati kan si. Ẹ jẹ ki a gbe igi ibẹnilori ró fun ni kiakia!” Ṣugbọn Luther ko ṣubu si ọwọ ibinu wọn. Ọlọrun ni iṣẹ fun lati ṣe, a si ran awọn angẹli ọrun lati wa daabo bo o. Ṣugbọn ọpọlọpọ awọn ti wọn gba imọlẹ iyebiye yii lati ọwọ Luther ri idojukọ ibinu Satani wọn si fi igboya fi ara da ijiya ati iku nitori otitọ.ANN 57.4

    Awọn ti wọn ni òye ni ilẹ Germany fi iye si awọn ikọni Luther. Imọlẹ ti o ta awọn eniyan ji, ti o si tan imọlẹ si wọn tan jade lati inu awọn iwaasu ati iwe rẹ. Igbagbọ ti o wa laaye n rọpo aṣa ti ko ni ẹmi ti ijọ ti wà ninu rẹ fun igba pipẹ. Awọn eniyan n padanu igbẹkẹle wọn ninu ẹtan ẹsin Romu lojoojumọ. Idena aimọkan n ya lulẹ. Ọrọ Ọlọrun ti Luther fi dan gbogbo ikọni ati igbagbọ wò dabi ida olojumeji ti n wọ ọkan awọn eniyan lọ. Ifẹ fun idagbasoke ẹmi sọji nibi gbogbo. Ìpebi ati ìpòùngbẹ fun ododo wa ni ibi gbogbo ni ọna ti a ko riri fun ọpọlọpọ igba sẹyin. Oju awọn eniyan, ti o ti n wo aṣa eniyan ati olubalaja aye fun igba pipẹ, wa n yi si Kristi ati Ẹni ti a kan mọ agbelebu pẹlu ironupiwada ati igbagbọ.ANN 57.5

    Bi ọrọ yii ti n tan kalẹ tun ru ibẹru awọn alaṣẹ ijọ paadi soke si. Luther gba ipe lati wa fi ara han ni Romu lati wa jẹjọ si awọn ẹsun ẹkọ odi. Aṣẹ yii dẹru ba awọn ọrẹ rẹ. Wọn mọ daju iru ewu ti o le wu u ninu ilu buburu naa, ilu ti o ti mu ẹjẹ awọn ajẹriku fun Jesu yó. Wọn tako bi o ti fẹ lọ si Romu, wọn wa sọ wipe ki a ṣe igbẹjọ rẹ ni Germany.ANN 57.6

    A gba ètò yii wọle, a si yan aṣoju popu ti yoo ṣe igbẹjọ naa. Ninu aṣẹ ti popu fun aṣoju yii, a sọ wipe a ti ri Luther ni ẹlẹkọ odi ná. Nitori naa, a paṣẹ fun aṣoju naa lati “ṣe igbẹjọ, ki o si sẹ ẹ rọ ni kiakia.” Bi o ba si duro gbọin, ti aṣoju naa ko si le sẹ ẹ rọ, a fun ni agbara lati “fi ofin de e ni gbogbo ilẹ Germany, lati lé gbogbo awọn ti wọn ba sun mọ kuro ni ilu, ki o fi wọn gegun, ki o si le wọn kuro ninu ijọ.” Siwaju si, popu pa aṣoju rẹ laṣẹ, lati le fa ẹkọ odi buburu yii tu ti gbongbo ti gbongbo, lati le ẹnikẹni, laika ipo rẹ ninu ilu tabi ijọ si, ayafi ọba, ti o ba kọ lati mu Luther ati awọn atẹle rẹ, ki o si fa wọn le ibinu Romu lọwọ.ANN 58.1

    Nibi ni a ti fi iru ẹmi ti ẹsin popu ni gan an han. A ko ri ilana Kristẹni, tabi ti idajọ ninu gbogbo akọsile yii. Ibi ti Luther wa jinna si Romu pupọpupọ; koi ti i ni anfani lati ṣe alaye tabi lati wi awijare nipa igbagbọ rẹ; sibẹ, ki a to ṣe ayẹwo ẹjọ rẹ, a ti pe e ni ẹlẹkọ odi, ni ọjọ kan naa, ni a gba a niyanju, ni a fi ẹsun kan an, ni a ṣe idajọ rẹ, ni a da a lẹbi; ẹni ti o pe ara rẹ ni baba mimọ, aṣẹ kan ṣoṣo ti o ga julọ ti ko si le baku ninu ijọ ati ninu oṣelu, ni o si n ṣe gbogbo eyi!ANN 58.2

    Ni akoko yii, nigba ti Luther nilo ibakẹdun ati imọran ọrẹ tootọ, ipese Ọlọrun ran Melancthon wa si Wittenberg. O kere ni ọjọ ori, o ni iwa itiju, ko si gbẹkẹle ara rẹ, ìronu Melancthon ti o peye, imọ rẹ ti o jinlẹ, ati iṣọwọsọrọ rẹ ti o fanimọra, pẹlu iwa mimọ ati iwa ododo rẹ jẹ ki awọn eniyan o ka a si, wọn si jẹ ki o ni iyin ni oju wọn. Bi ijafafa rẹ ti pọ to, bẹẹ naa ni iwa pẹlẹ rẹ ti pọ to. Laipẹ, o fi tọkantọkan di atẹle iyinrere, ọrẹ ti Luther fi ọkan tan julọ, ati alatilẹyin rẹ ti o ṣeyebiye julọ; iwa pẹlẹ, iṣọraṣe, ati iwa iṣe deede rẹ jẹ idakeji igboya ati agbara Luther. Ibaṣepọ wọn ninu iṣẹ naa fun iṣẹ Atunṣe ni okun o si jẹ ohun imoriya nla fun Luther.ANN 58.3

    A yan Augsburg gẹgẹ bi ibi igbẹjọ, Alatunṣe naa si lọ sibẹ pẹlu ẹsẹ rẹ. Ibẹru nla bo ọpọlọpọ nitori rẹ. A ti ṣe ileri ni gbangba wipe a yoo mu, a o si pa ni oju ọna, awọn ọrẹ rẹ si rọ ọ ki o maṣe lọ. Wọn tilẹ tun rọ ọ ki o fi Wittenberg silẹ fun igba diẹ, ki o si wa aabo ni ọdọ awọn ti yoo fi tayọtayọ daabo bo o. Ṣugbọn ko ni fi ipo ti Ọlọrun fi si silẹ. O nilati fi igbagbọ tẹsiwaju lati duro ti otitọ laika awọn iji ti wọn ba bi lu u si. Ohun ti o n sọ ni wipe: “Mo dabi Jeremaya, ọkunrin onija ati wahala; ṣugbọn bi wahala wọn ba ṣe n pọ si, bẹẹ ni ayọ mi n di pupọ si. . . . Wọn ti ba iyin ati orukọ mi jẹ. Ohun kan ṣoṣo ni o ku; ara kiku yii ni: jẹ ki wọn gba a; wọn a fi wakati diẹ din ẹmi mi ku. Ṣugbọn ni ti ọkan mi, wọn ko le gba a. Ẹnikẹni ti o ba fẹ lati polongo ọrọ Kristi fun araye nilati maa reti iku nigba gbogbo.”ANN 58.4

    Iroyin wipe Luther ti de si Augsburg dun mọ aṣoju popu ninu pupọpupọ. O dabi ẹnipe ẹlẹkọ odi oniwahala ti gbogbo eniyan n fiyesi ti wa ni ikawọ agbara Romu, aṣoju naa si pinu wipe ko ni bọyọ. Alatunṣe naa ko gba iwe idaabobo. Awọn ọrẹ rẹ rọ ọ lati maṣe fi ara han niwaju aṣoju naa laisi ọkan, awọn funra wọn si ṣe akitiyan lati gba ọkan lati ọwọ ọba. Aṣoju naa ro, bi o ba ṣe e ṣe, lati fi ipa mu Luther ki o yi ọrọ rẹ pada, ati bi eyi ko ba ṣe e ṣe, ki o mu ki a gbe lọ si Romu ki o baa le gba ninu ipin Huss ati Jerome. Nitori naa, o fẹ fi ẹtan mu Luther nipasẹ awọn aṣoju rẹ, lati le mu ki o fi ara han niwaju oun laini iwe idaabobo, ki o baa le ṣe e bi o ti fẹ. Ṣugbọn Alatunṣe naa kọ lati ṣe eyi. Afi igba ti o to gba iwe ti ọba fi ṣe ileri lati daabo bo o ni o to fi ara han niwaju aṣoju popu.ANN 58.5

    Gẹgẹ bi iṣe wọn, awọn ẹlẹsin Romu ti pinu lati jere ọkan Luther nipa fifi ara han ni ọna iwapẹlẹ. Ninu ifọrọwanilẹnuwo rẹ, aṣoju naa ṣe bi ọrẹ tootọ; ṣugbọn o sọ wipe ki Luther o fi tọkantọkan gba aṣẹ ijọ, ki o si fi ohun gbogbo silẹ laisi ibeere tabi ariyanjiyan. Ko wo iwa ẹni ti o n ba lo daradara. Nigba ti o n fesi, Luther sọ bi o ti bọwọ fun ijọ, o sọ nipa ifẹ rẹ fun otitọ, ati imura rẹ lati dahun si ibeere ti o jẹyọ lori ohunkohun ti oun fi kọni, ati lati gbe ikọni rẹ si abẹ ipinu awọn ile ẹkọ giga kan. Ṣugbọn nigba kan naa, o tako iwa aṣoju naa ni fifẹ ki oun o yi ohùn pada laikọkọ fihan ibi ti oun ti ṣe aṣiṣe.ANN 58.6

    Esi kan ṣoṣo ti o wa ni: “Yi ohùn pada, yi ọrọ rẹ pada!” Alatunṣe naa fihan wipe Iwe Mimọ gbe ẹkọ ohun lẹsẹ, o si fi igboya sọ wipe òun ko le kọ otitọ silẹ. Nitori pe aṣoju naa ko le fèsì sí awọn ọrọ Luther, o bẹrẹ si ni i rọjo eebu, ẹfẹ, ati ẹsín le lori, o n fi awọn akọsilẹ ijọ ati ti awọn Baba ijọ ru laarin, ko si fun Alatunṣe naa ni anfani lati sọrọ. Nigba ti o ri wipe apero naa ko le ni itumọ bi o ba n lọ bayii, Luther ba beere fun anfani lati kọ idahun rẹ silẹ.ANN 58.7

    Nigba ti o n kọwe si ọrẹ rẹ kan, o sọ wipe, “Nipa ṣiṣe eyi, ẹni ti a n fi iya jẹ ni anfani ni ọna meji; akọkọ ni wipe, a le gbé ohun ti a kọ silẹ siwaju elomiran lati ṣe idajọ le lori; ekeji si ni wipe, eniyan ni anfani ti o pọ si lati ṣiṣẹ lori ibẹru, ani ẹri ọkan onroro onigberaga ti o n sọrọ gbaugbau, ti i ba fi ariwo rẹ boni mọlẹ.” ANN 59.1

    Ninu iwanilẹnuwo ti o tẹle, Luther ṣe alaye awọn ero rẹ ni ọna ti o lagbara ti o si yeni yekeyeke, o si lo ọpọlọpọ ẹsẹ Iwe Mimọ lati fi gbe wọn lẹsẹ. Lẹyin ti o ka iwe yii soke tan, o fi le kádínà naa lọwọ, bi o tilẹ jẹ wipe o fi igberaga sọ ọ si ẹgbẹ kan, o n sọ wipe o kun fun awọn ọrọ asan ati ayọka ti ko ni itumọ. Inu wa bi Luther, o si da alufa onigberaga yii lohun pẹlu ọrọ rẹ—awọn aṣa ati ikọni ijọ—ti o si fọn gbogbo ero rẹ ká patapata.ANN 59.2

    Nigba ti alufa naa ri wipe awọn ọrọ Luther ko ṣe e fesi si, ko le ko ara rẹ ni ijanu mọ, o wa kigbe pẹlu ibinu wipe: “Yi ọrọ rẹ pada! Bi ko ba ri bẹẹ, maa ran ọ lọ si Romu, lati lọ fi ara han niwaju awọn adajọ ti a yan lati boju to ọrọ rẹ. Ma a lé iwọ ati gbogbo awọn atẹle rẹ, ati gbogbo awọn ti wọn ba fi oju rere wo ọ ni igba kan ri kuro ninu ijọ.” Nikẹyin o sọ pẹlu igberaga ati ibinu wipe: “Yi ọrọ rẹ pada, tabi ki o maṣe pada mọ.”ANN 59.3

    Alatunṣe naa yara kuro nibẹ pẹlu awọn ọrẹ rẹ, nipa eyi o n sọ ni gbangba wipe a ko gbọdọ reti ki oun yi ọrọ oun pada. Ki i ṣe ohun ti kadina naa gbero niyi. O ti dun ara rẹ ninu wipe oun yoo fi ipa sẹ Luther rọ. Bayi ti o wa ku oun ati awọn alatilẹyin rẹ nikan, o wo awọn iyoku pẹlu itiju nitori ibaku ti wọn ko lero ti o de ba ète wọn.ANN 59.4

    Ohun ti Luther ṣe nibi ni ayọrisi rere. Awọn eniyan ti wọn pejọ pọ ni anfani lati fi awọn mejeeji wé ara wọn, ati lati ṣe idajọ fun ara wọn iru ẹmi ti wọn fihan, ati bi ipo wọn ti ní okun, ti o si ti tọna si. Iyatọ naa ti pọ to! Alatunṣe naa, alaini-wahala, onirẹlẹ, o duro ṣinṣin, o duro ninu okun Ọlọrun, pẹlu otitọ ni ìhà rẹ; aṣoju popu jọ ara rẹ loju, o jẹ onijagidijagan, onigberaga, alainironu, ko ni ẹsẹ kan ṣoṣo lati inu Iwe Mimọ, sibẹ o n kigbe kikankikan wipe: “Yi ọrọ rẹ pada, tabi ki a ran ọ lọ si Romu fun ijiya.”ANN 59.5

    Bi o tilẹ jẹ wipe Luther ti gba iwe idaabobo, awọn ẹlẹsin Romu n pète lati mu ki wọn si ti i mọle. Awọn ọrẹ rẹ rọ ọ wipe ko ni itumọ bi o ba duro diẹ si, o nilati pada si Wittenberg kiakia, ati wipe wọn nilati sọra gidigidi ki wọn ma ba a mọ ohun ti o fẹ ṣe. Nitori naa, ki oju to mọ, o gun ẹṣin kuro ni Augsburg, pẹlu ẹṣọ kan ti alaṣe ilu naa fun. Pẹlu ibẹru ni oriṣiriṣi, o rọra la awọn adugbo ilu naa ti wọn ṣokunkun ti wọn si dakẹrọrọ kọja. Awọn ọta ti wọn ni ìkà n ṣe aisun, wọn n pète iparun rẹ. Ṣe yoo bọyọ kuro ninu ọdẹ ti a dẹ silẹ fun bi? Awọn akoko yii kun fun iporuuru ọkan ati adura atọkanwa. O de ibi ilẹkun kekere kan ni ara ogiri ilu naa. A ṣi silẹ fun, oun pẹlu ẹṣọ rẹ si jade laisi idiwọ. Lọgan ti wọn de ita, awọn ti n sa asala naa ba mura si irin ẹsẹ wọn; ki alufa naa to mọ wipe Luther ti salọ, o ti kọja ibi ti awọn oninunibini rẹ ti le ri mu. A ṣẹgun Satani ati awọn iranṣẹ rẹ. Ẹni ti wọn ro wipe o wa ni ikawọ wọn ti lọ, o sa asala bi ẹyẹ ti n salọ kuro lọwọ ikẹkun pẹyẹpẹyẹ.ANN 59.6

    Bi aṣoju naa ti gbọ wipe Luther ti salọ, o kun fun iyalẹnu ati ibinu. O gbero lati gba iyì nla fun ọgbọn ati iduroṣinṣin rẹ ninu iṣesi rẹ pẹlu ẹni ti n da ijọ laamu; ṣugbọn ijakulẹ ba ireti rẹ. O fi ibinu rẹ han ninu iwe ti o kọ si Frederick, afọbajẹ ti Saxony, o ba Luther wi gidigidi, o si sọ wipe ki Frederick o gbe Luther Alatunse naa wa si Romu, tabi ki o le kuro ni Saxony.ANN 59.7

    Ni awijare, Luther sọ wipe ki aṣoju naa tabi popu o fi aṣiṣe oun han oun lati inu Iwe Mimọ, o fi tọwọtọwọ jẹjẹ wipe oun yoo kọ awọn ikọni oun silẹ bi a ba le fihan wipe wọn tako ọrọ Ọlọrun. O si fi imoore rẹ han fun Ọlọrun nitori ti o ka oun yẹ lati jiya ninu iṣe mimọ.ANN 59.8

    Afọbajẹ naa koi ti i ni imọ ti o pọ nipa awọn ikọni ti a tunṣe yii, ṣugbọn igboya, okun, ati isọrọyeniyeke Luther mu lọkan; titi di igba ti a ba fihan wipe Alatunṣe naa ṣe aṣiṣe, Frederick pinu lati daabo bo o. O fesi si ohun ti aṣoju naa beere ninu iwe rẹ bayi pe: “Niwọn igba ti ọmọwe Martins ti fi ara han niwaju rẹ ni Augsburg, o yẹ ki iyẹn o tẹ ọ lọrun. A kò rò wipe wà á fẹ ki o yi ohùn rẹ pada laikọkọ fi han an ibi ti o ti ṣe aṣiṣe. Ko si ọkan ninu awọn ọmọwe ni agbegbe wa yii ti o ti i sọ fun mi wipe ikọni Luther ko ba ilana Ọlọrun mu, tabi pe ko ba ilana Kristẹni mu, tabi pe o jẹ ẹkọ odi.’ Ijoye naa si kọ lati ran Luther lọ si Romu, tabi lati le kuro ninu ilu.”ANN 60.1

    Afọbajẹ naa ri wipe ko si ikora-ẹni-nijanu mọ ni awujọ. A nilo iṣẹ atunṣe nla. A ko ba ti nilo ètò ati din iwa ibajẹ ku, ati fifi iya jẹ oniwa ibajẹ, eyi ti o nira, ti o tun nánilówó, bi awọn eniyan ba mọ ti wọn si n ṣe igbọran si ofin Ọlọrun, ti wọn si tẹle ẹri ọkan ti o ni òye. O ri wipe ohun ti Luther n ṣiṣẹ lati ṣe ni eyi, inu rẹ si n dun labẹlẹ wipe agbara tuntun n fi ara han ninu ijọ.ANN 60.2

    O tun ri wipe Luther n ṣe daradara gẹgẹ bi ọjọgbọn ninu ile ẹkọ giga. Ọdun kan ṣoṣo ni o tii kọja lẹyin ti Alatunṣe naa lẹ awọn afiyesi rẹ mọ ile ijọsin, ṣugbọn iye awọn arinrinajo ti wọn n bẹ ile ijọsin naa wo ni ọjọ ajọdun gbogbo eniyan mimọ ti dinku gan an ni. Romu ko ri awọn olujọsin ati owó ọrẹ mọ, ṣugbọn awọn ẹgbẹ miran ti gba ipo wọn, awọn ti wọn n wa si Wittenberg, ki i ṣe awọn arinrinajo ti yoo maa jọsin awọn ère rẹ, ṣugbọn awọn akẹkọ ti yoo kun awọn gbọngan ikẹkọ rẹ. Awọn iwe Luther ti sọ ifẹ tuntun ninu Iwe Mimọ ji, ki i ṣe lati gbogbo Germany nikan, ṣugbọn lati awọn ilẹ miran ni awọn akẹkọ ti n wa si ile ẹkọ ni Germany. Awọn ọdọmọkunrin ti wọn n wọ Wittenberg fun igba akọkọ “na ọwọ wọn si oke ọrun, wọn si n yin Ọlọrun nitori ti o jẹ ki imọlẹ otitọ o tan jade lati inu ilu yii wa, bii lati Sioni ni igba atijọ, ti o si tan de awọn orilẹ ede ti wọn jina rere lati ibẹ lọ.”ANN 60.3

    Luther koi ti i yipada kuro ninu awọn aṣiṣe ẹsin Romu tan. Ṣugbọn bi o ti n fi Ọrọ Mimọ ṣe afiwe awọn aṣẹ ati iwe ilana popu, o kun fun iyalẹnu. O kọwe wipe, “Mo n ka awọn aṣẹ awọn popu, . . . n ko si mọ boya popu ni aṣodi-si-Kristi naa funra rẹ, tabi apostoli rẹ, a ṣe afihan Kristi ninu wọn ni ọna ti ko tọ jọjọ, a tun kan An mọ agbelebu ninu wọn.” Sibẹ ni akoko yii, Luther si jẹ ọmọ Ijọ Romu, kò sì ní èrò wipe oun yoo kuro ninu agbo rẹ.ANN 60.4

    Awọn iwe ati ikọni Alatunṣe naa n tan de gbogbo orilẹ ede ti n ṣe ẹsin Kristẹni. Iṣẹ naa tan de Switzerland ati Holland. Awọn ẹda iwe rẹ de France ati Spain. A gba awọn ikọni rẹ bi ọrọ iye ni England. Otitọ naa tan de Belgium ati Italy. Ọpọlọpọ ni wọn taji kuro ninu orun ikú wọn si ayọ ati ireti igbesi aye igbagbọ.ANN 60.5

    Awọn atako Luther tubọ n pin Romu lẹmi, diẹ lara awọn alatako rẹ, ani awọn ọmọwe ninu ile ẹkọ giga ti wọn jẹ ti ijọ Katoliki sọ wipe, ẹnikẹni ti o ba pa alufa ọlọtẹ naa kò ní ní ẹṣẹ. Ni ọjọ kan, àjèjì kan, ti oun ti ìbọn ilewọ ni abẹ aṣọ rẹ lọ ba Alatunṣe naa o si beere ni ọwọ rẹ idi ti o fi n danikan rin. Luther dahun wipe, “Mo wa ni ọwọ Ọlọrun. Oun ni agbara ati asa mi. Kini eniyan le ṣe si mi?” Nigba ti o gbọ awọn ọrọ wọnyi, oju ajeji naa kọrẹ lọwọ, o si sa kuro niwaju rẹ afi bi ẹni ti o sa kuro niwaju angẹli ọrun.ANN 60.6

    Romu pinnu lati pa Luther run; ṣugbọn Ọlọrun ni aabo rẹ. Ibi gbogbo ni a ti n gbọ awọn ikọni rẹ—”ninu awọn abà oko ati ninu ile awọn ajẹjẹ esin obinrin, . . . ninu ile awọn eniyan pataki, ninu awọn ile ẹkọ giga, ati ninu aafin awọn ọba;” awọn eniyan pataki si dide ni iha gbogbo lati ran akitiyan rẹ lọwọ.ANN 60.7

    Ni aarin akoko yii, nigba ti Luther n ka iṣẹ Huss, o ri otitọ nla ti idalare nipa igbagbọ, eyi ti oun n fẹ lati tẹle ati lati fi kọni, wipe Alatunṣe ti Bohemia ti gba a gbọ. Luther sọ wipe, “Gbogbo wa, Pọlu, Augustine, ati emi funra mi, ti jẹ atẹle Huss ni aimọ!” O tẹsiwaju wipe, “Ọlọrun yoo ṣe abẹwo rẹ lori araye, nitori pe a waasu otitọ naa fun wọn ni ọgọrun ọdun sẹyin, ti wọn si jo níná.”ANN 60.8

    Ninu ipẹ si ọba ati awọn ijoye Germany nitori atunṣe ẹsin Kristẹni, Luther kọwe nipa popu wipe: “O jẹ ohun ti o buru jai lati ri ẹni ti o pe ara rẹ ni aṣoju Kristi, ki o maa gbe ninu ọrọ ti o ju ti gbogbo ọba lọ. Ṣe ohun ti o tumọ si lati dabi Jesu alaini niyi, tabi Peteru otoṣi? Wọn n sọ wipe oun ni oluwa aye! Ṣugbọn Kristi, Ẹni ti o n fọnu wipe oun jẹ aṣoju Rẹ, sọ wipe, ‘Ijọba mi ki i ṣe ti aye yii.’ Ṣe akoso aṣoju le ju ti ọga rẹ lọ ni?”ANN 60.9

    O kọwe nipa awọn ile ẹkọ giga wipe: “Ẹru n bami gidigidi wipe awọn ile ẹkọ giga a di ẹnu ọna ọrun apaadi ayafi bi wọn ba ṣiṣẹ takuntakun lati ṣe alaye Iwe Mimọ, ki wọn si tẹ wọn mọ ọkan awọn ọdọ. Mo gba awọn eniyan niyanju lati maṣe fi ọmọ wọn si ibi ti Iwe Mimọ ko ti ni iṣakoso. Ibikibi ti awọn eniyan ko ba ti fi iye si ọrọ Ọlọrun ni aisimi yoo dibajẹ dandan ni.”ANN 61.1

    A fi ipẹ yii ranṣẹ kaakiri ni gbogbo Germany, o si ni ipa ti o lagbara lori gbogbo awọn eniyan. Gbogbo orilẹ ede mi titi, ọpọlọpọ awọn eniyan si ko ara wọn jọ pọ lati duro ti ọpagun iṣẹ atunṣe. Awọn ọta Luther, ti ara wọn n gbona lati gbẹsan, rọ popu lati ṣe nnkan nipa rẹ. A ṣe ofin pe ki a tako awọn ikọni rẹ ni kiakia. A fun Alatunṣe naa ati awọn atẹle rẹ ni ọgọta ọjọ, lẹyin eyi bi wọn ko ba pa ohùn wọn dà, a yoo le gbogbo wọn kuro ninu ijọ.ANN 61.2

    Wahala nla ni eyi jẹ fun iṣẹ Atunṣe. Fun ọpọ ọdun sẹyin, aṣẹ ìléni kuro ninu ijọ lati ọdọ Romu maa n ṣẹruba awọn ọba alagbara; o ti ko ègbé ati iparun ba awọn ijọba nla. Ni ibi gbogbo ni a ti maa n fi oju ibẹru ati ipaya wo gbogbo ẹni ti a ba ṣe idajọ yii fun; a yọ wọn kuro ninu ibaṣepọ pẹlu awọn alajọgbe wọn, a n ṣe si wọn bi ọdaran, ti a yoo si dọdẹ wọn titi ti wọn yoo fi parun tan. Oju Luther ko fọ si iji ti o fẹ bọ lu u yii; ṣugbọn o duro gbọin, o gbẹkẹle Kristi lati jẹ iranlọwọ ati aabo rẹ. O kọwe pẹlu igboya ati igbagbọ ajẹriku wipe: “Emi ko mọ ohun ti o fẹ ṣẹlẹ, bẹẹ si ni n ko fẹ mọ ọ. . . . Ẹ jẹ ki iji naa o bọ si ibi ti o ba fẹ, ẹru ko ba mi. Ewé kan ko le jabọ, ki Baba wa ma mọ si. Ṣe ko wa ni ṣe itọju wa! O jẹ ohun ti o rọrun lati ku nitori Ọrọ naa, nitori Ọrọ naa ti o di ara funra Rẹ ku. Bi a ba ku pẹlu Rẹ, a yoo gbe pẹlu Rẹ; ni lila ohun ti O ti la kọja ṣaaju wa kọja, a yoo wa pẹlu Rẹ ni ibi ti o wa, a yoo si gbe pẹlu Rẹ titi lae.”ANN 61.3

    Nigba ti aṣẹ popu de ọdọ Luther, o sọ wipe: “Mo kẹgan rẹ, mo si kọlu u bi ohun ti ko tọ, ti o jẹ irọ. . . . Kristi funra Rẹ ni a da lẹbi ninu rẹ. . . . Inu mi dun nitori mo nilati jẹ iru iya yii nitori iṣẹ ti o dara julọ. Mo ni ominira ti o pọ si ninu ọkan mi ná; nitori nikẹyin mo mọ wipe popu ni aṣodi si Kristi, ati pe itẹ rẹ, ti Satani funra rẹ ni.ANN 61.4

    Sibẹ aṣẹ Romu ni ipa tirẹ. Ọgba ẹwọn, ijiya, ati ida jẹ ohun elo ti o lagbara lati mu ni ṣe igbọran. Awọn ojo ati alaimọkan n wariri niwaju aṣẹ popu; nigba ti gbogbo eniyan n ṣe ikaanu fun Luther, ọpọlọpọ ni wọn ro wipe ẹmi ṣe pataki ju ki a fi wewu fun iṣẹ atunṣe lọ. O dabi ẹnipe ohun gbogbo n tọka si wipe iṣẹ Alatunṣe naa ti fẹ pari.ANN 61.5

    Ṣugbẹn sibẹ, Luther ko bẹru. Romu ti fi gegun, awọn eniyan si n woran, wọn n wo boya yoo ṣegbe tabi ki o yi ọrọ rẹ pada. Ṣugbọn pẹlu agbara nla, o ju ọrọ idalẹbi rẹ pada si, o si kede ipinu rẹ nigbangba lati jade kuro ninu idapọ rẹ titi lae. Niwaju awọn akẹkọ, ọmọwe, ati awọn ọmọ ilu gbogbo, Luther sun aṣẹ popu, pẹlu awọn iwe ofin ijọ, awọn iwe aṣẹ, ati awọn iwe miran ti wọn gbe agbara popu ró níná. O sọ wipe, “Awọn ọta mi ṣe ipalara si iṣẹ otitọ ninu ọkan awọn eniyan gbogbo nipa sisun awọn iwe mi nina, wọn si ṣe ipalara si ọkan wọn; nitori idi eyi, mo pa iwe wọn run pẹlu. Ijakadi alagbara ṣẹṣẹ bẹrẹ ni. Tẹlẹ mo si n ba popu ṣere ni. Mo bẹrẹ iṣẹ naa ni orukọ Ọlọrun; ki yoo si pari pẹlu mi, bikoṣe pẹlu agbara Rẹ.”ANN 61.6

    Luther fesi si ẹgan awọn ọta rẹ ti wọn sọ wipe iṣẹ rẹ ko lagbara wipe: “Tani o mọ bi Ọlọrun ko ba yan mi tabi pe mi, bi eyi ko ba bà wọn lẹru, nipa kikẹgan mi wọn kẹgan Ọlọrun funra Rẹ? Mose dá wà ni oun nikan ni nigba ti o kuro ni Ijipti; Elijah nikan ni o da wa nigba ijọba ọba Ahabu; Aisaya nikan ṣoṣo ni Jerusalẹmu; Isikiẹli nikan ṣoṣo ni Babiloni. . . . Ọlọrun ki i yan olori alufa, tabi eniyan nla kan gẹgẹ bi woli; ṣugbọn O saba maa n yan awọn ẹni rirẹlẹ, ti a kẹgan, O tilẹ yan oluṣọ-aguntan kan ri, Amosi. Ni gbogbo igba, awọn eniyan mimọ nilati ba awọn eniyan nla, awọn ọba, awọn ijoye, awọn alufa, ati awọn amoye wi, pẹlu ewu si ẹmi wọn. . . . Emi ko sọ wipe woli ni mi; ṣugbọn mo sọ ni pato wipe wọn nilati bẹru nitori pe mo wa ni emi nikan, ṣugbọn awọn pọ. Eyi damiloju wipe, ọrọ Ọlọrun wa pẹlu mi, ko si si ni ọdọ wọn.”ANN 61.7

    Sibẹ pẹlu ijakadi nla ninu ara rẹ ni o fi pinu lati kuro ninu ijọ patapata. Laarin akoko yii o kọwe wipe: “Lojoojumọ ni mo n mọ bi o ti nira to lati kọ awọn iwa ti eniyan ti gba lati ọmọde silẹ. Ah! O ti ni mi lara to, bi o tilẹ jẹ wipe mo ni Iwe Mimọ ni ẹbá ọdọ mi lati fi da ara mi lare wipe mo nilati duro ni emi nikan lati tako popu, ki n si ri gẹgẹ bi aṣodi si Kristi! Iru ijiya wo ni ọkan mi koi ti i jẹ tan! Ọpọ igba ni mo maa n beere lọwọ ara mi iru ibeere ti o saba maa n jade lati ẹnu awọn atẹle popu wipe: ‘Ṣe iwọ nikan ni o gbọn ni? Ṣe gbogbo eniyan wa le ṣe aṣiṣe? Bawo ni yoo ti ri nikẹyin bi o ba jẹ wipe iwọ ni o ṣe aṣiṣe, ti o si fa ọpọlọpọ awọn eniyan si inu aṣiṣe rẹ, tani yoo wa jẹbi ayeraye?’ Bayi ni mo ṣe n ba ara mi jijakadi pẹlu Satani titi ti Kristi fi fi okun kun ọkan mi lati tako awọn iyemeji wọnyi pẹlu ọrọ Rẹ ti ko le baku.”ANN 62.1

    Popu ti halẹ mọ Luther wipe bi ko ba yi ero rẹ pada, oun yoo le kuro ninu ijọ, bayi ati mu ileri naa ṣe. A tun pa aṣẹ miran, ti o yọ Alatunṣe naa kuro ninu Ijọ Romu patapata, ti o si fi ré gẹgẹ bi ẹni ifibu Ọrun, o fi orukọ gbogbo ẹni ti yoo ba gba ikọni rẹ kun. Ijakadi nla naa wa ṣẹṣẹ bẹrẹ.ANN 62.2

    Atako ni ipin gbogbo awọn ti Ọlọrun lo lati waasu awọn otitọ ti a nilo ni akoko wọn. Otitọ ti o ṣe pataki wa ni akoko Luther,—otitọ ti o ṣe pataki julọ ni akoko naa; otitọ ti o ṣe pataki tun wa fun ijọ loni. ANN 62.3

    Ẹni ti O n ṣe ohun gbogbo gẹgẹ bi ero ọkan Rẹ n fi eniyan sinu oriṣiriṣi ipo, yoo si fi ojuṣe ti o ṣe pataki ni akoko ti wọn n gbe ati ni ibi ti a fi wọn si han wọn. Bi wọn yoo ba mọ rírì imọlẹ ti a fi fun wọn, a yoo fi awọn otitọ ti wọn tobi ju eyi lọ han wọn. Ṣugbọn awọn eniyan ko fẹran otitọ loni gẹgẹ bi wọn ko ti fẹran rẹ ni akoko awọn atẹle popu ti wọn n ṣe atako Luther. Iru ifẹ kan naa lati gba ero ati ikọni eniyan dipo ọrọ Ọlọrun si wa gẹgẹ bi o ti wa ni igba iṣaaju. Awọn ti wọn n waasu otitọ ti o yẹ fun akoko yii ko gbọdọ reti wipe a yoo fi oju rere pupọ gba wọn ju bi a ti gba awọn alatunṣe ti iṣaaju lọ. Ijakadi nla laarin otitọ ati eke, laarin Kristi ati Satani yoo tubọ maa gbona si bi itan aye ti n lọ si opin.ANN 62.4

    Jesu sọ fun awọn ọmọ ẹyin Rẹ wipe: “Bi ẹyin ba n ṣe ti aye, aye yoo fẹran awọn eniyan tirẹ: ṣugbọn nitori ẹyin ki i ṣe ti aye, ṣugbọn mo ti yan yin kuro ninu aye, nitori naa ni aye fi korira yin. Ẹ ranti ọrọ ti Mo sọ fun yin, Iranṣẹ ki i tobi ju Oluwa rẹ lọ. Bi wọn ba ṣe inunibini si Mi, wọn yoo ṣe inunibini si yin pẹlu; bi wọn ba pa ọrọ Mi mọ, wọn yoo pa ti yin mọ pẹlu.” Johanu 15:19, 20. Oluwa tun sọ ọ kedere ni idakeji wipe: “Ègbé ni fun yin nigba ti gbogbo eniyan ba n sọrọ rere nipa yin! nitori bẹẹ ni awọn baba wọn ṣe si awọn woli èké.” Luku 6:26. Ẹmi aye ko si ni iṣọkan pẹlu ẹmi Kristi loni gẹgẹ bi ko ti ṣe wa ni igba iṣaaju, a ko si fi oju rere wo awọn ti wọn n waasu ọrọ Ọlọrun ninu iwa mimọ rẹ nisisinyi gẹgẹ bi a ko ti ṣe wo o nigba naa lọhun. Bi a ti ṣe atako si otitọ le yipada, ikorira naa le fi ara sin, ki o mà fi ara han sita kedere; ṣugbọn iru atako kan naa si wa, yoo si maa fi ara han titi fi di opin akoko.ANN 62.5

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents