Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents
ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORI KEJILELỌGBỌN—AWỌN IDẸKUN SATANI

    Ijakadi nla laarin Kristi ati Satani ti o ti bẹrẹ lati bi i ẹgbẹrun ọdun mẹfa sẹyin yoo pari laipẹ; eṣu n si n ṣe akitiyan rẹ ni ilọpo meji lati ko ibaku ba iṣẹ Kristi nitori eniyan ki o si de awọn ọkan mọ igbekun rẹ. Afojusun rẹ gan an ni lati di awọn eniyan mọ inu okunkun ati aironupiwada titi ti ibalaja Olugbala a fi pari, ti ki yoo si ẹbọ fun ẹṣẹ mọ.ANN 231.1

    Nigba ti a ko ba ṣe akitiyan kankan lati doju kọ agbara rẹ, nigba ti aibikita ba gbilẹ kan ninu ijọ ati aye, Satani ko ni janpata nitori ko si ewu ati padanu awọn ti o n mu ni igbekun ninu ifẹ rẹ. Ṣugbọn nigba ti a ba pe akiyesi si ohun ayeraye, ti awọn ọkan si n beere pe, “Kini mo le ṣe lati le ri igbala?” yoo wa nibẹ lati fi agbara rẹ dan ti Kristi wo ki o si ṣiṣẹ tako agbara Ẹmi Mimọ.ANN 231.2

    Iwe Mimọ sọ fun wa nibi kan wipe, nigba ti awọn angẹli Ọlọrun pejọ lati fi ara wọn han niwaju Ọlọrun, Satani pẹlu wa laarin wọn (Jobu 1:6), ki i ṣe lati wa tẹriba niwaju Ọba Ayeraye, ṣugbọn lati le tẹsiwaju ninu iṣẹ buburu rẹ si awọn olododo ni. Pẹlu iru ero kan naa ni o fi maa n wa nibi ti awọn eniyan ba ti pejọ fun ijọsin Ọlọrun. Bi o tilẹ jẹ wipe oju eniyan ko ri, o n ṣiṣẹ pẹlu gbogbo itara lati dari iye awọn olujọsin. Bi ọlọgbọn jagunjagun ni o ṣe n ṣe eto rẹ silẹ. Bi o ti n ri ti iranṣẹ Ọlọrun n wa inu Iwe Mimọ, a fiye si koko ọrọ ti a fẹ ba awọn eniyan sọ. Yoo wa lo gbogbo alumọkọrọyi ati ayinike rẹ lati le dari awọn iṣẹlẹ debi pe iṣẹ iranṣẹ naa ko ni de ọdọ awọn ti o n tanjẹ lori koko ọrọ naa. A yoo pe ẹni ti o nilo ikilọ naa julọ si ibi ti a ti nilo iduro rẹ, tabi nipasẹ ọna miran a yoo di lọwọ lati gbọ ọrọ ti yoo jẹ òórùn ìyè sí ìyè fun.ANN 231.3

    Ẹwẹ, Satani ri ti iranṣẹ Oluwa kun fun ẹdun ọkan nitori okunkun ẹmi ti o yi awọn eniyan ka. O gbọ adura atọkanwa fun oore ọfẹ ọrun ati agbara lati ja ide aikọbiarasi, aibikita ati ọlẹ. Pẹlu itara tuntun á tẹsiwaju ninu ète rẹ. A dan awọn eniyan wo lati tẹ ara wọn lọrun nipa eyi, a sọ ifura wọn di oku debi pe wọn ko nile gbọ ohun gan ti wọn nilo lati kọ julọ.ANN 231.4

    Satani mọ daradara wipe ipenija oun yoo bori gbogbo awọn ti oun ba le dari lati kọ adura ati wiwa Iwe Mimọ silẹ. Nitori naa o wa gbogbo ete ti o ṣe e ṣe lati fi kun inu ọkan eniyan. Ẹgbẹ kan saba maa n wa ti wọn sọ wipe wọn ni iwabiọlọrun, ṣugbọn dipo ki wọn tẹsiwaju lati maa mọ otitọ, wọn sọ ọ di ẹsin wọn lati maa wa aṣiṣe ninu iwa tabi ibaku ninu igbagbọ awọn ti wọn kò jijọ fi ohun ṣọkan. Iru awọn wọnyi jẹ oluranlọwọ pataki fun Satani. Awọn olufisun awọn ara ko kere rara, wọn si maa n mura ṣiṣẹ ni nigba ti Ọlọrun ba n ṣiṣẹ ti awọn iranṣẹ Rẹ si n fun Un ni ijọsin tootọ. Wọn yoo ṣe afihan ọrọ ati iwa awọn ti wọn fẹran otitọ ti wọn si n ṣe igbọran si ni ọna ti ko tọ. Wọn yoo fi iranṣẹ Kristi ti n ṣiṣẹ tọkantọkan, ti o ni itara ti o ni ẹmi isẹra ẹni han bi atannijẹ tabi ẹni ti a n tanjẹ. Iṣẹ wọn ni lati fi ero ọkan gbogbo iṣẹ otitọ ati iṣẹ rere han ni ọna ti ko tọ, wọn yoo ro ẹjọ eke, wọn yoo si ru ẹmi iṣọnilẹsẹ ninu ọkan awọn alaimọkan soke. Ni gbogbo ọna ti wọn ba le gba, wọn a wa lati mu ki eyi ti o mọ ti o si jẹ ododo o fi ara han bi ohun aimọ ati eke.ANN 231.5

    Ṣugbọn a ko nilati tan ẹnikẹni jẹ nipa wọn. A le ri ni kiakia iru ọmọ ẹni ti wọn n ṣe, iru apẹẹrẹ ẹni ti wọn n tẹle ati iṣẹ ẹni ti wọn n ṣe. “Nipa awọn eso wọn ni ẹ o fi mọ wọn.” Matiu 7:16. Iṣẹ wọn jọ ti Satani abanijẹ oloro, “olufisun awọn ara.” Ifihan 12:10.ANN 231.6

    Atannijẹ nla naa ni ọpọlọpọ awọn aṣoju ti wọn ṣetan lati gbe oriṣiriṣi ẹtan kalẹ lati mu ọkan ni igbekun—ẹkọ odi ti a ṣeto rẹ lati ba ifẹ ati agbara ẹni ti o ba fẹ parun mu. O jẹ eto rẹ lati mu awọn alaiṣotitọ ti wọn ko ni iyipada wa sinu ijọ ti wọn yoo ru iyemeji ati aigbagbọ soke, ki wọn si ṣe idiwọ fun gbogbo ẹni ti o ba ni ifẹ lati ri wipe iṣẹ Ọlọrun tẹsiwaju, ti wọn si n fẹ tẹsiwaju pẹlu rẹ. Ọpọlọpọ ti wọn ko ni igbagbọ tootọ ninu Ọlọrun tabi ninu ọrọ Rẹ gbagbọ ninu awọn abala otitọ kan, eyi si sọ wọn di Kristẹni, nipasẹ eyi wọn ni agbara lati mu eke wa gẹgẹ bi ikọni Iwe Mimọ.ANN 231.7

    Igbagbọ wipe ohunkohun ti eniyan ba gbagbọ ko ṣe pataki jẹ ọkan lara itanjẹ Satani ti o n ṣiṣẹ julọ. O mọ wipe gbigba otitọ nitori pe a fẹran otitọ maa n ya ọkan ẹni ti o gba a si mimọ; nitori naa o n ṣiṣẹ ni gbogbo igba lati fi ero ti ko tọna, itan asan ati iyinrere miran rọpo. Lati ibẹrẹ wa awọn iranṣẹ Ọlọrun ti n jijadu pẹlu awọn ẹlẹkọ eke, ki i ṣe bi oniwa buburu nikan ṣugbọn bi ẹlẹkọ eke ti o lewu fun ọkan. Elija, Jeremaya, Pọlu, pẹlu iduro gbọin ati aibẹru doju kọ awọn ti wọn n yi awọn eniyan pada kuro ninu ọrọ Ọlọrun. Iru ilawọ ti o ri gbogbo igbagbọ ẹsin tootọ bi eyi ti ko nitumọ ko ri aaye lọdọ awọn agbeja otitọ wọnyi.ANN 232.1

    Itumọ Bibeli pẹlu ironu eniyan ni ọna ti ko lẹsẹ nilẹ, ati ọpọlọpọ ẹkọ ti wọn n tako ara wọn nipa ẹsin igbagbọ, ti a ri ninu ẹsin Kristẹni loni jẹ iṣẹ ọta nla nì lati dabaru ọkan awọn eniyan ki wọn ma ba a le mọ otitọ. Ainirẹpọ ati iyapa ti o wa laarin awọn ijọ Kristẹni loni waye latari aṣa ti o gbode kan ti i ṣe ti lilo Iwe Mimọ ni ọna ati gbè lẹyin ironu ti wọn fẹran. Dipo ki wọn kọ ẹkọ ọrọ Ọlọrun finifini pẹlu irẹlẹ ọkan lati le ni oye imọ Rẹ, ọpọlọpọ n wa lati ri ohun kan ti ko boju mu tabi ti o jẹ tuntun.ANN 232.2

    Lati le fi idi ikọni eke tabi aṣa ti ki i ṣe ti Kristẹni wọn mulẹ, awọn miran a mu ẹsẹ Iwe Mimọ kuro ninu ayika rẹ, tabi ki wọn lo aabọ ẹsẹ kan lati fi idi ero wọn mulẹ nigba ti abala iyoku a fihan wipe itumọ naa jẹ idakeji rẹ patapata. Pẹlu ọgbọn arekereke ejò, wọn a fi ẹsẹ ara wọn mulẹ si abẹ awọn ọrọ ti ko jọ ara wọn ti a sọ lati ba ero ọkan awọn ti ko yipada mu. Nipa eyi, ọpọlọpọ n mọọmọ ṣi ọrọ Ọlọrun lo. Awọn miran ti iye wọn sọji daradara, lo awọn apẹẹrẹ ati ami inu Iwe Mimọ, wọn tumọ wọn lati ba asan inu wọn pade, lainaani ẹri wipe oun ni olutumọ ara rẹ, wọn a wa gbe ero inu wọn kalẹ gẹgẹ bi ikọni Bibeli.ANN 232.3

    Nigbakugba ti a ba kọ ẹkọ Iwe Mimọ laisi adura, irẹlẹ ati ẹmi ti o ṣe e kọ, ẹsẹ ti o farahan kedere ti ko si ni wahala ati eyi ti o nira ni a o lọ lọrun kuro ninu itumọ wọn tootọ. Awọn adari ijọ padi yan awọn abala Iwe Mimọ ti o ba erongba wọn mu, wọn tumọ wọn lati tẹ ara wọn lọrun, wọn wa gbe eyi ka iwaju awọn eniyan, nigba ti wọn ko fun wọn ni anfani lati kọ ẹkọ Bibeli ki wọn si ni oye otitọ mimọ rẹ funra wọn. Gbogbo Bibeli ni o yẹ ki a fifunni gẹgẹ bi o ṣe wa. A dara fun wọn lati maṣe ni ikilọ Bibeli rara ju ki wọn ni ikọni Iwe Mimọ ti a ṣi tumọ pupọpupọ lọ.ANN 232.4

    A funni ni Bibeli lati jẹ atọna fun gbogbo ẹni ti o fẹ lati mọ ifẹ Ẹlẹda wọn. Ọlọrun fun awọn eniyan ni ọrọ asọtẹlẹ ti o daju; awọn angẹli, ani Kristi funra Rẹ wa lati sọ fun Daniẹli ati Johanu awọn ohun ti yoo ṣẹlẹ laipẹ. A ko fi awọn koko ọrọ pataki wọnni ti wọn ni i ṣe pẹlu igbala wa silẹ laiṣe itumọ wọn. A ko fi wọn han ni ọna ti yoo fi fa iporuuru ọkan lati le ṣi ẹni ti n wa otitọ tọkantọkan lọna. Oluwa sọ nipasẹ woli Habakuku pe: “Kọ iran naa silẹ, ki o si jẹ ki o han kedere, . . . ki ẹni ti o ka a le sare.” Habakuku 2:2. Ọrọ Ọlọrun han kedere si gbogbo ẹni ti o ba kọ pẹlu ọkan adura. Gbogbo ọkan ti o jẹ olootọ pẹlu ododo ni yoo wa si imọlẹ otitọ. “A funrugbin imọlẹ fun awọn olododo.” O. Dafidi 97:11. Ko si ijọ kankan ti o le dagba ninu iwa mimọ laiṣe wipe awọn eniyan inu rẹ ba n fi tọkantọkan wa otitọ bi ohun alumọni ti o pamọ.ANN 232.5

    Pẹlu ariwo, ilawọ, awọn eniyan n fọ oju si awọn ete ọta wọn, nigba ti oun si n ṣiṣẹ nigba gbogbo lati ri afojusun rẹ. Bi o ti ṣe aṣeyọri ni fifi ironu eniyan rọpo Bibeli, a kọ ofin Ọlọrun silẹ, awọn ijọ si wa ni igbekun si ẹṣẹ nigba ti wọn n sọ wipe wọn wa ninu ominira.ANN 232.6

    Egun ni iwadi imọ ijinlẹ jẹ fun awọn miran. Ọlọrun gba ọpọ imọlẹ laaye lati tan si aye ninu awọn awari ninu imọ sayẹnsi ati ọgbọn; ani iyè ti o yè kooro julọ, ti ọrọ Ọlọrun ko ba tọ sọna ninu iwadi rẹ, yoo ṣina ninu akitiyan rẹ lati ṣe iwadi ibaṣepọ ti o wa laarin imọ ijinlẹ ati ifihan.ANN 232.7

    Oye eniyan nipa ohun ti ara ati ti ẹmi ko kun to, ko si pe; nitori idi eyi ọpọlọpọ ko le ri ibaṣepọ laarin ọrọ imọ sayẹnsi ati Iwe Mimọ. Ọpọlọpọ ni wọn gba ero ati idaba lasan gẹgẹ bi otitọ sayẹnsi, wọn si ro wipe a nilati dan ọrọ Ọlọrun wo pẹlu ikoni “ti a n fi eke pe ni imọ.” 1 Timoti 6:20. Ẹlẹda ati iṣẹ Rẹ kọja oye wọn; nitori ti wọn ko le ṣe alaye awọn nnkan wọnyi pẹlu ofin iṣẹda, wọn ri itan Bibeli bi eyi ti ko ṣe e fọkan tan. Awọn ti wọn ko fi ọkan tan awọn akọsilẹ Majẹmu Laelae ati Tuntun saba maa n tẹsiwaju lati ṣe iyemeji nipa iwalaaye Ọlọrun ti wọn si n fi agbara ainipẹkun fun iṣẹda. Nigba ti idakọro wọn ti sọnu, a fi wọn silẹ lati kọlu apata aigbagbọ.ANN 232.8

    Bayi ni ọpọ eniyan ṣe ṣina kuro ninu igbagbọ ti eṣu si ṣetan lati tan wọn jẹ. Awọn eniyan ṣe akitiyan lati gbọn ju Ẹlẹda wọn lọ; ọgbọn eniyan ti gbiyanju lati wa ohun ijinlẹ, ti wọn si fẹ alaye awọn ohun ti a ko ni fihan laelae. Bi awọn eniyan ba maa wa ohun ti Ọlọrun ti fihan nipa ara Rẹ ati erongba Rẹ, ki wọn si ni oye rẹ, wọn i ba ri ogo ọla nla, ati agbara Jehofa ti i ba mu ki wọn ri bi wọn ti kere to ti wọn i ba si jẹ ki ohun ti a fihan o to fun wọn ati fun awọn ọmọ wọn.ANN 233.1

    Olubori itanjẹ Satani ni lati jẹ ki eniyan o maa wadi, ki o si maa ronu lori ohun ti Ọlọrun ko fihan, ti ko si fẹ ki o ye wa. Eyi ni o mu ki Lusifa o padanu ipo rẹ ni ọrun. O di alainitẹlọrun nitori pe a ko sọ gbogbo aṣiri eto Ọlọrun fun, ko si bọwọ fun gbogbo eyi ti a fihan nipa iṣẹ nla ti a gbe le lọwọ rara. Nipa riru ẹmi ainitẹlọrun kan naa soke ninu awọn angẹli ti wọn wa labẹ akoso rẹ, o fa iṣubu wọn. Bayii o n wa lati fi iru ẹmi yii sinu ọkan eniyan ki o si dari wọn lati maṣe bọwọ fun ofin Ọlọrun.ANN 233.2

    Awọn ti wọn ko fe gba otitọ pọnbele inu Bibeli n fi gbogbo igba wa arosọ ti yoo pa ẹri ọkan wọn lẹnu mọ. Bi ikọni ti a gbe kalẹ ko ba ti ṣe jẹ ti ẹmi to, bi ko ba ti ṣe nilo isẹra-ẹni ati irẹra-ẹni-silẹ to, bẹẹ ni wọn a ṣe fi gbogbo agbara gba a to. Awọn wọnyi n ba agbara ọpọlọ wọn jẹ lati sin ifẹkufẹ ara. Wọn ti gbọn ju ninu ero wọn lati wa inu Iwe Mimọ pẹlu irẹlẹ ọkan ati adura tọkantọkan fun itọsọna Ọlọrun, wọn ko ni aabo kuro lọwọ itanjẹ. Satani ṣetan lati fun ọkan ni ohun ti o n fẹ, o si n fi itanjẹ le wọn lọwọ dipo otitọ. Bayi ni ijọ padi ṣe ni agbara lori ọkan awọn eniyan; nipa kikọ otitọ silẹ nitori ti o ni agbelebu, awọn Protestant n rin ọna kan naa. Gbogbo awọn ti wọn kọ ọrọ Ọlọrun silẹ lati wo irọrun ati iṣesi, ki wọn ma ba a wa ni ainirẹpọ pẹlu aye, yoo tẹwọgba ẹkọ odi patapata gbaa dipo otitọ ẹsin. Gbogbo eke ti a ba le ronu kan ni awọn ti wọn ba mọọmọ kọ otitọ silẹ yoo gba. Ẹni ti o ba fi ibẹru wo eke kan yoo gba omiran.ANN 233.3

    Apostoli Pọlu sọ nipa ẹgbẹ ti “ko gba ifẹ fun otitọ, ki a baa le gba wọn la,” o sọ wipe: “Nitori idi eyi Ọlọrun yoo ran ẹtan lile si wọn, ki wọn ba le gba eke gbọ; ki gbogbo awọn ti ko gba otitọ gbọ, ṣugbọn ti wọn ni inu didun ninu aiṣododo le di ẹni ègbé.” 2 Tẹsalonika 2:10—12. Pẹlu iru ikilọ yii niwaju wa o yẹ ki a wa ni iṣọra nipa iru ikọni ti a n gba.ANN 233.4

    Lara awọn iṣọwọṣiṣẹ atannijẹ ti o ṣiṣẹ julọ ni ikọni ẹtan ati irọ agbayanu ti ibẹmilo. O fi ara pamọ bi angẹli imọlẹ, o n ta ẹwọn rẹ kalẹ si ibi ti a ko lero. Bi awọn eniyan yoo ba kọ ẹkọ Iwe Ọlọrun pẹlu adura atọkanwa ki wọn baa le ni oye rẹ, a ko ni fi wọn sinu okunkun lati gba ẹkọ eke. Ṣugbọn bi wọn ba ṣe n kọ otitọ silẹ, wọn di ẹran ijẹ fun èké.ANN 233.5

    Itanjẹ buburu miran ni ikọni ti ko gba Kristi ni Ọlọrun, ti o n sọ wipe ko wa laaye ṣaaju ki O ti wa sinu aye yii. Awọn ẹgbẹ nla ti wọn sọ wipe wọn gba Bibeli gbọ fi oju rere wo ikọni yii; sibẹ o tako gbolohun kedere ti Olugbala wa sọ nipa ibaṣepọ Rẹ pẹlu Baba, iwabiọlọrun Rẹ, ati iwalaaye Rẹ ṣaaju ki O to wa saye. A ko le faaye gba a lailọ Iwe Mimọ lọrun lainidi. Ki i ṣe wipe o tabuku bi o ṣe yẹ ki a ri iṣẹ irapada nikan, ṣugbọn o jin igbagbọ wa ninu Bibeli gẹgẹ bi ifihan lati ọdọ Ọlọrun lẹsẹ. Nigba ti eleyi mu ki o lewu si, o tun jẹ ki o nira lati ṣe atako rẹ. Bi eniyan ba kọ ẹri Iwe Mimọ silẹ nipa bi Kristi ti jẹ Ọlọrun, lasan nipe a n ba wọn jiroro lori ọrọ naa, nitori ko si bi iṣọwọsọrọ naa ti le lagbara to, wọn ko ni gbagbọ. “Eniyan ti ara ko le gba awọn ohun ti i ṣe ti Ẹmi Ọlọrun: nitori pe wọn je ohun alailọgbọn ni oju rẹ: bẹẹ ni oun ko si le mọ wọn, nitori pe nipa Ẹmi ni a fi n wadi wọn.” 1 Kọrintin 2:14. Ko si ẹni ti o gba eke yii gbọ ti o le ni oye pipe nipa iwa tabi iṣẹ Kristi, tabi eto nla Ọlọrun fun irapada eniyan.ANN 233.6

    Ẹwẹ, eke miran ti o jẹ alarekereke, ti o tun nika ni igbagbọ ti o n tan kaakiri wipe ko si ẹda ti n jẹ Satani; wipe a tilẹ lo orukọ naa ninu Iwe Mimọ lati ṣe afihan ero ati ifẹ buburu inu eniyan lasan ni.ANN 234.1

    Ikọni ti a n waasu rẹ kikankikkan lati ori pẹpẹ iwaasu wipe ipadabọ Kristi lẹẹkeji ni wiwa si ọdọ enikọọkan nigba ti o ba ku, jẹ ete lati yi ọkan eniyan kuro ninu wiwa Rẹ ni eniyan ninu ikuuku awọsanma. Fun ọpọ ọdun, Satani ti n sọ wipe, “Kiyesi, O wa ninu iyẹwu” (Matiu 24:23—26), ọpọlọpọ ọkan ni wọn si ti ṣegbe nipa gbigba ẹtan yii.ANN 234.2

    Ọgbọn aye kọni wipe adura ko ṣe pataki. Awọn akẹkọ sayẹnsi sọ wipe ko le si idahun tootọ si adura; wipe eyi yoo jẹ riru ofin, yoo jẹ iṣẹ iyanu, ko si sí ohun ti o n jẹ iṣẹ iyanu. Wọn sọ wipe ofin ti ko ṣe e yipada ni o n dari gbogbo agbaye ati wipe Ọlọrun funra Rẹ ko le tako awọn ofin yii. Wọn fi Ọlọrun han gẹgẹ bi Ẹni ti ofin ara Rẹ dè—a fi bi ẹnipe iṣọwọṣiṣẹ ofin Ọlọrun ko faaye gba ominira Ọlọrun. Iru ikọni yii tako ẹri Iwe Mimọ. Ṣe Kristi ati awọn apostoli Rẹ ko ṣe iṣẹ iyanu bi? Olugbala alaanu kan naa ṣi wa laaye loni, O si ṣetan lati tẹti si adura igbagbọ, gẹgẹ bi O ti ṣe nigba ti O n rin laarin awọn eniyan. Ohun ti ara n ṣiṣẹ pẹlu ti ẹmi. O jẹ ara eto Ọlọrun lati fun wa, ni idahun si adura igbagbọ, ohun ti ko le fun wa bi a ko ba beere.ANN 234.3

    Jantirẹrẹ ni awọn ẹkọ eke ati ero ti ko lẹsẹ nilẹ ti a n ri ninu awọn ijọ Kristẹni. Ko ṣe e ṣe lati ṣiro ewu buburu ti o maa n tẹle mimu ọkan lara awọn aala ti ọrọ Ọlọrun fi lelẹ kuro. Diẹ lara awọn ti wọn ṣe eyi duro pẹlu kikọ ẹyọ otitọ kan ṣoṣo silẹ. Ọpọlọpọ tẹsiwaju lati kọ awọn ikọni otitọ silẹ lẹyọkọọkan titi ti wọn fi di alaigbagbọ pọnbele.ANN 234.4

    Awọn eke inu awọn ikoni ti wọn gbajugbaja ti sọ ọpọlọpọ ọkan ti wọn i ba jẹ onigbagbọ ninu Iwe Mimọ di oniyemeji. Ko ṣe e ṣe fun lati gba awọn ikọni ti ko ba oye rẹ nipa ododo, aanu ati inu rere mu, nigba ti a si ṣe alaye awọn wọnyi gẹgẹ bi ikọni Bibeli, o kọ lati gba a gẹgẹ bi ọrọ Ọlọrun.ANN 234.5

    Ohun ti Satani fẹ gan ni eleyi. Ko si ohun ti o fẹ ju ki o ba igbagbọ eniyan jẹ ninu Ọlọrun ati ọrọ Rẹ lọ. Satani jẹ olori awọn ẹgbẹgun nla oniyemeji, o si n ṣiṣẹ pẹlu gbogbo agbara rẹ lati tan awọn ọkan jẹ sinu ẹgbẹ rẹ. O ti n di ohun ọlaju lati ṣe iyemeji. Ẹgbẹ nla kan wa ti wọn fi aifọkantan wo ọrọ Ọlọrun nitori idi kan naa ti wọn fi wo Ẹni ti o kọ ọ—nitori ti o ba ẹṣẹ wọn wi, o si ṣe idalẹbi rẹ. Awọn ti wọn ko ṣetan lati ṣe igbọran si ọrọ Rẹ n ṣe akitiyan lati bi aṣẹ rẹ wó. Wọn n ka Bibeli, tabi wọn n tẹti si ikọni rẹ bi a ti n sọ ọ lati ori pẹpẹ iwaasu lati le ri aṣiṣe ninu Iwe Mimọ tabi ninu iwaasu lasan ni. Ki i ṣe awọn diẹ ni wọn di alaigbagbọ nitori ati le da ara wọn lare tabi lati le ṣe awawi nitori ojuṣe ti wọn ko ṣe. Awọn miran di oniyemeji nitori igberaga ati ọlẹ. Wọn fẹran faaji pupọ titi ti wọn ko fi le ṣe ohunkohun ti a o fi bu ọla fun wọn, eyi ti o nilo akitiyan ati isẹra-ẹni, wọn n wọna lati ni okiki fun ọgbọn nipa bibu ẹnu atẹ lu Bibeli. Ọpọlọpọ nnkan ni oye eniyan, ti ọgbọn ọrun ko mọlẹ si, ko ni agbara lati mọ, nitori idi eyi wọn ri idi lati ṣe awawi. Ọpọ wa ti wọn ri bi ohun ti o dara lati duro ninu aigbagbọ, iyemeji ati jijẹ keferi. Ṣugbọn labẹ inu rere wọn, a o ri wipe idara-ẹni-loju ati igberaga ni o n ti wọn lati wuwa. Ọpọ n fẹ lati ri ohun kan ninu Iwe Mimọ lati da ọkan ẹlomiran laamu. Awọn miran a kọkọ ṣe awawi, wọn a ronu ni ọna ti kotọ, nitori ti wọn fẹran ariyanjiyan. Wọn ko mọ wipe wọn n ti ara wọn bọ inu ikẹkun pẹyẹpẹyẹ ni. Nigba ti wọn si ti fi aigbagbọ wọn han, wọn ro wipe wọn nilati duro ninu ipo wọn. Nipa eyi wọn fi ọwọsowọpọ pẹlu awọn alaiwabiọlọrun wọn si ti ilẹkun Paradise mọ ara wọn.ANN 234.6

    Ọlọrun ti funni ni ẹri ti o to ninu ọrọ mimọ nipa imisi rẹ. A ṣe alaye kikun nipa awọn otitọ ti wọn ni i ṣe pẹlu irapada wa. Nipasẹ iranlọwọ Ẹmi Mimọ, eyi ti a ṣeleri fun gbogbo awọn ti wọn fi tọkantọkan wa, gbogbo eniyan le ni oye awọn otitọ wọnyi funra wọn. Ọlọrun ti fun awọn eniyan ni ipilẹ ti o lagbara ti wọn le gbe igbagbọ wọn le.ANN 234.7

    Sibẹ oye eniyan ko lagbara lati ni oye kikun nipa awọn eto ati erongba Ẹni Ailopin. A ko le ri Ọlọrun nipa iwadi laelae. A ko gbọdọ fi ọwọ ikugbu ṣi aṣọ loju iboju ti O fi bo ọlanla Rẹ. Apostoli sọ wipe: “Awamaridi ni idajọ Rẹ, ọna Rẹ si kọja ohun ti a n wari!” Romu 11:33. A le ni oye ibalo Rẹ pẹlu wa, ati idi ti o fi ṣe bẹ ẹ, ki a le ri ifẹ ati aanu ti ko lopin ti wọn sopọ mọ agbara ailopin. Baba wa ọrun n fi ọgbọn ati ododo dari ohun gbogbo, a ko si gbọdọ jẹ alainitẹlọrun ati alainigbẹkẹle, ṣugbọn ki a tẹriba tọwọtọwọ. Yoo fi eto Rẹ han wa ní bí ó ti dara fun wa lati mọ mọ, lẹyin eyi, a nilati gbẹkẹle Ọwọ ti o ni gbogbo agbara ati Ọkan ti o kun fun ifẹ.ANN 235.1

    Nigba ti Ọlọrun fun wa ni ọpọlọpọ idi lati gbagbọ, ko ni mu awawi fun aigbagbọ kuro lae. Gbogbo awọn ti n wa ohun ti wọn yoo fi iyemeji wọn kọ yoo ri. Ati awọn ti wọn kọ lati gba ati lati ṣe igbọran si ọrọ Ọlọrun titi ti a o fi dahun gbogbo ibeere, ti ko si ni si anfani fun iyemeji mọ ko ni wa si inu imọlẹ.ANN 235.2

    Ainigbẹkẹle ninu Ọlọrun jẹ ohun ti o boju mu fun ọkan ti a ko sọ dọtun, ti o wa ni iṣọta pẹlu Rẹ. Ṣugbọn Ẹmi Mimọ ni i mu igbagbọ wa, yoo si dagba bi a ti n nifẹ rẹ. Ko si ẹni ti o le jẹ alagbara ninu igbagbọ laisi iṣẹ atọkanwa. Aigbagbọ maa n lagbara si bi a ba ti n gba a laaye; bi awọn eniyan, dipo ki wọn duro lori ẹri tí Ọlọrun fifunni lati di igbagbọ wọn mu, ba gba ara wọn laaye lati maa beere ibeere, ki wọn si maa ṣe awawi eke, wọn a ri wipe awawi wọn a tubọ maa fẹsẹ mulẹ ni.ANN 235.3

    Ṣugbọn awọn ti wọn ṣeyemeji ninu awọn ileri Ọlọrun ti wọn ko gbẹkẹle idaniloju oore ọfẹ Rẹ n tabuku Rẹ; ipa wọn, dipo ki o fa awọn miran wa si ọdọ Kristi, saba maa n le wọn sa kuro ni ọdọ Rẹ ni. Wọn jẹ igi alaileso, ti wọn tan ẹka wọn kaakiri, ti wọn ko jẹ ki oorun o tan si awọn eweko miran, wọn rọ wọn si ku labẹ ojiji tutu. Iṣẹ aye awọn wọnyi duro gẹgẹ bi ẹri ti ko kaarẹ lati tako wọn. Wọn n gbin irugbin iyemeji ati aigbagbọ ti yoo mu ikore ti ko ni baku wa.ANN 235.4

    Ọna kan wa fun awọn tí wọn ko fẹ ni ohun kan ṣe pẹlu iyemeji lati inu ọkan wọn le rìn. Dipo ki wọn maa beere ki wọn si maa ṣe awawi eke nipa ohun ti ko ye wọn, jẹ ki wọn wo imọlẹ ti o n tan si ori wọn, wọn a si gba imọlẹ ti o tobi ju eyi lọ. Jẹ ki wọn ṣe ohun gbogbo ti o ye wọn, wọn yoo si ni agbara lati ni oye ati lati ṣe awọn ohun ti o n jẹ ki wọn ṣe iyemeji.ANN 235.5

    Satani le funni ni ayederu ti yoo jọ otitọ debi pe yoo tan awọn ti wọn ba fẹ jẹ, awọn ti wọn fẹ lati kọ isẹra-ẹni ati irubọ ti otitọ nilo silẹ; ṣugbọn ko ṣe e ṣe fun lati de ọkan kan ṣoṣo, ti o fi tọkantọkan fẹ lati mọ otitọ lai naani ohun ti yoo na, mọ abẹ agbara rẹ. Kristi ni otitọ ati “Imọlẹ, ti o mọlẹ si gbogbo ẹni ti o wa ninu aye.” Johanu 1:9. A ti ran Ẹmi otitọ lati dari gbogbo eniyan sinu gbogbo otitọ. Pẹlu aṣẹ Ọmọ Ọlọrun a sọ wipe: “Ẹ wa kiri ẹyin yoo si ri.” “Bi ẹnikẹni ba fẹ lati ṣe ifẹ Rẹ, yoo mọ ikọni Rẹ.” Matiu 7:7; Johanu 7:17.ANN 235.6

    Awọn ohun perete ni awọn atẹle Kristi mọ nipa awọn ete ti Satani ati awọn ọmọ ogun rẹ n pa si wọn. Ṣugbọn Ẹni ti o joko ninu ọrun yoo mu ki gbogbo awọn ete wọnyi o ṣiṣẹ fun eto ijinlẹ Rẹ. Oluwa n gba awọn eniyan laaye lati ri wahala gbigbona ti idanwo, ki i ṣe nitori ti O ni inu didun si ijya ati ipọnju wọn, ṣugbọn nitori pe wọn nilo rẹ, fun iṣẹgun wọn nikẹyin. Ni ibamu pẹlu ogo Rẹ, ko le daabo bo wọn kuro ninu idanwo nitori pe idi fun idanwo ni lati pese wọn silẹ lati le doju ija kọ gbogbo itanjẹ buburu.ANN 235.7

    Awọn eniyan buburu tabi awọn ẹmi aimọ ko le di iṣẹ Ọlọrun lọwọ, bẹẹ ni wọn ko le di awọn eniyan Rẹ lọwọ lati de ọdọ Rẹ, bi wọn ba fẹ, pẹlu ọkan irẹlẹ ti o kaanu fun ẹṣẹ, lati jẹwọ ẹṣẹ wọn ki wọn si kọ wọn silẹ, ki wọn si fi igbagbọ di ileri Rẹ mu. Gbogbo idanwo, gbogbo agbara itako, boya ni gbangba tabi ni ikọkọ ni a le bori, “ki i ṣe nipa ipa tabi agbara, ṣugbọn nipa Ẹmi Mi ni Oluwa awọn ọmọ ogun wi.” Sekaraya 4:6.ANN 235.8

    “Oju Oluwa wa lori awọn olododo, eti Rẹ si ṣi silẹ si adura wọn. . . . Tani yoo le ṣeyin nijamba, bi ẹyin ba n tẹle ohun ti o dara?” 1 Peteru 3:12, 13. Nigba ti Balamu, ẹni ti ileri ọrọ wọ loju, fẹ lo afọṣẹ si Israeli, ti o rubọ si Oluwa lati le fi awọn eniyan Rẹ gegun, Ẹmi Ọlọrun da ibi ti o fẹ sọ duro, Balamu si fi agidi kede: “Emi o ha ti ṣe fibu ẹni ti Ọlọrun ko fibu? tabi emi o ha ti ṣe fi ré ẹni ti Ọlọrun ko fi ré?” “Jẹ ki n ku iku olododo, si jẹ ki igbẹyin mi o dabi tirẹ!” Nigba ti o tun rubọ lẹẹkan si, woli alaiwabiọlọrun naa kede wipe: “Kiyesi mo ti gba aṣẹ lati sure: Oun si ti sure; emi ko si le yi pada. Oun ko ri ẹṣẹ ninu Jakọbu, bẹẹni ko ri iwa buburu ninu Israeli. Oluwa Ọlọrun rẹ wa pẹlu rẹ, ìhó Ọba si wa laarin rẹ.” “Nitootọ ko si asasi kan ti o le ran Jakọbu, bẹẹni ko si afọṣẹ ti o le ran Israeli: Nisinsinyii ni a o maa wi niti Jakọbu ati Israeli pe, Ohun ti Ọlọrun ti ṣe!” Sibẹ ni ẹẹkẹta a tun to awọn pẹpẹ, Balamu tun pete lati gegun. Ṣugbọn Ẹmi Ọlọrun kede ibukun awọn eniyan Rẹ lati ẹnu woli ti ko fẹ sọ ọ, o si ba iwa omugọ ati arankan ọta wọn wi: “Alabukun ni fun ẹni ti o bukun fun ọ, egun si ni fun ẹni ti o fi ọ gegun.” Numeri 23:8, 10, 20, 21, 23; 24:9.ANN 235.9

    Ni akoko yii awọn eniyan Israeli jẹ olootọ si Ọlọrun; niwọn igba ti wọn si tẹsiwaju ninu igbọran si ofin Rẹ, ko si agbara ninu aye tabi ni ọrun apaadi ti o le bori wọn. Ṣugbọn egun ti a ko gba Balamu laaye lati fi wọn ré ni o ṣe aṣeyọri lati mu wa sori wọn nipa titan wọn sinu ẹṣẹ. Nigba ti wọn ru ofin Ọlọrun, wọn ya ara wọn nipa kuro ni ọdọ Rẹ, a si fi wọn silẹ lati ni imọlara agbara apanirun.ANN 236.1

    Satani mọ daju wipe ọmọ ogun okunkun ko le doju kọ ọkàn ti o jẹ alaarẹ julọ ti o ba wa ninu Kristi, ati pe bi o ba yọ ara rẹ sita, a o doju kọ, a o si ṣẹgun rẹ. Nitori naa o n wa ọna lati fa awọn ọmọ ogun agbelebu kuro ni ibi aabo wọn, nigba ti o fi awọn agbara rẹ dènà de wọn, o si ṣetan lati pa ẹnikẹni ti o ba wọ inu ilẹ rẹ run. Ninu igbara le Ọlọrun pẹlu irẹlẹ nikan, ati igbọran si gbogbo ofin Rẹ ni a ti le ri aabo.ANN 236.2

    Ko si ẹni ti o ni aabo fun ọjọ kan tabi wakati kan laisi adura. Ni pataki julọ, o yẹ ki a ṣipẹ si Ọlọrun fun ọgbọn lati ni oye ọrọ Rẹ. Nibi ni a ti fi itanjẹ adanniwo, ati ọna ti a file bori rẹ pẹlu aṣeyege han. Satani jẹ amoye ninu kika Iwe Mimọ, tí á si ṣe itumọ awọn ẹsẹ rẹ bi o ti fẹ, nipasẹ eyi ti o ro lati gbe wa ṣubu. A nilati kọ Bibeli pẹlu irẹlẹ ọkan, ki a maṣe gbagbe wipe a nilati gbe ara le Ọlọrun. Nigba ti a nilati ṣọra fun awọn ete Satani nigba gbogbo, a nilati maa gbadura pẹlu igbagbọ loorekoore pẹlu: “Maṣe tì wa sinu idanwo.”ANN 236.3

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents