Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents
ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORI KEJILA—IṢẸ ÀTUNṢE NI ORILẸ-EDE FRANCE

    Awọn akoko ogun ati okunkun ni wọn tẹle ifẹhonuhan ti Spires ati ijẹwọ ni Augsburg, awọn iṣẹlẹ ti wọn jẹ ami iṣẹgun iṣẹ Atunṣe ni Germany. Iyapa laarin awọn atẹle rẹ sọ ọ di alailagbara, ọta alagbara si n gbéja kò o, o dabi ẹnipe a yoo pa ẹsin Protestant run patapata. Ọpọ awọn eniyan ni wọn fi ẹjẹ wọn ṣe edidi si ijẹri wọn. Ogun abẹle bẹ silẹ; ọkan lara awọn aṣaju ninu ẹsin Protestant tu aṣiri rẹ; ẹni ti o gbayi julọ ninu awọn ijoye ti wọn gba igbagbọ ti a tunṣe ṣubu si ọwọ ọba, o si n wọ lati ilu de ilu bi ẹlẹwọn. Ṣugbọn ni akoko iṣẹgun rẹ yii, ọba ri ijakulẹ. O ri ti a gba ẹlẹwọn rẹ kuro ni ọwọ rẹ, o wa di dandan fun lati ni ifarada fun ikọni ti o jẹ wipe erongba ọjọ aye rẹ ni lati parun. O ti fi ijọba rẹ, ohun ini rẹ, ati ẹmi ara rẹ wewu nitori pe o fẹ pa ẹkọ odi run. O ri pe a ti fi awọn ọmọ ogun rẹ ṣofo ninu ogun, ohun ini rẹ ti gbalọ tan, ọpọ awọn ilẹ ijọba rẹ si n mura lati ṣọtẹ, nigba ti igbagọ ti o n ṣiṣẹ lasan lati parun n tan kalẹ ni ibi gbogbo. Charles V n ba agbara ti o ju gbogbo agbara lọ ja. Ọlọrun ti sọ wipe, “Jẹ ki imọlẹ ki o wa,” ṣugbọn ọba naa ko fẹ ki okunkun o lọ. Ète rẹ baku; o di arugbo laitọjọ, wahala fun igba pipe ti sọ di ogbó, o fi itẹ silẹ, o lọ ti ara rẹ mọ inu ile awọn ajẹjẹ ẹsin.ANN 93.1

    Ni Switzerland, gẹgẹ bi o ti ṣẹlẹ ni Germany, awọn akoko okunkun de si iṣẹ Atunṣe. Bi o tilẹ jẹ wipe ọpọ awọn agbegbe ni wọn ti gba igbagbọ ti a tun ṣe, sibẹ awọn miran si fi aimọkan di mọ igbagbọ Romu. Bi wọn ti ṣe inunibini si awọn ti wọn fẹ lati gba otitọ wa yọri si ogun abẹle. Zwingli ati ọpọ awọn ti wọn darapọ mọ ninu iṣẹ atunṣe ni wọn ṣubu ninu ogun gbigbona ti Cappel. Wahala yii pọju fun Oecolampadius, laipẹ o ku. Romu di aṣẹgun, ni ibi pupọ, o dabi ẹnipe o fẹrẹ ri ohun gbogbo ti o ti padanu gba pada. Ṣugbọn Ẹni ti imọran Rẹ wa lati irandiran ko kọ iṣẹ tabi awọn eniyan Rẹ silẹ. Ọwọ Rẹ yoo fun wọn ni itusilẹ. Ni awọn ibomiran, O n gbe awọn oṣiṣẹ dide lati tẹsiwaju ninu iṣẹ atunṣe naa.ANN 93.2

    Ṣaaju ki a to gbọ orukọ Luther gẹgẹ bi Alatunṣe, ọjọ ti bẹrẹ si nii yọ ni France. Ọkan lara awọn ti wọn kọkọ ri imọlẹ naa ni Lefevre; o ti di arugbo; o jẹ ẹni ti o kawe gan an, ọjọgbọn ninu ile ẹkọ giga ti Paris, o si jẹ ẹni ti o fi tọkantọkan ati itara tẹlẹ ẹsin popu. Nigba ti o n ṣe iwadi lori awọn iwe igba atijọ, ọkan rẹ lọ si ara Bibeli, o si fihan fun awọn akẹkọ rẹ.ANN 93.3

    Lefevre jẹ ẹni ti o fi tayọtayọ n jọsin awọn eniyan mimọ, o si mura lati kọ itan awọn eniyan mimọ ati awọn ajẹriku gẹgẹ bi a ti fifunni ninu itan ijọ. Iṣẹ yii nilo wahala pupọ; ṣugbọn o ti ṣe e de ibi ti o ni apẹẹrẹ, nigba ti o ro wipe oun le ri iranlọwọ daradara ninu Bibeli, o bẹrẹ si nii kọ pẹlu ero yii lọkan. O ri awọn eniyan mimọ bi wọn ti ri gan an nibi, ṣugbọn ki i ṣe bi iwe ijọ Romu ti sọ. Imọlẹ ọrun rọ wọ inu iye rẹ. Pẹlu iyalẹnu ati itiju, o yipada kuro ninu iṣẹ ti o fun ara rẹ ṣe yii o si fi ara rẹ jin fun ọrọ Ọlọrun. O bẹrẹ si nii kọni ni awọn otitọ iyebiye ti o ri.ANN 93.4

    Ni 1512, ṣaaju ki Luther tabi Zwingli to bẹrẹ iṣẹ atunṣe, Lefevre kọwe wipe: “Ọlọrun ni o n fun wa ni ododo naa ti o n dawalare nipa oore ọfẹ nikan ṣoṣo si iye ainipẹkun nipa igbagbọ.” Nigba ti o n ronu lori awọn ohun ijinlẹ irapada, o sọ wipe: “Ah titobi pasiparọ naa ko ṣe e fi ẹnu sọ,—a da Alailẹṣẹ lẹbi ti ẹlẹbi si lọ lọfẹẹ; Ibukun gba egun, a si mu egun wa sinu ibukun; Iye ku, oku si ye; okunkun bo Ogo mọlẹ, ẹni ti ko si mọ ohunkohun ayafi itiju wa ninu ogo.”ANN 93.5

    Nigba ti o n kọni wipe ogo igbala jẹ ti Ọlọrun nikan ṣoṣo, o tun sọ wipe ojuṣe igbọran jẹ ti eniyan. O sọ wipe, “Bi iwọ ba jẹ ọmọ ijọ Kristi, iwọ di ẹya ara Rẹ; bi iwọ ba di ara Rẹ, nitori naa iwọ kun fun ẹda ọrun. . . . Ah, bi awọn eniyan ba le ni oye anfani yii, igbesi aye wọn yoo ti jẹ mimọ, alailabawọn, ati alailẹṣẹ tó, bawo ni gbogbo ogo aye yii yoo ti jẹ ẹlẹgbin to nigba ti a ba fi we ogo inu wọn,—ogo naa ti oju ẹran ara ko le ri.”ANN 93.6

    Awọn kan wa lara awọn akẹkọ Lefevre ti wọn n fi tọkantọkan tẹti si ọrọ rẹ, wọn yoo tẹsiwaju lati maa kede otitọ lẹyin ọpọ ọdun ti ohùn olukọ naa ba dakẹ. Iru wọn ni William Farel. Ọmọ awọn obi onifọkansin, ti a kọ lati gba awọn ikọni ijọ pẹlu igbagbọ bi ọmọde, o le sọ gẹgẹ bi Pọlu ti sọ nipa ara rẹ wipe: “Gẹgẹ bi ẹya isin wa ti o le julọ ti n ṣe Farisi ni emi.” Iṣe 26:5. O ṣe ẹsin Romu tọkantọkan, o si kun fun itara lati pa gbogbo awọn ti wọn ba gboya lati tako ijọ run. O sọ ni ọjọ iwaju nigba ti o n sọ nipa abala yii ninu igbesi aye rẹ wipe, “Maa pa eyín mi keke bi ìkooko ti o n binu nigba ti mo ba gbọ ti ẹnikan ba sọrọ tako popu.” Ko kaarẹ ninu bi o ti n jọsin awọn eniyan mimọ, pẹlu Lefevre, wọn a maa yi awọn ile ijọsin ti wọn wa ni Paris kiri, wọn a maa jọsin lori pẹpẹ, wọn a si maa fi ẹbun ṣe awọn ojubọ mimọ lọṣọ. Ṣugbọn awọn iṣẹ wọnyi ko le mu alaafia ọkan wa. Idalẹbi ẹṣẹ ko fi i silẹ, gbogbo iṣẹ idariji ti o ṣe ko le mu u kuro. Bi ohùn ti o wa lati ọrun, o tẹti silẹ si ọrọ Alatunṣe naa: “Nipasẹ oore ọfẹ ni igbala.” “A da alailẹṣẹ lẹbi, a si tu ọdaran silẹ.” “Agbelebu Kristi nikan ṣoṣo ni o ṣi ilẹkun ọrun, ti o si ti ilẹkun ipo oku.ANN 94.1

    Farel fi tayọtayọ gba otitọ naa. Pẹlu iyipada ọkan ti o dabi ti Pọlu, o yiju kuro ninu igbekun aṣa wa si ominira awọn ọmọ Ọlọrun. “Dipo ọkan apaniyan bii ti ikooko ti n ṣiwere,” o pada wa sọ pe, “bi ọdọ aguntan ọlọkan tutu ti ko le ṣeni nijamba, o gba ọkan rẹ kuro lọdọ popu patapata, o si fifun Kristi.”ANN 94.2

    Bi Lefevre ti n tẹsiwaju lati tan imọlẹ naa laarin awọn akẹkọ rẹ, Farel, onitara ninu iṣẹ Kristi gẹgẹ bi o ti ṣe ninu iṣẹ popu, jade lati kede iṣẹ naa ni gbangba. Oloye ijọ kan, bisobu ti Meaux, darapọ mọ wọn laipẹ. Awọn olukọ miran ti wọn ti goke agba nitori ẹbun ati ẹkọ wọn darapọ mọ wọn lati kede iyinrere, o si ni awọn atẹle laarin gbogbo eniyan, lati ile awọn oniṣẹ ọwọ ati aroko titi de aafin ọba. Arabinrin ọba Francis I, ọba ti o jẹ ni igba naa gba igbagbọ ti a fọ mọ yii. Ọba funra rẹ, ati iya iyawo ọba fi oju rere wo o fun igba diẹ, pẹlu ireti nla awọn Alatunṣe n wo igba ti a yoo jeere France wa si inu iyinrere.ANN 94.3

    Ṣugbọn ireti wọn ko ni wa si imuṣẹ. Ijiya ati inunibini ni o n duro de awọn ọmọlẹyin Kristi. Ṣugbọn pẹlu aanu, a bo eyi kuro ni oju wọn. Akoko alaafia wa ki wọn baa le ri okun lati pade wahala; iṣẹ Atunṣe si n gbilẹ ni kiakia. Biṣọbu ti Meaux ṣiṣẹ takuntakun lati kọ awọn eniyan ati awọn alufa ni agbegbe rẹ. O mu awọn alufa alaimọkan ati oniwa ibajẹ kuro, bi o ba si ti ṣe ṣe e ṣe to a fi awọn ti wọn mọwe, ati olufọkansin rọpo. Biṣọbu naa fẹ ki awọn eniyan naa o ni ọrọ Ọlọrun funra wọn, o si ṣe eyi kankan. Lefevre ṣe itumọ Majẹmu Tuntun; ni akoko naa gan an ti Bibeli Luther ni ede Germany n jade kuro ninu ile itẹwe ni Wittenberg, a n tẹ Majẹmu Tuntun ni ede French jade ni Meaux. Biṣọbu naa ṣe ohun gbogbo ti o yẹ ti o tun na owo lati ri wipe o wa kaakiri agbegbe rẹ, laipẹ, awọn agbẹ ni Meaux ni Iwe Mimọ.ANN 94.4

    Bi arinrin ajo ti n ṣegbe lọ nitori ongbẹ ti n fi ayọ wo orisun omi, bẹẹ gẹgẹ ni awọn ọkan wọnyi ṣe gba iṣẹ iranṣẹ lati ọrun. Awọn oṣiṣẹ ninu oko, awọn oniṣẹ ọwọ ni ibi iṣẹ wọn, n fi ayọ kun iṣẹ ojumọ wọn nipa sisọ nipa awọn otitọ ti wọn ṣe iyebiye to wa ninu Bibeli. Ni aṣalẹ, dipo ki wọn lọ si ile ọti, wọn a pejọ pọ sinu ile ara wọn lati ka ọrọ Ọlọrun, wọn a si jumọ parapọ ninu adura ati iyin. Iyatọ nla fi ara han ninu awọn ileto wọnyi. Bi o tilẹ jẹ wipe wọn jẹ otoṣi, awọn ti ko kẹkọ, ti wọn jẹ agbẹ, agbara oore ọfẹ Ọlọrun ti n yini pada, ti si n gbeni soke fi ara han ninu aye wọn. Onirẹlẹ, onifẹ, ati oniwa mimọ, wọn duro gẹgẹ bi ẹlẹri si ohun ti iyinrere le ṣe fun awọn ti wọn ba fi tọkantọkan gba a.ANN 94.5

    Itansan ina ti a tan ni Meaux rin jinna gan an ni. Ojoojumọ ni iye awọn ti wọn n yipada n pọ si. Ibinu awọn alaṣẹ ijọ ko fi ara han fun igba diẹ nitori pe ọba kẹgan aimọkan awọn ajẹjẹ ẹsin; ṣugbọn nikẹyin awọn adari ijọ padi ri ohun ti wọn n fẹ. A gbe igi isuninina ro. A fi ipa mu biṣọbu ti Meaux lati yan ninu ina tabi ki o yi ohun rẹ pada, o yan eyi ti o rọrun ju; ṣugbọn pẹlu iṣubu adari yii, awọn agbo rẹ si duro ṣinṣin. Ọpọlọpọ ni wọn jẹri fun otitọ ninu ina. Pẹlu igboya ati iduroṣinṣin wọn ninu ina, awọn Kristẹni onirẹlẹ wọnyi ba ọpọ awọn ti koi tii gbọ ijẹri wọn ri ni akoko alaafia sọrọ.ANN 94.6

    Ki i ṣe awọn alaini ati awọn otoṣi nikan ni wọn gboya lati jẹri fun Kristi laarin ijiya ati ẹgan. Ninu gbọngan ile iṣọ ati ni aafin, a ri awọn ọkan pataki ti otitọ ṣe iyebiye loju wọn ju ọrọ, ipo, ani ati ẹmi funra rẹ lọ. Aṣa ọba fi ẹmi giga ati ẹmi iduroṣinṣin han ju aṣọ ati fila biṣọbu lọ. Louis ti Berquin ti ile ti o dara jade wa. O jẹ jagunjagun onigboya o tun mọ iwaawu ni aafin, o fi ara rẹ jin fun ẹkọ, o ni iṣesi ti o wuni, iwa rẹ si jẹ alailabawọn. Onkọwe kan sọ wipe, “O fi tọkantọkan tẹle ofin ijọ padi, o si nifẹ lati gbọ mass ati iwaasu; . . . o de iwa rẹ lade nipa kikorira ẹsin Luther pẹlu ikorira ti o yatọ.” Ṣugbọn bii ti ọpọ awọn eniyan yoku, Ọlọrun dari rẹ si Bibeli, o si ya a lẹnu wipe “ki i ṣe ikọni Romu, ṣugbọn titi ti Luther” ni o wa nibẹ. Lati akoko naa lọ, o fi ara rẹ jin fun iṣẹ iyinrere.ANN 94.7

    “Ẹni ti o mọwe julọ ninu gbogbo awọn ijoye France,” ijafafa ati isọrọjageere rẹ, igboya ti kii baku ati itara akikanju rẹ, ati agbara rẹ ninu aafin,—nitori pe ọba fẹran rẹ,— jẹ ki gbogbo eniyan o ri gẹgẹ bi ẹni ti a yan lati jẹ Alatunṣe fun orilẹ ede rẹ. Beza sọ wipe: “Berquin i ba jẹ Luther keji, bi o ba ṣe wipe o ri afọbajẹ keji ninu Francis I.” Awọn ẹlẹsin padi n kigbe wipe, “O buru ju Luther lọ.” Awọn ẹlẹsin Romu ni France bẹru rẹ ju u lọ ni tootọ. Wọn sọ ọ sinu ọgba ẹwọn gẹgẹ bi ẹlẹkọ odi, ṣugbọn ọba tu u silẹ. Fun ọpọ ọdun, ijakadi naa n tẹsiwaju. Francis n ṣiyemeji laarin Romu ati iṣẹ Atunṣe, o si n fi ara da itara gbigbona awọn ajẹjẹ ẹsin ni igba miran, a tun da wọn lẹkun ni igba miran. Ẹẹmẹta ni awọn alaṣẹ ijọ padi ju Berquin sinu ọgba ẹwọn, ṣugbọn ọba n tu silẹ, nitori ti o fẹran ijafafa ati iwa rere rẹ, o kọ lati fi silẹ fun arankan awọn oloye ijọ.ANN 95.1

    A ki Berquin nilọ nipa iru ewu ti o le wu u ni France, a si rọ ọ lati tẹle iṣiṣẹ awọn ti wọn wa aabo nipa mimọọmọ kuro ni ile. Erasmus ti i ṣe ojo ati arirebanijẹ, pẹlu iyi ikẹkọ rẹ, o baku ninu iwa akikanju o kọ lati ri ẹmi ati ipo bi ohun ti o kere si otitọ, o kọwe si Berquin wipe: “Beere ki a ran ọ gẹgẹ bi aṣoju ọba lọ si orilẹ ede miran; rin irin ajo lọ si Germany. O mọ Beda ati iru awọn eniyan bii tirẹ — o jẹ ẹranko buburu olori popu ti n yọ oró ni gbogbo ara. Legioni ni orukọ awọn ọta rẹ n jẹ. Bi igbagbọ rẹ ba ju ti Jesu Kristi lọ, wọn ko ni jẹ ki o lọ titi ti wọn yoo fi pa ọ ni ipa ailaanu. Maṣe ni igbẹkẹle pupọ ninu aabo ọba. Ninu ohun gbogbo, maṣe gba mi niyanju pẹlu ikọni nipa ọrọ Ọlọrun.”ANN 95.2

    Ṣugbọn bi ewu ti n pọ si, bẹẹ ni itara Berquin naa n lokun si. Dipo ki o gba imọran ati ọgbọn arirebanijẹ ti Erasmus, o pinu lati ṣe awọn ohun ti o gboya si ni. Kii ṣe wipe a gbeja otitọ nikan, ṣugbọn yoo tun ṣe atako èke. Ẹsun ẹkọ odi ti awọn ẹlẹsin Romu fi kan an ni o yi le wọn lori pada. Awọn ti wọn ṣe akitiyan ti wọn si korò julọ ninu awọn ọta rẹ ni awọn ọmọwe ati awọn ajẹjẹ ẹsin ti ẹka ti n kọ nipa Ọlọrun ninu ile ẹkọ giga nla ti Paris, ọkan ninu aṣẹ ti o ga julọ ninu ilu ati orilẹ ede naa. Lati inu iwe awọn ọmọwe wọnyi, Berquin yọ awọn koko ọrọ mejila eyi ti o kede ni gbangba pe wọn “tako Bibeli, ti wọn si jẹ ẹkọ odi;” o si parọwa si ọba lati jẹ onidajọ lori ariyanjiyan naa.ANN 95.3

    Ọba yara kankan fi agbara ati ijafafa awọn ẹgbẹ mejeeji yii we ara wọn, ti inu rẹ si dun wipe oun ni anfani lati sẹ igberaga awọn alufa ọlọkan giga wọnyi rọ, o sọ fun awọn ẹlẹsin Romu lati fi Bibeli gbeja ara wọn. Wọn mọ daradara wipe ohun ija yii ko le ran wọn lọwọ pupọ; itimọle, ifiyajẹni, ati isuninina ni ohun ija ti wọn le lo daradara. Bayi ni iṣẹlẹ ṣe yipada ti awọn funra wọn ri wipe wọn ti fẹ ṣubu sinu koto ti wọn fẹ ju Berquin si. Pẹlu iyalẹnu, wọn wa ọna abayọ fun ara wọn.ANN 95.4

    “Ni akoko naa gan ni a ba ère Wundia ti o wa ni ẹba adugbo kan jé.” Irọkẹkẹ nla bẹ silẹ ninu ilu. Ọpọ awọn eniyan ni wọn lọ sibẹ lati ṣọfọ ti wọn si binu. Eyi mu ọba lọkan pupọpupọ. Eyi si jẹ anfani ti awọn ajẹjẹ ẹsin le lo daradara, wọn si yara kankan lati lo o. Wọn kigbe wipe, “Ayọrisi awọn ikọni Berquin niyii.” “Iṣọtẹ awọn atẹle Luther yii yoo fẹrẹ doju ohun gbogbo bolẹ—ẹsin, ofin, ani itẹ funra rẹ.”ANN 95.5

    A tun mu Berquin lẹẹkan si. Ọba kuro ni Paris, bayi ni a ṣe fi awọn ajẹjẹ ẹsin silẹ lati ṣe ifẹ inu wọn. A ṣe igbẹjọ Alatunṣe naa a si da ẹjọ iku fun; ki Francis ma baa tun wa gba a silẹ, a mu idajọ naa ṣẹ ni ọjọ naa gan an ti a ṣe. A mu Berquin lọ si ibi ti wọn a ti pa ni ọsan. Ọpọ eniyan ni wọn pejọ lati wo iṣẹlẹ naa, wọn n woye pẹlu iyalẹnu ati iyemeji wipe a mu ẹlẹṣẹ naa lati inu awọn ti wọn dara julọ ti wọn si gboya julọ lati inu awọn ile oloye ni France. Iyalẹnu, ibinu, ẹgan, ati ikorira kikoro kun oju awọn ero ti wọn pejọ naa; ṣugbọn ibanujẹ ko si ni oju ẹnikan nibẹ. Ero ajẹriku naa jinna rere kọja iṣẹlẹ idarudapọ ibẹ yẹn; ohun ti o mọ ni wipe Oluwa wa pẹlu oun.ANN 95.6

    Ẹranko didoti tí o gùn, ibojujẹ awọn oninunibini rẹ, iku ẹlẹru ti yoo ku—ko kọbi ara si awọn wọnyi; Ẹni ti o wa laaye, ti O ku, ti O si tun wa laaye titi lae, ti O si ni kọkọrọ ipo oku wa lẹgbẹ rẹ. Oju Berquin tan pẹlu imọlẹ ati alaafia ọrun. O wọ aṣọ daradara, o wọ “aṣọ àrán, aṣọ ìlekè satin ati ṣéda alarabara, ati ṣokoto oniwura.” O fẹ jẹri si igbagbọ rẹ niwaju Ọba awọn ọba ati gbogbo agbala aye ti n woran, ko si si ibanujẹ naa bi o tile kere to ti yoo ba ayọ rẹ jẹ.ANN 96.1

    Bi iwọde naa ti n lọ diẹdiẹ laarin awọn adugbo ti wọn kun fun ero, awọn eniyan ṣe akiyesi pẹlu iyalẹnu, alaafia ti o han kedere, ati ayọ iṣẹgun ti o han ni oju ati irisi rẹ. Wọn sọ wipe, “O dabi ẹniti o joko ninu tẹmpili, ti o n ṣe aṣaro lori awọn ohun mimọ.”ANN 96.2

    Ni ibi idanasunni, Berquin gbiyanju lati ba awọn eniyan sọrọ diẹ; ṣugbọn awọn alufa ajẹjẹ ẹsin bẹru ohun ti o le yọri si, wọn bẹrẹ si ni pariwo, ti awọn jagunjagun si n lu ohun ija wọn papọ mọ ara wọn, ariwo naa bo ohùn ajẹriku naa mọlẹ. Bayi ni awọn ọlaju ati alaṣẹ ijọ ni ilu ọlaju Paris ni 1529 ṣe “ṣe apẹẹrẹ ti ko boju mu lati maa bo ọrọ pataki ẹni ti n ku lọ mọlẹ ni ibi iṣekupani fun awọn eniyan ni ọdun 1793.”ANN 96.3

    A yi Berquin lọrun, a si dana sun un. Iroyin iku rẹ ko ibanujẹ ba awọn ọrẹ iṣẹ Atunṣe kaakiri ilẹ France. Ṣugbọn apẹẹrẹ rẹ ko parẹ. Awọn ẹlẹri fun otitọ sọ wipe, “Awa naa ṣetan lati fi ayọ koju iku, nipa gbigbe oju wa si igbesi aye ti n bọ.”ANN 96.4

    Ni akoko inunibini ni Meaux, a ko fun awọn olukọ igbagbọ ti a tunṣe ni anfani lati waasu, wọn si lọ si awọn ibomiran. Lẹyin igba diẹ, Lefevre lọ si Germany. Farel pada si ilẹ abinibi rẹ ni iha ila oorun France lati lọ tan ina imọlẹ kaakiri ni ilu ti o gbe dagba. Wọn ti gbọ iroyin ohun ti o n ṣẹlẹ ni Meaux, awọn eniyan si tẹti silẹ si otitọ ti o fi n kọni pẹlu itara ati igboya. Laipẹ awọn alaṣẹ ilu taji lati pa lẹnu mọ, a si le kuro ninu ilu naa. Bi o tilẹ jẹ wipe ko le ṣiṣẹ ni ita gbangba mọ, o lọ si awọn abule ati ileto, o si n kọ awọn eniyan ninu ile wọn ati ninu igbo; o n gbe ninu igbo ati laarin iho okuta, nibi ti o saba maa n lọ ni igba ewe rẹ. Ọlọrun n pese rẹ silẹ fun awọn idanwo ti o tobi si ni. O sọ wipe, “Agbelebu, inunibini, ati ete Satani, ti a ti ki mi nilọ nipa wọn ṣaaju ko baku, wọn tilẹ nira ju eyi ti mo le fi ara da lọ; ṣugbọn Ọlọrun ni Baba mi; O n fun mi, yoo si maa fun mi ni okun ti mo nilo.”ANN 96.5

    Gẹgẹ bi o ti ṣẹlẹ ni igba awọn apostoli, inunibini “wa yọri si ilọsiwaju iyinrere.” Filipi 1:12. A le wọn kuro ni Paris ati Meaux, “awọn ti a fọnka naa si lọ si ibi gbogbo, wọn n waasu ọrọ naa.” Iṣe 8:4. Bayi ni imọlẹ naa ṣe ri ọna wọ ọpọlọpọ agbegbe ti wọn jijina rere ni ilẹ France.ANN 96.6

    Ọlọrun si n pese awọn oṣiṣẹ lati mu ki iṣẹ rẹ o lọsiwaju. Ninu ọkan lara awọn ile ẹkọ ti wọn wa ni Paris ni ọdọ ti o nironu, ti o si ni ẹmi idakẹjẹ kan wa, o n ṣe afihan iye ti o yè kooro, o si le ronu jinlẹ, a mọ ọ fun iwa ailẹgan, ọpọlọ ti o ja fafa, ati ifọkansin ẹsin rẹ. Ijafafa ati iwuwasi rẹ sọ ọ di ohun amuyangan fun ile ẹkọ rẹ laipẹ, a si n fi idaniloju n nireti wipe John Calvin yoo jẹ ọkan ninu awọn olugbeja ijọ ti o jafafa, ti o si lọla julọ. Ṣugbọn itansan imọlẹ ọrun tan si Calvin, ani laarin ogiri ẹkọ eniyan ati igbagbọ asan ti o wa. O gbọ nipa awọn ikọni tuntun naa pelu iwariri, o si gbagbọ wipe awọn elekọ odi yẹ fun ina ti a fi n sun wọn. Sibẹ laimọ, o fi oju koju pẹlu ẹkọ odi, o wa di dandan fun lati dan agbara ikọni Romu wo nipa fifi ba ikọni Protestant ja.ANN 96.7

    Ibatan Calvin kan, ẹni ti o ti darapọ mọ awọn Alatunṣe, wa ni Paris. Awọn ibatan mejeeji yii saba maa n pade, wọn si maa n jiroro lori awọn ohun ti wọn n damu ẹsin Kristẹni. Olivean ti i ṣe Protestant sọ wipe, “Oriṣi ẹsin meji pere ni o wa laye.” Abala ẹsin kan ni eyi ti awọn eniyan gbe kalẹ, ninu eyi ti eniyan n gba ara rẹ la nipa iṣẹ isin ati iṣẹ rere; ekeji ni ẹsin kan ṣoṣo ti a fihan ninu Bibeli, eyi ti o n kọ eniyan lati maa wọna fun igbala lati ọdọ oore ọfẹ Ọlọrun nikan ṣoṣo.”ANN 96.8

    Calvin sọ wipe, “Mi o ni ohunkohun ṣe pẹlu ikọni tuntun rẹ; ṣe o ro wipe mo ti wa ninu aṣiṣe ninu gbogbo ọjọ aye mi ni?”ANN 97.1

    Ṣugbọn ero kan dide ninu ọkan rẹ, eyi ti ko le mu kuro pẹlu agbara rẹ. O ronu lori ọrọ ibatan rẹ yii ni ohun nikan ninu yara rẹ. O ni imọlara idalẹbi ẹṣẹ; o ri ara rẹ niwaju Adajọ mimọ ati olododo laini olubalaja. Ibalaja awọn eniyan mimọ, awọn iṣẹ rere, awọn isin ijọ, gbogbo wọn ko lagbara lati mu ẹṣẹ kuro. Ko ri ohunkohun niwaju rẹ ayafi okunkun ainireti ayeraye. Lasan ni awọn ọmọwe ijọ ṣe akitiyan lati tán isoro rẹ. Ijẹwọ ẹṣẹ, iṣẹ ironupiwada ti o ṣe ko mu ere kankan wa. Wọn ko le ba ọkan laja pẹlu Ọlọrun.ANN 97.2

    Nigba ti o si n ṣe iṣẹ ainitumọ rẹ yii, Calvin ni anfani ni ọjọ kan lati ṣe abẹwo si ibi ojutaye kan, o ri bi wọn ti n dana sun ẹlẹkọ odi kan. Ẹnu ya a nigba ti o ri alaafia ti o fi ara han ni oju ajẹriku naa. Laarin ijiya iku oró, ati labẹ idalẹbi inira ijọ, o fi igbagbọ ati igboya han, eyi ti akẹkọ ti o jẹ ọdọ yii fi we okunkun ati ainireti ara rẹ, nigba ti o n gbe ni igbọran ti o nira julọ si ofin ijọ. O mọ wipe lori Bibeli ni awọn ẹlẹkọ odi gbe igbagbọ wọn le. O pinu lati kẹkọ rẹ, ki o si ṣe awari, bi o ba ṣe e ṣe, aṣiri ayọ wọn.ANN 97.3

    Ninu Bibeli, o ri Kristi. O kigbe wipe, “Baba irubọ Rẹ ti tu ibinu Rẹ loju; ẹjẹ Rẹ ti fọ abawọn mi danu; agbelebu Rẹ ti ru egun mi; iku Rẹ ti ṣe imukuro ẹṣẹ mi. A ti wa ọpọlọpọ iwa omugọ ti ko ni itumọ fun ara wa, ṣugbọn Iwọ gbe ọrọ Rẹ siwaju mi bi imọlẹ, Iwọ si fi ọwọ bami ni ọkan, ki n le korira gbogbo iṣẹ miran ayafi ti Kristi nikan ṣoṣo.”ANN 97.4

    Calvin kẹkọ lati di alufa. Nigba ti o jẹ ọmọ ọdun mejila pere, a yan an lati jẹ oniwaasu ni ile ijọsin kekere kan, ti biṣọbu si ti fa ori rẹ ni ibamu pẹlu ofin ijọ. Ko gba iyasimimọ, bẹẹ ni ko ṣe ojuṣe ti o yẹ fun awọn alufa, sibẹ o di ọkan ninu awọn ẹgbẹ alufa, o ni orukọ ti o rọ mọ ipo yii, o si n gba owo ti o tọ nitori rẹ.ANN 97.5

    Ni akoko yii, nigba ti o ro wipe oun ko le di alufa, o lọ kọ nipa ofin, ṣugbọn lẹyin-ọrẹyin, o fi eyi silẹ, o wa lọ fi ẹmi rẹ jin fun iyinrere. Ṣugbọn o lọra lati di olukọ ni gbangba. O maa n tiju, ojuṣe ipo naa si di ẹru wuwo ru u, o wa pinu lati si maa kẹkọ na. Nikẹyin, o gba ipẹ awọn ọrẹ rẹ. O sọ wipe, “O jẹ ohun iyanu ki ẹni ti ko lokiki o de iru ipo nla yii.”ANN 97.6

    Laisi ariwo, Calvin bẹrẹ iṣẹ rẹ, awọn ọrọ rẹ si dabi iri ti n tu ilẹ lara. O ti kuro ni Paris, o wa ni ileto kan ti o wa labẹ aabo ọmọ ọbabinrin Margaret, ẹni ti o fẹran iyinrere, ti o si daabo bo awọn atẹle rẹ. Calvin si jẹ ọdọ, oniwapẹlẹ ti ko lágbaja. O bẹrẹ iṣẹ rẹ pẹlu awọn eniyan ninu ile wọn. Awọn ara ile a yii ka, yoo ka Bibeli, yoo si sọ awọn otitọ igbala. Awọn ti wọn gbọ iṣẹ iranṣẹ naa sọ iyinrere naa fun awọn miran, laipẹ olukọ naa kuro ninu awọn ilu lọ si awọn ileto ati abule ti wọn wa ni ayika. Ati ile iṣọ, ati ahéré ni o wọ, o si tẹsiwaju lati fi ipilẹ awọn ijọ ti yoo ni awọn ajẹri onigboya fun otitọ lelẹ.ANN 97.7

    Lẹyin osu diẹ, o pada si Paris. Ariyanjiyan ti o yatọ bẹ silẹ laarin agbo awọn ọmọwe ati olukọ. Ẹkọ ede atijọ dari awọn eniyan si Bibeli, ti ọpọlọpọ ti ko mọ itumọ otitọ rẹ si n fi gbogbo agbara ṣe alaye rẹ, ani ti wọn tun n ba awọn akikanju ninu ẹsin Romu ṣe ariyanjiyan. Bi o tilẹ jẹ wipe Calvin jẹ alariyanjiyan ti o kunju oṣuwọn ninu ẹkọ nipa Ọlọrun, o ni iṣẹ lati ṣe, eyi ti o ga ju ti awọn akẹkọ alariwo yii lọ. A ti ta awọn eniyan lọpọlọ ji, akoko si ti to lati ṣe alaye otitọ fun wọn. Nigba ti ariyanjiyan nipa ẹkọ nipa Ọlọrun n gba gbọngan awọn ile ẹkọ giga kan, Calvin n lọ lati ile de ile, o n ṣi Bibeli fun awọn eniyan, o si n sọ fun wọn nipa Kristi, ati Ẹni ti a kan mọ agbelebu.ANN 97.8

    Ninu iṣeto Ọlọrun, Paris yoo tun gba ipẹ miran lati gba iyinrere. A ti kọ ipẹ Lefevre ati ti Farel silẹ, ṣugbọn gbogbo awọn eniyan inu ilu nla naa yoo tun gbọ iṣẹ iranṣẹ naa lẹẹkan si. Nitori ọrọ oṣelu, ọba koi tii ṣe ipinu lati kin Romu lẹyin ni atako si iṣẹ Atunṣe. Margaret si ni ireti wipe ẹsin Protestant yoo ṣẹgun ni France. O pinu wipe a nilati waasu igbagbọ ti a fọmọ yii ni Paris. Nigba ti ọba ko si nile, o paṣẹ ki awọn oniwaasu Protestant o waasu ninu awọn ile ijọsin ti wọn wa ninu ilu naa. Nitori ti awọn oloye ijọ padi ko faaye gba eyi, ọmọ ọba naa wa ṣi aafin silẹ. A sọ gbọngan kan di ile ijọsin, a si ṣe ikede wipe lojoojumọ, laarin akoko ti a yan, a yoo maa waasu, gbogbo eniyan ni a pe laika ipo wọn si. Ọpọ eniyan ni wọn wọ lọ si ibi isin naa. Ki i ṣe ile ijọsin naa nikan, ṣugbọn ati awọn gbọngan ti wọn doju kọ ọ ni wọn kun fọfọ. Ọgọọrọ awọn eniyan ni wọn n pejọ lojoojumọ—awọn ijoye, oloṣelu, amofin, oniṣowo, ati awọn oniṣẹ ọwọ. Dipo ki ọba o dawọ apejọ yii duro, o paṣe ki a ṣi ile ijọsin meji silẹ ni Paris. Ọrọ Ọlọrun koi tii mi ilu naa bayẹn ri. Ẹmi iye lati ọrun wa mi si awọn eniyan. Iwọntuwọnsi, iwa mimọ, ibọwọfun ofin, ati imura siṣẹ n gba ipo iwa ọmuti, ailekora-ẹni-nijanu, ija ati ọlẹ.ANN 97.9

    Ṣugbọn awọn oloye ijọ ko kawọ gbinra. Sibẹ ọba ko jẹ ki a da iwaasu naa duro, wọn wa yiju si awọn eniyan. Ko si ohun ti wọn ko ṣe tan lati ru ibẹru, aimọkan, ati igbonara awọn eniyan alaimọkan ati ti wọn gba erokero gbọ soke. Ni gbigba awọn olukọ eke rẹ gbọ laironu, Paris, bi i Jerusalemu ko mọ igba ibẹwo rẹ, tabi awọn ohun ti wọn ni i ṣe pẹlu alaafia rẹ. Fun ọdun meji, a waasu ọrọ Ọlọrun ninu olú ilu naa; ṣugbọn nigba ti ọpọ awọn eniyan gba iyinrere, eyi ti o pọju ninu awọn eniyan ni wọn kọ ọ silẹ. Francis fi ara han gẹgẹ bi onifarada lati mu ero rẹ ṣẹ ni, awọn atẹle popu n ni agbara si. Lẹẹkan si, a ti ilẹkun awọn ile ijọsin, a tun gbe igi idanasunni ro.ANN 98.1

    Calvin si wa ni Paris, o n kẹkọ, o n ṣe aṣaro, o si n gba adura lati pese ara rẹ silẹ fun iṣẹ ọjọ iwaju rẹ, bẹẹ ni o si n tan imọlẹ naa ka. Nikẹyin, ara bere si ni fu u. Awọn alaṣẹ pinu lati sun un nina. O ro wipe oun ni aabo ninu ibi ti o sapamọ si, ko ro nipa ewu, nigba ti awọn ọrẹ rẹ yára wa sinu yàrá rẹ pẹlu iroyin wipe awọn iranṣẹ ilu n bọ lati fipa mu. Ni akoko naa ni a gbọ ti wọn n kan ilẹkun ita. Ko si akoko lati fi ṣofo. Diẹ lara awọn ọrẹ rẹ da awọn alaṣẹ duro lẹnu ọna, nigba ti a gbe Alatunṣe naa sokalẹ lati oju ferese, o si yara salọ si igun ilu naa. O ri aabo ni ile oṣiṣẹ kan ti i ṣe ọrẹ iṣẹ atunṣe, o fi ara rẹ pamọ ninu aṣọ ẹni ti o gba a sile, o gbe ọkọ si ejika, o si bẹrẹ irin ajo rẹ. O lọ si iha guṣu, o tun ri aabo ninu ijọba Margaret lẹẹkan si.ANN 98.2

    O duro fun oṣu diẹ nibi, o wa lailewu labẹ aabo awọn ọrẹ rẹ ti wọn jẹ alagbara, o tun bẹrẹ si ni i kọ ẹkọ rẹ bi i ti iṣaaju. Ṣugbọn ọkan rẹ fẹ lati jere ọkan France, ko si fẹ wa laiṣiṣẹ fun igba pipẹ. Ni kete ti iji naa dawo duro diẹ, o wa ibi iṣẹ tuntun miran si Poitiers, ti ile ẹkọ giga kan wa, ti wọn ti fi oju rere wo igbagbọ tuntun yii. Awọn eniyan lati ibi gbogbo fi ayọ tẹti si iyinrere. Ko si iwaasu ita gbangba, ṣugbọn ninu ile alaṣẹ agba ilu naa, ninu ile ara rẹ, ati nigba miran ninu ọgba ilu, Calvin a waasu ọrọ iye ainipẹkun fun awọn ti wọn ba fẹ lati gbọ. Lẹyin igba diẹ, bi iye wọn ti n pọ si, wọn ri wipe ko si ewu bi wọn ba pejọ pọ si òde ilu naa. Iho ilẹ kan wa ni ẹba ibi tooro, ti o jinlẹ kan, nibi ti igi ati awọn apata ti wọn wa ni oke rẹ jẹ ki o fi ara sin daradara, ibẹ ni a yan fun ibi ipade. Awọn ẹgbẹ kekeeke n gba orisirisi ọna kuro ni ilu lati debẹ. A ka Bibeli soke, a tun ṣe alaye rẹ ninu ibi ti o fara sin yii. Awọn Protestant ni France jẹ onjẹ alẹ Oluwa fun igba akọkọ nibẹ. Lati inu ijọ kekere yii a ran awọn ajiyinrere olufọkansin diẹ jade.ANN 98.3

    Calvin tun pada si Paris lẹẹkan si. Koi tii sọ ireti nu wipe France gẹgẹ bi orilẹ ede yoo tẹwọ gba iṣẹ Atunṣe. Ṣugbọn o ri wipe ko si aye lati ṣiṣẹ rara, lati kọni ni iyinrere jẹ ọna taara lọ si ibi isunni nina, nikẹyin, o pinu lati lọ si Germany. Ko pẹ ti o kuro ni France ti iji kan bọ lu awọn Protestant, eyi ti o jẹ wipe, bi o ba si wa nibẹ ni, i ba bá iparun naa lọ.ANN 98.4

    Awọn Alatunṣe France, ninu itara wọn lati ri ki orilẹ ede wọn o wa nibi kan naa pẹlu Germany ati Switzerland, wọn pinu lati ṣe atako si awọn ẹkọ eke Romu, eyi ti yoo ta gbogbo orilẹ ede naa ji. Nitori naa, a lẹ iwe ti o ṣe atako mass mọ gbogbo France ni ọjọ kan. Dipo ki o jẹ ki iṣẹ atunṣe o tẹsiwaju, awọn ẹgbẹ onitara ti ko mọ eto yii, mu iparun wa, ki i ṣe si ori awọn ti n waasu rẹ nikan, ṣugbọn si ori awọn ọrẹ igbagbọ ti a fọ mọ ni gbogbo ilẹ France. O fun awọn ẹlẹsin Romu ni ohun ti wọn ti n wa fun igba pipẹ—ohun ti yoo mu ki wọn beere fun iparun awọn ẹlẹkọ odi patapata gẹgẹ bi oniwahala ti o lewu si alaafia itẹ ati ti ilu.ANN 98.5

    Nipasẹ awọn ti a ko mọ kan—boya ọrẹ ti ko mọ ohun ti o yẹ ni, tabi, ọta alarekereke, a ko mọ—a lẹ ọkan lara awọn iwe pelebe yii mọ ilẹkun yara ọba. Ikorira ọba ru soke. A ṣe atako igbagbọ eke ijọ ti a ti n bọwọ fun fun ọjọ pipẹ wá lailaanu ninu iwe yii. Igboya ti ko ṣe e tẹle ti o mu iru awọn otitọ ti wọn janilaya wọnyi wa siwaju ọba bi ọba ninu gidigidi. O duro pẹlu iyalẹnu fun igba diẹ, o n wariri laile sọrọ. O wa sọrọ pẹlu ibinu wipe: “Ẹ mu gbogbo ẹni ti ẹ ba funra si wipe o jẹ atẹle Luther. Maa pa gbogbo wọn run laiku ẹyọ kan.” A ti ṣe ipinu ná. Ọba ti pinu nikẹyin lati duro si ẹgbẹ Romu patapata.ANN 99.1

    Lọgan ni a bẹrẹ eto fun itimọle gbogbo awọn atẹle Luther ni Paris. Oniṣẹ ọwọ otoṣi kan, ti o gbagbọ ninu igbagbọ ti a tunṣe ti o saba maa n pe awọn onigbagbọ lọ si ibi kọlọfin wọn ti wọn ti n pejọ pọ, ni a mu, pẹlu ihalẹ wipe yoo ku loju ẹsẹ nibi ti a ti n suni nina, a pasẹ ki o mu awọn aṣoju ijọ padi lọ si ile gbogbo awọn Protestant to wa ninu ilu naa. Inu bi nitori ibeere buburu yii, ṣugbọn nikẹyin ibẹru ina bori rẹ, o si gba lati tu aṣiri awọn arakunrin rẹ. Wọn gbe akara mass siwaju, awọn ẹgbẹ alufa, agbé turari, awọn alufa ajẹjẹ ẹsin, rọgba yii ka, awọn jagunjagun, Morin, awọn ọtẹlẹmuyẹ ọba, pẹlu afinihan naa rọra n lọ laarin ilu naa ni idakẹjẹ. Ohun ti o jọ ni oju awọn eniyan ni wipe wọn n bọwọ fun “akara mimọ” lati le mu iwa ẹgan ti awọn ti n fi ẹhonu han wu si kuro. Ṣugbọn erongba buburu ni wọn fi pamọ si abẹ afihan yii. Bi wọn ba ti de ile atẹle Luther kan, afinihan naa a fun wọn ni ami kan, ṣugbọn ko ni sọrọ. Iwọde naa á duro, wọn a wọ inu ile naa lọ, wọn a wọ awọn idile naa sita wọn a si fi ẹwọn dè wọn, iwọde buburu yii a tun tẹsiwaju lati lọ wa olujiya miran. Wọn “kò dá ilé kankan si, ẹni nla tabi ẹni kekere, titi de ori awọn olukọ ile ẹkọ giga ti Paris. . . . Morin mi ilu naa tìtì. . . . Akoko ibẹru ni.”ANN 99.2

    A pa awọn olujiya naa pẹlu ijiya buburu, nitori ti a sọ wipe ki ina naa maṣe gbona ju ki irora wọn le pẹ si. Ṣugbọn wọn ku gẹgẹ bi aṣẹgun. Iduroṣinṣin wọn ko yẹ, alaafia wọn ko ṣokunkun. Awọn ti n ṣe inunibini si wọn ko ni agbara lati mi iduroṣinṣin wọn, wọn ri wipe wọn baku. “A pin ohun ifiyajẹni kaakiri gbogbo Paris, ti wọn si n sunni nina lojoojumọ, wọn pa ète yii lati le tan ibẹru ẹkọ odi kálẹ nipa titan ijiya rẹ kalẹ. Ṣugbọn iyinrere ni o ri anfani nikẹyin. Gbogbo ilu Paris ri iru awọn eniyan ti igbagbọ tuntun naa mu sita. Ko si pẹpẹ iwaasu ti o dabi ina ti n sun awọn ajẹriku. Ayọ alaafia awọn eniyan wọnyi fi ara han ni oju wọn bi wọn ti n kọja lọ . . . si ibi ti a yoo ti pa wọn, iwa akikanju wọn bi wọn ti wa laarin ina gbigbona, ki i ṣe igba diẹ ni o yi ibinu pada si ikaanu, ikorira di ifẹ, o si jẹ ẹri ti a ko le ta danu fun iyinrere.”ANN 99.3

    Awọn ti wọn ti pinu lati maṣe jẹ ki ibinu awọn eniyan o sẹrọ, fi awọn oriṣiriṣi ẹsun kan awọn Protestant. A fi ẹsun kan wọn wipe wọn n pète lati pa gbogbo ọmọ ijọ Katoliki, lati doju ijọba bolẹ, ati lati pa ọba. Ko si ohunkohun ti wọn le fi fi ìdi awọn ẹsun wọnyi mulẹ. Sibẹ awọn asọtẹlẹ wọnyi yoo wa si imuṣẹ; ṣugbọn labẹ iṣẹlẹ miran, ohun ti yoo fa a yoo si jẹ idakeji si eyi. Awọn iwa ika ti awọn Katoliki n wu si awọn Protestant alaiṣẹ n ko ara wọn jọ pọ fun igbẹsan, ni ọjọ iwaju yoo si ṣe iparun naa gan an ti wọn sọtẹlẹ si ori ọba, ijọba rẹ, ati si ori awọn ọmọ ijọba rẹ; ṣugbọn awọn alaigbagbọ ati awọn atẹle popu funra wọn ni yoo muṣẹ. Ki i ṣe ifilọlẹ ẹsin Protestant, bikoṣe bi a ti ṣe tẹẹri, ni o fa awọn ijamba nla wa si ori France ni ọgọrun ọdun mẹta lẹyin eyi.ANN 99.4

    Ifunra si, aifọkantan, ati ibẹru wa gba gbogbo ilu kan. Ninu ibẹru ti o wọpọ yii, a ri bi ikọni Luther ti gbilẹ to laarin awọn ti wọn tayọ ninu ẹkọ, okiki ati iwa rere. Lojiji a dede ri wipe ipo iyi ati ifọkantan ṣofo. Awọn oniṣẹ ọwọ, awọn tẹwetẹwe, awọn olukọ, awọn ọjọgbọn ninu ile ẹkọ giga, awọn onkọwe, ani ati awọn iranṣẹ ni aafin ọba poora.ANN 99.5

    Ọpọlọpọ sa kuro ni Paris, wọn sọ ara wọn di isansa kuro ni ilẹ abinibi wọn, ni ọpọ igba, eyi kọkọ fihan wipe wọn fi oju rere wo igbagbọ ti a tunṣe naa. Awọn atẹle popu wo ayika wọn pẹlu iyalẹnu nitori awọn ẹlẹkọ odi ti a ko fiyesi ti wọn fi aaye gba ni aarin wọn. Wọn yi oju ibinu wọn si ori awọn ọpọ eniyan ti wọn jẹ otoṣi to wa ni ikawọ wọn ti wọn le fiyajẹ. Awọn ọgba ẹwọn kun, afẹfẹ si dudu nitori eefin ina ti n jo, ti a tan nitori awọn ti wọn jẹwọ iyinrere.ANN 99.6

    Francis I yin ara rẹ wipe oun jẹ adari ninu ẹgbẹ nla fun iṣoji ẹkọ, eyi ti o bẹẹrẹ ni ọrundun kẹrindinlogun. Inu rẹ dun lati ko awọn ọmọwe lati gbogbo orilẹ ede jọ si aafin rẹ. Ifẹ rẹ fun ẹkọ ati ikorira rẹ fun aimọkan ati igbagbọ ninu asan awọn ajẹjẹ ẹsin ni o fa a, ni ọna diẹ, bi a ti fi ara da iṣẹ atunṣe. Ṣugbọn pẹlu itara lati fa ẹkọ odi tu, ẹni ti o fẹran ẹkọ yii pa aṣẹ ti o sọ wipe ki a pa iṣẹ iwe titẹ rẹ kuro ni France! Francis I jẹ ọkan lara ọpọlọpọ awọn apẹẹrẹ ti a kọ silẹ ti o fihan wipe ọlaju iwe ki i ṣe aabo fun ainifarada ẹsin ati inunibini.ANN 100.1

    Nipa eto itagbangba ti o ṣe pataki kan, France yoo fi ara rẹ jin patapata lati pa ẹsin Protestant run. Awọn alufa beere wipe ki a mu iwa ọyaju ti a wu si Ọrun nipa bibu ẹnu atẹ lu mass kuro nipasẹ ẹjẹ, ki ọba si fi ọwọ si iṣẹ laabi yii ni orukọ gbogbo ilu.ANN 100.2

    January 21, 1535 ni a yan fun ayẹyẹ buburu yii. A ru ibẹru alaimọkan ati ikorira itara alaimoye gbogbo orilẹ ede naa soke. Paris kun fun ọpọlọpọ awọn eniyan ti wọn wa lati gbogbo agbegbe ti wọn yi ka; wọn kun inu awọn adugbo rẹ. Ọjọ naa yoo bẹrẹ pẹlu iwọde nla pataki kan. “A ta aṣọ ọfọ mọ awọn ile ti iwọde naa yoo gba iwaju wọn kọja, ti awọn pẹpẹ si duro lati ibuṣọ de ibuṣọ.” A tan ina siwaju gbogbo ilẹkun ni ibọwọ fun “ami majẹmu mimọ.” Ki oju to mọ, awọn oluwọde ti pejọ si aafin ọba. “Awọn asia ati agbelebu awọn agbegbe rẹ ni wọn kọkọ kọja; lẹyin eyi awọn ara ilu, wọn n rin ni mejimeji, wọn si gbe atupa si ọwọ wọn.” Awọn ẹgbẹ ajẹjẹ ẹsin mẹrẹẹrin tẹle, olukuluku wọn ninu aṣọ idanimọ wọn. Lẹyin eyi ni ọpọlọpọ awọn ère ti wọn lokiki. Lẹyin eyi ni awọn ijoye inu ijọ ti wọn wọ aṣọ elese aluko ati aṣọ alawọ pupa ati awọn ohun iṣeralọṣọ, aṣọ daradara ti n dan.ANN 100.3

    “Biṣọbu Paris ni o gbe mass naa labẹ ibori igunwa nla, . . . ti awọn ijoye ẹjẹ mẹrin dìmú. . . . Ọba n rin bọ lẹyin mass naa. . . . Francis I ko de ade, tabi wọ aṣọ igunwa ni ọjọ naa.” Pẹlu “ori rẹ ti o ṣi silẹ, oju rẹ ti n wo ilẹ, ati abẹla kan ni ọwọ rẹ,” ọba France fi ara han “bi ẹni ti n ṣe ikaanu fun ẹṣẹ.” O tẹriba ni irẹlẹ lẹba gbogbo pẹpẹ, ki i ṣe fun awọn iwa ibi ti wọn ko idọti ba ọkan rẹ, tabi fun ẹjẹ awọn alaiṣẹ ti wọn dọti ọwọ rẹ, ṣugbọn fun ẹṣẹ buburu awọn ọmọ ijọba rẹ, ti wọn ni igboya lati ṣe atako mass. Ayaba ati awọn ijoye ilu tẹle, awọn naa n rin ni mejimeji pẹlu atupa lọwọ wọn.ANN 100.4

    Gẹgẹ bi ara eto ọjọ naa, ọba funra rẹ ni o ba awọn ijoye nla inu ijọba naa sọrọ ninu gbọngan nla ti o wa ni aafin biṣọbu. O duro niwaju wọn ni irisi ẹni ti n ṣọfọ, o ṣe idaro “iwa ọdaran, isọrọ odi, ọjọ ibanujẹ ati itiju” ti o wa si ori orilẹ ede wọn ni ọna ti o wọnilọkan. O si pe gbogbo eniyan ilu lati ṣe iranwọ lati pa ẹkọ odi onirira ti o n fi iparun ṣẹruba France run. O sọ wipe, “Bi mo ti jẹ ọba yin ni tootọ, ẹyin arakunrin, bi mo ba ri wipe idibajẹ onirira yii ti ran mọ ọkan ninu awọn ọwọ mi tabi ẹsẹ mi, ma a fifun yin lati ge kuro. . . . Siwaju si, bi mo ba ri ti o sọ ọkan ninu awọn ọmọ mi di aimọ, mi o ni dasí. . . . Emi funra mi ni yoo jọwọ rẹ lọwọ, ti n o si fi rubọ si Ọlọrun.” O n sọkun ninu ọrọ rẹ, gbogbo apejọ naa si sọkun, wọn wi ni ohun kan wipe: “Awa yoo wa laaye, a o si ku fun ẹsin Katoliki.”ANN 100.5

    Okunkun orilẹ ede ti o kọ imọlẹ otitọ silẹ naa po gan an ni. Oore ọfẹ “ti o mu igbala wa” ti fi ara han; ṣugbọn lẹyin ti France ri agbara ati iwa mimọ rẹ, lẹyin ti onfa ẹwa rẹ ti fa ọpọlọpọ mọra, lẹyin ti itansan rẹ ti mọlẹ si awọn ilu nla ati awọn abule, o yipada, o yan okunkun ju imọlẹ lọ. Wọn kọ ẹbun ọrun silẹ nigba ti a fi fun wọn. Wọn pe ibi ni rere, ati rere ni ibi, titi ti wọn fi ṣubu sinu itan-ara-ẹnijẹ ti wọn mọọmọ yan. Bi o tilẹ jẹ wipe wọn le gbagbọ ni tootọ wipe wọn ṣe Ọlọrun loore ni nipa ṣiṣe inunibini si awọn eniyan Rẹ ni akoko yii, sibẹ iṣẹ atọkanwa wọn ko mu ẹbi wọn kuro. Wọn ti mọọmọ kọ imọlẹ ti i ba gba wọn la kuro ninu ẹtan, kuro ninu didọti ọkan wọn pẹlu ẹbi ẹjẹ, silẹ.ANN 100.6

    Wọn jẹ ẹjẹ pataki lati fa ẹkọ odi tu ninu katidra nla naa, nibi ti, lẹyin bi ọgọrun mẹta ọdun, orilẹ ede ti o ti gbagbe Ọlọrun alaaye yoo ti gbe Ọlọrunbunrin Imọ si ori itẹ. Wọn tun bẹrẹ iwọde naa, awọn aṣoju France si jade lati bẹrẹ iṣẹ ti wọn jẹjẹ lati ṣe. “A gbe akasọ kalẹ si awọn ibusọ ti ko jinna si ara wọn, nibẹ ni a o ti dana sun awọn Kristẹni Protestant kan laaye, a si ti ṣe eto lati dana si igi naa lara lọgan ti ọba ba ti yọ, ti iwọde naa yoo si duro lati wo ipaniyan naa.” Alaye ijiya ti awọn ajẹri fun Kristi wọnyi la kọja banilọkanjẹ ju eyi a le kọ silẹ lọ; ṣugbọn awọn ti n jiya yii ko yẹsẹ. Nigba ti a rọ wọn lati ronupiwada, ọkan dahun wipe: “Ohun ti awọn woli ati awọn apostoli waasu tẹlẹ, ti gbogbo awọn eniyan gbagbọ, nikan ni mo gbagbọ. Igbagbọ mi ni igboya ti yoo koju ija si gbogbo agbara ipo oku ninu.”ANN 100.7

    Latigbadegba ni iwọde naa n duro ni ibi ifiyajẹni. Nigba ti wọn de ibi ti wọn ti bẹrẹ ni aafin ọba, awọn ero tuka, ọba ati awọn alufa kuro nibẹ, inu wọn dun si iwọde ọjọ naa wọn si n ki ara wọn ku ori ire wipe iṣẹ ti wọn bẹrẹ yoo tẹsiwaju titi ti yoo fi pa ẹkọ odi run patapata.ANN 101.1

    A yoo fa iyinrere alaafia ti France kọ silẹ tu patapata lootọ, atubọtan rẹ yoo si buru jọjọ. Ni January 21, 1793, ni ọtadinlaadọta o din meji ọdun, ni ayajọ ọjọ naa gan an ti France fi ara rẹ jin patapata lati ṣe inunibini si awọn Alatunṣe, iwọde miran fun idi ti o yatọ patapata gba aarin awọn adugbo Paris kọja. “Ọba naa ni o tun jẹ ẹni pataki; irọkẹkẹ ati ariwo tun wa; a gbọ igbe lati fi iya jẹ awọn miran si; awọn akasọ ti wọn ti dudu wà pẹlu; awọn iṣẹlẹ ọjọ naa tun pari pẹlu ipaniyan lọna to banilẹru; a wọ Louis XVI, pẹlu bi o ti n jijadu ọwọ rẹ pẹlu awọn oniletubu rẹ ati awọn ti yoo pa, lọ si ibi pepele, nibẹ ni a dè e mọ titi ti aake fi ṣubu le lori, ti ori rẹ si n jo belebele lori pepele.” Kii ṣe ọba nikan ni o jiya; lẹgbẹ ibudo kan naa (ẹgbẹẹdogun din nigba) 2800 eniyan ni wọn padanu ẹmi wọn nibi ibẹnilori ni akoko buburu ti Akoso Ẹru naa.ANN 101.2

    Iṣẹ Atunṣe fi Bibeli ti a ṣi silẹ fun araye, o n ṣe alaye awọn ilana ofin Ọlọrun, o si n ṣe alaye ohun ti o n fẹ si ọkan awọn eniyan. Ifẹ Ainipẹkun ti ṣipaya ilana ati ẹkọ ọrun fun awọn eniyan. Ọlọrun ti sọ wipe: “Pa wọn mọ ki o si ṣe wọn, nitori eyi ni ọgbọn ati oye rẹ niwaju awọn orilẹ ede ti wọn yoo gbọ awọn ofin wọnyi, ti wọn yoo si wipe, Lootọ orilẹ ede nla yii jẹ ọlọgbọn ati amoye eniyan.” Diuteronomi 4:6. Nigba ti France kọ ẹbun ọrun silẹ, o fun irugbin idarudapọ ati iparun, atubọtan ti a ko le yipada si yori si akoko idoju ijọba bolẹ, ati iṣakoso ẹru.ANN 101.3

    Ni igba pipẹ ṣaaju ki iwe pelebe to fa inunibini, o ti di dandan ki Farel, ẹni ti o gboya ti o si ni itara o kuro ni ilẹ abinibi rẹ. O lọ si switzerland, o fi iṣẹ rẹ ti ti Zwingli lẹyin, o ṣeranwọ lati jẹ ki iṣẹ Atunṣe o gbilẹ. Nibi ni o ti lo akoko ti o kẹyin ninu igbesi aye rẹ, sibẹ o tẹsiwaju lati ko ipa pataki ninu iṣẹ atunṣe ni France. O ṣiṣẹ lati tan iyinrere kalẹ ni ilẹ abinibi rẹ ninu awọn ọdun ti o kọkọ lo ni ilẹ ajeji. O lo ọpọlọpọ akoko lati waasu si awọn eniyan ilu rẹ ti wọn wa ni ẹnu ibode, nibi ti o ti n woye ijakadi naa laisimi, ti o si ran an lọwọ pẹlu ọrọ igbaniyanju ati amọran rẹ. Pẹlu iranlọwọ awọn miran ti wọn sa kuro ni ilu, a ṣe itumọ awọn iwe awọn Alatunṣe ti ilẹ Germany si ede ilu France, a si tẹ wọn jade ni ọpọ yanturu pẹlu Bibeli ni ede French. Awọn tawetawe ta awọn iwe wọnyi daradara ni France. A ta wọn ni owo kekere fun awọn tawetawe wọnyi, èrè ti wọn ri lori wọn si ran wọn lọwọ lati tẹsiwaju.ANN 101.4

    Farel bẹrẹ iṣẹ rẹ ni Switzerland gẹgẹ bi olukọ otoṣi kan. O lọ si agbegbe kan ti o farasin, o bẹrẹ si i kọ awọn ọmọde. Ni afikun si awọn ẹka ẹkọ ti wọn n kọ, o rọra n fi awọn otitọ inu Bibeli kọ wọn, o ni ireti wipe oun yoo de ọdọ awọn obi nipasẹ awọn ọmọ. Awọn kan wa ti wọn gbagbọ, ṣugbọn awọn alufa wa da iṣẹ naa duro, awọn eniyan ilu alaimọkan naa si dide lati tako o. Awọn alufa n wipe, “Eyi ko le jẹ iyinrere Kristi, nitori pe iwaasu rẹ kii mu alaafia wa, bikoṣe ogun.” Bii ti awọn ọmọ ẹyin akọkọ, bi a ba ṣe inunibini si wọn ninu ilu kan, wọn sa lọ si omiran. Lati ileto de ileto, lati ilu de ilu, o lọ, o n fi ẹsẹ rin, o n fi ebi, otutu ati ikaarẹ mọra, ẹmi rẹ si wa ninu ewu ni ibi gbogbo. O waasu ni aarin ọja, ninu awọn ile ijọsin, ati ni igba miran, lori pẹpẹ iwaasu awọn katidra. Ni igba miran, a ri ti ko ni si olugbọ kankan ninu ile ijọsin, ni igba miran ẹwẹ, wọn a fi ariwo ati yẹyẹ ṣiṣe di iwaasu rẹ lọwọ; ni igba miran a a fi ipa wọ kuro lori pẹpẹ iwaasu. Ki i ṣe ẹẹkan pere ni awọn ọmọ ita kọlu u ti wọn si fẹrẹ lu u de oju iku. Sibẹ o tẹsiwaju. Bi o tilẹ jẹ wipe a saba maa n le pada, pẹlu iforiti ti ko kaarẹ, á tun pada sibẹ; ni menimeji, o ri ti awọn ilu ti wọn ti gbọrẹgẹtigẹ ninu ẹsin popu n ṣi ilẹkun wọn silẹ fun iyinrere. Laipẹ, agbegbe kekere ti o ti kọkọ bẹrẹ iṣẹ rẹ gba igbagbọ ti a tunṣe naa. Awọn ilu Morat ati Neuchatel tun kọ aṣa Romu silẹ, wọn si ko awọn ere ibọriṣa kuro ninu awọn ile ijọsin wọn.ANN 101.5

    O ti pẹ ti Farel ti fẹ lati fi asia Protestant sọlẹ ni Geneva. Bi a ba le jere ilu yii, yoo jẹ olu ile iṣẹ fun iṣẹ Atunse ni France, ni Swizerland ati ni Italy. Pẹlu ero yii niwaju rẹ, o tẹsiwaju titi ti o fi jere ọpọ awọn ilu ati ileto ti wọn wà layika. Pẹlu olubakọwọrin kan ṣoṣo, o wọ ilu Geneva lọ. Ṣugbọn iwaasu meji pere ni a gba a laaye lati wa. Lẹyin ti awọn alufa ṣe akitiyan ki aṣẹ ijọba o da lẹbi, ṣugbọn ti ko bọ si, wọn wa pe e siwaju igbimọ ijọ, wọn wá sibẹ pẹlu awọn ohun ija olóró ti wọn kó pamọ si abẹ aṣọ wọn, wọn pinu lati gba ẹmi rẹ. Awọn ọmọ ita pejọ pẹlu ida ati kumọ si ita lati ri wipe, bi o ba sá asala kuro ninu igbimọ, wọn yoo ri wipe o ku. Ṣugbọn nitori awọn adajọ ati awọn ologun ti wọn wa nibe, a da ẹmi rẹ si. Ni aarọ kutukutu ọjọ keji, a mu oun ati ekeji rẹ kọja ibi adagun omi kan lọ si ibi aabo. Bayi ni ipa rẹ akọkọ lati jere ọkan Geneva ṣe pari.ANN 102.1

    Fun igba keji, ohun elo ti ko niyi to ni a yàn—ọdọmọkunrin kan, ti irisi rẹ ko fanimọra rara debi pe awọn ti wọn pe ara wọn ni ọrẹ iṣẹ atunṣe gan ko ṣe si daradara. Ṣugbọn ki ni iru ẹni yii le ṣe nibi ti a ti kọ Farel silẹ? Bawo ni ẹni ti igboya ati iriri rẹ ko pọ yii ṣe le doju kọ iji ti o le awọn alagbara ati akikanju julọ sa? “Ki i ṣe nipa ipa, tabi nipa agbara, bikoṣe nipa Ẹmi Mi ni Oluwa wi.” Sekaraya 4:6. “Ọlọrun ti yan awọn ohun alailagbara aye lati doju ti awọn alagbara.” “Nitori ailera Ọlọrun lagbara ju eniyan lọ.” I Kọrintin 1:27, 25.ANN 102.2

    Froment bẹrẹ iṣẹ rẹ gẹgẹ bi olukọ. Otitọ ti o ba kọ awọn ọmọ ni ile ẹkọ, wọn a tunsọ ni ile. Laipẹ, awọn obi n wa lati gbọ alaye Bibeli titi ti yara ikawe naa fi kun fun awọn akẹkọ. A pin Majẹmu Tuntun ati awọn iwe ilewọ lọfẹ, wọn si de ọdọ awọn ti ko to bẹẹ lati jade si gbangba lati wa gbọ awọn ikọni tuntun wọnyi. Lẹyin igba diẹ, o tun di dandan fun oṣiṣẹ yii lati salọ; ṣugbọn awọn otitọ ti o fi kọni wa ninu ọkan awọn eniyan. A ti gbin iṣẹ Atunṣe silẹ, o si tẹsiwaju lati lokun, ti o si n tan kalẹ si. Awọn oniwaasu naa pada wa, nipasẹ iṣẹ wọn, ẹsin Protestant fi ẹsẹ mulẹ ni Geneva nikẹyin.ANN 102.3

    Ilu naa ti jẹwọ Iṣẹ Atunṣe nigba ti Calvin, lẹyin ọpọlọpọ irinkiri ati ayipada ninu igbesi aye rẹ, wọ inu rẹ lọ. Nigba ti o n pada bọ ninu ibẹwo ti o ṣe kẹyin si ilẹ abinibi rẹ, ni oju ọna lọ si Basel, o ri awọn ẹgbẹgun Charles V ni oju ọna ti o lọ taara, eyi si jẹ ki o di dandan fun lati gba ọna Geneva ti o ṣe kọrọ.ANN 102.4

    Ninu ibẹwo yii, Farel ri ọwọ Ọlọrun. Bi o tilẹ jẹ wipe Geneva ti gba igbagbọ ti a fọ mọ, sibẹ, iṣẹ nla si wa nibẹ lati ṣe. Ki i ṣe gẹgẹ bi ilu, bikoṣe gẹgẹ bi ẹnikọọkan ni a n yi pada si Ọlọrun; agbara Ẹmi Mimọ nilati ṣe iṣẹ iyipada ninu ọkan ati ẹmi, ki i si i ṣe nipasẹ aṣẹ igbimọ. Nigba ti awọn ara Geneva ti kọ aṣẹ Romu silẹ, wọn ko ṣetan lati kọ awọn iwa ibajẹ ti wọn wọpọ labẹ akoso rẹ silẹ. Ki i ṣe iṣẹ kekere ni lati fi idi ilana mimọ ti iyinrere mulẹ, ati lati pese awọn eniyan wọnyi silẹ lati duro si ipo ti Ọlọrun pe wọn si.ANN 102.5

    Farel ni igboya wipe oun ri ninu Calvin ẹni ti o le so pọ mọ ara rẹ ninu iṣẹ yii. O rọ ọdọmọde ajiyinrere naa ni orukọ Ọlọrun lati duro ki o si ṣiṣẹ nibi. Calvin fi ibẹru fasẹyin. Ẹni ti o n tiju ti o si fẹran alaafia, o sa fun ibaṣepọ pẹlu igboya, ominira ati iwa ipa awọn ara Geneva. Ailera rẹ, pẹlu iwa rẹ lati maa kawe mu ki o fẹran lati maa danikan wa. Pẹlu igbagbọ rẹ wipe ohun le ṣe atilẹyin fun iṣẹ atunṣe pẹlu gègé ikọwe oun, o fẹ lati lọ si ibi idakẹrọrọ lati kawe, ati nipasẹ ile itẹwe, yoo gba awọn ijọ niyanju, yoo si gbe wọn ro. Ṣugbọn ipẹ Farel wa si ọdọ rẹ gẹgẹ bi ipe lati Ọrun, ko si gbọdọ kọ ọ. O sọ wipe, o dabi ẹnipe, “A na ọwọ Ọlọrun silẹ lati ọrun, o di oun mu, o si fi oun si ibi ti oun ti fẹ yara kuro kankan, laile kuro nibẹ.”ANN 102.6

    Ni akoko yii, ewu nla rọgba yi iṣẹ Protestant ka. Ifibu popu n bu ramuramu mọ Geneva, awọn orilẹ ede nla si n dun kukulaja mọ lati paarun. Bawo ni ilu kekere yii yoo ṣe doju ija kọ ijọba ẹsin alagbara ti o saba maa n fi ipa mu ki awọn ọba ati olotu ijọba o tẹriba? Bawo ni yoo ṣe koju awọn ọmọ ogun nla aye yii?ANN 102.7

    Kaakiri awọn ilẹ ti n ṣe ẹsin Kristẹni, awọn ọta alagbara n dun mọhuru mọhuru mọ ẹsin Protestant. Awọn iṣẹgun akọkọ ti iṣẹ Atunṣe ti kọja, Romu wa ko awọn agbara tuntun jọ, o fẹ paarun. Ni akoko yii ni a da ẹgbẹ Jesuit, ẹgbẹ ti o nika julọ, ti ko ni ibẹru ofin, ti o si lagbara julọ ninu awọn olugbeja ẹsin popu silẹ. Wọn yọ ara wọn kuro ninu gbogbo ifẹ aye ati ibatan eniyan, wọn di oku si ifẹ eniyan, wọn pa iṣọwọronu ati ẹri ọkan lẹnu mọ patapata, wọn ko mọ aṣẹ tabi ibatan kan, ayafi ti ẹgbẹ wọn, wọn ko si ni ojuṣe kan ayafi lati tan agbara rẹ kalẹ. Iyinrere Kristi fun awọn atẹle rẹ lagbara lati doju kọ ewu, lati fi ara da ijiya, lati maṣe bẹru òtutu, ebi, wahala, ati aini, lati gbe ọpagun otitọ soke loju ijiya, tubu ati idanasunni. Lati le doju kọ awọn agbara wọnyi, ẹgbẹ Jesuit fi igbonara aimọkan kọ awọn atẹle rẹ, eyi ti o fun wọn ni okun lati le fi ara da iru awọn ewu kan naa, ati lati le doju kọ agbara otitọ pẹlu gbogbo ohun ija ẹtan. Ko si iwa ọdaran ti o tobi julọ fun wọn lati wu, ko si irọ kan ti o buru ju lati pa, ko si ohun ti o nira ju fun wọn lati fi ara we. Wọn jẹ ẹjẹ lati jẹ otoṣi ati alaini titi lae, erongba wọn ni lati ni ọrọ ati agbara, lati fi ara wọn jin fun iṣubu ẹsin Protestant, ki wọn si fi idi aṣẹ popu mulẹ lẹẹkan sii.ANN 103.1

    Nigba ti wọn ba fi ara han gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ wọn, wọn a wọ aṣọ iwa mimọ, wọn a bẹ ọgba ẹwọn ati ile iwosan wo, wọn a ṣe itọju alaisan ati alaini, wọn n kede wipe wọn ti kọ aye silẹ, wọn si ti gba orukọ mimọ ti Jesu, Ẹni ti O rin kaakiri lati ṣe rere. Ṣugbọn erongba iwa ọdaran ti o buru jai ni wọn fi pamọ si abẹ iwa alailẹgan yii. Ẹkọ ipilẹ ẹgbẹ naa ni wipe ayọrisi nnkan yoo ṣe idalare ọna ti a gba ṣe e. Pẹlu ofin yii, ki i ṣe wipe irọ pipa, ole jija, ibura eke, ipaniyan jẹ awọn iwa ti a le fi oju fo da nikan, ṣugbọn a le gboriyin fun wọn bi wọn ba ṣiṣẹ fun ifẹ ijọ. Ni abẹ oriṣiriṣi iboju, wọn a dé awọn ipo oṣelu, wọn a goke agba dé ipo oludamọran ọba, wọn a si ṣe awọn ofin orilẹ ede. Wọn a ṣiṣẹ bi iranṣẹ lati le jẹ amí lori ọga wọn. Wọn da ile ẹkọ silẹ fun awọn ọmọ ọba ati ijoye, wọn tun da ile ẹkọ silẹ fun awọn eniyan lasan; a si n jẹ ki awọn ọmọ ti obi wọn n ṣe ẹsin Protestant o maa bọwọ fun awọn ilana ẹsin popu. Gbogbo ogo ati iwuga ẹsin Romu dà wọn niye rú, á sì gbà wọn lọkan, bayi ni awọn ọmọ ṣe ṣe iku pa ominira ti awọn baba wọn jiya ti wọn tun ta ẹjẹ silẹ lati gba. Awọn ọmọ ẹgbẹ Jesu yara kankan tan ka ilẹ Europe, nibikibi ti wọn ba si lọ, isọji ẹsin popu maa n tẹle ni.ANN 103.2

    Lati le fun wọn ni agbara si, a pa aṣẹ ti o da igbimọ igbẹjọ ti o n ri si ohun ti eniyan gbagbọ silẹ lẹẹkan si. Bi o tilẹ jẹ wipe gbogbo awọn eniyan ni wọn korira rẹ, ani ni awọn orilẹ ede ti wọn n ṣe ẹsin Katoliki paapa, awọn adari ẹsin popu tun gbe igbimọ ẹlẹru naa kalẹ lẹẹkan si, ti wọn si n wu awọn iwa ti o buru jai ju eyi ti a le fi han lọ ninu awọn ile tubu rẹ. Ni ọpọlọpọ awọn orilẹ ede, ẹgbẹẹgbẹrun awọn ọdọ orilẹ ede, awọn oniwa alailabawọn, awọn ẹni iyì, awọn amoye ati ọlọgbọn, awọn alufa olufọkansin ti wọn jẹ oniwabiọlọrun, awọn ara ilu ti wọn ni aapọn, ti wọn tun fẹran orilẹ ede wọn, awọn olukọ ti wọn ja fafa, awọn oluyaworan ti wọn dangajia, awọn oniṣẹ ọwọ ti wọn ni òye, ni a pa tabi ti wọn salọ si awọn ilẹ miran.ANN 103.3

    Awọn ọna ti Romu lo lati pa ina iṣẹ Atunṣe niyii, lati mu Bibeli kuro ni ọdọ awọn eniyan, ati lati da aimọkan ati igbagbọ asan ti akoko oju dudu pada. Ṣugbọn labẹ ibukun Ọlọrun ati iṣẹ awọn ẹni pataki ti O gbe dide lati rọpo Luther wọnyi, iṣẹ Protestant ko ṣubu. Ki i ṣe ọdọ ohun ija tabi oju rere awọn ijoye ni o ti ri agbara rẹ. Awọn orilẹ ede ti wọn kere julọ, awọn orilẹ ede ti wọn ko lọrọ ti wọn ko si lagbara julọ ni wọn di ile agbara rẹ. Geneva kekere laarin awọn orilẹ ede nla ti wọn n pete lati pa a run; Holland ni eti bebe okun ni iha ariwa, ti o n jijadu ni atako si iwa ipa Spain, ijọba ti o lagbara, ti o si lọrọ julọ nigba naa; orilẹ ede Sweden ti o jẹ aṣalẹ, ti o si motutu, ni wọn gba iṣẹgun fun iṣẹ Atunṣe.ANN 103.4

    Fun bi ọgbọn ọdun, Calvin ṣiṣẹ ni Geneva, ni akọkọ, lati da ijọ ti yoo tẹle ilana iwuwasi ti Bibeli silẹ, ati lati jẹ ki iṣẹ Atunṣe o tẹsiwaju ni gbogbo Europe. Iṣẹ rẹ gẹgẹ bi alaṣẹ ilu ni abuku tirẹ, bẹẹ ni awọn ikọni rẹ ni aṣiṣe ti wọn. Ṣugbọn o wulo ni titan awọn otitọ ti wọn ṣe pataki ni akoko tirẹ kalẹ, ni titẹle awọn ikọni ẹsin Protestant ni atako si ilana popu ti o n yara pada wa kankan, ati ni wiwaasu iwa mimọ ati igbe aye otitọ ninu awọn ijọ ti a fọ mọ, dipo igberaga ati iwa ibajẹ ti wọn wọpọ labẹ ikọni Romu.ANN 103.5

    Awọn iwe atẹjade ati olukọ jade lati Geneva lati lọ tan awọn ikọni ti a fọmọ kalẹ. Gbogbo awọn ti a n ṣe inunibini si ni ilẹ gbogbo n wo ibi fun ikọni, imọran ati igbaniyanju. Ilu Calvin di ibi aabo fun awọn Alatunṣe ti a n dọdẹ kiri ni gbogbo iha iwọ oorun Europe. Ni sisa fun iji lile ti o tẹsiwaju fun igba pipẹ, awọn isansa wọnyi wa si ẹnu ọna Geneva. Ebi n pa wọn, a pa wọn lara, wọn ko ni ilẹ tabi ará, a gba wọn pẹlu idunnu, a si fi pẹlẹkutu ṣe itọju wọn; wọn ri ibugbe nibẹ, wọn bukun ilu ti o gba wọn sile pẹlu imọ, ẹkọ ati ifọkansin wọn. Ọpọ awọn ti wọn wa aabo wa sibẹ pada si ilẹ wọn lati dojukọ iwa onroro Romu. John Knox, Alatunṣe onigboya ti ilu Scotch, ọpọ awọn Puritans ti ilẹ Gẹẹsi, awọn Protestant ti Holland, ati Spain, awọn Huguenots ti France gbe imọlẹ otitọ lati Geneva lati lọ tan an si okunkun ilẹ abinibi wọn.ANN 104.1

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents