Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents
ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORI KỌKANDINLỌGBỌN—IPILẸSẸ IWA BUBURU

    Si ọpọlọpọ eniyan ibẹrẹ ẹṣẹ ati idi fun wiwa rẹ jẹ orisun iporuuru ọkan nla. Wọn ri iṣẹ ibi, pẹlu ayọrisi rẹ ti o banilẹru—wahala ati isọdahoro, wọn wa n beere bawo ni gbogbo eyi ṣe le maa ṣẹlẹ labẹ iṣakoso Ẹni ti O pọ ni ọgbọn ati agbara ati ifẹ. Eyi jẹ ohun ijinlẹ ti wọn ko le ṣalaye. Ninu ainidaniloju ati iyemeji wọn, oju wọn fọ si otitọ ti o han kedere ninu ọrọ Ọlọrun ti o ṣe pataki fun igbala. Awọn kan wa, ninu iwadi wọn nipa bi ẹṣẹ ṣe wa, ti wọn ṣe akitiyan lati wo inu ohun ti Ọlọrun ko fihan; nitori naa wọn ko ri idahun si iṣoro wọn; awọn ti wọn ni ẹmi iyemeji ati awawi èké ri eyi gẹgẹ bi idi lati kọ ọrọ Iwe Mimọ silẹ. Awọn miran ẹwẹ, wọn baku lati ni oye kikun nipa iṣoro nla ti ibi, nitori pe aṣa ati ìṣi Bibeli tumọ ti ṣokunkun bo ikọni Bibeli nipa iwa Ọlọrun, bi ijọba Rẹ ti ri, ati iwuwasi Rẹ ni didoju kọ ẹṣẹ.ANN 219.1

    Ko ṣe e ṣe lati ṣe alaye ibẹrẹ ẹṣẹ ni ọna lati funni ni idi fun bi o ṣe wa. Sibẹ, a le ni oye ti o to nipa ibẹrẹ ati opin ẹṣẹ lati le ṣe afihan ni kikun ododo ati aanu Ọlọrun ninu gbogbo iṣesi Rẹ si ibi. Ko si ohun ti a kọni yekeyeke ninu Iwe Mimọ ju eyi pe Ọlọrun kọ ni O mu ẹṣẹ wá; wipe ko ṣa dede fa ọwọ oore ọfẹ Rẹ sẹyin, ko si ibaku ninu iṣejọba Ọlọrun, ti o wa fa iṣọtẹ. Ẹṣẹ jẹ ohun ti o farahan laipẹ yii, ti a ko si le ṣe alaye wiwa rẹ. O jẹ ijinlẹ, ti a ko le ṣalaye; lati ṣe awawi fun tumọ si wipe a n gbeja rẹ. Bi a ba ri awawi fun, tabi bi a ba ri idi ti o fi yẹ ki o wa, ko ni jẹ ẹṣẹ mọ. Alaye kan ṣoṣo ti a le ṣe nipa ṣe ni eyi ti a funni ninu ọrọ Ọlọrun; o jẹ “riru ofin;” o jẹ ifihan ero ti o n wọya ija pẹlu ofin ifẹ nla eyi ti i ṣe ipilẹ ijọba Ọlọrun.ANN 219.2

    Ki iwa ibi to wọle, alaafia ati ayọ wa ni gbogbo agbala aye. Ohun gbogbo wa ni irẹpọ pẹlu ifẹ Ẹlẹda. Ifẹ fun Ọlọrun ni o ga ju, ifẹ fun ẹnikeji si wa ni aisi ojuṣaju. Kristi, Ọrọ naa, Ọmọ bibi kan ṣoṣo Baba, jẹ ọkan pẹlu Baba ayeraye,—ọkan ninu iwalaaye, ninu iwa, ati ninu ero—ẹnikan ṣoṣo ninu gbogbo agbalaaye ti O le mọ gbogbo imọran ati erongba Ọlọrun. Baba da gbogbo ẹda ọrun nipasẹ Kristi. “Nipasẹ Rẹ ni a da ohun gbogbo, ti o wa ni ọrun, . . . ibaajẹ itẹ, tabi agbara ijọba, tabi ijọba oju ọrun, tabi agbara” (Kolose 1:16); gbogbo ọrun si n jọsin Kristi ati Baba bakan naa.ANN 219.3

    Ofin ifẹ ni o jẹ ipilẹ ijọba Ọlọrun, idunnu gbogbo awọn ohun ti a da duro lori igbọran pipe si ipilẹ nla ododo rẹ. Ọlọrun fẹ iṣẹ ifẹ lati ọdọ gbogbo iṣẹda Rẹ—igbọran ti o wa latari imọriri iwa Rẹ. Ko ni inu didun si fifi ipa muni ṣe igbọran, O si fun gbogbo eniyan ni ominira lati ṣe ipinu, ki wọn ba a le sin In gẹgẹ bi ọkan wọn ti yan.ANN 219.4

    Ṣugbọn ẹnikan wa ti o yan lati ṣi ominira yii lo. Ẹṣẹ bẹrẹ pẹlu ẹni naa, ti o tẹle Kristi, o jẹ ẹni ti Ọlọrun bu ọla fun julọ, o si ni agbara ati ogo julọ laarin awọn olugbe ọrun. Ṣaaju iṣubu rẹ, Lusifa jẹ akọkọ ninu awọn kerubu ti n bò, o jẹ mimọ ko si ni abawọn. “Bayii ni Oluwa Ọlọrun wi; Iwọ fi edidi di iye naa, o kun fun ọgbọn, o si pe ni ẹwa. Iwọ ti wa ni Edẹni ọgba Ọlọrun; gbogbo okuta iyebiye ni ibora rẹ. . . . Iwọ ni Kerubu ti a yan ti n bò; Emi ṣi ti ṣe ọ bẹẹ; iwọ wa ni oke mimọ Ọlọrun; iwọ rin soke rin sodo laarin okuta ina. Iwọ pe ni ọna rẹ lati ọjọ ti a ti da ọ, titi ti a fi ri aiṣedeede ninu rẹ.” Isikiẹli 28:12—15.ANN 219.5

    Lusifa i ba ṣi maa ri oju rere Ọlọrun, ti gbogbo awọn angẹli i ba ṣi fẹran rẹ ti wọn i ba si bọwọ fun, ti oun i ba si maa lo agbara giga rẹ lati bukun awọn eniyan ati lati fi ogo fun Ẹlẹda rẹ. Ṣugbọn woli naa sọ pe, “Ọkan rẹ gbé ga nitori ẹwa rẹ, iwọ ti ba ọgbọn rẹ jẹ nitori didan rẹ.” Ẹsẹ 17. Diẹdiẹ, Lusifa gba ẹmi igberaga laaye. “Iwọ gbe ọkan rẹ ga bi ọkan Ọlọrun.” “Iwọ ti sọ wipe, . . . emi yoo goke kọja ikuuku awọsanma; emi yoo dabi Ẹni Giga Julọ.” Ẹsẹ 6; Aisaya 14:13, 14. Dipo ki o jẹ ki Ọlọrun o ga julọ ninu ifẹ ati igbọran awọn ẹda, ifẹ Lusifa ni lati gba iṣẹ ati ijọsin wọn fun ara rẹ. O ṣe ojukokoro si ọla ti Baba ayeraye fun Ọmọ Rẹ, ọmọ alade awọn angẹli gbero lati ni agbara ti o tọ si Kristi nikan ṣoṣo.ANN 219.6

    Gbogbo ọrun ni o yọ lati fi ogo Ẹlẹda ati iyin Rẹ han. Nigba ti a ba bu ọla fun Ọlọrun bayii, alaafia ati idunnu yoo wa. Ṣugbọn ohùn orin ti ko bojumu wa ba orin awọn angẹli jẹ bayi. Iṣẹ ati igbe ara ẹni ga, ti o yatọ si erongba Ọlọrun ta ero ibi ji ninu awọn ẹni ti o jẹ wipe ogo Ọlọrun ni o ga ju ninu ọkan wọn. Igbimọ ọrun bẹ Lusifa. Ọmọ Ọlọrun ṣe alaye titobi, didara ati ododo Ẹlẹda, ati bi ofin Rẹ ti jẹ mimọ to ti ko si ṣe e yipada. Ọlọrun funra Rẹ ni o fi idi eto ọrun lelẹ, ni yiyago kuro ninu rẹ, Lusifa a kẹgan Ẹlẹda rẹ, yoo si ko iparun ba ara Rẹ. Ṣugbọn ikilọ ti a ṣe ninu ifẹ ati aanu tilẹ n ru ẹmi atako soke ni. Lusifa jẹ ki ẹmi owu si Kristi o gba iṣakoso, o wa tubọ n se ọkan rẹ le si.ANN 220.1

    Igberaga ninu ogo rẹ mu ifẹ fun iṣakoso wa. Lusifa ko ri ọla giga ti a fifun gẹgẹ bi ẹbun Ọlọrun, ko si jẹ ki o fi imoore rẹ han si Ẹlẹda. O ṣogo ninu didan rẹ, o si fẹ lati dọgba pẹlu Ọlọrun. Gbogbo ogun ọrun fẹran rẹ wọn si bọwọ fun. Inu awọn angẹli n dun lati jiṣẹ fun, a si fi ọgbọn ati ogo wọ ọ ni aṣọ ju gbogbo wọn lọ. Sibẹ Ọmọ Ọlọrun ni a mọ gẹgẹ bi Alayeluwa ọrun, ọkan ni agbara ati aṣẹ pẹlu Baba. Ninu gbogbo erongba Ọlọrun, Kristi maa n wa nibẹ, ṣugbọn a ko gba Lusifa laaye lati wọ inu erongba Ọlọrun. Angẹli alagbara yii beere, “Bawo ni Kristi ṣe le jọ ọga? Kilode ti a fi n bọwọ fun ju Lusifa lọ?”ANN 220.2

    O fi ipo rẹ niwaju Ọlọrun silẹ, Lusifa jade lọ lati tan ẹmi ainitẹlọrun ka laarin awọn angẹli. O ṣiṣẹ ni ọna ikọkọ ti o lagbara, fun igba diẹ o fi erongba rẹ ni pato pamọ labẹ irisi wipe oun n bọwọ fun Ọlọrun, o ṣe akitiyan lati ru ẹmi ainitẹlọrun soke nipa ofin ti o n ṣe akoso awọn olugbe ọrun, o n sọ wipe wọn din ominira wọn ku ni ainidi. O sọ wipe awọn angẹli le ṣe igbọran si ifẹ ọkan wọn niwọn igba ti o ṣe wipe wọn jẹ mimọ. O wa lati ri ikaanu fun ara rẹ nipa fifihan pe Ọlọrun ko ṣe ododo pẹlu oun nipa fifi ọla ti o ga julọ fun Kristi. O sọ wipe ni gbigbero lati ni agbara ati ọla ti o pọ si, ki i ṣe ero oun ni lati gbe ara oun ga, ṣugbọn lati le fun gbogbo awọn olugbe ọrun ni ominira, nipasẹ eyi, wọn a le ni igbesi aye ti o ga si.ANN 220.3

    Ọlọrun ninu aanu Rẹ fi ara da Lusifa fun igba pipẹ. Ki i ṣe lọgan ti o kọkọ gba ẹmi ainitẹlọrun laaye, tabi nigba ti o gbe ero irọ rẹ kalẹ niwaju awọn angẹli ti wọn jẹ olootọ ni a yọ kuro ninu ipo giga rẹ. Fun igba diẹ a fi aaye gba a ni ọrun. Lati igbadegba ni a ṣeleri idariji fun bi o ba ronupiwada ti o si ṣe igbọran. Iru akitiyan bayi ti ifẹ ati ọgbọn ayeraye le ṣe ni a lo lati fi ibi ti o ti ṣe aṣiṣe ye. Ko si ẹmi ainitẹlọrun ni ọrun tẹlẹ ri. Lusifa funra rẹ ko kọkọ ri ibi ti oun n lọ; ko ni oye ohun ti ero ọkan rẹ jẹ nitootọ. Ṣugbọn bi a ti fi han wipe ko si idi fun ainitẹlọrun rẹ, Lusifa ri wipe oun ṣe aṣiṣe, wipe ohun ti Ọlọrun sọ jẹ otitọ, ati wipe oun nilati sọ eyi niwaju gbogbo ọrun. Bi o ba ṣe eyi ni, i ba ti gba ara rẹ ati ọpọlọpọ awọn angẹli là. Ni akoko yii, koi ti i sọ igbọran rẹ si Ọlọrun nu patapata. Bi o tilẹ jẹ wipe o ti fi ipo rẹ silẹ gẹgẹ bi kerubu ti n bò, sibẹ bi o ba jẹ wipe o fẹ lati pada si ọdọ Ọlọrun, ki o gba ọgbọn Ẹlẹda, ki o si jẹ ki ipo ti a fun oun ninu eto nla Ọlọrun o tẹ oun lọrun, a ba da pada sinu ipo rẹ. Ṣugbọn igberaga ko jẹ ki o tẹriba. O fi agidi gbeja ero rẹ, o sọ wipe oun ko nilo ironupiwada, o wa jọwọ ara rẹ silẹ ni kikun fun ijakadi nla, ni atako si Ẹlẹda rẹ.ANN 220.4

    Gbogbo agbara ọpọlọ giga rẹ ni o wa n lo lati ṣe iṣẹ itanjẹ, lati le ri ikaanu awọn angẹli ti wọn wa labẹ akoso rẹ. O lo pípè tí Kristi pe e lati ki i nilọ ati lati gba a niyanju fun ète ọlọtẹ rẹ. Satani sọ fun awọn ti ifẹ wọn fun jẹ ki wọn sunmọ julọ wipe a ko ṣe idajọ oun daradara, wipe a ko bọwọ fun ipo oun ati wipe a fẹ din ominira oun ku. Lati ibi gbigbe ọrọ kalẹ ni ọna ti ko tọ, o de ibi itanjẹ ati pipa irọ ojukoju, nipa fifi ẹsun kan Ọmọ Ọlọrun wipe o ti pete lati doju ti oun niwaju awọn olugbe ọrun. O wa ọna lati wa ija eke laarin oun ati awọn angẹli ti wọn ṣe otitọ. Gbogbo awọn ti ko le tanjẹ ki o si mu wọn wa si ọdọ rẹ ni kikun ni o fi ẹsun kan wipe wọn ko kọbi ara si alaafia awọn olugbe ọrun. O fi ẹsun iṣẹ ti o n ṣe gan kan awọn ti wọn jẹ olootọ si Ọlọrun. Lati le mu ki ẹsun ti o fi kan Ọlọrun nipa aiṣododo si o duro, o bẹrẹ si ni i ṣe afihan ọrọ ati iṣesi Ẹlẹda ni ọna ti ko tọ. Iwa rẹ ni lati damu awọn angẹli pẹlu ọrọ arekereke nipa erongba Ọlọrun. Gbogbo ohun ti o han kedere ni o sọ di ohun ijinlẹ, nipa ọgbọn arekereke, o mu wọn ṣe iyemeji si ọrọ Jehofa ti o han kedere. Ipo giga rẹ, pẹlu bi o ti sunmọ iṣejọba Ọlọrun to, fun ọrọ rẹ lokun, ọpọlọpọ si fẹ lati darapọ mọ ninu iṣọtẹ rẹ si aṣẹ Ọlọrun.ANN 220.5

    Ọlọrun ninu ọgbọn Rẹ fi aaye gba Satani lati tẹsiwaju ninu iṣẹ rẹ, titi ti ẹmi ainitẹlọrun fi fi ara han di iṣọtẹ nla. O ṣe pataki ki eto rẹ o dagbasoke daradara, ki ohun ti wọn jẹ gan an ati ibi ti wọn yoo jasi le farahan fun gbogbo wọn. A gbe Lusifa ga pupọpupọ gẹgẹ bi kerubu ti n bo; awọn olugbe ọrun fẹran rẹ jọjọ, agbara rẹ lori wọn si pọ. Ki i ṣe awọn olugbe ọrun nikan ni wọn wa ninu ijọba Ọlọrun, bikoṣe ati ti awọn aye ti O da pẹlu; Satani ro wipe bi oun ba le ko awọn angẹli ọrun si ọdọ oun lati ṣọtẹ, oun le ko awọn aye yoku pẹlu. O fi arekereke ro eyi ti o kan an ninu ọrọ naa, nipa lilo ọgbọn ẹwẹ ati irọ lati ri ohun ti o fẹ. Agbara rẹ lati tannijẹ pọ pupọ, ati nipa fifi aṣọ eke bo ara rẹ o ni anfani. Ani awọn angẹli ti wọn ṣegbọran ko ni oye kikun nipa iwa rẹ tabi ri ibi ti iṣẹ rẹ n lọ.ANN 221.1

    A bu ọla fun Satani pupọpupọ, gbogbo iṣesi rẹ ni o fi juuju bo loju, ti o fi jẹ wipe o nira lati sọ fun awọn angẹli ohun ti iṣẹ rẹ jẹ ni tootọ. Ayafi ti o ba dagba daradara, ẹṣẹ ko ni farahan ni iwa buburu ti o jẹ. Titi di akoko yii, ko ni aaye ninu aye ti Ọlọrun da, awọn ẹda mimọ ko si ni oye bi o ti ri ati bi o ti buru to. Wọn ko le mọ ayọrisi buburu ti yoo jade latari kikọ ofin Ọlọrun silẹ. Ni akọkọ, Satani fi iṣẹ rẹ pamọ sabẹ ifarahan wipe oun n ṣe igbọran si Ọlọrun. O sọ wipe oun n wa lati bu ọla fun Ọlọrun, lati fi idi ijọba Rẹ mulẹ, ati lati wa rere gbogbo awọn olugbe ọrun. Nigba ti o n gbin ainitẹlọrun sinu ọkan awọn angẹli ti wọn wa labẹ rẹ pẹlu ọgbọn arekereke, o mu ki o han wipe oun n fẹ mu ainitẹlọrun kuro. Nigba ti o sọ wipe ki a yi eto ati ofin ijọba Ọlọrun pada, o sọ ọ labẹ ifarahan wipe o ṣe pataki lati le jẹ ki iṣọkan o wa ni ọrun.ANN 221.2

    Ni didoju kọ ẹṣẹ, ododo ati otitọ nikan ni Ọlọrun le lo. Satani le lo ohun ti Ọlọrun ko le lo—irọ ati ẹtan. O n wa lati fi ọrọ Ọlọrun han ni ọna eke, o si ṣe afihan eto ijọba Rẹ ni ọna ti ko tọ niwaju awọn angẹli, o n sọ wipe Ọlọrun ko ṣe daradara ni ṣiṣe ofin ati ilana fun awọn olugbe ọrun; wipe ni fifẹ ki awọn ẹda Rẹ o tẹriba, ki wọn si ṣe igbọran, O n wa lati gbe ara Rẹ ga lasan ni. Nitori naa a nilati fihan niwaju awọn olugbe ọrun ati awọn aye yoku wipe ijọba Ọlọrun jẹ eyi ti o tọna, ofin Rẹ si pe. Satani jẹ ki o dabi ẹnipe oun funra oun n fẹ rere agbala aye. Iwa tootọ afipa-gba-ohun-ti-ko-tọ si ati afojusun rẹ gan an nilati yé gbogbo wọn. O nilati ni akoko lati fi iwa rẹ han nipa iṣẹ buburu rẹ.ANN 221.3

    Satani di aisirẹpọ ti iwa rẹ fa ni ọrun le ofin ati iṣejọba Ọlọrun lori. O sọ pe gbogbo iwa buburu ti n ṣẹlẹ waye nitori iṣejọba Ọlọrun. O sọ pe afojusun oun ni lati tun aṣẹ Jehofa ṣe. Nitori naa o ṣe pataki ki o fi ọrọ rẹ han, ki o si fi ayọrisi iru atunṣe ti o fẹ ṣe ninu ofin Ọlọrun han. Iṣẹ rẹ nilati da a lẹbi. Satani kọkọ sọ wipe ki i ṣe wipe oun n ṣọtẹ. Gbogbo agbaye ni yoo ri ti a o fi opurọ naa han.ANN 221.4

    Ani nigba ti a ṣe ipinu wipe ko le duro ni ọrun mọ, Ọgbọn Ayeraye ko pa Satani run. Niwọn igba ti o jẹ wipe iṣẹ ifẹ nikan ni o le jẹ itẹwọgba lọwọ Ọlọrun, igbọran awọn ẹda Rẹ nilati duro lori igbagbọ wọn ninu iṣotitọ ati aanu Rẹ. Nitori ti awọn olugbe ọrun ati aye yoku koi ti i ṣetan lati mọ ohun ti ẹṣẹ jẹ tabi ayọrisi rẹ, wọn ko le ri ododo ati aanu Ọlọrun ninu pipa Satani run. Bi o ba ṣe wipe lọgan ni a pa run ni, wọn i ba maa sin Ọlọrun lati inu ibẹru dipo ifẹ. A ba ma le pa ipa atannijẹ naa run patapata, bẹẹ si ni a ba ma le ká iṣẹ ẹmi iṣọtẹ kuro nilẹ patapata. A nilati jẹ ki iwa ibi o dagba daradara, ki gbogbo ẹda le ri awọn ẹsun ti o fi kan iṣejọba Ọlọrun ni bi wọn ti ri gan, ki ododo ati aanu Ọlọrun ati iwatiti lae ofin rẹ le wa ni airiwisi titi lae.ANN 221.5

    Iṣọtẹ Satani yoo jẹ ẹkọ fun gbogbo agbaye lati irandiran ẹri titi lae si iwa ati ayọrisi buburu ẹṣẹ. Iṣọwọṣẹjọ Satani, ipa rẹ lori eniyan ati angẹli yoo fihan ohun ti yoo jẹ eso kikọ aṣẹ Ọlọrun silẹ. Yoo jẹ ẹri wipe a so iṣedeede awọn ẹda Ọlọrun pọ pẹlu iṣejọba ati ofin Rẹ. Bayi itan ifarahan buburu iṣọtẹ yoo jẹ aabo ayeraye fun gbogbo awọn ẹda mimọ, lati maṣe jẹ ki a tan wọn jẹ nipa iwa ẹṣẹ lati gba wọn kuro ninu didẹṣẹ ati jijiya rẹ.ANN 221.6

    Titi di opin ijakadi naa ni ọrun, afipa-gba-ohun-ti-ko-tọ-si naa si tẹsiwaju lati da ara rẹ lare. Nigba ti a ṣe ikede wipe a o le oun pẹlu awọn abanikẹdun rẹ kuro ni ibi igbadun, nigba naa ni aṣaju iṣọtẹ naa fi igboya fi irira rẹ si ofin Ẹlẹda han. O ṣe atunsọ ọrọ rẹ wipe awọn angẹli ko nilo akoso, ṣugbọn ki a fi wọn silẹ lati tẹle ero ọkan wọn, eyi ti yoo tọ wọn sọna rere lọjọkọjọ. O kọ aṣẹ Ọlọrun silẹ gẹgẹ bi ihamọ fun ominira wọn o si wipe afojusun oun ni lati ri wipe a pa ofin rẹ; wipe ni gbigba wọn kuro ninu ihamọ rẹ, ogun ọrun a bẹrẹ igbesi aye ti o ga ti o si logo julọ.ANN 221.7

    Pẹlu ohun kan, Satani ati ogun rẹ da Kristi lẹbi patapata fun iṣọtẹ wọn, wọn n sọ wipe ti o ba jẹ wipe a ko ba wọn wi ni, wọn ki ba ti ṣọtẹ. Pẹlu agidi ati orikunkun ninu aigbọran wọn, wọn n ṣa ipa asan lati bi ijọba Ọlọrun wo, sibẹ wọn n sọ pẹlu ọrọ odi wipe wọn jẹ alailẹṣẹ ti n jiya lọwọ agbara aninilara, lẹyin-ọrẹyin, aṣọtẹ nla naa ati awọn ti n ba kaanu kuro ni ọrun.ANN 222.1

    Iru ẹmi kan naa ti o fa iṣọtẹ ni ọrun ṣi n fa iṣọtẹ ni aye. Satani n lo iru ete kan naa ti o lo pẹlu awọn angẹli pẹlu awọn eniyan. Ẹmi rẹ ni o wa n gbe inu awọn ọmọ alaigbọran. Gẹgẹ bi i tire wọn n wa lati wo aala ti ofin Ọlọrun pa lulẹ ki wọn si ṣe ileri ominira fun eniyan nipa riru awọn ilana rẹ. Biba ẹṣẹ wi ṣi n fa iru ẹmi ikorira ati atako kan naa. Nigba ti iṣẹ iranṣẹ ikilọ Ọlọrun ba wọ inu ọkan eniyan lọ, Satani a dari eniyan lati da ara wọn lare ki wọn si wa ikaanu awọn yoku ninu iwa ẹṣẹ wọn. Dipo ki wọn ṣe atunṣe aṣiṣe wọn, wọn a binu si ẹni ti o ba wọn wi, a fi bi ẹnipe oun nikan ṣoṣo ni o fa wahala. Lati akoko Abeli olododo titi di akoko wa ni a ti n fi iru ẹmi kan naa han si awọn ti n ba ẹṣẹ wi.ANN 222.2

    Nipa ṣiṣe ifihan iwa Ọlọrun, gẹgẹ bi o ti ṣe ni ọrun, ti o n jẹ ki a ri I gẹgẹ bi ẹni lile ati onroro, Satani mu ki eniyan o dẹṣẹ. Pẹlu aṣeyege yii, o sọ wipe ikilọ Ọlọrun ti ko tọ ni o fa iṣubu eniyan, gẹgẹ bi o ti fa iṣọte oun.ANN 222.3

    Ṣugbọn Ẹni Ailopin funra Rẹ kede iwa ara Rẹ: “Oluwa Ọlọrun, alaanu ati oloore ọfẹ, onipamọra, ti o kun fun oore ati otitọ, ti o n pa aanu mọ fun ẹgbẹẹgbẹrun, ti o n dari aiṣedeede ji ati irekọja ati ẹṣẹ, ti ki yoo si jẹ ki ẹlẹbi o lọ laijiya.” Eksodu 34:6, 7.ANN 222.4

    Ni lile Satani kuro ni ọrun, Ọlọrun kede ododo Rẹ, o si daabo bo ọwọ itẹ Rẹ. Ṣugbọn nigba ti eniyan ṣẹ nipa ṣiṣe igbọran si itanjẹ ẹmi iyapa, Ọlọrun fi ẹri ifẹ Rẹ han nipa fifi Ọmọ bibi Rẹ kan ṣoṣo silẹ lati ku fun iran ti o baku. Ninu iwẹnumọ ẹṣẹ, a fi iwa Ọlọrun han. Ọrọ nla lati ori agbelebu n fihan gbogbo agbaye wipe a ko le dẹbi iwa ẹṣẹ ti Lusifa yan ru iṣejọba Ọlọrun.ANN 222.5

    Ninu ijakadi laarin Kristi ati Satani, ni akoko iṣẹ iranṣẹ Kristi laye, a fi iwa atannijẹ nla ni han. Ko si ohun ti o le mu ifẹ Satani kuro ni ọkan awọn angẹli ni ọrun ati gbogbo agbaye to ṣegbọran bii ogun buburu ti o gbe ko Olugbala araye. Ọrọ odi onigboya rẹ ti o sọ wipe ki Kristi o jọsin oun, igboya ikugbu rẹ ni gbigbe lọ si ori oke ati sonso tẹmpili, ero arankan ti o farahan ni rirọ Ọ ki O bẹ silẹ lati ori oke giga naa, arankan tí kò sùn, ti o n dọdẹ Rẹ lati ibi kan de ikeji, ti o ru ọkan awọn alufa ati awọn eniyan soke lati kọ ifẹ Rẹ silẹ, ati nikẹyin lati kigbe, “Kan An mọ agbelebu! Kan An mọ agbelebu!”—gbogbo iwọnyi ni o jẹ iyalẹnu fun gbogbo agbaye ti o si bi wọn ninu.ANN 222.6

    Satani ni o fa ki araye o kọ Kristi silẹ. Ọmọ alade iwa buburu lo gbogbo agbara ati alumọkọrọyi rẹ lati pa Jesu run nitori ti o ri wipe aanu ati ifẹ Olugbala, iyọnu ati iṣe jẹjẹ ikaanu Rẹ, n fi iwa Ọlọrun han araye. Satani jijadu fun gbogbo ọrọ ti Ọmọ Ọlọrun sọ, o si lo awọn eniyan gẹgẹ bi aṣoju rẹ lati mu ki igbesi aye Jesu o kun fun ijiya ati ibanujẹ. Ayinike ati ẹtan eyi ti o fẹ fi di iṣẹ Kristi lọwọ, ikorira ti awọn ọmọ alaigbọran fihan, ẹsun buburu ti o fi kan Ẹni ti igbesi aye Rẹ jẹ kiki da ohun rere ti a kò rírí, gbogbo wọn wá lati inu ifẹ jijinlẹ lati gbẹsan. Ina ilara ati arankan ti ko tete jade, ikorira ati igbẹsan, tu jade si Ọmọ Ọlọrun lori Kalfari, nigba ti gbogbo ọrun n wo iṣẹlẹ naa pẹlu ibẹru ati idakẹrọrọ.ANN 222.7

    Nigba ti irubọ nla naa pari, Kristi goke lọ si ọrun, ko gba ijọsin awọn angẹli titi ti O fi bẹbẹ wipe: “Emi fẹ ki awọn ti Iwọ fifun Mi wa pẹlu Mi, nibi ti Mo ba wa.” Johanu 17:24. Nigba naa pẹlu ifẹ ati agbara ti a ko le fẹnusọ ni idahun fi jade wa lati ori itẹ Baba: “Jẹ ki gbogbo awọn angẹli Ọlọrun jọsin fun.” Heberu 1:6. Ko si abawọn kankan lara Jesu. Irẹsilẹ Rẹ pari, irubọ Rẹ pari, a fun ni orukọ kan ti o ju gbogbo orukọ lọ.ANN 222.8

    Bayi ẹbi Satani duro gbọin laisi awawi. O ti fi iwa bi o ti jẹ han gẹgẹ bi onirọ ati apaniyan. A ri i wipe iru ẹmi kan naa ti o fi ṣe akoso awọn ọmọ eniyan, ti wọn wa labẹ agbara rẹ, ni i ba lo bi a ba gba a laaye lati ṣe akoso awọn olugbe ọrun. O ti sọ wipe riru ofin Ọlọrun yoo mu ominira ati igbega wa; ṣugbọn a ri wipe o yọri si igbekun ati irẹsilẹ.ANN 223.1

    Ẹsun irọ ti Satani fi kan iwa ati iṣejọba Ọlọrun farahan bi wọn ti ri gan an. O ti fi ẹsun kan Ọlọrun wipe O n wa ọna lati gbe ara Rẹ ga lasan ni nipa bibeere fun ijọsin ati igbọran lati ọdọ awọn ẹda Rẹ, o si wipe nigba ti Ẹlẹda n beere fun isẹra-ẹni lati ọdọ gbogbo awọn yoku, Oun funra Rẹ ko wuwa isẹra-ẹni bẹẹ ni ko fi ohunkohun silẹ. Ni bayii ti a ti ri wipe Alaṣẹ gbogbo agbaye ti ṣe irubọ ti o ga julọ ti ifẹ le ṣe fun igbala iran ti o baku; nitori “Ọlọrun wa ninu Kristi, O n ba araye laja pẹlu ara Rẹ.” 2 Kọrintin 5:19. A tun ri pẹlu wipe nigba ti Lusifa ṣilẹkun fun atiwọle ẹṣẹ nipasẹ ifẹ rẹ fun ọla ati iṣakoso, Kristi rẹ ara Rẹ silẹ lati le pa ẹṣẹ run, O si ṣe igbọran de oju iku.ANN 223.2

    Ọlọrun fi ikorira Rẹ han si iwa iṣọtẹ. Gbogbo ọrun ri wipe a fi ododo Rẹ han ni dida Satani lẹbi ati ni rira eniyan pada. Lusifa ti sọ wipe bi a ko ba le yi ofin Ọlọrun pada, a ko ni le mu ijiya rẹ kuro pẹlu, gbogbo arufin ni a gbọdọ di lọna lati ri oju rere Ẹlẹda titi lae. O ti sọ wipe iran ti o ṣẹ ti kọja eyi ti a le rapada, nitori naa wọn jẹ ẹran ijẹ ti ọ tọ si oun. Ṣugbọn iku Kristi jẹ itilẹyin fun eniyan, eyi ti a ko le bi lulẹ. Ijiya ofin ṣubu le Ẹni ti O ba Ọlọrun dọgba lori, eniyan si ni ominira lati gba ododo Kristi ati, pẹlu igbe aye ironupiwada ati irẹsilẹ lati ṣẹgun, bi Ọmọ Ọlọrun ti ṣẹgun, lori agbara Satani. Bayi ni Ọlọrun ṣe jẹ olododo ti O tun jẹ Ẹni ti o da gbogbo ẹni ti o gbagbọ ninu Jesu lare.ANN 223.3

    Ṣugbọn ki i ṣe nitori irapada eniyan nikan ni Kristi ṣe wa si aye lati jiya ati lati ku. O wa lati “gbe ofin ga” ati lati “bu iyin fun.” Ki i ṣe ki awọn olugbe aye yii le ri ofin gẹgẹ bi o ti yẹ ki wọn ri nikan; ṣugbọn lati fihan awọn aye yoku ni gbogbo agbala aye wipe ofin Ọlọrun ko le yipada. Bi o ba ṣe wipe a le kọ ọrọ Rẹ silẹ ni, ki ba ti nilo ki Ọmọ Ọlọrun O fi ẹmi Rẹ lelẹ lati ṣe etutu fun titẹ ẹ loju. Iku Kristi fihan wipe o duro titi lae. Ati irubọ ti ifẹ mu ki Baba ati Ọmọ o ṣe, ki a baa le ra ẹlẹṣẹ pada, fihan gbogbo agbaye—ohun ti eto iwẹnumọ nikanṣoṣo tó lati ṣe—wipe ododo ati aanu ni ipilẹ ofin ati iṣejọba Ọlọrun.ANN 223.4

    Ninu idajọ ikẹyin a o ri wipe ko si idi ti o fi yẹ ki ẹṣẹ o wa. Nigba ti Onidajọ gbogbo aye a bere lọwọ Satani, “Kilode ti o fi ṣọtẹ si Mi, ti o si jí awọn ọmọ ijọba Mi?” Ipilẹsẹ ibi ko ni ri awawi kan ṣe. Gbogbo ẹnu ni yoo dakẹ, ti gbogbo ogun iṣọtẹ a si wa ni airiwi.ANN 223.5

    Agbelebu Kalfari, nigba ti o n sọ wipe ofin Ọlọrun wa titi lae, o kede fun gbogbo agbaye wipe iku ni ere ẹṣẹ. Ninu igbe ikẹyin Olugbala, “O pari,” a lu agogo iku Satani. Nigba naa ni a ṣe ipinu lori ijakadi nla ti o ti wa fun ọjọ pipẹ, ti o si daniloju wipe a o pa iwa buburu run nikẹyin. Ọmọ Ọlọrun la inu iboji kọja, ki “O le tipasẹ iku pa ẹni ti o ni agbara iku run, eyi ti i ṣe eṣu.” Heberu 2:14. Ifẹ Lusifa fun igbega ni o jẹ ki o sọ wipe: “Emi yoo gbe itẹ mi ga ju irawọ Ọlọrun lọ: . . . Emi yoo dabi Ẹni Giga julọ.” Ọlọrun sọ wipe: “Emi yoo sọ ọ di eeru lori ilẹ aye, . . . iwọ ki yoo si sí mọ titi lae.” Aisaya 14:13, 14; Isikiẹli 28:18, 19. Nigba ti “ọjọ naa ba de, ti yoo jo bi ina ileru; . . . gbogbo agberaga, bẹẹni ati gbogbo awọn ti wọn wuwa ibi, yoo dabi ageku koriko: ọjọ naa n bọ wa ti yoo jo wọn run, ni Oluwa awọn ọmọ ogun wi, ti ki yoo si fi gbongbo tabi ẹka wọn silẹ.” Malaki 4:1ANN 223.6

    Gbogbo agbala aye ni yoo ṣe ẹlẹri si iwa ati ayọrisi ẹṣẹ. Iparun rẹ patapata, eyi ti i ba ba awọn angẹli lẹru, ti ko si ni bu ọla fun Ọlọrun ni ibẹrẹ, yoo wa da ifẹ Rẹ lare yoo si fi idi ọla Rẹ mulẹ laarin gbogbo awọn ti wọn fẹ lati ṣe ifẹ Rẹ, ati awọn ti ofin Rẹ wa ninu ọkan wọn. Iwa buburu ki yoo si farahan mọ. Ọrọ Ọlọrun sọ wipe: “Ijiya ki yoo dide lẹẹkeji.” Nahumi 1:9. Ofin Ọlọrun ti Satani kẹgan gẹgẹ bi ajaga inira ni a o bọwọ fun bi ofin ominira. Ẹda ti a ti danwo ti o si ti yege ko tun ni yipada kuro ninu igbọran si Ẹni ti a fi iwa Rẹ han ni kikun niwaju wọn gẹgẹ bi ifẹ ti a ko ri idi rẹ ati ọgbọn ailopin.ANN 223.7

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents