Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents
ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORI KẸRINLA—ALATUNṢE IKẸYIN NI ENGLAND

    Bi Luther ti n ṣi Bibeli ti a pade silẹ fun awọn ara Germany, Ẹmi Ọlọrun n mi si Tyndale lati ṣe ohun kan naa fun England. Bibeli Latin ti o ni ọpọlọpọ aṣiṣe ni a fi ṣe itumọ Bibeli Wycliffe. A koi ti i tẹ ẹ jade lati inu ile itẹwe, ọwọ ẹda ti a fi ọwọ kọ ko pọ rara ti o fi jẹ wipe awọn perete ti wọn jẹ ọlọrọ ati awọn ijoye ni wọn le ni; siwaju si, nitori pe ijọ ti fi ofin ti o lagbara de e, ẹda rẹ ko pọ nita. Ni 1516, ọdun kan ṣaaju ki Luther to gbe awọn afiyesi rẹ sita, Erasmus ti tẹ ẹda Majẹmu Tuntun jade ni ede Greek ati Latin. Ni akoko yii fun igba akọkọ, a tẹ ọrọ Ọlọrun jade ni ede ti a fi kọ gan an. Gbogbo aṣiṣe awọn ẹda ti atẹyinwa ni a ṣe atunṣe si ninu iṣẹ yii, a tun kọ ọ ni ọna ti o yeni daradara. O jẹ ki ọpọ ninu awọn ọmọwe o ni oye otitọ ni ọna ti o dara si, o si fi okun fun iṣẹ atunṣe. Ṣugbọn pupọ ninu awọn ti ko kawe ni koi tii mọ nipa ọrọ Ọlọrun. Tyndale yoo pari iṣẹ Wycliffe nipa fifun awọn ara ilu rẹ ni Bibeli.ANN 109.1

    Akẹkọ ti n mura siṣẹ, ati ẹni ti n fi tọkantọkan wa otitọ, o gba iyinrere lati inu Majẹmu Tuntun ni ede Greek ti Erasmus ṣe. O waasu igbagbọ rẹ laibẹru, o fi n kọni wipe a nilati fi Iwe Mimọ dan gbogbo ikọni wo. Awọn atẹle popu n sọ wipe ijọ ni o funni ni Bibeli, ati pe ijọ nikanṣoṣo naa ni o le ṣe itumọ rẹ, ṣugbọn Tyndale dawọn lohun wipe: “Njẹ ẹ mọ ẹni ti o kọ awodi lati maa dọdẹ? Nitori naa, Ọlọrun ọun kan naa ni O kọ awọn ọmọ Rẹ ti ebi n pa lati wa Baba wọn ninu ọrọ Rẹ. Ẹyin kọ ni o fun wa ni Iwe Mimọ rara, ẹyin ni o pa a mọ kuro ni oju wa; ẹyin ni ẹ n sun awọn ti n waasu rẹ nina, bi o ba si ṣe e ṣe ni, ẹ ba sun Iwe Mimọ funra rẹ nina.”ANN 109.2

    Ọpọ eniyan ni wọn fi iye si iwaasu Tyndale; ọpọ si gba otitọ naa. Ṣugbọn awọn alufa kun fun iṣọra, ko pẹ ti o kuro nibi iṣẹ rẹ ti wọn wa lati fi idẹruba ati ṣiṣe afihan ni ọna ti ko tọ ba iṣẹ rẹ jẹ. Ni ọpọ igba wọn maa n ṣe aṣeyọri. Á sọ wipe, “Kini a fẹ ṣe.” “Nigba ti a ba n funrugbin si ibi kan, ọta a wa ba ibi ti o ṣẹṣẹ fi silẹ jẹ. Mi o le wà ni ibi gbogbo. Ah! bi awọn Kristẹni ba ni Iwe Mimọ ni ede ara wọn, wọn a le doju kọ awọn ọlọgbọn ẹwẹ wọnyi. Laisi Iwe Mimọ, ko ṣe e ṣe lati fi ẹsẹ awọn ọmọ ijọ duro ninu otitọ.”ANN 109.3

    Erongba miran gba ọkan rẹ kan. O sọ wipe, “Èdè Israeli ni wọn fi n kọ O. Dafidi ninu tẹmpili Jehofa; ṣe ko wa yẹ ki iyinrere o sọ ede ilẹ Gẹẹsi fun wa bi? . . . Ṣe o yẹ ki ijọ o ri imọlẹ ni afẹmọjumọ ju ọsan gangan lọ bi? . . . Awọn Kristẹni gbọdọ ka Majẹmu Tuntun ni ede abinibi wọn.” Ede aiyede bẹ silẹ laarin awọn ọmọwe ati olukọ ijọ. Nipasẹ Bibeli nikan ṣoṣo ni eniyan fi le ri otitọ. “Ọkan gba ọmọwe yii gbọ, ekeji gba omiran gbọ. . . . Awọn wọnyi tun wa n tako ara wọn. Bawo wa ni a ṣe le mọ ẹni ti o n sọ otitọ yatọ si ẹni ti ko sọ otitọ? . . . Nitootọ nipasẹ ọrọ Ọlọrun ni.”ANN 109.4

    Ko pẹ lẹyin eyi ti ọmọwe ọmọ ijọ Katoliki kan n ba ṣe ariyanjiyan, o sọ wipe: “O dara fun wa lati maṣe ni ofin Ọlọrun ju lati maṣe ni ofin popu lọ.” Tyndale da lohun wipe: “Mo tako popu ati gbogbo awọn ofin rẹ; bi Ọlọrun ba da ẹmi mi si, ni ọdun diẹ si, maa jẹ ki ọmọde ti n roko o mọ Iwe Mimọ ju o lọ.”ANN 109.5

    Erongba ti o bẹrẹ si ni i yan laayo, eyi ni lati fun awọn eniyan ni Majẹmu Tuntun ni ede abinibi wọn bẹrẹ si ni i wa si imuṣẹ, loju ẹsẹ o bẹrẹ iṣẹ naa. Inunibini le e kuro ni ile rẹ, o lọ si London, fun igba diẹ o ri aaye lati ṣe iṣẹ rẹ laisi idiwọ. Ṣugbọn inunibini awọn atẹle popu tun mu ki o sa kuro nibẹ. O dabi ẹnipe ilẹkun gbogbo England ti mọ, o wa pinu lati wa aabo ni Germany. Nibi ni o ti bẹrẹ titẹ Majẹmu Tuntun ni ede Gẹẹsi. Ẹẹmeji ni a da iṣẹ naa duro; ṣugbọn bi a ba di lọwọ ni ilu kan, a lọ si ibomiran. Nikẹyin, o lọ si Worms, nibi ti Luther ti wi awijare fun iyinrere niwaju igbimọ ni ọdun diẹ sẹyin. Ọpọ awọn ọrẹ iṣẹ Atunṣẹ ni wọn n gbe ninu ilu naa, Tyndale si tẹsiwaju ninu iṣẹ rẹ nibẹ laisi idiwọ mọ. A tẹ ẹgbẹrun mẹta Majẹmu Tuntun jade laipẹ, ẹda miran tun jade ni ọdun kan naa.ANN 109.6

    Pẹlu ifẹ ọkan ti o lagbara ati iforiti, o tẹsiwaju ninu iṣẹ rẹ. Bi o tilẹ jẹ wipe awọn alaṣẹ England sọ ibudo igunlẹsi wọn pẹlu iṣọra ti o lagbara, ni oriṣiriṣi ọna ni a n gba gbe ọrọ Ọlọrun wọ inu London ni bonkẹlẹ, ti a si n pin kaakiri gbogbo orilẹ ede naa. Lasan ni awọn ẹlẹsin popu n ṣe lati tẹ otitọ rì. Ni igba kan, biṣọbu ti Durham ra gbogbo Bibeli ti ontawe ti o jẹ ọrẹ Tyndale kan ni lori, pẹlu ero lati pa wọn run, o rò wipe eyi yoo di iṣẹ naa lọwọ jọjọ. Ṣugbọn dipo eyi, a lo owo naa lati ra awọn ohun elo ti a fi tẹ ẹda tuntun ti o tun dara si jade, eyi ti ki ba ti ṣe e ṣe, bikoba i se tori eyi. Nigba ti a wa ti Tyndale mọle, a ṣe ileri lati da a silẹ bi yoo ba daruko awọn ti wọn n ran an lọwọ lati ri owo ti o fi n tẹ awọn Bibeli naa jade. O dahun wipe biṣọbu ti Durham ṣiṣẹ ju ẹnikẹni lọ; nitori nipa sisan owo nla fun iwe ti o wa nilẹ, o ran an lọwọ lati tẹsiwaju pẹlu igboya.ANN 110.1

    A fi Tyndale han si ọwọ awọn ọta rẹ, ni igba kan, o wa ni atimọle fun ọpọ oṣu. Nikẹyin, o jẹri si igbagbọ rẹ pẹlu iku ajẹriku; ṣugbọn awọn ohun elo ti o pese silẹ ran awọn ọmọ ogun miran lọwọ lati tẹsiwaju ninu ija naa lati akoko yẹn titi di isinsinyii.ANN 110.2

    Latimer waasu lati ori pẹpẹ iwaasu wipe ede awọn eniyan ni o yẹ ki a maa fi ka Bibeli. O sọ wipe “Ọlọrun funra Rẹ” ni o kọ Iwe Mimọ; Iwe Mimọ si kopa ninu agbara ati iwa titi lae Ẹni ti o kọ ọ. “Ko si ọba, olotu ijọba, adajọ, ati alaṣẹ . . . ti ko ni ojuṣe lati ṣe igbọran si . . . ọrọ mimọ Rẹ.” “Ẹ maṣe jẹ ki a gba ọna abuja kan, ṣugbọn ki ẹ jẹ ki ọrọ Ọlọrun o dari wa: ẹ maṣe jẹ ki a tọ ipasẹ awọn baba nla wa, tabi ki a wa ohun ti wọn wa, bikoṣe ohun ti o yẹ ki wọn ṣe”ANN 110.3

    Barnes ati Frith, ọrẹ Tyndale tootọ dide lati gbeja otitọ. Ridleys ati Cranmer tẹle. Awọn adari ninu iṣẹ Atunṣe ti ilẹ England jẹ ọmọwe, a gbe oriyin fun pupọ ninu wọn gẹgẹ bi awọn ti wọn ti goke agba ninu itara tabi ifọkansin ninu ẹsin Romu. Wọn tako ẹsin ijọ padi nitori imọ ti wọn ni nipa “ijọ mimọ” naa. Imọ ti wọn ni nipa awọn ohun ijinlẹ Babiloni fun ijẹri atako ti wọn ṣe si lagbara.ANN 110.4

    “Latimer sọ wipe, “Mo fẹ beere ibeere ti o ṣajeji kan.” “Tani biṣọbu ati alufa ti o mura siṣẹ julọ ni England?. . . Mo ri wipe ẹ tẹti silẹ, ẹ fẹ ki n darukọ rẹ. . . . Ma a sọ fun yin: eṣu ni. . . . Ko jade kuro ninu agbegbe rẹ ri; nigbakugba ti ẹ ba wa, o maa n wa nile ni; . . . o maa n wa nibi iṣẹ rẹ. . . . Ẹ ko le ri laiṣe iṣẹ, mo fi da a yin loju. . . . Nibi ti eṣu n gbe, . . . ko ni si iwe nibẹ, bikoṣe abẹla; ko ni si Bibeli nibẹ, ṣugbọn ilẹkẹ a wa nibẹ; ko ni si imọlẹ iyinrere nibẹ; bikoṣe imọlẹ abẹla, ani ni ọsan gangan; . . . agbelebu Kristi a wá silẹ, ibi idaniloro awọn yọpoyọpo a wa sókè; . . . ko ni si dida aṣọ bo awọn to wa ni ihoho, awọn otoṣi, ati awọn alailagbara, bikoṣe siṣe awọn ère, ati awọn okuta lọṣọ; wọn a wo awọn ilana Ọlọrun ati ọrọ mimọ Rẹ lulẹ. . . . Ah bi awọn alufa wa ba le mura siṣẹ lati gbin ọka ikọni rere bi Satani ti n gbin korofo ati asan!”ANN 110.5

    Ipilẹ ẹkọ nla ti awọn Alatunṣe wọnyi tẹle—ọkan naa ti awọn Waldenses, Wycliffe, John Huss, Luther, Zwingli, ati awọn ti wọn dara pọ mọ wọn gbagbọ—ni wipe Iwe Mimọ ni aṣẹ ti ko le baku fun igbagbọ ati iṣesi. Wọn ko gba ẹtọ awọn popu, igbimọ, awọn Baba ijọ, ati awọn ọba lati dari ọkan awọn eniyan lori ọrọ ẹsin. Bibeli ni aṣẹ wọn, ikọni rẹ ni wọn si fi dan gbogbo ikọni ati igbagbọ wo. Igbagbọ ninu Ọlọrun ati ọrọ Rẹ fun awọn eniyan mimọ wọnyi lokun bi wọn ti n fi ẹmi wọn lelẹ nibi idanasunni. “Tu ara rẹ ninu” ni Latimer sọ fun ajẹriku ẹlẹgbẹ rẹ bi ina ti fẹ pa wọn lẹnu mọ, “nipa oore ọfẹ Ọlọrun, a yoo tan imọlẹ kan ni England loni, ti mo ni igbagbọ wipe a ki yoo le paku.”ANN 110.6

    Irugbin otitọ ti Columba ati awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ fọn kalẹ ni Scotland koi tii parun tan. Fun ọpọ ọdun lẹyin ti awọn ijọ ni England tẹriba fun aṣẹ Romu, awọn ti Scotland ṣi ni ominira wọn. Ṣugbọn ni ọrundun kejila, a fi ẹsin popu lọlẹ nibẹ, ko si si ilu miran ti o ti jẹ abaṣẹ wàá bi ti ibẹ. Ko si ibi ti okunkun rẹ ti tun gbilẹ. Sibẹ awọn itansan imọlẹ n wa lati tan si okunkun, wọn si n funni ni ileri ọjọ ti n yọ. Awọn Lollards wa lati England pẹlu Bibeli ati awọn ikọni Wycliffe, wọn ṣiṣẹ pupọ lati pa imọ iyinrere mọ, ko si akoko ti ko ni awọn ẹlẹri ati ajẹriku tirẹ.ANN 110.7

    Nigba ti iṣẹ Atunṣe nla bẹrẹ, awọn iwe Luther ti jade, lẹyin eyi, Majẹmu Tuntun ti Tyndale ni ede England. Awọn oloye ijọ ko mọ, awọn iranṣẹ wọnyi rọra la awọn oke ati afonifoji kọja laisi ariwo, wọn n tun imọlẹ otitọ ti o ti fẹrẹ paku tan ni Scotland tan, wọn si n ṣe atunṣe si iṣẹ ti ifiyajẹni Romu ṣe fun irinwo ọdun.ANN 111.1

    Ẹjẹ awọn ajẹriku fun ẹgbẹ naa ni okun tuntun. Awọn adari ijọ padi taji si ewu ti o n wu iṣẹ wọn lojiji, wọn si sun diẹ lara awọn ti wọn níyì, ti wọn si lọla julọ ninu awọn ọmọ ilẹ Scotland níná. Wọn gbe pẹpẹ iwaasu dide, nibi ti a ti n gbọ ọrọ awọn ajẹri ti n ku lọ wọnyi kaakiri gbogbo ilẹ naa, o si n mu inu awọn eniyan dun pẹlu erongba ainipẹkun lati ja ide igbekun Romu.ANN 111.2

    Hamilton ati Wishart, iwa wọn dara gẹgẹ bi a ti bi wọn lati ile rere, pẹlu ọpọ awọn ọmọ ẹyin wọn fi ẹmi wọn lelẹ ninu ina. Ṣugbọn ẹnikan jade wa lati ibi ti a ti dana sun Wishart, ẹni ti ina ko le pa lẹnu mọ, ẹni ti yoo ṣe akọlu si ẹsin popu patapata ni Scotland labẹ itọsọna Ọlọrun.ANN 111.3

    John Knox yipada kuro ninu aṣa ati mimọ Ọlọrun pẹlu adura ati asaro ti ijọ lati jẹ ninu awọn otitọ ọrọ Ọlọrun; ikọni Wishart tun fun ipinu rẹ lokun lati fi ijọ Romu silẹ, ati lati darapọ mọ awọn Alatunṣe ti a n ṣe inunibini si.ANN 111.4

    Awọn ọrẹ rẹ rọ ọ lati ṣe iṣẹ oniwaasu, ko fe gba ojuṣe yii nitori ibẹru, lẹyin ọjọ diẹ ti o se ara rẹ mọle, ti o si ṣe asaro kikankikan ninu ọkan ara rẹ ni o to gba. Ṣugbọn lẹyin igba ti o gba ipo yii, o tẹsiwaju pẹlu ipinu ti a ko le yipada ati igboya ti ko yẹ ni gbogbo igba ti o wa laaye. Alatunṣe ọlọkan tootọ yii ko bẹru oju eniyan. Ina ajẹriku ti n jo layika rẹ tubọ n jẹ ki itara rẹ o pọ si ni. Pẹlu aake onroro ti n jo belebele lori rẹ, o duro gbọin, o n tako ẹsin ibọriṣa lọtunlosi ati lati le bi i wo.ANN 111.5

    Nigba ti o fi ojukoju pẹlu ọbabinrin Scotland, niwaju ẹni ti itara ọpọlọpọ awọn adari Protestant ti n dinku, John Knox jẹri si otitọ laimikan. A ko le fi oju rere yi ọkan rẹ pada; ko si ṣojo niwaju ihalẹ. Ọbabinrin naa fi ẹsun ẹkọ odi kan an. O kọ awọn eniyan lati gba ẹsin ti ilu ko fi ọwọ si, o wa sọ wipe, o ru ofin Ọlọrun ti o ni ki awọn ọmọ ilu o ṣe igbọran si awọn ijoye wọn. Knox dahun pẹlu iduroṣinṣin wipe:ANN 111.6

    “Niwọn igba ti ẹsin tootọ ki i ti i gba agbara tabi aṣẹ rẹ lati ọdọ awọn ijoye aye, bikoṣe lati ọdọ Ọlọrun ayeraye nikanṣoṣo, bẹẹ gẹgẹ ni awọn ọmọ ilu wọn ko gbọdọ ṣe ẹsin wọn gẹgẹ bi ifẹ awọn ijoye wọn. Nitori ni ọpọ igba ni awọn ijoye maa n jẹ òpè julọ ninu gbogbo awọn eniyan nipa ẹsin Ọlọrun tootọ. . . . Bi gbogbo iru ọmọ Abrahamu ba n ṣe ẹsin Farao, ẹni ti wọn jẹ ọmọ ilu rẹ fun igba pipẹ, mo bẹ ọ arabinrin, iru ẹsin wo ni iba wa ninu aye? Tabi bi gbogbo eniyan ba n ṣe ẹsin awọn ọba Romu ni akoko awọn apostoli, iru ẹsin wo ni iba wa ni ori ilẹ aye? . . . Nitori naa arabinrin, o le ri wipe ko jẹ dandan ki awọn ọmọ ilu o ṣe ẹsin awọn ijoye wọn, bi o tilẹ jẹ wipe a paṣẹ wipe o yẹ ki wọn ṣe igbọran si wọn.”ANN 111.7

    Maria dahun wipe: “Ẹyin n tumọ Iwe Mimọ ni ọna kan, awọn [awọn olukọ Katoliki ti Romu] n tumọ rẹ ni ọna miran; tani ki emi o gbagbọ, ati tani yoo jẹ adajọ?”ANN 111.8

    Alatunṣe naa dahun wipe, “Iwọ gba Ọlọrun, ti n sọrọ kedere lati inu ọrọ Rẹ gbọ; ati pe o ko gbọdọ gba ohunkohun ti o ba yatọ si ohun ti ọrọ naa ba fi kọni gbọ. Ọrọ Ọlọrun han kedere ninu ara rẹ; bi ohunkohun ba ṣokunkun, Ẹmi Mimọ ti ki i tako ara Rẹ yoo ṣe alaye rẹ yekeyeke ni ibo miran, ti ko fi ni si iyemeji mọ ayafi fun ẹnikẹni ti o ba mọọmọ jẹ alaimọkan.”ANN 111.9

    Iru awọn otitọ bawọnyi ni Alatunṣe ti ko bẹru naa sọ ni eti ọbabinrin pẹlu ẹmi rẹ ninu ewu. Pẹlu iru igboya kan naa, o di ero rẹ mu ṣinṣin, o n gbadura, o si n ja ogun Oluwa titi ti Scotland fi bọ kuro lọwọ ẹsin popu.ANN 111.10

    Bi a ti fi ẹsin Protestant mulẹ ni England gẹgẹ bi ẹsin orilẹ ede din inunibini ku, ṣugbọn ko da duro patapata. Nigba ti wọn kọ ọpọlọpọ awọn ikọni Romu silẹ, wọn si tun di ọpọlọpọ awọn aṣa rẹ mu. Wọn kọ aṣẹ popu silẹ, ṣugbọn wọn fi ọba jẹ olori ijọ dipo rẹ. Wọn yapa pupọpupọ kuro ninu iwa mimọ ati ailabawọn iyinrere ninu isin wọn. Wọn koi ti i ni oye ẹkọ nla ominira ti ẹsin. Bi o tilẹ jẹ wipe awọn alaṣẹ ti wọn jẹ Protestant ki i saba maa n lo awọn iwa onroro ti Romu maa n lo lati tako ẹkọ odi, sibẹ a ko bọwọ fun ẹtọ olukuluku lati jọsin Ọlọrun gẹgẹ bi ẹri ọkan rẹ ti sọ ọ. Gbogbo eniyan ni a fẹ ki o gba awọn ikọni ki wọn si tẹle ilana ijọsin ti ijọ ilu ba gbe kalẹ. Awọn ti ko gbà a jiya inunibini lọna pupọ tabi kekere fun ọpọ ọdun.ANN 111.11

    Ni ọrundun kẹtadinlogun, ọpọ alufa ni a yọ kuro ninu ipo wọn. A fi ofin de awọn eniyan, bi wọn ko ba fẹ san owo itanran nla, tabi ki wọn lọ si ọgba ẹwọn, tabi ki a lé wọn kuro ninu ilu, lati maṣe kopa ninu ipade ẹsin kankan ayafi eyi ti ijọ ba fi ọwọ si. O pan dandan fun awọn ti wọn jẹ olootọ ti wọn ko le ṣe e lati ma jọsin Ọlọrun lati pade ni ibi hiha ati ibi ti o farasin lati maa jọsin, ati ni igba miran ninu igbo ni aṣalẹ. Awọn ọmọ Oluwa ti a fọnka ti a n ṣe inunibini si n pejọ pọ sinu igbo ti o n daabo bo wọn, tẹmpili ti Ọlọrun funra Rẹ kọ, lati tu ọkan wọn sita ninu adura ati iyin. Ṣugbọn pẹlu gbogbo iṣọra wọn, ọpọlọpọ ni wọn jiya nitori igbagbọ wọn. Ọgba ẹwọn kun akunfaya. A le awọn miran lọ si ilẹ ajeji. Sibẹ Ọlọrun wa pẹlu awọn eniyan Rẹ, inunibini ko si le ṣiṣẹ lati pa ijẹri wọn lẹnu mọ. Ọpọlọpọ ni a le lọ kọja okun lọ si ilẹ America, ti wọn si fi ipilẹ ominira ẹsin ati ijọba lelẹ nibi, eyi ti o jẹ agbara ati ogo orilẹ ede yii.ANN 112.1

    O tun ṣẹlẹ gẹgẹ bi o ti ṣẹlẹ ni akoko awọn apostoli, inunibini ṣiṣẹ lati jẹ itẹsiwaju fun iyinrere. Ninu ile ẹwọn ẹlẹgbin ti a ko awọn ọdaran ati awọn oniwabuburu si, John Bunyan n gbe ni ayika ọrun; nibẹ ni o ti kọ iwe apejuwe agbayanu rẹ ti o sọ nipa arinrin ajo kan ti o n kọja lọ lati ilẹ iparun lọ si ilu mimọ. Fun bi igba ọdun ohùn naa lati inu ọgba ẹwọn Bedford si n ba ọkan awọn eniyan sọrọ pẹlu agbara ti n mi ni lọkan. Pilgrim’s Progress (Itẹsiwaju Arinrinajo) ati Grace Abounding to the Chief of Sinners (Oore ọfẹ ti o pọ Yanturu fun Ọga awọn Ẹlẹṣẹ) ti Bunyan kọ ti dari ọpọlọpọ ẹsẹ si ọna iye.ANN 112.2

    Baxter, Flavel, Alleine, ati awọn eniyan miran ti wọn ni ẹbun, ti wọn mọwe, ti wọn tun ni iriri ti o jinlẹ ninu igbagbọ Kristẹni dide lati ṣe igbeja akọni fun igbagbọ ti a fun awọn eniyan mimọ lẹẹkan ṣoṣo. Iṣẹ ti awọn eniyan wọnyi ṣe, awọn ti awọn alaṣẹ aye fi ofin de, ti wọn tun tako, ko le parun laelae. Fountain of Life (Orisun Iye) ati Method of Grace (Ilana Oore Ọfẹ) ti Flavel kọ ti kọ ọpọlọpọ awọn eniyan bi wọn ti ṣe le pa ọkan wọn mọ si ọdọ Kristi. Reformed Pastor (Alufa ti a Fọ Mọ) ti Baxter kọ ti jẹ ibukun fun ọpọlọpọ ti wọn fẹ isọji ninu iṣẹ Ọlọrun, ati Saints’ Everlasting Rest (Isinmi Ainipẹkun fun Awọn Eniyan Mimọ) rẹ ti ṣiṣẹ lati dari awọn eniyan si “isinmi” ti o kù fun awọn eniyan Ọlọrun.ANN 112.3

    Ọgọrun ọdun lẹyin eyi, ni akoko okunkun nla, Whitefield ati awọn Wesley fi ara han gẹgẹ bi atan-imọlẹ fun Ọlọrun. Labẹ akoso ijọ ilu, awọn eniyan England rẹwẹsi ninu ẹsin ti o fi jẹ wipe a nira pupọ lati da a mọ yatọ si ẹsin ibọriṣa. Ẹsin ibilẹ ni ohun ti o n wu awọn alufa lati kọ, o si wọpọ ninu awọn ohun ti wọn gbagbọ nipa Ọlọrun. Awọn eniyan pataki ninu ilu kẹgan ẹmi ifọkansin, nitori wọn ri ara wọn bi ẹni ti o ga ju erokero ẹsin rẹ lọ. A fi awọn eniyan lasan ti wọn ku ninu ilu, ti wọn jẹ ope paraku silẹ fun iwa ipa, ti ijọ ko si ni igboya tabi igbagbọ lati ṣe atilẹyin fun iṣẹ otitọ ti o ti ṣubu.ANN 112.4

    Ikọni nla ti idalare nipa igbagbọ ti Luther fi kọni yekeyeke ni a ti fẹrẹ gbagbe tan; ilana ẹsin Romu ti gbigbẹkẹle iṣẹ rere fun igbala si ti rọpo rẹ. Whitefield ati awọn Wesley, jẹ ọmọ ijọ ilu, ṣugbọn wọn fi tọkantọkan wa ojurere Ọlọrun, a si ti kọ wọn wipe wọn le ri nipa igbesi aye mimọ ati ṣiṣe awọn ojuṣe ẹsin.ANN 112.5

    Nigba ti ara Charles Wesley ko ya nigba kan, ti a si ro wipe yoo ku, a beere lọwọ rẹ ohun ti ireti iye ainipẹkun rẹ duro le lori. Idahun rẹ ni pe: “Mo ti fi gbogbo agbara mi sin Ọlọrun.” Nigba ti o dabi ẹnipe idahun rẹ ko tẹ awọn ọrẹ rẹ ti wọn beere ibeere yii lọrun, Wesley ro wipe: “Kini! ṣe awọn akitiyan mi ko to ipilẹ fun ireti ni? Ṣe yoo wa fi awọn akitiyan mi dun mi ni? Mi o ni ohun miran lati gbẹkẹle?” Iru okunkun dudu yii ni o ṣubu si ori ijọ, ti o mu iwẹnumọ ẹṣẹ pamọ, ti o fi ogo Kristi dun Un, ti o si n yi ọkan awọn eniyan kuro ninu ireti kan ṣoṣo fun igbala—ẹjẹ Olurapada ti a kan mọ agbelebu.ANN 112.6

    A dari Wesley ati awọn ẹlẹgbẹ rẹ lati ri wipe inu ọkan ni ẹsin tootọ wa, ati wipe ofin Ọlọrun tàn de inu ero ati iṣe pẹlu. Pẹlu igbagbọ wipe o jẹ dandan ki ọkan o jẹ mimọ ati wipe o yẹ ki iwa o tọna, wọn fi tọkantọkan bẹrẹ igbesi aye tuntun. Pẹlu iṣẹ agbara ati adura wọn ṣe akitiyan lati bori iwa ibi ti o wa ninu ọkan. Wọn gbe igbesi aye isẹra-ẹni, ifẹ, ati irẹlẹ, wọn n fi okun nla ṣe akiyesi ati aṣerege ohun gbogbo ti wọn ro wipe yoo ran wọn lọwọ lati ri ohun ti wọn nifẹsi julọ—iwa mimọ naa ti yoo jẹ ki wọn ri oju rere Ọlọrun. Ṣugbọn wọn ko ri ohun ti wọn n wa. Pabo ni gbogbo akitiyan wọn lati yọ ara wọn kuro ninu idalẹbi ẹṣẹ tabi lati ja ara wọn gba kuro lọwọ agbara rẹ. Iru ijakadi yii kan naa ni Luther ni iriri rẹ ni yara rẹ ni Erfurt. Iru ibeere kan naa ni o n damu ọkan rẹ—”Bawo ni eniyan ṣe le jẹ olododo niwaju Ọlọrun?” Jobu 9:2.ANN 113.1

    A yoo tun ina otitọ ti o ti fẹrẹ ku tan ni ori pẹpẹ ẹsin Protestant tan lati ara ina atijọ ti a mu wa lati ọdun gbọọrọ nipasẹ awọn Kristẹni Bohemia. Lẹyin iṣẹ Atunṣe, awọn ọmọ ogun Romu pa ẹsin Protestant rẹ ni Bohemia. O di dandan fun gbogbo awọn ti wọn kọ lati kọ otitọ silẹ lati salọ. Awọn miran ri aabo ni Saxony, wọn si pa igbagbọ atijọ mọ nibẹ. Lati ọdọ awọn arọmọdọmọ Kristẹni wọnyi ni imọlẹ ti wa si ọdọ Wesley ati awọn akẹgbẹ rẹ.ANN 113.2

    A ran John ati Charles Wesley lọ gẹgẹ bi ajiyinrere ni ilẹ Amerika lẹyin ti a ti gbe ọwọ le wọn lori ninu iṣẹ iwaasu. Ẹgbẹ awọn Moravia kan wa ninu ọkọ oju omi ti wọn wa. Wọn koju ìjì líle ni oju ọna, John Wesley fi oju koju pẹlu iku, o si ri wipe ohun ko ni idaniloju alaafia pẹlu Ọlọrun. Awọn ara Germany ni idakeji fi idakẹrọrọ ati igbẹkẹle ti o ṣajeji si han.ANN 113.3

    O sọ wipe, “O ti pẹ ti mo ti n wo iwa atọkanwa wọn. Gbogbo igba ni wọn n jẹri si ẹmi irẹlẹ wọn, nipa ṣiṣe iṣẹ pẹpẹẹpẹ fun awọn ero inu ọkọ ti eyikeyi ninu awọn ara England ko le ṣe; eyi ti wọn n fẹ lati ṣe laigba owo, wọn n sọ wipe o dara fun ọkan igberaga wọn, ati Olugbala wọn ti O jẹ onifẹ ti ṣe ju iyẹn lọ fun wọn. Ojoojumọ si ni wọn maa n ri anfani lati fi iwa tutu han, eyi ti iwa ipa kan ko le yẹ. Bi a ba ti wọn, lu wọn, tabi ju wọn si ẹgbẹ kan, wọn a dide, wọn a si gba ibomiran lọ; ko si aroye kan ni ẹnu wọn. Anfani wa wa nisinsinyi lati fihan boya a ti gbà wọn kuro lọwọ ẹmi ibẹru gẹgẹ bi a ti gba wọn kuro lọwọ ẹmi igberaga, ibinu ati igbẹsan. Ni akoko ti wọn n kọ orin ti wọn fi bẹrẹ isin wọn, okun ru soke, o si fọ ìgbòkun ọkọ ti o ṣe pataki julọ si wẹwẹ, omi bo inu ọkọ, o si kun bebe ọkọ ti o fi dabi ẹnipe omi ti gbe wọn mi. Awọn ara England bẹrẹ si ni i pariwo. Awọn ara Germany n fi pẹlẹkutu kọrin lọ. Nigba ti o ya, mo beere lọwọ ọkan lara wọn wipe ‘Ṣe ẹru ko ba yin ni?’ O dahun wipe, ‘Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun, rara.’ O fi irẹlẹ dahun wipe, ‘Rara; awọn obinrin ati awọn ọmọde wa ko bẹru lati ku’”ANN 113.4

    Nigba ti wọn de Savannah, Wesley gbe pẹlu awọn ara Moravia fun igba diẹ, iwa Kristẹni wọn si fi ọwọ ba a lọkan pupọpupọ. Nigba ti o n fi ilana ẹsin ijọ England ti ko ni ẹmi we ọkan lara isin wọn, o kọwe wipe: “Ailabula ati ọwọ gbogbo rẹ fẹrẹ jẹ ki n gbagbe ẹẹdẹgbẹsan (1700) ọdun ti o wa ni aarin wọn, mo ronu wipe mo wa ninu awujọ ti ko ti si aṣa tabi ijọba; ṣugbọn ti Pọlu apàtíbàbà, tabi Peteru apẹja dari eto naa; sibẹ pẹlu ifihan Ẹmi ati agbara.”ANN 113.5

    Nigba ti o pada si England, labẹ itọsọna oniwaasu ara Moravia, Wesley ni oye kikun nipa igbagbọ inu Bibeli. O ri wipe oun nilati kọ gbogbo igbẹkẹle oun ninu iṣẹ ọwọ ara oun fun igbala silẹ, oun si nilati gbẹkẹle “Ọdọ Aguntan Ọlọrun ti o ko ẹṣẹ araye lọ” patapata. Ninu ipade ẹgbẹ awọn ara Moravia kan ni London, a ka gbolohun kan lati inu iwe Luther, ti o ṣe alaye iṣẹ Ẹmi Ọlọrun ninu ọkan onigbagbọ. Bi Wesley ti tẹti silẹ, igbagbọ tan ninu ọkan rẹ. O sọ wipe, “Mo ri ti ọkan mi gbona ni ọna ti o ṣajeji.” “Mo ni imọlara wipe mo gbẹkẹle Kristi, Kristi nikan ṣoṣo fun igbala: a fun mi ni idaniloju wipe O ti ko awọn ẹṣẹ mi ani temi, o si ti gbami la kuro ni ọwọ ofin ẹṣẹ ati iku.”ANN 113.6

    Ni gbogbo ọdun gbọọrọ ti o fi n ṣe wahala ti n kaarẹ bani, ti ko si fun ni itunu—awọn ọdun isẹra kikoro, itiju ati irẹra-ẹni silẹ—Wesley fi tọkantọkan rọ mọ ero rẹ kan ṣoṣo lati ri Ọlọrun. Ni akoko yii, o ri I, o si ri oore ọfẹ ti o n ṣe wahala lati ni nipa awẹ ati adura, nipa ṣiṣe itọrẹ aanu ati isẹra ẹni, wipe ẹbun ni, “laisi owo tabi idiyele.”ANN 114.1

    Lọgan ti a fi ẹsẹ rẹ mulẹ ninu Kristi, ọkan rẹ gbona pẹlu ifẹ lati tan imọ iyinrere ologo ti oore ọfẹ Ọlọrun lọfẹ kalẹ si ibi gbogbo. O sọ wipe, “Mo ri gbogbo aye gẹgẹ bi agbegbe mi; nibikibi ti mo ba wa ninu rẹ, mo ri wipe o yẹ o tọ, ojuṣe mi si ni lati sọ iroyin ayọ igbala fun gbogbo ẹni ti o ba fẹ lati gbọ.”ANN 114.2

    O tẹsiwaju ninu igbesi aye ofin toto ati isẹra ẹni rẹ, ṣugbọn nisinsinyii, ki i ṣe idi, bikoṣe ayọrisi igbagbọ; ki i ṣe gbongbo, bikoṣe eso iwa mimọ. Oore ọfẹ Ọlọrun ninu Kristi ni ipilẹ ireti Kristẹni, oore ọfẹ yii yoo si fi ara han ninu igbọran. Wesley fi igbesi aye rẹ jin fun iwaasu awọn otitọ nla ti o ti gba—idalare nipa igbagbọ ninu ẹjẹ iwẹnumọ Kristi, ati agbara iyipada Ẹmi Mimọ ninu ọkan, ti n mu eso wa ninu igbesi aye ti o ba apẹẹrẹ Kristi mu.ANN 114.3

    A ti pese Whitefield ati awọn Wesley silẹ fun iṣẹ wọn pẹlu imọlara inira ọlọjọ pipẹ nipa bi wọn ti sọnu; ki wọn baa le fi ara da ijiya gẹgẹ bi ọmọ ogun rere fun Kristi. Wọn ti fi ara da inira nla ti ẹgan, ifini sẹsin, ati inunibini, ninu ile ẹkọ giga, ati bi wọn ti fẹ wọ inu iṣẹ iwaasu. Awọn ati awọn perete miran ti wọn n tẹle wọn ni awọn ẹlẹgbẹ wọn ti ko mọ Ọlọrun n fi ẹgan pe ni awọn Methodist—orukọ ọkan ninu awọn ijọ ti wọn tobi julọ ni ilẹ Amerika ati England ti a wa n ri gẹgẹ bi eyi ti o ni iyin.ANN 114.4

    Gẹgẹ bi ọmọ ijọ England, wọn n fi gbogbo agbara tẹle ilana isin rẹ, ṣugbọn Oluwa ti fi ipele ti o ga ju eyi lọ han wọn ninu ọrọ Rẹ. Ẹmi Mimọ rọ wọn lati waasu Kristi, Ẹni ti a kan mọ agbelebu. Agbara Ẹni Giga julọ wa pẹlu iṣẹ wọn. Ọpọlọpọ ni wọn gbagbọ ti wọn si yipada ni tootọ. O di dandan ki a daabo bo awọn aguntan wọnyi kuro ni ọwọ awọn ikooko ti n dọdẹ kiri. Wesley ko ni erongba lati da ijọ tuntun silẹ, ṣugbọn o ko wọn jọ si abẹ ohun ti o pe ni Methodist Connection (Ifarakora Eleto).ANN 114.5

    Atako ti awọn oniwaasu wọnyi ba pade ninu ijọ ilu yanilẹnu, o si lagbara; sibẹ Ọlọrun, ninu ọgbọn Rẹ jẹ ki awọn iṣẹlẹ o mu ki atunṣe o bẹrẹ ninu ijọ naa funra rẹ. Bi o ba jẹ wipe lati ita nikan ni o ti wa ni, ki i ba ti gbilẹ de ibi ti a ti nilo rẹ. Ṣugbọn niwọn igba ti awọn ti wọn n waasu isọji jẹ awọn ọmọ ijọ lasan, ti wọn si n ṣiṣẹ laarin ijọ nibikibi ti wọn ba ti ni anfani, otitọ naa ri aaye wọ inu ibi ti à bá ti ti ilẹkun mọ bi ki i ba ṣe bẹẹ. Diẹ lara awọn alufa ijọ taji kuro ni oju orun wọn, wọn si fi itara waasu ninu agbegbe wọn. Awọn ijọ ti aṣa ti sọ di oku ji dide wa si iye.ANN 114.6

    Ni akoko Wesley, gẹgẹ bi o ti ṣẹlẹ ninu gbogbo itan ijọ, awọn eniyan ti wọn ni oriṣiriṣi ẹbun ṣe iṣẹ ti a fifun wọn. Wọn ko fi ohùn ṣọkan lori gbogbo ikọni, ṣugbọn Ẹmi Ọlọrun dari gbogbo wọn, wọn si parapọ ninu erongba kan ṣoṣo lati jere ọkan fun Kristi. Awọn iyatọ ti o wa laarin awọn Wesley ati Whitefield fẹ fa iyapa ni aarin kan; ṣugbọn bi wọn ti kọ nipa ọkan tutu ni ile ẹkọ Kristi, ifarada ati ifẹ ṣe ibalaja laarin wọn. Wọn ko ni akoko lati ṣe ariyanjiyan, nigba ti eke ati ẹṣẹ n gbilẹ ni ibi gbogbo, ti awọn ẹlẹṣẹ si n ṣegbe.ANN 114.7

    Awọn iranṣẹ Ọlọrun rin ni ọna hiha. Awọn alagbara ati ọmọwe lo agbara wọn lati tako wọn. Lẹyin igba diẹ, ọpọ awọn alufa mọọmọ ṣe atako si wọn, a si ti ilẹkun awọn ile ijọsin mọ igbagbọ mimọ ati awọn ti wọn n waasu rẹ. Iwa awọn alufa, ni titako wọn lati ori pẹpẹ iwaasu ru okunkun, aimọkan ati ẹṣẹ soke. Lati igba de igba ni John Wesley bọ kuro lọwọ iku nipasẹ iṣẹ iyanu aanu Ọlọrun. Nigba ti ibinu awọn janduku ru si, ti o da bi ẹnipe ko si ọna abayọ, angẹli kan ni irisi eniyan wa si ẹgbẹ rẹ, awọn janduku naa ṣubu sẹyin, iranṣẹ Kristi si kuro ninu ewu ni alaafia.ANN 114.8

    Wesley sọ nipa igbasilẹ rẹ kuro lọwọ awọn janduku ti n binu ninu ọkan ninu iru awọn iṣẹlẹ wọnyi pe: “Ọpọlọpọ sa ipa lati ju mi silẹ nigba ti a n sọkalẹ lori oke kan ni oju ọna ti n yọ lọ si inu ilu; wọn ri wipe bi mo ba le balẹ, mi o nile dide mọ lae. Ṣugbọn mi o ṣubu rara, ani mi o yẹsẹ, titi ti mo fi kuro ni ọwọ wọn patapata. . . . Bi o tilẹ jẹ wipe ọpọ ni wọn fẹ di aṣọ tabi ìborùn mi mu, lati le fa mi silẹ, ṣugbọn wọn ko ri mu rara: ọkan ṣoṣo ni o di bebe aṣọ ileke mi mu, ti o si jabọ kuro ni ọwọ rẹ kankan; a ya abala keji ti owo wa ninu apo rẹ si meji. . . . Ọkunrin kan ti o ṣigbọnlẹ lẹyin mi fi igi nla kan lu mi fun igba diẹ; eyi ti o jẹ wipe bi o ba ba mi lẹyin ori, ko ni nilo lati ṣe wahala kankan mọ. Ṣugbọn gbogbo igba ni ìkúùkù naa n bọ si ibomiran, mi o mọ bi o ṣe ṣẹlẹ; nitori pe mi o le mi si ọtun tabi osi. . . . Omiran sare jade wa laarin ero, o gbe ọwọ rẹ soke lati lumi, ṣugbọn lojiji ọwọ rẹ jabọ, o wa fi ọwọ pa mi lori, o wipe, ‘Irun rẹ ti fẹlẹ to!’ . . . Awọn akọkọ ti ọkan wọn yipada jẹ awọn akikanju ninu ilu naa, awọn adari awọn ọmọ ita, ti ọkan ninu wọn ti gba ẹbun fun jija ni ọgba beari. . . .ANN 114.9

    “Ṣugbọn diẹdiẹ ni Ọlọrun n pese wa silẹ fun ifẹ Rẹ! Ni ọdun meji sẹyin, biriki kan fo ejika mi kọja. Ọdun kan lẹyin eyi, okuta kan bami ni aarin oju. Ni osu to kọja, ikuuku kan ba mi, ni aṣalẹ yii meji, ọkan ṣaaju ki a to wọ inu ilu yii, ekeji lẹyin ti a jade; ṣugbọn awọn mejeeji ko jasi ohun kankan: bi o tilẹ jẹ wipe ẹnikan fi gbogbo agbara rẹ gba mi laya, ti omiran si gba mi lẹnu pẹlu gbogbo agbara ti o fi jẹ wipe ẹjẹ n jade ni ẹnu mi loju ẹsẹ, ko si eyi ti o ro mi lara ninu mejeeji, o dabi ẹnipe wọn fi koriko gbigbẹ kàn mi lasan ni.”ANN 115.1

    Awọn Methodist ti akoko iṣaaju naa—awọn eniyan pẹlu awọn oniwaasu—fi ara da ifiniṣẹsin, ati inunibini lati ọdọ awọn ọmọ ijọ ati awọn ti ko lẹsin ti ara wọn gbona nitori bi a ti ṣe afihan wọn lọna ti ko tọ. A pe wọn lẹjọ si ile ẹjọ—ile idajọ ni orukọ lasan—nitori idajọ ṣọwọn ni akoko naa. Ni ọpọ igba wọn jiya ipa lọwọ awọn oninunibini wọn. Awọn ọmọ ita n lọ lati ile de ile, wọn n ba dukia ati ohun ẹsọ ile jẹ, ti wọn si n ji ohunkohun ti wọn ba fẹ, wọn a fiya jẹ awọn ọkunrin, ati obinrin ati ọmọde lọna ika. Ni igba miran, wọn a gbe ikede sita ti wọn a pe gbogbo awọn ti wọn ba fẹ lati fọ oju ferese ati lati ji ẹru ko ni ile awọn Methodist lati pade ni ibi kan ati ni akoko kan. A si n jẹ ki titẹ ofin eniyan ati ti Ọlọrun loju yii maa lọ laisi ibawi. A fi eto gbé inunibini kalẹ si awọn ti o jẹ wipe ẹṣẹ kan ṣoṣo ti wọn ṣẹ ko ju wipe wọn n wa lati yi ẹsẹ awọn ẹlẹṣẹ kuro ni ọna iparun pada si oju ọna iwa mimọ lọ.ANN 115.2

    Nigba ti John Wesley n sọrọ nipa awọn ẹsun ti wọn fi kan an ati awọn ẹlẹgbẹ rẹ, o sọ wipe: “Awọn kan sọ wipe irọ ni awọn ikọni awọn eniyan wọnyi, ati wipe ko tọna, ariwo lasan si ni; wipe wọn jẹ ọtun, a koi si ti i gbọ nipa wọn ri; wipe ikọni awọn Quaker ni, irokuro nipa ẹsin ni, ẹsin popu ni. Gbogbo irọ wọnyi ni a ti gé ti gbongbo ti gbongbo, nigba ti a ti fihan daradara wipe gbogbo ẹka ikọni yii jẹ ikọni ti o han kedere lati inu Iwe Mimọ ti ijọ wa ṣe itumọ rẹ. Nitori naa, a ko le sọ wipe irọ ni wọn tabi wipe wọn jẹ aṣiṣe, bi Iwe Mimọ ba le jẹ otitọ.” “Awọn miran sọ wipe, ‘Ikọni wọn ti nira ju; wọn ti jẹ ki ọna ọrun o ṣe tooro ju.’ Eyi si ni atako gan an ni pato, (nitori òhun nikanṣoṣo ni a ri fun igba diẹ,) ohun si ni o wa ni idi ọpọlọpọ omiran, ti wọn fi ara han ni oriṣiriṣi ọna. Ṣugbọn ṣe wọn jẹ ki ọna si ọrun o tooro ju bi Oluwa wa ati awọn apostoli Rẹ ti ṣe e lọ ni? Ṣe ikọni wọn nira ju ti Bibeli lọ ni? Ẹ wo awọn ẹsẹ diẹ wọnyi: ‘Ki iwọ ki o fẹran Oluwa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkan rẹ, ati pẹlu gbogbo ẹmi rẹ, ati pẹlu gbogbo aya rẹ, ati pẹlu gbogbo agbara rẹ.’ ‘Nitori gbogbo oro were ti eniyan ba sọ ni yoo jiyin rẹ ni ọjọ idajọ.’ ‘Bi ẹyin ba jẹ, tabi bi ẹyin ba mu, tabi ohunkohun ti ẹyin ba ṣe, ẹ ṣe wọn si ogo Ọlọrun.’ANN 115.3

    “Bi ikọni wọn ba nira ju eyi lọ, awọn ni a maa da lẹbi; ṣugbọn ẹyin mọ ninu ọkan yin wipe ko ri bẹẹ. Tani o si le pa ọrọ Ọlọrun mọ ṣugbọn ti o yọ eyi ti o kere julọ kuro ninu rẹ ti ko ni ba ọrọ Ọlọrun jẹ? Sẹ iriju awọn ohun ijinlẹ Ọlọrun ṣi le jẹ olootọ bi o ba yi eyikeyi ninu ọrọ mimọ pada? Rara! Ko le mu ohunkohun kuro, ko le sẹ ohunkohun rọ; o nilo lati sọ fun gbogbo eniyan, ‘Mi o le fa Iwe Mimọ sisalẹ lati ba ifẹ yin mu. Ẹ nilati wa si ọdọ rẹ ni, tabi ki ẹ di ẹni iparun laelae.’ Eyi ni idi kan ṣoṣo ti gbogbo eniyan fi n kigbe nipa ‘ainifẹ awọn eniyan wọnyi.’ Alainifẹ, ṣe lootọ ni? Ni ọna wo? Ṣe wọn ko fun ẹni ti ebi n pa ni ounjẹ ni tabi wọn ko fi aṣọ wọ ẹni ti o wa ni ihoho? Rara; ki i ṣe iyẹn ni: wọn ko baku ninu eyi: ṣugbọn wọn jẹ alainifẹ ninu ṣiṣe idajọ! wọn ro wipe a ko le gba ẹnikẹni la ayafi awọn ti n rin ni ọna wọn.’”ANN 115.4

    Ifasẹyin ti ẹmi ti o fi ara han ninu ijọ England ni kete ṣaaju akoko Wesley waye, ni ọna ti o pọ julọ, nitori ikọni wipe ko si ofin mọ. Ọpọlọpọ ni wọn sọ wipe Kristi ti pa ofin rẹ ati wipe awọn Kristẹni ko ni ojuṣe lati paamọ mọ; wipe a ti yọ awọn onigbagbọ kuro ninu “igbekun iṣẹ rere.” Bi o tilẹ jẹ wipe awọn miran gba wipe ofin naa wa titi lae, wọn sọ wipe ko ṣe pataki ki awọn alufa wọn o kọ awọn eniyan lati ṣe igbọran si awọn ilana rẹ, nitori pe awọn ti Ọlọrun ti yan si igbala a, “pẹlu agbara oore ọfẹ Ọlọrun ti a ko le tako, ni agbara lati wu iwa ifọkansin ati iwa ti o dara,” nigba ti awọn ti a ti yan fun iparun ayeraye “ko ni agbara lati pa ofin Ọlọrun mọ.”ANN 116.1

    Awọn miran gbagbọ wipe “awọn ti a ti yan ko le ṣubu kuro ninu oore ọfẹ tabi padanu oju rere Ọlọrun,” wọn tun ṣe akotan ti o buru ju eyi lọ wipe “iwa buburu ti wọn ba wu ki i ṣe ẹṣẹ, bẹẹ si ni a ko le ri bi ẹnipe wọn tako ofin Ọlọrun, nitori naa wọn ko nilo lati ṣe ijẹwọ ẹṣẹ tabi lati kọ wọn silẹ nipa ironupiwada.” Nitori naa, wọn sọ wipe ọkan lara ẹṣẹ ti o ba buru julọ, “ti gbogbo aye ka si riru ofin Ọlọrun, ki i ṣe ẹṣẹ ni oju Ọlọrun,” bi o ba jẹ wipe ọkan lara awọn ayanfẹ ni o da a, “nitori pe o jẹ ọkan lara awọn ohun ti a fi n da awọn ayanfẹ mọ wipe wọn ko le ṣe ohun ti ko tẹ Ọlọrun lọrun tabi ti ofin Rẹ tako.”ANN 116.2

    Awọn ikọni buburu bawọnyi ni iru awọn ikọni kan naa ti awọn olukọ ati ẹlẹkọ nipa Ọlọrun—wipe ko si ofin kan ti ko ṣe e yipada gẹgẹ bi odiwọn fun ohun ti o tọna, ṣugbọn awujọ funra rẹ ni o maa n ṣe odiwọn fun ohun ti o tọna, eyi ti o maa n yipada nigba gbogbo. Ẹmi nla kan naa ni o n mu gbogbo awọn ero wọnyi wa—ẹni ti o bẹrẹ iṣẹ lati bi ijanu ododo ofin Ọlọrun wo, ani laarin awọn olugbe alailẹṣẹ ni ọrun.ANN 116.3

    Ikọni nipa aṣẹ Ọlọrun, ti o fi ontẹ lé iwa eniyan ni ọna ti a ko le yipada, ti jẹ ki ọpọlọpọ eniyan o kọ ofin Ọlọrun silẹ. Wesley tako aṣiṣe awọn olukọ ti n kọni wipe ko si ofin yii pẹlu iduroṣinṣin, o si fihan wipe awọn ikọni ti wọn yọri si igbagbọ wipe ko si ofin wọnyi tako Iwe Mimọ. “Oore ọfẹ ti n mu igbala wa ti fi ara han fun gbogbo eniyan.” “Eyi ni o dara ti o si jẹ itẹwọgba ni oju Ọlọrun Olugbala wa; ti o fẹ ki gbogbo eniyan o di ẹni igbala, ki wọn si wa si imọ otitọ. Nitori Ọlọrun kan ṣoṣo ni o wa, ati olubalaja kan laarin Ọlọrun ati eniyan, ọkunrin ni Jesu Kristi; ẹni ti o fi ara Rẹ silẹ fun irapada gbogbo eniyan.” Titu 2:11; I Timoti 2:3-6. A fi Ẹmi Ọlọrun funni lọfẹ lati le ran gbogbo eniyan lọwọ lati gba ilana igbala. Nitori naa, Kristi “Imọlẹ tootọ,” ti tan imọlẹ si gbogbo eniyan ti o wa sinu aye.” Johanu 1:9. Awọn eniyan baku ninu igbala nitori bi wọn ti mọọmọ kọ ẹbun iye silẹ.ANN 116.4

    Ni idahun si igbagbọ wipe nigba ti Kristi ku, a ti mu Ofin Mẹwa kuro pẹlu ofin ti o ni i ṣe pẹlu ilana ẹsin, Wesley sọ wipe: “Ofin iwuwasi, ti o wa ninu Ofin Mẹwa ti awọn woli ni ki a pamọ, ko mu awọn iyẹn kuro. Ki i ṣe ara ète wiwa Rẹ ni lati mu ọkan ninu eyi kuro. Ofin ti a ko le ge kuro ni eyi, ‘ti o duro gẹgẹ bi ẹlẹri tootọ ni ọrun.’ . . . Eyi wà lati ibẹrẹ aye wa, ‘ki i ṣe ori walaa okuta ni a kọ si’ bikoṣe ọkan awọn ọmọ eniyan, nigba ti wọn wa lati ọwọ Ẹlẹda wọn. Bi o tilẹ jẹ wipe ẹṣẹ ti ba lẹta ti a fi ika Ọlọrun kọ jẹ pupọpupọ, sibẹ a ko le pawọnrẹ patapata, niwọn igba ti a ba si ni imọ nipa rere ati buburu. Gbogbo abala inu ofin yii ni agbara lori gbogbo eniyan, ni akoko gbogbo, ko da lori akoko tabi ibi ti a wa, tabi ohunkohun ti o le yipada, ṣugbọn lori iwa Ọlọrun, ati iwa eniyan ati ibaṣepọ wọn si ara wọn ti ko le yipada.ANN 116.5

    ” ‘Emi ko wa lati pa a run bikoṣe lati mu ṣẹ.’ . . . Laisi aniani, itumọ ti o ni nibi (ni iṣọkan pẹlu ohun gbogbo ti o wa ṣaaju ati eyi ti o tẹle), —Mo wa lati fi idi rẹ mulẹ ni kikun, laika gbogbo itumọ eniyan si: Mo wa lati jẹ ki ohunkohun ti o ba ṣokunkun, tabi ti o ba fi ara sin ninu rẹ o han kedere, ki o si yeni yekeyeke: Mo wa lati sọ itumọ gbogbo rẹ ni kikun; lati fihan gígùn ati ìbú gbogbo rẹ, gbogbo ofin ti wọn wa ninu rẹ, ati giga ati jinjin, iwa mimọ rẹ ti ko le yeni tan ati bi o ti jẹ ohun ẹmi to ninu gbogbo ẹka rẹ.”ANN 116.6

    Wesley kede ibaṣepọ pipe ti o wa laarin ofin ati iyinrere. “Nitori naa, ibaṣepọ ti o sunmọ ara wọn pẹkipẹki ti eniyan le rò, wa laarin ofin ati iyinrere. Ni ọna kan, ofin la ọna fún, o si n tọka wa si iyinrere ni gbogbo igba; ni ọna keji, iyinrere n dari wa lati le pa ofin mọ ni pipe si. Bi apẹẹrẹ, ofin fẹ ki a fẹran Ọlọrun, ki a fẹran ẹnikeji wa, ki a jẹ oniwatutu, onirẹlẹ tabi ẹni mimọ. A mọ wipe a kò kun oju oṣuwọn fun gbogbo nnkan wọnyi; sibẹ, ‘eyi ko ṣe e ṣe pẹlu eniyan;’ ṣugbọn a ri ileri Ọlọrun lati fun wa ni ifẹ naa, lati jẹ ki a jẹ onirẹlẹ, ọlọkan tutu ati ẹni mimọ: a di iyinrere yii mu, iroyin ayọ yii; a ṣe e fun wa gẹgẹ bi igbagbọ wa; ‘ododo ofin a si wa di mimuṣe ninu wa,’ nipa igbagbọ ti o wa ninu Kristi Jesu. . . .ANN 117.1

    Wesley sọ wipe, “Awọn ti wọn ga julọ ninu awọn ọta iyinrere Kristi ni awọn ti wọn n ṣe ‘idajọ lori ofin’ funra rẹ ni gbangba lai pẹ ọrọ sọ, ‘ti wọn n sọrọ ibi nipa ofin;’ ti wọn n kọ awọn eniyan lati ru (lati fọnka, lati sẹ ẹ rọ, lati yọni kuro ninu ojuṣe rẹ), ki i ṣe ẹyọkan ṣoṣo, boya eyi ti o kere julọ tabi ti o tobi julọ, ṣugbọn gbogbo ofin lapapọ. . . . Ohun ti o yanilẹnu julọ ninu gbogbo awọn ti wọn tẹle itanjẹ lile yii ni wipe, awọn ti wọn ti fi ara wọn jin fun, gbagbọ nitootọ wipe wọn n bu ọla fun Kristi nipa bibi ofin Rẹ ṣubu, ati wipe wọn n gbe iṣẹ Rẹ larugẹ ni nigba ti wọn ba ikọni Rẹ jẹ! Bẹẹni, wọn n bọwọ fun bi Judasi ti ṣe nigba ti o sọ wipe, ‘Alaafia Oluwa, ti o si fi ẹnu ko O ni ẹnu.’ O jẹ ohun ti o tọna bi o ba sọ fun gbogbo wọn wipe, ‘Ṣe pẹlu ifẹnukonu ni iwọ fẹ fi fi Ọmọ eniyan han?’ Ko yatọ si wipe a n fihan pẹlu ifẹnukonu bi a ba n sọrọ nipa ẹjẹ Rẹ, ti a si n mu ade Rẹ kuro; ti a tẹnbẹlu eyikeyi ninu ofin Rẹ, labẹ itanjẹ wipe a n jẹ ki iyinrere Rẹ o tẹsiwaju. Bẹẹ si ni ẹnikẹni ko le bọyọ kuro ninu ifẹsunkan yii, bi o ba n waasu igbagbọ ninu ohunkohun boya ni gbangba tabi ni bonkẹlẹ ni ọna ti o le ṣá eyikeyi ninu igbọran tì si ẹgbẹ kan: ti o waasu wipe Kristi ti fagile, tabi sẹ rọ ni ọnakọna, eyi ti o kere julọ ninu awọn ofin Ọlọrun.”ANN 117.2

    Wesley fesi fun awọn ti wọn n sọ wipe “iwaasu iyinrere ni opin ofin” bayi pe: “A ko gba eyi rara. Ko dahun si idi akọkọ fun ofin, eyi ti i ṣe lati fi oye ẹṣẹ ye eniyan, lati ta awọn ti wọn si n sun ni eti bebe ipo oku ji.” Apostoli Pọlu sọ wipe “nipasẹ ofin ni a fi ni imọ ẹṣẹ;” “ati pe igba ti eniyan ba ni oye ẹṣẹ, ni o to le mọ wipe oun nilo ẹjẹ iwẹnumọ ẹṣẹ Kristi nitootọ. . . . Bi Olugbala funra Rẹ ti woye, ‘Awọn ti wọn ko ṣe aisan ko nilo oniṣegun, bikoṣe awọn ti n ṣe aisan.’ Ko boju mu lati fun ẹni ti ara rẹ ya, tabi ti o ro wipe ara oun ya, ni oniṣegun. O nilati kọkọ fi ye wọn wipe wọn n ṣe aisan; lalaiṣe bẹẹ, wọn ko ni dupẹ lọwọ rẹ fun gbogbo wahala rẹ. Bẹẹ gẹgẹ ni ko ṣe bojumu lati fi Kristi lọ awọn ti ọkan wọn pé, nitori pe wọn koi ti i ṣe ikaanu fun ẹṣẹ.”ANN 117.3

    Nitori naa, nigba ti o n waasu iyinrere oore ọfẹ Ọlọrun, Wesley gẹgẹ bi ti Oluwa rẹ, wá lati “gbe ofin ga, ki o si jẹ ki o lọwọ.” O fi otitọ inu ṣe iṣẹ ti Ọlọrun gbe fun, a si gba a laaye lati ri awọn aṣeyọri ti o logo. Ni opin igbesi aye rẹ, ti o lé ni ọgọrin ọdun—o fi ó le ni aadọta ọdun ṣe iṣẹ oniwaasu arinkaakiri—awọn atẹle rẹ ju aabọ miliọnu eniyan lọ. Ṣugbọn ọpọ awọn eniyan ti a gbe dide lati inu iparun ati ibajẹ ẹṣẹ lati gbe igbesi aye ti o ga si ti o tun jẹ mimọ nipasẹ iṣẹ rẹ, ati iye awọn ti wọn ri iriri kikun ti o jinlẹ si nipasẹ ikọni rẹ, ni a ko le mọ titi ti gbogbo idile awọn ti a rapada yoo fi ko ara wọn jọ pọ ni ijọba Ọlọrun. Igbesi aye rẹ fun wa ni ẹkọ ti o ṣe iyebiye fun gbogbo Kristẹni. I ba ti dara to bi a ba le fi igbagbọ ati irẹlẹ, itara ti ki i kaarẹ, ìfi ara ẹni rubọ, ati ifọkansin iranṣẹ Kristi yii han ninu awọn ijọ lonii!ANN 117.4

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents