Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents
ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORI KARUNDINLOGOJI—IGBOGUNTI OMINIRA ẸRI ỌKAN

    Awọn Protestant ti n fi oju rere wo ẹsin Romu ni akoko yii ju ti awọn ọdun to kọja sẹyin lọ. Ni awọn orilẹ ede ti ẹsin Katoliki ko ti wọpọ, ti awọn atẹle popu n ṣiṣẹ ilaja lati le ni agbara, awọn eniyan si n tubọ ṣe alaibikita si nipa awọn ikọni ti wọn pin ijọ ti a fọ mọ niya kuro ninu ijọ padi; o n gbilẹ kan wipe, ṣe bí a ko yatọ to bẹẹ ju bẹẹ lọ bi a ti ro tẹlẹ, ati wipe bi a ba jọwọ awọn ohun diẹdiẹ silẹ, yoo jẹ ki a ni ibaṣepọ ti o dara si pẹlu Romu ni. Ni igba kan ri awọn Protestant ri ominira ẹri ọkan gẹgẹ bi ohun ti o niye lori ti a ra pẹlu ohun iyebiye. Wọn kọ awọn ọmọ wọn lati korira ẹsin popu ati lati gbagbọ wipe wiwa ni ibamu pẹlu Romu yoo tumọ si aiṣotitọ si Ọlọrun. Ṣugbọn ohun ti a n fihan lode oni ti yatọ to!ANN 251.1

    Awọn olugbeja ẹsin ijọ paadi n sọ wipe a n sọrọ buburu si ijọ, awọn ẹlẹsin Protestant si n gba bẹẹ. Ọpọ ni wọn n sọ wipe ko boju mu ki a maa wo ijọ ti ode oni pẹlu awọn iwa irira ati iwa aitọ ti wọn wọpọ ni akoko iṣejọba rẹ ni awọn igba aimọkan ati okunkun. Wọn dariji awọn iwa buburu rẹ gẹgẹ bi eyi ti o wa latari iwa aimoye ti o wa ni akoko naa, wọn si sọ wipe agbara ọlaju ti yi ero rẹ pada.ANN 251.2

    Ṣe awọn wọnyi ti gbagbe igbagbọ nipa aibaku ti agbara agberaga yii gbe kalẹ fun ẹgbẹsan (1800) ọdun sẹyin ni? Dipo ki wọn kọ ọ silẹ, wọn tun n tẹnumọ ni ọrundun kọkandinlogun pẹlu aiyi ohun pada ti o ju ti atẹyinwa lọ. Gẹgẹ bi Romu ti sọ wipe ijọ “ko ṣe aṣiṣe ri; bẹẹ ni ko ni ṣe aṣiṣe laelae; gẹgẹ bi Iwe Mimọ ti wi,” bawo ni yoo ṣe kọ awọn igbagbọ ti o ti n dari iṣesi rẹ latẹyinwa silẹ?ANN 251.3

    Ijọ padi ko ni fi igbagbọ nipa aibaku rẹ silẹ lae. Gbogbo ohun ti o ṣe ninu inunibini rẹ si awọn ti wọn kọ igbagbọ rẹ silẹ ni o ri gẹgẹ bi eyi ti o dara; ṣe ko wa ni wu iru iwa kan naa, bi o ba ri anfani rẹ bi? Ẹ jẹ ki awọn idilọwọ ti awọn ijọba oṣelu la kalẹ o kuro, ki a si da Romu pada sinu agbara rẹ tẹlẹ, a o si ri isọji iwa ika ati inunibini rẹ pẹlu iyara kankan.ANN 251.4

    Onkọwe gbajugbaja kan sọ nipa iwuwasi ijọ padi nipa ominira ẹri ọkan, ati awọn ewu ti n pokuru mọ United States latari aṣeyọri ijọba rẹ bayii:ANN 251.5

    “Ọpọlọpọ wa ti wọn ni inu didun lati ri ibẹrukibẹru nipa ẹsin Roman Katoliki gẹgẹ bi agbaju ẹsin tabi iwa ọmọde. Awọn wọnyi ko ri ohunkohun ninu iwa ati iṣesi Romu ti o ṣodi si awọn agbekalẹ olominira wa, tabi ri ohunkohun ti o buru ninu idagbasoke rẹ. Ẹ jẹ ki a kọkọ fi ipilẹ iṣejọba wa wé titi ijọ Katoliki.ANN 251.6

    “Iwe iṣejọba United States fi aaye gba ominira ẹri ọkan. Ko si ohun ti o dara tabi ti o ṣe pataki ju u lọ. Popu Pius IX, ninu lẹta rẹ ti o kọ si awọn biṣọbu ni August 15, 1854, sọ pe: ‘Ikọni eke ti ko boju mu tabi isọrọwere ni igbeja fun ominira ẹri ọkan jẹ aṣiṣe ti o niyọnu julọ—aarun ti o yẹ ki a bẹru ni ilu ju eyikeyi lọ.’ Popu yii kan naa ninu lẹta rẹ ti December 8, 1864, fi ‘gbogbo ẹni ti o ba beere fun ominira ẹri ọkan ati ifarada ẹsin’ gegun pẹlu gbogbo awọn ti wọn n sọ wipe ijọ ko gbọdọ fi agbara muni.ANN 251.7

    “Ọrọ alaafia Romu ni United States ki i ṣe nitori iyipada ọkan. O maa n ni ifarada nibi ti ko ba ti ri iranlọwọ. Biṣọbu O’ Connor sọ wipe: ‘Ijọ Katoliki n fi ara da ominira ẹsin lasan ni titi ti yoo fi le ṣe idakeji rẹ lai ṣe e nijamba.’ . . . Kadina ti St Louis ṣo nigba kan wipe: “Ẹkọ odi ati aigbagbọ jẹ iwa ọdaran; ni awọn orilẹ ede Kristẹni, bii Itali ati Spain fun apẹẹrẹ, nibi ti gbogbo eniyan ti jẹ Katoliki, ati nibi ti ẹsin Katoliki ti jẹ eyi ti o ṣe pataki ninu ofin, a n jẹ wọn niya gẹgẹ bi iwa ọdaran yoku.’ . . .ANN 251.8

    “Gbogbo kadina, biṣọbu agba, ati biṣọbu ninu ijọ Katoliki n jẹjẹ igbọran si popu, ninu eyi ti awọn ọrọ wọnyi wa: ‘Ẹlẹko odi, oniyapa, ati oluṣọtẹ si oluwa wa (popu), tabi si awọn ti yoo wa ni ipo rẹ, ni maa tako ti maa si ṣe inunibini si pẹlu gbogbo ipa mi.’”ANN 251.9

    Otitọ ni wipe awọn Kristẹni tootọ wa ninu ijọ Roman Katoliki. Ọpọlọpọ ninu ijọ naa n sin Ọlọrun gẹgẹ bi imọlẹ ti wọn ni. A ko fun wọn ni aaye si ọrọ Rẹ, nitori idi eyi, wọn ko mọ otitọ. Wọn koi ti i ri iyatọ laarin iṣẹ ọkan alaaye ati aṣa ati isin lasan. Ọlọrun n fi ikaanu wo awọn ọkan wọnyi, ti wọn ni imọ ninu iru igbagbọ ti o jẹ ẹtan ti ko si le tẹnilọrun. Yoo jẹ ki itansan imọlẹ o wọ inu okunkun biribiri ti o yi wọn ka. Yoo fi otitọ han wọn, gẹgẹ bi o ti wa ninu Jesu, ti ọpọlọpọ yoo si wa si ọdọ awọn eniyan Rẹ.ANN 252.1

    Ṣugbọn ẹsin Romu gẹgẹ bi agbekalẹ ko si ni ibamu pẹlu iyinrere Kristi nisinsinyii gẹgẹ bi ko ti ṣe wa ni igba kankan latẹyinwa. Awọn ijọ Protestant wa ninu okunkun nla tabi wọn i ba mọ awọn ami akoko. Ijọ Romu ti n jinlẹ ninu awọn agbekalẹ ati iṣọwọṣiṣẹ rẹ. Gbogbo ipa ni o n sa lati jẹ ki agbara rẹ o tankalẹ si ati ki ipa rẹ o pọ si ni imura silẹ fun ijakadi alagbara ti yoo ṣe pẹlu agidi lati gba akoso lori aye pada, lati pada fi idi inunibini rẹ mulẹ, ati lati mu gbogbo ohun ti ẹsin Protestant ti ṣe kuro. Ẹsin Katoliki n fi ẹsẹ mulẹ ni ibi gbogbo. Ẹ wo bi ijọ rẹ ati ile ijọsin rẹ ti n pọ si ni awọn orilẹ ede Protestant. Ẹ wo bi awọn ile ẹko ati ile ẹkọ ẹsin rẹ ti n lokiki ni ilẹ Amẹrika, ti awọn Protestant si n lọ sibẹ lati ibi gbogbo. Ẹ wo idagbasoke ilana ẹsin ni England ati iyapa loorekoore sinu ijọ Katoliki. Awọn nnkan wọnyi nilati ta ibẹru awọn ti ẹkọ iyinrere ailabawọn ṣe iyebiye loju wọn ji.ANN 252.2

    Protestant ti fi ọwọ ba ẹsin popu, o si ti ran an lọwọ; wọn ti pa ohun da, wọn si ti jọwọ ọpọ nnkan silẹ fun debi pe o ya wọn lẹnu lati ri bẹẹ ti ko si ye wọn. Awọn eniyan n di oju ara wọn si ohun ti ẹsin Romu jẹ gan an, ati ewu ti ijọba rẹ yoo mu wa. A nilati ta awọn eniyan ji lati koju ija si itẹsiwaju ọta ti o lewu fun ominira iṣelu ati ti ẹsin yii.ANN 252.3

    Ọpọlọpọ ni wọn ro wipe ẹsin Katoliki ko fanilojumọra ati wipe iṣọwọjọsin rẹ jẹ isin lemọlemọ ti o tutu ti ko si nitumọ. Nibi wọn ṣe aṣiṣe. Nigba ti ẹsin Romu duro lori itanjẹ, ki i ṣe ẹtan onipagunpagun ati alailọgbọn. Ijọsin Roman Katoliki jẹ eyi ti o lẹwa jọjọ. Afihan olowonla rẹ ati aṣa ọlọwọ rẹ n fa si iye eniyan ti yoo si pa ironu ati eri ọkan lẹnu mọ. O rániloju. Ile ijọsin nla, itolọwọọwọ, pẹpẹ oniwura, ibi ijọsin ti a ṣe lọṣọ, aworan ile ti o niye lori, ati awọn ere ti wọn lẹwa daradara lati ṣipẹ si ifẹ ẹwa. Etí ẹni a kun pẹlu. Orin ti ko lẹgbẹ. Awọn ohun elo orin to rinlẹ dodo, to dapọ mọ iro ọpọlọpọ ohùn bi o ti n goke lọ lara opó ilé ati àjà gíga awọn ile ijọsin nla rẹ, ko le ṣe ki o ma mu ọwọ ati iyin kun ọkan eniyan.ANN 252.4

    Ọla, iwuga ati ẹsin ti ode yii, ti o n fi ònfà ọkan ti o kun fun ẹṣẹ ṣe ẹlẹya lasan jẹ ẹri fun ibajẹ inu. Ẹsin Kristi ko nilo iru ẹwa bayii lati ṣe afihan rẹ. Ninu imọlẹ ti n tan lati ara agbelebu, ẹsin Kristẹni tootọ n fi ara han ni ọna ti o mọ ti o si rẹwa ti ko nilo ẹṣọ ode ara lati buyi fun. Ẹwa iwa mimọ, ẹmi irẹlẹ ti n dakẹ jẹẹ ni o niye lori niwaju Ọlọrun.ANN 252.5

    Iṣesi daradara ki i ṣe ohun ti a fi le mọ ero giga ati eyi ti o mọ. Nini oye giga nipa iṣẹ ọnà, nini ifẹ si ohun ti o dara julọ, saba maa n waye ninu ọkan ẹni ti o kun fun ohun ti ara ati ti aye. Satani saba maa n lo wọn lati mu ki eniyan o gbagbe ohun ti o ṣe pataki julọ fun ọkan, lati gbagbe nipa ọjọ iwaju, iye ainipẹkun, lati yi wọn pada kuro ni ọdọ Oluranlọwọ ayeraye wọn, ati lati mu ki wọn o gbe fun aye yii nikan.ANN 252.6

    Ẹsin ti ode ara a maa wu awọn ti a koi ti i sọ ọkan wọn di ọtun. Igbega ati iṣọwọṣesin Katoliki ni agbara ti o n tannijẹ ti o si n rániniye; wọn a wa maa wo Ijọ Romu gẹgẹ bi oju ọna lọ si ọrun. Ko si ẹni naa bikoṣe awọn ti wọn fi ẹsẹ wọn mulẹ gbọin si ori ipilẹsẹ otitọ, ti Ẹmi Ọlọrun si ti sọ ọkan wọn di ọtun nikan ni ipa rẹ ko le mu. Ọpọlọpọ ti ko ni iriri imọ Kristi yoo gba afarawe iwabiọlọrun laini agbara. Iru ẹsin bayi ni ọpọ ero n fẹ.ANN 252.7

    Bi ijọ ti sọ wipe oun ni ẹtọ lati dari ẹṣẹ ji jẹ ki awọn atẹle Romu o ni ominira lati dẹṣẹ, ati ilana ijẹwọ, eyi ti ko si idariji laisi rẹ, saba maa n fun eniyan ni ominira lati wuwa ibi. Ẹnikẹni ti o ba kunlẹ niwaju eniyan ti o bàkù, ti o si n sọ awọn ero ikọọkọ ati ironu ọkan rẹ ninu ijẹwọ ẹṣẹ, n ba ohun ti o fi n jẹ eniyan jẹ o si n rẹ gbogbo ohun ti o dara ninu ọkan rẹ silẹ. Ni jijẹwọ awọn ẹṣẹ ara rẹ si alufa—ẹlẹran ara, ẹlẹṣẹ ti o baku, ti o ti dibajẹ nipasẹ ọti ati iwakuwa,—odiwọn iwa rẹ ti wa silẹ, oun naa si di aimọ nipasẹ eyi. Ero rẹ nipa Ọlọrun ti dibajẹ bi irisi iran eniyan ti o ti ṣubu—nitori alufa duro gẹgẹ bi aṣoju Ọlọrun. Ijẹwọ abanijẹ laarin eniyan si eniyan yii jẹ orisun ikọọkọ nibi ti ọpọlọpọ iwa buburu tí n ko aimọ ba aye ti o si n pese rẹ silẹ fun iparun ikẹyin ti n sun jade wa. Sibẹ fun ẹni ti o fẹran itẹra-ẹni-lọrun, o rọrun lati jẹwọ ẹṣẹ fun eniyan bii ti ara rẹ ju ki o ṣipaya ọkan rẹ si Ọlọrun lọ. O rọrun fun iṣẹda eniyan lati ṣe iṣẹ ironupiwada ju lati kọ ẹṣẹ rẹ silẹ lọ; o rọrun lati jẹ ara ẹni niya pẹlu aṣọ ọfọ, ati ẹgun ọgan, ati ẹwọn wuwo ju ki o kan ifẹkufẹ ara mọ agbelebu lọ. Ọkan ti ko yipada ṣetan lati gbe ẹru wuwo ju lati tẹriba fun ajaga Kristi lọ.ANN 252.8

    Ijọ Romu ati ijọ Ju ni akoko ti Kristi kọkọ wá ni awọn ohun kan papọ ti wọn jọra wọn ni ọna ti o yanilẹnu. Nigba ti awọn Ju n tẹ gbogbo ipilẹ ofin Ọlọrun loju ni ikọkọ, niti ode ara, wọn n fi gbogbo agbara n pa akọsilẹ rẹ mọ, wọn n di ẹru wuwo le lori pẹlu ofin ati aṣa ti o mu ki igbọran o nira ti o si dabi ẹru wuwo. Bi awọn Ju ti sọ wipe wọn bọwọ fun ofin, bẹẹ gẹgẹ ni awọn atẹle Romu sọ wipe wọn bọwọ fun agbelebu. Wọn gbe ami ijiya Kristi ga nigba ti wọn sẹ Ẹni ti o duro fun ninu aye wọn.ANN 253.1

    Awọn ọmọ ijọ padi gbe agbelebu si ori awọn ile ijọsin wọn, si ori pẹpẹ wọn ati si ara aṣọ wọn. Ni ibi gbogbo ni a ti n ri ami agbelebu. Ni ibi gbogbo ni a ti n bọwọ fun ti a si n gbega ni ode ara. Ṣugbọn a tẹ awọn ikọni Kristi rì si abẹ awọn aṣa ti ko nitumọ, itumọ eke, ati ojuṣe ti o rorò. Ọrọ Olugbala nipa awọn Ju onitara alaimoye naa ba awọn adari ijọ Roman Katoliki mu ni ọna ti o nipọn si: “Nitori wọn a di ẹru wuwo ti o ṣòro lati ru, wọn a si gbe e ka awọn eniyan lejika; ṣugbọn awọn tikara wọn ko jẹ fi ika wọn kan ẹru naa.” Matiu 23:4. Awọn ọkan tootọ n wa ninu ibẹru nigba gbogbo wọn n bẹru ibinu Ọlọrun ti a dẹṣẹ si, nigba ti ọpọ awọn ijoye ijọ n gbe ninu ọrọ ati faaji ifẹ ara.ANN 253.2

    Ijọsin awọn ère ati ohun iranti, gbigbadura ni orukọ awọn eniyan mimọ ati gbigbe popu ga jẹ ète Satani lati yi ọkan awọn eniyan kuro ni ọdọ Ọlọrun ati kuro ni ọdọ Ọmọ Rẹ. Lati ṣiṣẹ iparun wọn, o ṣa ipa lati yi akiyesi wọn kuro ni ọdọ Rẹ, nipasẹ ẹnikan ṣoṣo ti wọn fi le ri igbala. Yoo dari wọn si ohunkohun ti o ba le rọpo Ẹni ti O sọ pe: “Ẹ wa si ọdọ Mi, gbogbo ẹyin ti n ṣiṣẹ, ti a si di ẹru wuwo le lori, Emi yoo si fi isinmi fun yin.” Matiu 11:28.ANN 253.3

    Iṣẹ Satani nigba gbogbo ni lati fi iwa Ọlọrun, ohun ti ẹṣẹ jẹ, ati awọn koko ọrọ ti wọn ṣe pataki ninu ijakadi nla naa han ni ona ti ko tọ. Ọgbọn ẹwẹ rẹ jẹ ki eniyan o ri ojuṣe rẹ si ofin Ọlọrun gẹgẹ bi eyi ti ko nitumọ, eyi si fun eniyan ni ominira lati dẹṣẹ. Ni akoko kan naa o jẹ ki wọn fẹran lati ni oye nipa Ọlọrun ni ọna ti ko tọ ki wọn baa le ri pẹlu ibẹru ati ikorira dipo ki wọn ri pẹlu ifẹ. Iwa ika ti o wa ninu rẹ ni o fihan wipe o jẹ ti Ẹlẹda; a gbe e wọ ilana ẹsin a si n fihan ninu ilana ijọsin. A fọ awọn eniyan níyè, Satani si n lo wọn gẹgẹ bi aṣoju rẹ lati ba Ọlọrun jagun. Nipa mimu ki a ri iwa Ọlọrun ni ọna ti ko tọ, awọn orilẹ ede abọriṣa wa gbagbọ wipe wọn nilo lati fi eniyan rubọ lati le ri oju rere Ọlọrun; a si n wu iwa ika ti o buru julọ labẹ ẹsin ibọriṣa ni gbogbo abala rẹ.ANN 253.4

    Ijọ Roman Katoliki, so aṣa ibọriṣa mọ ẹsin Kristẹni, ati bi ẹsin ibọriṣa, a fi iwa Ọlọrun han ni ọna ti ko tọ, o si n ṣe awọn ohun ti wọn roro ti wọn si n ṣini lara bii ti rẹ. Ni awọn ọjọ agbara Romu a ni awọn ohun elo ijẹniniya lati fipa muni lati gba awọn ikọni rẹ gbọ. Igi idanasunni wa fun awọn ti ko ni igbagbọ ninu ikọni rẹ. Ipaniyan nipakupa wa ni ọna ti a mọ mọ titi ti a o fi ṣe afihan rẹ ni idajọ. Awọn oloye ijọ kẹkọ labẹ Satani oluwa wọn lati wa ọna lati fiyajẹni ni ọna ti o ga julọ ti ẹni ti a n fiya jẹ ko si ni ku. Ni ọpọlọpọ igba a n tu ifiyajẹni yii ṣe debi ti eniyan ko ni le farada a mọ, titi ti ẹni naa a fi juwọ silẹ, ti ẹni ti a n fiyajẹ a fi ri iku gẹgẹ bi idasilẹ didun.ANN 253.5

    Eyi ni atubọtan awọn ti wọn jẹ alatako Romu. Fun awọn atẹle rẹ, o ni ibawi pẹlu pasan, ebi kikankikan, ati jijẹ ara niya nigbogbo ọna ti a ba le gba ronu rẹ, ni ọna ti o n bani lọkan jẹ. Lati ri oju rere Ọrun, onironupiwada a ru ofin Oluwa nipa riru ofin ilera. A kọ wọn lati ja ide eyi ti O dá lati bukun ati lati mu inu eniyan dun ninu irin ajo aye rẹ. Agbala ile ijọsin kun fun ọpọ eniyan ti wọn lo igbesi aye wọn ninu akitiyan asan lati tẹ ifẹ ara ti a da mọ wọn ri, lati tẹ gbogbo ero ati imọlara ikaanu fun awọn ẹda ẹlẹgbẹ wọn ri gẹgẹ bi eyi ti o n bi Ọlọrun ninu.ANN 253.6

    Bi a ba fẹ lati ni oye iwa onroro Satani, ti o ti n fi ara han fun ọpọ ọdun, ki i ṣe laarin awọn ti wọn ko gbọ nipa Ọlọrun, ṣugbọn ni aaringungun ati ni gbogbo ibi ti ipa Kristẹni de, ohun ti a nilati ṣe lasan ni ki a wo itan ẹsin Romu. Nipasẹ ilana nla fun itanjẹ yii, ọmọ alade okunkun mu erongba rẹ lati ko ẹgan ba Ọlọrun ati ijiya ba eniyan ṣẹ. Bi a si ti n ri bi o ti n ṣe aṣeyege ni fifi ara rẹ pamọ ti o si n ṣe iṣẹ rẹ nipasẹ awọn adari ijọ, o yẹ ki a ni oye si nipa idi ti o fi ni ikorira ti o pọ bẹẹ si Bibeli. Bi a ba ka Iwe Mimo, ifẹ ati aanu Ọlọrun yoo farahan, a o ri wipe ko gbe ọkan ninu awọn ẹru wuwo wọnyi ru ni. Gbogbo ohun ti O n beere fun ni ọkan onirobinujẹ ti n ṣe ikaanu, ẹmi irẹlẹ ti n ṣe igbọran.ANN 254.1

    Kristi ko funni ni apẹẹrẹ ninu igbesi aye Rẹ lati de ara ẹni mọ inu ile ijọsin lati le yẹ fun ọrun. Ko kọni wipe ki a tẹ ero ifẹ ati ikaanu ri. Ọkan Olugbala kun fun ifẹ. Bi eniyan ba ti n jẹ pipe ni iwa si, bẹẹ ni akiyesi rẹ a ṣe lagbara si, bẹẹ ni yoo ni oye ẹṣẹ si, bẹẹ si ni ikaanu rẹ fun awọn ti a n fiya jẹ a jinlẹ si. Popu sọ wipe oun ni arọpo Kristi, ṣugbọn bawo ni iwa rẹ ṣe jọ ti Olugbala wa to? Ṣe a ri ki Kristi o ti awọn eniyan mọ ọgba ẹwọn tabi igi ifiyajẹni nitori pe wọn ko jọsin Rẹ gẹgẹ bi Ọba ọrun? Njẹ a gbọ ki o ṣe idajọ iku fun awọn ti ko gba A? Nigba ti awọn eniyan abule Samaria kan fi oju tinrin Rẹ, inu bi apostoli Johanu, o si beere: “Oluwa iwọ ko ha fẹ ki a pe ina sọkalẹ lati ọrun, ki o si jo wọn run, ani bi Elija ti ṣe?” Jesu wo ọmọ ẹyin Rẹ pẹlu ikaanu, O si ba ẹmi lile inu rẹ wi, ni wiwipe: “Ọmọ eniyan ko wa lati pa ẹmi awọn eniyan run, bikoṣe lati gba a la.” Luku 9: 54, 56. Ẹmi ti Kristi fihan ti yatọ si ẹmi ẹni ti o pe ara rẹ ni arọpo Rẹ to.ANN 254.2

    Bayi ijọ Romu n fi oju rere han si araye, o n tọrọ idariji fun awọn iwa ika onroro ti wọn wa ninu akọsilẹ rẹ. O ti wọ ara rẹ ni aṣọ bi Kristi, ṣugbọn ko yipada. Gbogbo ikọni ijọ padi ti wọn wa tẹlẹ ni wọn si wa loni. Wọn si gba awọn ikọni ti a ṣe nigba ti oju dudu gbọ. Ki ẹnikẹni maṣe tan ara rẹ jẹ. Ijọ padi ti awọn Protestant ṣetan bayi lati buyi fun sì ni eyi ti o ṣe akoso aye ni awọn ọjọ iṣẹ Atunṣe, nigba ti awọn eniyan Ọlọrun dide, laika ẹmi wọn si, ti wọn si n fi awọn aiṣedeede rẹ han. O si ni irera ati igberaga ti o n mu ki o lo agbara lori awọn ọba ati ijoye, o si n sọ wipe oun ni aṣẹ lati ọdọ Ọlọrun. Ẹmi ika ati onroro rẹ ko dinku nisinsinyii ju ti igba ti o pa ominira eniyan run ti o si pa awọn ẹni mimọ Ẹni Giga julọ.ANN 254.3

    Ijọ padi si jẹ ohun ti isọtẹlẹ sọ wipe yoo jẹ, iyapa ti igba ikẹyin. 2 Tẹsalonika 2:3, 4. O jẹ ara iṣesi rẹ lati wu iwa ti yoo jẹ ki o ri ohun ti o ba fẹ julọ, ṣugbọn labẹ ifarahan alayipada alagẹmọ, o fi oró ejo ti ko yipada pamọ. “Ko yẹ ki a pa igbagbọ mọ pẹlu ẹlẹkọ odi, tabi ẹnikẹni ti a ba funra si wipe o le ni ẹkọ odi,” ni o wi. Ṣe agbara yii, eyi ti a ṣe akọsilẹ rẹ fun ẹgbẹrun ọdun pẹlu ẹjẹ awọn eniyan mimọ ni a o wa gba nisinsinyii gẹgẹ bi ara ijọ Kristi?ANN 254.4

    O ni idi ti awọn orilẹ ede Protestant fi n sọ wipe ẹsin Katoliki ko yatọ pupọ si ẹsin Protestant ju ti atẹyinwa lọ. Iyatọ wa nitootọ, ṣugbọn ki i ṣe ninu ijọ padi. Ẹsin katoliki jọ ẹsin Protestant ode oni yii nitootọ, nitori ẹsin Protestant ti bajẹ pupọpupọ lati akoko awọn Alatunṣe wa.ANN 254.5

    Bi awọn ijọ Protestant ti n wa oju rere aye, ifẹ eke ti fọ wọn loju. Wọn ko ri ju wipe o tọna lati gbagbọ ninu inurere inu gbogbo iwa buburu lọ, ni opin rẹ, laisi idaduro wọn a gbagbọ ninu iwa ibi ti o wa ninu gbogbo iwa rere. Dipo ki wọn duro lati gbeja igbagbọ ti a fun awọn eniyan mimọ lẹẹkan ṣoṣo, bayi, wọn n tọrọ aforiji lọwọ Romu fun ero ti ko dara ti wọn ni nipa rẹ, wọn n bẹbẹ fun idariji fun igbagbọ aimọkan wọn.ANN 254.6

    Ọpọ eniyan, ani awọn ti wọn ko fi oju rere wo ẹsin Romu ni ko ri ewu ti o pọ ninu agbara ati ipa rẹ. Ọpọ ni wọn n sọ wipe okunkun ninu ironu ati iwuwasi ti o wọpọ nigba Middle Ages ni o gba awọn ikọni, eke ati ifiyajẹni rẹ laaye lati tan kalẹ, ati pe bi oye akoko ọlaju wa yii ti pọ to, bi imọ ti n tan kalẹ to, ti awọn eniyan si ti n lawọ si nipa ẹsin ko ni gba ki ainifarada ati iwa onroro rẹ o sọji. A n fi ero wipe iru awọn nnkan bayii yoo ṣẹlẹ ni akoko ọlaju wa yii ṣẹfẹ. Lootọ ni wipe imọlẹ nla ninu imọ, iwuwasi, ati ẹsin, n tan si ori iran yii. Ninu Ọrọ Mimọ Ọlọrun, a ti tan imọlẹ lati ọrun sori aye. Ṣugbọn a nilati ranti wipe bi imọlẹ ba ti pọ to, bẹẹ ni okunkun awọn ti wọn ba ṣi i lo, ti wọn tun kọ ọ silẹ a ti pọ to.ANN 254.7

    Kikọ ẹkọ Bibeli pẹlu adura a fihan awọn Protestant ohun ti ijọ padi jẹ gan, yoo si jẹ ki wọn korira rẹ, ti wọn yoo si kọ ọ silẹ; ṣugbọn ọpọlọpọ ni wọn gbọn ninu ero wọn ti wọn ko ni idi lati wa Ọlọrun pẹlu irẹlẹ ki a baa le dari wọn sinu otitọ. Bi o tilẹ jẹ wipe wọn n gbe ara wọn ga nitori ọlaju wọn, wọn jẹ ope ninu ọrọ Ọlọrun ati nipa agbara Ọlọrun. Wọn nilati wa awọn ọna lati pa ẹri ọkan wọn lẹnu mọ, wọn n wa eyi ti ko ni i ṣe pẹlu ohun ẹmi ni ọna to pọ ti ko si nilo irẹlẹ pupọ. Ohun ti wọn n fẹ ni ọna ti yoo mu ki wọn gbagbe Ọlọrun ṣugbọn ti a o gba gẹgẹ bi ọna lati maa ranti Rẹ. Ijọ padi mọ ọna lati ba awọn aini wọnyi pade. A ṣe e fun ẹgbẹ eniyan meji ti o fẹrẹ ko gbogbo aye ja—awọn ti wọn fẹ ki iṣẹ ọwọ wọn o gba wọn la, ati awọn ti wọn fẹ ki a gba wọn la ninu ẹṣẹ wọn. Nibi ni aṣiri agbara rẹ wa.ANN 255.1

    A ti fihan wipe akoko okunkun ninu imọ ran aṣeyọri ijọ padi lọwọ. A a tun fihan wipe akoko imọlẹ nla nipa imọ ran aṣeyọri rẹ lọwọ pẹlu. Ni awọn ọdun ti o kọja sẹyin, nigba ti awọn eniyan ko ni ọrọ Ọlọrun ti wọn ko si ni imọ otitọ, a di wọn loju, a si ko ọpọlọpọ sinu idẹkun, ti wọn ko ri àwọn ti a dẹ fun ẹsẹ wọn. Ninu iran yii, ọpọlọpọ wa ti itansan ironu eniyan kọ mọna mọ loju, “eyi ti a n fi eke pe ni imọ;” wọn ko ri awọn naa, wọn si n rin lọ taara a fi bi ẹni ti a di loju. Ọlọrun ṣe e ki eniyan o ri agbara imọ rẹ gẹgẹ bi ẹbun lati ọdọ Ẹlẹda rẹ ki o si lo o fun iṣẹ otitọ ati ododo, ṣugbọn nigba ti a ba fẹran igberaga ati ọkanjuwa, ti eniyan si gbe ero rẹ ga ju ọrọ Ọlọrun lọ, nigba naa, imọ rẹ a ṣiṣẹ buburu ju aimọkan lọ. Bayi ni awọn imọ eke ti ode oni, eyi ti o n sẹ igbagbọ inu Bibeli, yoo ṣe ṣe aṣeyọri ni pipese ọna silẹ fun titẹwọ gba ijọ padi pẹlu awọn aṣa rẹ ti wọn wuni, gẹgẹ bi fifi imọ pamọ ti ṣe ni ṣiṣi ọna silẹ fun igbega rẹ ni Akoko oju Dudu.ANN 255.2

    Ninu awọn ẹgbẹ ti wọn wa ni United States nisinsinyii, ti wọn n fẹ lati ri atilẹyin ilu fun agbekalẹ ati aṣa ijọ, awọn Protestant n tẹle igbesẹ awọn atẹle popu. Rara, ju eyi lọ, wọn n ṣi ọna silẹ fun ijọ padi lati ri agbara ti o padanu ni Europe ni Protestant Amẹrika. Ohun ti o si mu ki ẹgbẹ yii o ṣe pataki ni wipe erongba wọn ni pato ni pe ki a fi ofin muni pa ọjọ kini ọsẹ mọ—aṣa ti o ti ọdọ Romu wa, eyi ti o sọ wipe oun ni ami aṣe oun. Ẹmi ijọ padi—ẹmi ibarẹ pẹlu aṣa aye, ibọwọfun aṣa eniyan ju ofin Ọlọrun lọ—ni o n wọ awọn ijọ Protestant ti o si n dari wọn lati ṣe iṣẹ gbigbe Sọnde ga, eyi ti ijọ padi ṣe ṣaaju wọn.ANN 255.3

    Bi ẹni ti o n ka iwe yii ba fẹ ni oye awọn ohun elo ti a o lo ninu ijakadi ti n bọ laipẹ, ohun ti o nilati ṣe ni ki o tọpasẹ akọsilẹ nipa ọna ti Romu lo fun ohun kan naa ni atẹyinwa. Bi yoo ba mọ bi awọn atẹle popu ati awọn Protestant a ṣe lẹdi apo pọ lati jẹ awọn ti wọn ba kọ ikọni wọn silẹ niya, jẹ ki o wo ẹmi ti Romu fihan si ọjọ Isinmi ati awọn ti wọn duro ti i.ANN 255.4

    Aṣẹ ọba, igbimọ apapọ ati ilana ijọ ti agbara oṣelu mu duro ni ọna ti ọjọ isin ibọriṣa yii fi de ipo ọla ninu ẹsin Kristẹni. Ọna akọkọ ti a fi fi ofin mu gbogbo eniyan pa ọjọ kini ọsẹ mọ ni ofin ti Constantine ṣe (AD 321). Aṣẹ yii mu ki awọn eniyan inu ilu o sinmi “ni ọjọ ọlọwọ oorun,” ṣugbọn o gba awọn ti n gbe igberiko laaye lati tẹsiwaju ninu iṣẹ wọn. Bi o tilẹ jẹ wipe aṣẹ ibọriṣa ni patapata, lẹyin ti ọba Costantine fi ẹnu gba ẹsin Kristẹni tan ni o ṣe ofin yii.ANN 255.5

    Aṣẹ ọba ko kun oju oṣuwọn to lati yi aṣẹ Ọlọrun pada, Eusebius, biṣọbu ti n wa oju rere awọn ijoye, ti o si jẹ ọrẹ pataki ati asọrọ didun si Constantine, sọ wipe Kristi ti yi ọjọ Isinmi pada si Sọnde. A ko funni ni ẹri kan ṣoṣo ninu Iwe Mimọ lati gbe ikọni tuntun yii lẹsẹ. Eusebius funra rẹ ni aimọ fi ọwọ si eke ti o wa nibẹ ti o si tọka si ẹni ti o fa iyipada naa. O sọ pe, “Ohun gbogbo ti o ba yẹ lati ṣe ni ọjọ Isinmi, awọn wọnyi ni a ti gbe wa si ọjọ Oluwa.” Ṣugbọn igbagbọ nipa ọjọ Sọnde pẹlu bi ko ti lẹsẹ nilẹ to, mu ki awọn eniyan o nigboya lati tẹ ọjọ Isinmi Oluwa loju. Gbogbo awọn ti wọn fẹ lati ni iyi loju aye gba ọjọ isinmi gbogboogbo naa.ANN 255.6

    Bi ijọ padi ti n fẹsẹ mulẹ si, o n tẹsiwaju ninu iṣẹ rẹ lati gbe Sọnde ga. Fun igba diẹ awọn eniyan n ṣiṣẹ agbẹ nigba ti wọn ko ba lọ si ile ijọsin, ti wọn si n ri ọjọ keje gẹgẹ bi ọjọ Isinmi. Ṣugbọn diẹdiẹ ni wọn ṣe ayipada naa. A ko faaye gba awọn ti wọn wa ninu ipo mimọ lati ṣe idajọ lori ọrọ ilu kankan ni ọjọ Sọnde. Laipẹ a pa gbogbo eniyan, ipokipo yoo wu ki wọn wa, laṣẹ lati maṣe ṣe iṣẹ kankan bi wọn ko ba fẹ san owo itanran, eyiini fun ominira, ati bi iranse ko ba fẹ ki a na oun ni pasan. A tun paṣẹ wipe a yoo jẹ ọlọrọ niya nipa pipadanu aabọ ohun ini rẹ; ati nikẹyin, a o sọ ẹni ti ko ba ṣe igbọran di ẹru. A yoo le awọn ti ko ba ni ọrọ kuro ni ilu.ANN 256.1

    A tun ṣe ijẹri awọn iṣẹ iyanu pẹlu. Lara awọn iyanu ti a royin rẹ ni agbẹ kan ti o fẹ ro oko rẹ ni ọjọ Sọnde ti o fọ ohun ìroko rẹ, irin naa tamọ lọwọ, ti o si gbe bẹẹ fun ọdun meji, “si irora ati itiju.”ANN 256.2

    Nigba ti o ṣe, popu paṣẹ ki awọn alufa o gba awọn ti n ba ọjọ Sọnde jẹ niyanju, oun si fẹ ki wọn lọ si ile ijọsin, ki wọn si gbadura, ki wọn ma baa ko ijamba nla ba ara wọn ati alabagbe wọn. Igbimọ awọn alufa kan sọrọ, ti a si n lo o lati igba yẹn, ani ti awọn Protestant n lo o pẹlu, wipe nitori ti mọnamọna bọ lu ẹnikan ti n ṣiṣẹ ni ọjọ Sọnde, o nilati jẹ ọjọ Isinmi. Awọn alufa sọ wipe, “O han gbangba bi inu Ọlọrun ko ti dun si bi wọn ko ti ka ọjọ yii si.” A parọwa si awọn alufa ati oniwaasu, awọn ọba ati ijoye, ati gbogbo awọn olootọ lati “lo gbogbo agbara ati ipa wọn ki a le da ọjọ naa pada si ipọ ọla rẹ, ati fun ọla ẹsin Kristẹni, ki wọn fi tọkantọkan pa a mọ fun akoko ti n bọ.”ANN 256.3

    Nigba ti aṣẹ igbimọ ko to, a rọ awọn alaṣẹ ilu lati pa aṣẹ ti yoo dẹru ba ọkan awọn eniyan ti yoo si fi ipa mu wọn lati ṣiwọ iṣẹ ni ọjọ Sọnde. Ninu ipade awọn alufa kan ti a ṣe ni Romu, gbogbo ipinu awọn ipade ti iṣaaju ni a fi ontẹ lu pẹlu agbara ati ọwọ ti o ju ti iṣaaju lọ. A ko wọn wọ inu ofin ijọ a si fi aṣẹ ilu ti i lẹyin ni gbogbo ibi ti wọn ti n ṣe ẹsin Kristẹni.ANN 256.4

    Sibẹ ki i ṣe itiju kekere ni aisi aṣẹ Iwe Mimọ fun pipa ọjọ Sọnde mọ ko ba wọn. Awọn eniyan beere ẹtọ ti awọn olukọ wọn ni lati kọ aṣẹ Jehofa silẹ, “Ọjọ keje ni ọjọ Isinmi Oluwa Ọlọrun rẹ,” lati le bọwọ fun ọjọ oorun. Lati le funni ẹri ti Bibeli ko ni, a nilati da ọgbọn miran. Onitara oniwaasu ọjọ Sọnde kan, ni opin ọrundun kejila bẹ awọn ijọ ni England wo, ti awọn ẹlẹri ododo si koju ija si, iṣẹ rẹ ko leso, o si fi ilẹ naa silẹ fun igba diẹ, o n wa ọna miran lati fun awọn ikọni rẹ ni aṣẹ. Nigba ti o pada wa, o gbe ohun ti ko ni tẹlẹ dani, ninu iṣẹ rẹ lẹyin eyi, o ṣe aṣeyọri ti o pọ. O mu iwe kan wa ti o sọ wipe lati ọdọ Ọlọrun funra Rẹ ni o ti wa, eyi ti o ni aṣẹ ti a nilo lati pa ọjọ Sọnde mọ, pẹlu awọn ikilọ ti o lagbara lati dẹruba awọn alaigbọran. Akọsilẹ ti o ṣeyebiye yii—ti o jẹ ẹtan nla bii agbekalẹ ti o ti lẹyin—ni a sọ wipe o jabọ lati ọrun ti wọn si ri ni Jerusalẹmu, lori pẹpẹ St. Simon, ni Golgota. Ṣugbọn nitootọ, afin alufa ni Romu ni ibi ti o ti jade wa. Awọn alaṣẹ ijọ padi ri ẹtan ati ẹru gẹgẹ bi ohun ti o ba ofin mu nigba ti a ba lo o lati tan agbara ati ọrọ ijọ kalẹ.ANN 256.5

    Akọsilẹ naa fi ofin de iṣẹ lati wakati kẹsan, aago mẹta ni ọsan ọjọ Satide, titi di igba ti oorun ba yọ ni ọjọ Mọnde; a si sọ wipe ọpọlọpọ iṣẹ iyanu ni o ti aṣẹ rẹ lẹyin. A royin wipe ẹni ti o ṣiṣẹ kọja wakati ti a la kalẹ ni arun ẹgba. Alọgbado ti o lọ agbado rẹ ri, dipo iyẹfun, àgbàrá ẹjẹ ni o n jade wa, ti ọlọta naa si duro soju kan bi o tilẹ jẹ wipe omi n san daradara. Obinrin ti o gbe iyẹfun sinu ile idana gbe jade ni tutu, bi o tilẹ jẹ wipe ile idana naa gbona janjan. Ẹlomiran ti o pese iyẹfun rẹ silẹ lati gbe sinu ina ni wakati kẹta, ṣugbọn ti o pinu lati gbe pamọ di ọjọ Monde ri ni ọjọ keji wipe a ti sọ ọ di iyẹfun kekeeke, ti agbara Ọlọrun si ti mu ki o jinna. Ọkunrin kan gbe iyẹfun rẹ sinu ina lẹyin wakati kẹsan ọjọ ni ọjọ Satide ri nigba ti o bu u ni ọjọ keji, ti ẹjẹ n jade lati inu rẹ. Nipasẹ iru awọn itan arosọ eke ti ko boju mu wọnyi ni awọn ti n pa ọjọ Sọnde mọ ṣa ipa lati fi fi idi rẹ mulẹ wipe o jẹ mimọ.ANN 256.6

    Ni Scotland, bi ti ilẹ England, a bọwọ ti o ga julọ fun ọjọ Sọnde nipa siso o pọ mọ diẹ ninu ọjọ Isinmi atijọ. Ṣugbọn akoko ti a o pa mọ yatọ. Aṣẹ lati ọdọ ọba Scotland sọ wipe “a nilati ka ọjọ Satide lati aago mejila si mimọ,” ati pe ẹnikẹni, lati akoko naa titi di aarọ Mọnde ko gbọdo ṣe iṣẹ ara kan.ANN 256.7

    Ṣugbọn pẹlu gbogbo ipa lati fi idi ọjọ kini ọsẹ mulẹ bi ọjọ mimọ, awọn atẹle popu funra wọn jẹwọ nigbangba nipa aṣẹ Ọlọrun ti o wa lẹyin ọjọ Isinmi, ati bi aṣa ti o bo o mọlẹ ṣe ti ọdọ eniyan wa. Ni ọrundun kẹrindinlogun, igbimọ ijọ padi sọ ọ ni kedere wipe: “Jẹ ki gbogbo Kristẹni ranti pe Ọlọrun ni o ya ọjọ keje si mimọ, ti ki si i ṣe awọn Ju nikan ni wọn gba a ti wọn si n pa a mọ, bikoṣe gbogbo awọn ti wọn n sọ pe awọn n jọsin Ọlọrun bi o tilẹ jẹ wipe awa Kristẹni ti yi ọjọ Isinmi wọn pada si ọjọ Oluwa.” Awọn ti wọn n tẹ ofin Ọlọrun loju ko ṣe alaimọ iru iṣẹ ti wọn n ṣe. Wọn mọọmọ n gbe ara wọn ga ju Ọlọrun lọ.ANN 257.1

    Apejuwe ti o yanilẹnu nipa iṣesi Romu si awọn ti ko ba fi ohun ṣọkan pẹlu rẹ ni a ri ninu inunibini rẹ si awọn Waldenses fun igba pipẹ, ti diẹ lara wọn pa ọjọ Isinmi mọ. Awọn miran jẹ iru iya kan naa nitori igbọran wọn si ofin kẹrin. Itan awọn ijọ ni Etiopia ati Abyssinia ṣe pataki pupọ. Laarin okunkun Igba Oju Dudu, araye ko mọ nipa awọn Kristẹni ni Aringungun Afrika, ti wọn si n jẹgbadun ominira lati fi igbagbọ wọn han fun ọpọlọpọ ọdun. Ṣugbọn ni ikẹyin, Romu mọ nipa wọn, a si fi ẹtan mu ki ọba Abyssinia o gba popu gẹgẹ bi aṣoju Kristi. Awọn ifayegba miran tẹle. A ṣe ofin ti ko faaye gbani lati pa ọjọ Isinmi mọ labẹ awọn ijiya to le. Ṣugbọn laipẹ onroro ijọ padi di ajaga ti o wuwo to bẹẹ gẹẹ ti awọn ara Abyssinia pinu lati ja kuro lọrun wọn. Lẹyin ijakadi ti o lagbara, a le awọn atẹle Romu kuro ni ilẹ wọn, a si da igbagbọ atijọ pada. Inu awọn ijọ dun fun ominira wọn, wọn ko si gbagbe ẹkọ ti wọn kọ nipa ẹtan, igbonara ẹsin, ati agbara onroro Romu. O tẹ wọn lọrun ki wọn wa ni awọn nikan ninu ilẹ wọn, ki awọn Kristẹni yoku ma mọ nipa wọn.ANN 257.2

    Awọn ijọ ni Africa gba ọjọ Isinmi gẹgẹ bi ijọ padi ti gba a ki o to yapa patapata. Nigba ti wọn pa ọjọ keje mọ ni igbọran si ofin Ọlọrun, wọn ki i ṣe iṣẹ ni ọjọ Sọnde ni ibamu pẹlu aṣa ijọ. Lẹyin ti o gba agbara ti o ga julọ, Romu tẹ ọjọ Isinmi Ọlọrun loju lati le gbe aṣẹ tirẹ ga; ṣugbọn awọn ijọ Afrika, ti wọn wa ni ifarasin fun bi ẹgbẹrun ọdun kan, ko pin ninu iyapa rẹ. Nigba ti wọn bọ si ọwọ akoso Romu, a fi ipa mu wọn lati kọ ọjọ Isinmi otitọ silẹ, wọn si gbe ọjọ isinmi eke ga; ṣugbọn ni kete ti wọn gba ominira wọn, wọn pada lati ṣe igbọran si ofin kẹrin.ANN 257.3

    Awọn akọsilẹ nipa atẹyinwa yii fihan kedere ikorira ti Romu ni si ọjọ Isinmi tootọ ati awọn ti n ṣe atilẹyin rẹ, ati ọna ti o lo lati buyi fun aṣa ti o da silẹ. Ọrọ Ọlọrun kọni wipe awọn iṣẹlẹ wọnyi yoo tun ṣẹlẹ bi awọn ara Roman Katoliki ati Protestant ba ti parapọ lati gbe ọjọ Sọnde ga.ANN 257.4

    Asọtẹlẹ Ifihan 13 sọ wipe agbara ẹranko ti o ni iwo bi ọdọ aguntan yoo mu “aye ati awọn ti n gbe inu wọn” o jọsin ẹsin ijọ padi—eyi ti a fi ẹranko “ti o dabi amọtẹkun” juwe. Ẹranko ti o ni iwo meji yii tun sọ “fun awọn ti n gbe lori ilẹ aye ki wọn ya ere fun ẹranko naa;” ati siwaju si, yoo paṣẹ fun gbogbo eniyan, “ati kekere ati nla, ọlọrọ ati otoṣi, ominira ati onde,” lati gba ami ẹranko naa. Ifihan 13:11—16. A ti fihan wipe United States ni agbara ti ẹranko ti o ni iwo bi ọdọ aguntan naa duro fun, asọtẹlẹ yii yoo si wa si imuṣẹ nigba ti United States ba fi ofin muni pa ọjọ Sọnde mọ, eyi ti Romu ri gẹgẹ bi ohun pataki ti o jẹ ami agbara rẹ. Ṣugbọn ki i ṣe United States nikan ni yoo wa ninu igbọran si popu yii. Agbara Romu ninu awọn orilẹ ede ti wọn fi igba kan ṣe igbọran si ri si wa sibẹ. Asọtẹlẹ si sọ fun wa wipe agbara rẹ yoo pada wa. “Mo ri ọkan ninu awọn ori rẹ ti o ni ọgbẹ aṣapa; a si ti wo ọgbẹ aṣapa rẹ san: gbogbo aye si n fi iyanu tẹlẹ ẹranko naa.” Ẹsẹ 3. Igba ti a fun ni ọgbẹ aṣapa yii tọka si akoko ti popu ṣubu ni 1798. Lẹyin eyi, woli naa sọ pe, “a wo ọgbẹ aṣapa rẹ san: ti gbogbo aye si n fi iyanu tẹle ẹranko naa.” Pọlu sọ ọ ni gbangba wipe “ọkunrin ẹṣẹ,” yoo wa titi di akoko ipadabọ lẹẹkeji. 2 Tẹsalonika 2:3—8. Titi di opin akoko, yoo tẹsiwaju ninu iṣẹ itanjẹ. Onifihan si sọ, nigba ti o n tọka si wipe: “Gbogbo awọn ti n gbe lori ilẹ aye yoo si jọsin rẹ, awọn ti a ko kọ orukọ wọn sinu iwe iye.” Ifihan 13:8. Ninu ilẹ Amẹrika ati Europe, popu yoo gba ijọsin ninu ọla ti a bu fun aṣa ọjọ Sọnde, eyi ti o duro lori aṣẹ ijọ Romu nikan ṣoṣo.ANN 257.5

    Lati aarin ọrundun kọkandinlogun, awọn ti n kẹkọ asọtẹlẹ ni United States ti fi ijẹri yii han fun araye. Ninu awọn iṣẹlẹ ti wọn n ṣẹlẹ bayii, a n ri ti asọtẹlẹ yii n yara kankan wa si imuṣẹ. Awọn olukọni Protestant sọ ẹri aṣẹ Ọlọrun kan naa fun pipa ọjọ Sọnde mọ, ati aisi ẹri Iwe Mimọ kan naa, gẹgẹ bi o ti ri fun awọn adari ijọ padi ti wọn ṣe arosọ awọn iṣẹ iyanu lati duro ni ipo aṣẹ Ọlọrun. A o tun sọ wipe a fi idajọ Ọlọrun bẹ awọn eniyan wo nitori ti wọn ko pa ọjọ Sọnde mọ; wọn tilẹ ti n sọ ọ na. Ẹgbẹ ti n ja fun fifi ofin muni pa ọjọ Sọnde mọ si n gbilẹ kan.ANN 258.1

    Ijọ Romu fi tiyanutiyanu jẹ alarekereke ati ọlọgbọn ẹwẹ. O le mọ ohun ti yoo ṣẹlẹ, o duro de akoko rẹ, ni riri wipe awọn ijọ Protestant n jọsin rẹ nipa gbigba ọjọ isinmi eke ati pe wọn tun n wa ọna lati fi ofin muni pa a mọ pẹlu ọna ti oun funra rẹ lo ni aye atijọ. Awọn ti wọn kọ imọlẹ otitọ silẹ yoo wa iranlọwọ ẹni ti o pe ara rẹ ni agbara ti ko le baku yii lati gbe agbekalẹ ti o bẹrẹ pẹlu rẹ ga. Bi yoo ti yara kankan wa ran wọn awọn Protestant lọwọ ki i ṣe ohun ti o nira lati ro. Tani o mọ bi wọn ti n ṣe pẹlu awọn ti wọn jẹ alaigbọran si ijọ bi awọn olori ijọ padi?ANN 258.2

    Ijọ Roman Katoliki, pẹlu gbogbo awọn aṣoju rẹ kaakiri gbogbo aye, jẹ ẹgbẹ nla kan labẹ akoso popu, ti a si n dari rẹ lati ṣe ifẹ rẹ. A kọ awọn atẹle rẹ ni gbogbo orilẹ ede aye lati ri wipe wọn ni ojuṣe lati ṣe igbọran si popu. Orilẹ ede yoo wu ki wọn ti wá, tabi ijọba wọn, wọn nilati ri aṣẹ ijọ gẹgẹ bi eyi ti o ga ju eyikeyi lọ. Lootọ wọn le jẹjẹ igbọran wọn fun ilẹ wọn, ṣugbọn lẹyin eyi ni ẹjẹ igbọran si Romu wa, ti o si yọ wọn kuro ninu gbogbo ẹjẹ ti o ba lewu si awọn erongba rẹ.ANN 258.3

    Itan sọ fun wa ọna alumọkọrọyi pẹlu aisimi ti o n gba tẹ ara rẹ bọ inu iṣelu awọn orilẹ ede; nigba ti ẹsẹ rẹ ba si rinlẹ tan, a maa mu erongba rẹ ṣẹ, ani bi yoo ba tilẹ pa awọn alaṣẹ ati eniyan ibẹ run. Ninu ọdun 1204, popu Innocent III mu ki Peteru II ọba ilẹ Aragon o jẹ ẹjẹ yii: “Emi, Peteru, ọba awọn ara Aragon, jẹjẹ, mo si ṣe ileri lati jẹ olootọ ati olugbọran nigba gbogbo si oluwa mi, Pope Innocent, si awọn ara Katoliki ti yoo gun ori ipo lẹyin rẹ, ati Ijọ Romu, ati lati fi ododo pa ijọba mi mọ ninu igbọran si, ni igbeja igbagbọ Katoliki, ati ṣiṣe inunibini si awọn ẹlẹkọ odi.” Eyi wa ni ibamu pẹlu igbagbọ nipa agbara alufa Romu “wipe o bofin mu fun lati yọ ọba loye” ati “pe o le sọ fun awọn ọmọ ilu lati maṣe ṣe igbọran si adari ti ki i ṣe olododo.”ANN 258.4

    Ẹ si jẹki a ranti wipe Romu n fọnnu wipe oun ko yipada ri. Igbagbọ Gregory VII ati Innocent III si ni igbagbọ Ijọ Roman Katoliki. Bi o ba ni iru agbara lati ṣe bẹẹ ni, yoo ṣe wọn pẹlu gbogbo ipa gẹgẹ bi o ti ṣe ni atẹyinwa. Awọn Protestant ko ni oye pupọ nipa ohun ti wọn n ṣe nigba ti wọn ro lati wa iranlọwọ Romu ninu iṣẹ ati gbé ọjọ Sọnde ga. Nigba ti wọn n mu erongba wọn ṣẹ, afojusun Romu ni lati fi idi agbara rẹ mulẹ lẹẹkansi, lati gba akoso ti o sọnu pada. Ẹ jẹki a fi idi ofin naa mulẹ ni United States wipe ijọ le lo tabi ṣe akoso agbara ilu, wipe a le fi ofin ijọba de ojuṣe ẹsin, ni kukuru wipe aṣẹ ijọ ati ti ijọba ni ki o ṣe akoso ẹri ọkan, iṣẹgun Romu ninu orilẹ ede yii a daju.ANN 258.5

    Ọrọ Ọlọrun ti funni ni ikilọ nipa ewu ti n bọ yii; ẹ jẹ ki a ṣe aigbọran si eyi, awọn Protestant a wa kọ nipa ohun ti erongba Romu jẹ gan an, ayafi wipe a ti pẹ ju lati sa asala kuro ninu idẹkun naa. Ninu idakẹrọrọ, agbara rẹ n pọ si. Ikọni rẹ n fi ipa wọn han ninu gbọngan awọn aṣofin, ninu ile ijọsin, ati ninu ọkan awọn eniyan. O n kọ ile nla si awọn ilu ti o farasin nibi ti yoo ti tun awọn inunibini atẹyinwa rẹ ṣe. Ni ikọkọ ati aifiyesi, o n fun awọn agbara rẹ lokun lati le mu erongba rẹ ṣe nigba ti akoko ba to fun lati ṣiṣẹ. Gbogbo ohun ti o n fẹ ni anfani ti o tọ, a si ti n fun ni eyi. Laipẹ a o ri, a o si mọ ohun gbogbo ti erongba Romu jẹ gan an. Ẹnikẹni ti yoo ba gbagbọ ti yoo si ṣe igbọran si ọrọ Ọlọrun yoo ri ẹgan ati inunibini.ANN 258.6

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents