Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents
ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORI ỌGBỌN—IKORIRA LAARIN ENIYAN ATI SATANI

    “Emi yoo si fi ọta si aarin iwọ ati obinrin naa, ati si aarin iru ọmọ rẹ ati iru ọmọ rẹ; yoo pa ọ ni ori, iwa yoo si pa ni gigisẹ.” Jẹnẹsisi 3:15. Idajọ ti Ọlọrun ṣe fun Satani lẹyin iṣubu eniyan jẹ asọtẹlẹ pẹlu, ti o yi gbogbo akoko po titi de opin akoko ti o si ṣe awojiji fun ijakadi nla ti yoo kan gbogbo ẹni ti yoo gbe ni ori ilẹ aye.ANN 225.1

    Ọlọrun sọ pe: “Emi yoo fi ọta.” Iṣọta yii ki i ṣe eyi ti a dani mọ. Nigba ti eniyan ṣẹ si ofin Ọlọrun, iṣẹda rẹ da ibi, o wa ni iṣọkan, ki i ṣe iṣọta, pẹlu Satani. Ko si iṣọta kankan laarin ẹlẹṣẹ ati olupilẹsẹ ẹṣẹ. Awọn mejeeji ni wọn ti di ẹni buburu nipasẹ iyapa. Ẹni iyapa nì ko ni sinmi ayafi igba ti o ba ri ikaanu ati iranlọwọ nipa mimu ki awọn eniyan o tẹle apẹẹrẹ rẹ. Fun idi eyi awọn angẹli ti wọn ṣubu ati awọn eniyan buburu wa ni iṣọkan pẹlu ibaṣepọ ti o lagbara. Bi ki i ba n ṣe wipe Ọlọrun da a duro ni ọna pataki ni, Satani ati eniyan i ba wa ni iṣọkan lati tako Ọrun; dipo ki a fẹ lati korira Satani, gbogbo idile eniyan i ba wa ni iṣọkan lati tako Ọlọrun.ANN 225.2

    Satani tan eniyan jẹ lati dẹṣẹ, gẹgẹ bi o ti mu ki awọn angẹli o ṣọtẹ, ki o baa le ri ifọwọsowọpọ wọn ninu ijakadi rẹ pẹlu ọrun. Ko si ede aiyede laarin oun ati awọn angẹli ti wọn ṣubu nipa ikorira wọn fun Kristi; bi o tilẹ jẹ wipe lori gbogbo awọn ohun yoku ede wọn ko yera, wọn fọwọsowọpọ gidigidi ni titako aṣẹ alakoso gbogbo aye. Ṣugbọn nigba ti Satani gbọ ti a kede wipe iṣọta yoo wa laarin oun ati obinrin naa, laarin iru ọmọ rẹ ati iru ọmọ rẹ, o mọ wipe a ti da akitiyan oun lati ba irisi eniyan jẹ duro; nipasẹ ọna kan, a yoo fun eniyan lokun lati doju ija kọ agbara oun.ANN 225.3

    Ikorira Satani ru si iran eniyan nitori pe, nipasẹ Kristi, wọn jẹ afojusun ifẹ ati aanu Ọlọrun. O fẹ lati ba eto Ọlọrun fun irapada eniyan jẹ, lati ko abuku ba Ọlọrun, nipa biba iṣẹ ọwọ Rẹ loju jẹ ati sisọ ọ di aimọ; yoo fa ibanujẹ ni ọrun yoo si fi wahala ati iparun kun inu aye. A wa nawọ si gbogbo iwa buburu wọnyi gẹgẹ bi ayọrisi iṣẹ Ọlọrun ni dida eniyan.ANN 225.4

    Oore ọfẹ ti Kristi fi sinu ọkan ni o fa iṣọta si Satani ninu ọkan eniyan. Laisi oore ọfẹ ti n yini pada ati agbara atunnkanṣe yii, eniyan a tẹsiwaju lati jẹ igbekun Satani, iranṣẹ ti yoo ṣetan ni gbogbo igba lati tẹle aṣẹ rẹ. Ṣugbọn ilana tuntun ninu ọkan da ija silẹ nibi ti alaafia ti wa tẹlẹ. Agbara ti Kristi n fifunni ran eniyan lọwọ lati koju ija si onroro ati ẹni ti o fi ipa gba ohun ti ko tọ si naa. Ẹnikẹni ti a ba ri ti o ba korira ẹṣẹ dipo ki o fẹran rẹ, ẹnikẹni ti o ba doju ija kọ ifẹ ọkan ti n jọba ninu ti o si ṣẹgun rẹ ṣe afihan agbara ti o ti oke wa.ANN 225.5

    Ikorira ti o wa laarin ẹmi Kristi ati ẹmi Satani ni a fihan ni pataki julọ ninu bi araye ṣe tẹwọgba Jesu. Ki i ṣe nitori pe ko ni ọrọ aye, iwuga tabi ẹwa ni iri ni o jẹ ki awọn Ju o kọ Ọ. Wọn ri wipe O ni agbara ti o niyelori ju awọn aini ti ode ara wọnyi lọ. Ṣugbọn iwa ailabawọn ati iwa mimọ Kristi ni o fa ikorira ti awọn alaiwabiọlọrun fun. Igbesi aye isẹra-ẹni Rẹ ati ifọkansin alailẹṣẹ Rẹ jẹ ibawi atigbadegba fun awọn eniyan agberaga ati onifẹkufẹ ara. Eyi ni o fa iṣọta si Ọmọ Ọlọrun. Satani ati awọn angẹli buburu sowọpọ mọ awọn eniyan buburu. Gbogbo agbara ẹmi iyapa ni wọn ṣọtẹ papọ si Aṣẹgun fun otitọ.ANN 225.6

    Iru iṣọta kan naa ni a fihan si awọn atẹle Kristi gẹgẹ bi a ti fihan si Ọga wọn. Ẹnikẹni ti o ba ri bi ẹṣẹ ti jẹ irira to, ti o si doju ija kọ idanwo pẹlu agbara lati oke wa, yoo ru ibinu Satani ati ti awọn atẹle rẹ soke ni dandan. Ikorira ẹkọ otitọ ti ko labawọn, ati ifiṣẹsin ati inunibini si awọn ti n waasu rẹ, yoo wa niwọn igba ti ẹṣẹ ati awọn ẹlẹṣẹ ba wa. Awọn atẹle Kristi ati iranṣẹ Satani ko le wa ni irẹpọ. Ohun idigbolu ninu agbelebu koi tii kuro. “Gbogbo ẹni ti yoo gbe ni iwabiọlọrun ninu Kristi Jesu yoo jiya inunibini.” 2 Timoti 3:12.ANN 225.7

    Awọn aṣoju Satani n ṣiṣẹ loorekoore labẹ akoso rẹ lati fi idi aṣẹ rẹ mulẹ ati lati kọ́ ijọba rẹ ni atako si ijọba Ọlọrun. Nitori eyi wọn wa ọna lati tan awọn atẹle Kristi jẹ ati lati fa wọn kuro ninu igbọran wọn. Bi i ti olori wọn, wọn n ṣe afihan Iwe Mimọ ni ọna ti ko tọ, wọn si n lọ lọrun lati ṣe iṣẹ wọn. Bi Satani ti n ṣe akitiyan lati ko ẹgan ba Ọlọrun, bẹẹ gẹgẹ ni awọn aṣoju rẹ n ṣiṣẹ lati ṣaata awọn eniyan Ọlọrun. Ẹmi ti o ṣe iku pa Kristi n mi si awọn ẹni buburu lati pa awọn atẹle Rẹ run. Gbogbo eyi ni a sọtẹlẹ ninu asọtẹlẹ akọkọ: “Emi yoo fi ọta si aarin iwọ ati obinrin naa, ati si aarin iru ọmọ rẹ ati iru ọmọ rẹ.” Eyi yoo tẹsiwaju titi di opin akoko.ANN 226.1

    Satani ko gbogbo ipa rẹ jọ, o si ju gbogbo agbara rẹ sinu ija naa. Kilo de ti ko ri atako ti o ga? Kilo de ti awọn ọmọ ogun Kristi fi n sun ti wọn ko si bikita? Nitori ti wọn ko ni ibaṣepọ ti o lagbara pẹlu Kristi ni; nitori ti wọn ko ni Ẹmi Rẹ ni. Ẹṣẹ ko jẹ irira si wọn, ko si kà wọn laya, gẹgẹ bi o ti ṣe si Oluwa wọn. Wọn ko doju kọ ọ bi Kristi ti ṣe, pẹlu igbejako ti o lagbara ti o si ni ipinu. Wọn ko ri bi ẹṣẹ ti buru jọjọ ti o si ṣe ni iwa ika to, wọn fọju si iwa ati agbara ọmọ alade okunkun. Iṣọta kekere ni o wa fun Satani ati iṣẹ rẹ, nitori aimọkan nla ni o wa nipa agbara ati arankan rẹ, ati bi ijakadi rẹ pẹlu Kristi ati ijọ Rẹ ti pọ to. Nibi ni a ti tan ọpọlọpọ jẹ. Wọn ko mọ wipe ọgagun alagbara ti o n dari ọkan awọn angẹli buburu ni ọta wọn, ẹni ti o n ba Kristi jagun lati maṣe jẹ ki a gba ọkan la pẹlu eto ti o gbe kalẹ rẹgi, ati iṣọwọṣiṣẹ pẹlu ọgbọn. Laarin awọn ti wọn pe ara wọn ni Kristeni, ani laarin awọn oniwaasu iyinrere, a ki i saba n sọ nipa Satani, ayafi bi ba kan mẹnu ba a lerefe lori pẹpẹ iwaasu. Wọn fi oju fo awọn ẹri fun iṣẹ rẹ nigba gbogbo ati aṣeyọri rẹ da; wọn ko naani ọpọlọpọ ikilọ nipa arekereke rẹ; o dabi ẹnipe wọn jẹ alaimọkan nipa iwalaaye rẹ.ANN 226.2

    Nigba ti awọn eniyan jẹ alaimọkan nipa ete rẹ, ọta ti n ṣọra yii n ṣọ gbogbo irinsi wọn. Gbogbo abala ile ni o n fi ipa wọ, ninu gbogbo adugbo wa, ninu awọn ijọ, ninu awọn igbimọ orilẹ ede, ninu gbọngan idajọ, o n ko iporuuru ọkan bani, o n tannijẹ, o n danni wo, ni ibi gbogbo o n ba ọkan ati ara ọkunrin ati obinrin ati ọmọde jẹ, o n fọ idile ka, o n gbin ikorira, ijowu, ija, iyapa, ati ipaniyan kalẹ. O dabi ẹnipe awọn Kristẹni ri awọn nnkan wọnyi bi ẹnipe Ọlọrun ti ṣe wọn bẹẹ ati pe wọn gbọdọ wa.ANN 226.3

    Satani n ṣiṣẹ ni gbogbo igba lati bori awọn eniyan Ọlọrun nipa bibi ohun ti o pin wọn niya pẹlu aye lulẹ. A ti awọn ọmọ Israeli atijọ sinu ẹṣẹ nigba ti wọn ba wọ inu ibaṣepọ ti ko tọ pẹlu awọn alaigbagbọ. “Ọlọrun aye yii ti fọ awọn ti ko gbagbọ niye, ki imọlẹ ologo ti iyinrere Kristi, Ẹni ti i ṣe aworan Ọlọrun, ma baa tan si wọn.” 2 Korintin 4:4. Iranṣẹ Satani ni gbogbo awọn ti ko ba pinnu lati tẹle Kristi jẹ. Ifẹ ẹṣẹ ati ẹmi lati fẹ ati lati ṣe awawi saba maa n wa ninu ọkan ti koi tii yipada. Ikorira ẹṣẹ, ati ipinu lati koju ija si saba maa n wa ninu ọkan ti a sọ dọtun. Nigba ti Kristẹni ba yan awujọ awọn alaiwabiọlọrun ati awọn alaigbagbọ, wọn fi ara wọn silẹ fun idanwo. Satani fi ara rẹ pamọ, a si maa fi ẹtan rẹ bo wọn loju diẹdiẹ. Wọn ko le ri wipe awujo naa wa lati ṣe wọn nijamba; nigba ti wọn ba si n dabi aye ni iwa, ọrọ ati iṣe ni gbogbo igba bẹẹ ni oju wọn a maa fọ si.ANN 226.4

    Ibadọgba pẹlu aṣa aye maa n yi ọkan ijọ pada sinu aye ni; ki i maa n yi aye pada sinu Kristi. Ni dandan, ibarẹ pẹlu ẹṣẹ koni jẹ ki o kanilaya mọ. Ẹnikẹni ti o ba yan lati ba awọn iranṣẹ Satani ni ajọṣepọ ko ni bẹru ọga wọn mọ laipẹ. Bi a ba bọ sinu idanwo lẹnu ojuṣe wa, bi i Daniẹli ninu aafin ọba, o yẹ ki o da wa loju wipe Ọlọrun a daabo bo wa; ṣugbọn bi a ba fi ara wa si abẹ idanwo, boopẹ booya, a yoo ṣubu.ANN 226.5

    Adanniwo maa n ṣiṣẹ pẹlu aṣeyọri nipasẹ awọn ti wọn ko lero pe wọn wa labẹ iṣakoso rẹ. A maa n yin awọn ti wọn ni ẹbun ti wọn tun kawe a si tun n bọla fun wọn, a fi bi ẹnipe awọn ẹbun wọnyi le rọpo ainibẹru Ọlọrun wọn tabi ki wọn mu eniyan ri oju rere Ọlọrun. Ẹbun ati ọlaju funra wọn jẹ ẹbun Ọlọrun; ṣugbọn nigba ti a ba fẹ ki awọn wọnyi rọpo iwabiọlọrun, nigba ti wọn ba n dari wa kuro ni ọdọ Ọlọrun dipo ki wọn mu wa sunmọ si, wọn ti di egun ati ẹbiti ikọsẹ. O jẹ igbagbọ ti o wọpọ wipe ohun gbogbo ti o ba fara han bi inu rere ati iwa ti o bojumu, ni ọna kan tabi omiran nilati jẹ ti Kristi. Ko si aṣiṣe ti o tobi ju eyi lọ. Awọn iwa wọnyi nilati sọ gbogbo iwa Kristẹni lọjọ, nitori ti wọn ni ipa ti o lagbara lati le mu ki a fi oju rere wo ẹsin tootọ; ṣugbọn a nilati ya wọn si mimọ fun Ọlọrun, laiṣe bẹẹ, wọn le jẹ agbara fun ibi. Ọpọlọpọ awọn ti wọn jẹ ọlaju ti wọn n wuwa ti o yẹ, ti wọn ko ni rẹ ara wọn silẹ debi ti wọn yoo fi wuwa ti a ka si iwa aitọ, ni wọn jẹ ohun elo ni ọwọ Satani. Iwa itannijẹ ati ẹlẹtan wọn ati apẹẹrẹ wọn mu ki wọn jẹ ọta ti o lewu fun iṣẹ Kristi ju awọn ti ko laju ti wọn si jẹ alaimọkan lọ.ANN 226.6

    Pẹlu adura atọkanwa ati igbarale Ọlọrun, Solomoni ni ọgbọn eyi ti o jẹ iyalẹnu ati ijọloju fun aye. Ṣugbọn nigba ti o yipada kuro ni ọdọ Ipilẹ okun rẹ, ti o tẹsiwaju lati gbẹkẹle ara rẹ, o ṣubu bi ẹran ijẹ fun idanwo. Agbara agbayanu ti a fun ọba ti o gbọn julọ naa wa sọ ọ di ọta ọkan ti o lagbara.ANN 227.1

    Nigba ti Satani n ṣiṣẹ ni gbogbo igba lati maṣe jẹ ki wọn ri eyi, awọn Kristẹni ko gbọdọ gbagbe wipe, “ki i ṣe ẹjẹ tabi ẹran ara ni a n ba jijakadi ṣugbọn awọn ijọba oju ọrun, awọn alagbara, awọn alaṣẹ ibi okunkun aye yii, ati awọn ẹmi buburu ni oju ọrun.” Efesu 6:12. Ikilọ imisi lati atẹyinwa titi di akoko wa yii ni: “Ẹ maa wa ni airekọja, ẹ maa ṣọra; nitori eṣu ọta yin, bi kiniun ti n ke ramuramu, n rin kaakiri, o n wa ẹni ti yoo pajẹ.” 2 Peteru 5:8. “Ẹ gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ, ki ẹyin le duro doju kọ awọn arekereke eṣu.” Efesu 6:11.ANN 227.2

    Lati igba Adamu titi di akoko wa yii, ọta nla wa ti n lo agbara rẹ lati jẹni niya ati lati panirun. Bayi o n mura silẹ fun ijakadi ikẹyin rẹ pẹlu ijọ. Gbogbo ẹni ti o ba n fẹ lati tẹle Jesu yoo doju ija kọ ọta ti ki i dẹyin yii. Bi Kristẹni ba ti n tẹle Apẹẹrẹ ọrun to, bẹẹ ni o n fi ara rẹ han sita to fun atako Satani. Gbogbo awọn ti wọn n mura siṣe Ọlọrun, ti wọn n wa lati yọ oju irọ ẹni ibi ni sita ti wọn si fẹ fi Kristi han awọn eniyan yoo fi ohun ṣọkan pẹlu ẹri Pọlu, nibi ti o ti sọ nipa sisin Ọlọrun pẹlu irẹlẹ ọkan, pẹlu ọpọlọpọ omije ati idanwo.ANN 227.3

    Satani doju kọ Kristi pẹlu idanwo rẹ ti o le, ti o tun ṣe arekereke julọ. A ja awọn ogun wọnyi nitori wa; awọn iṣẹgun wọnni ni wọn jẹ ki o ṣe e ṣe fun wa lati ṣẹgun. Kristi yoo fi okun Rẹ fun gbogbo ẹni ti o ba wa. Ko si ẹni ti Satani le bori laiṣe wipe o ba fi ọwọ si. Oludanwo ko ni agbara lati dari ọkan eniyan tabi lati fi ipa muni lati dẹṣẹ. O le danilaamu, ṣugbọn ko le banijẹ. O le fa ibanujẹ, ṣugbọn ko le sọni di eeri. Nitori pe Kristi ti ṣẹgun, o yẹ ki eyi o fun awọn atẹle Rẹ ni igboya lati ja bi ọkunrin ninu ogun pẹlu ẹṣẹ ati Satani.ANN 227.4

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents