Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents
ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORI KỌKANDINLOGOJI—AKOKO IDAMU

    “Nigba naa ni Maikẹli yoo dide, Ọmọ Alade nla ti n dide fun awọn ọmọ eniyan rẹ: akoko idamu yoo si wa, iru eyi ti koi ti i wa ri lati igba ti orilẹ ede ti wa ani titi di akoko naa: ni akoko naa ni a o gba awọn eniyan Rẹ la, gbogbo awọn ti a kọ orukọ wọn sinu iwe.” Danieli 12:1.ANN 272.1

    Nigba ti iṣẹ iranṣẹ angẹli kẹta ba pari, aanu ko ni bẹbẹ fun awọn ẹlẹṣẹ ti n gbe inu aye mọ. Awọn eniyan Ọlọrun a ti pari iṣẹ wọn. Wọn ti gba “ojo arọkuro,” “itura lati iwaju Oluwa wa,” a si ti pese wọn silẹ fun akoko wahala to wa niwaju wọn. Awọn angẹli n yara lọ wọn si n bọ ni ọrun. Angẹli kan to n ti inu aye bọ ṣe ikede wipe iṣẹ naa ti pari; a ti ṣe idanwo ti o kẹyin fun araye, gbogbo awọn ti wọn fi ara wọn han gẹgẹ bi olootọ si ilana Ọlọrun si ti gba “edidi Ọlọrun alaaye.” Nigba naa ni Jesu dawọ iṣẹ ibalaja Rẹ ni ibi mimọ loke duro. O gbe ọwọ Rẹ soke, pẹlu ohun nla, O sọ pe, “O pari,” gbogbo ẹgbẹgun awọn angẹli si fi ade wọn lelẹ bi O ti n ṣe ikede ẹlẹru ni wipe: “Ẹni ti n ṣe alaiṣootọ, jẹ ki o maa ṣe alaiṣootọ niso: ati ẹni ti n ṣe alaimọ, jẹ ki o maa ṣe alaimọ niso: ati ẹni ti n ṣe olododo jẹ ki o maa ṣe olododo niso: ati ẹni ti o jẹ mimọ, jẹ ki o maa jẹ mimọ niso.” Ifihan 22:11. A ti ṣe ipinu lori gbogbo ẹjọ boya fun iku tabi fun iye. Kristi ti ṣe iwẹnumọ fun awọn eniyan Rẹ, O si ti pa ẹṣẹ wọn rẹ. Iye awọn ọmọ ijọba Rẹ ti pe; a ti fẹ fi “ijọba ati agbara ijọba naa, ati titobi ijọba naa labẹ gbogbo ọrun,” fun awọn ajogun igbala, Jesu yoo si ṣe akoso bi Ọba awọn ọba ati Oluwa awọn oluwa.ANN 272.2

    Nigba ti O ba kuro ni ibi mimọ, okunkun a ṣubo awọn olugbe aye. Ni akoko ẹlẹru naa awọn olododo nilati gbe niwaju Ọlọrun mimọ laisi olubalaja. A ti mu ijanu ti o wa lori awọn eniyan buburu kuro, Satani si ni akoso patapata lori awọn ti ko ronupiwada nikẹyin. Ipamọra Ọlọrun ti pari. Aye ti kọ aanu Rẹ silẹ, wọn ti kẹgan ifẹ Rẹ, wọn si ti tẹ ofin Rẹ loju. Awọn ẹni ibi ti kọja aala oore ọfẹ wọn, lẹyinọreyin o mu Ẹmi Ọlọrun, ti wọn n fi gbogbo igba kọ silẹ, kuro. Laini aabo oore ọfẹ Ọlọrun, wọn ko ni aabo kuro lọwọ eṣu. Ni akoko naa Satani a ti awọn olugbe aye sinu rogbodiyan nla ti o kẹyin. Bi awọn angẹli Ọlọrun ti ṣiwọ lati ṣe idena fun ẹfufu lile ibinu eniyan, gbogbo awọn agbára omi, ina, ati ti ilẹ ni a o tu silẹ. Gbogbo aye ni yoo kun fun iparun ti o lẹru ju eyi ti o wa si ori Jerusalẹmu igbaa ni lọ.ANN 272.3

    Angẹli kan ṣoṣo ni o pa gbogbo akọbi awọn ara Ijibiti ti o si fi ọfọ kun ilẹ naa. Nigba ti Dafidi ṣẹ si Ọlọrun nipa kika awọn eniyan, angẹli kan ni o fa iparun nla ti a fi ṣe ijiya ẹṣẹ naa. Iru agbara iparun kan naa ti awọn angẹli mimọ lo nigba ti Ọlọrun paṣẹ ni awọn angẹli buburu a lo nigba ti O ba faaye gba a. Awọn agbara wà ti wọn ti ṣetan wọn tilẹ n duro de ifaye gba Ọlọrun lasan ni lati le tan iparun kalẹ si ibi gbogbo.ANN 272.4

    A ti fi ẹsun kan awọn ti wọn bọwọ fun ofin Ọlọrun wipe awọn ni wọn n mu idajọ wa sori aye, a o ri wọn bi okunfa rogbodiyan ẹlẹru ninu aye, ija ati itajẹsilẹ laarin awọn ti wọn n fi iparun kun inu aye. Agbara ti o tẹle ikilọ ikẹyin bi awọn eniyan buburu ninu, ibinu wọn ru si gbogbo awọn ti wọn gba iṣẹ iranṣẹ naa, yoo si ru ẹmi ikorira ati inunibini soke de gongo.ANN 272.5

    Nigba ti Ọlọrun kuro laarin awọn orilẹ ede Ju, awọn alufa ati awọn eniyan ko mọ. Bi o tilẹ jẹ wipe wọn wa labẹ akoso Satani, ti ibinu nla ti o buru julọ si n dari wọn, wọn ṣi ri ara wọn bi ayanfẹ Ọlọrun. Iṣẹ iranṣẹ inu tẹmpili n tẹsiwaju, a n ṣe irubọ lori pẹpẹ ti a ti sọ di eeri, lojoojumọ ni a n ṣe ibukun Ọlọrun sori awọn eniyan ti wọn jẹbi ẹjẹ Ọmọ ti Ọlọrun fẹran ti wọn si n wa lati pa awọn oniwaasu ati apostoli Rẹ. Bẹẹ gẹgẹ nigba ti a ba ṣe idajọ ti ko ṣe e yipada ninu ibi mimọ, ti a si ti ṣe ipinu atubọtan aye yii laileyipada, awọn olugbe aye yii ko ni mọ. Awọn ti a ti gba Ẹmi Ọlọrun kuro lọdọ wọn lẹyinọrẹyin a si tẹsiwaju lati maa tẹle ilana ẹsin, ti itara bii ti Satani eyi ti ọmọ alade iwa buburu a fi kun wọn lati ṣe ete ika rẹ yoo farajọ itara fun Ọlọrun.ANN 272.6

    Bi ọjọ Isinmi ti jẹ koko ọrọ pataki fun ariyanjiyan kaakiri inu ẹsin Kristẹni, ti awọn alaṣẹ ẹsin ati ti ilu si ti parapọ lati ṣe ofin lati pa ọjọ Sọnde mọ, kikọ ti iwọnba awọn eniyan perete kọ jalẹ lati ṣe ohun ti gbogbo awọn eniyan beere fun yoo mu ki wọn di ẹni ifibu loju gbogbo aye. A o sọ wipe a ko gbọdọ faaye gba awọn ti wọn duro lati tako agbekalẹ ijọ ati ofin ilu, wipe o dara fun wọn lati jiya ju ki a ju gbogbo awọn orilẹ ede sinu rogbodiyan ati iwa ailofin lọ. Bakan naa ni “awọn adari awọn eniyan” ṣe sọrọ nipa Kristi ni ẹgbẹsan (1800) ọdun sẹyin. Alarekereke Kaifa wipe, “O san fun wa ki ẹnikan o ku fun awọn eniyan ki gbogbo orilẹ ede ma baa ṣegbe.” Johanu 11:50. Yoo dabi ẹnipe iṣọwọsọrọ yii peye, nikẹyin a o ṣe ofin lati lodi si awọn ti wọn ya ọjọ Isinmi si mimọ, a o da wọn lẹbi gẹgẹ bi awọn to yẹ fun ijiya ti o buru julọ, a o si fun awọn eniyan ni ominira, lẹyin akoko kan lati pa wọn. Ẹsin Romu ni Europe ati ẹsin Protestant ti o ti yan apẹyinda ni Amẹrika yoo ṣe ohun kan naa si awọn ti wọn bu ọla fun ilana Ọlọrun.ANN 273.1

    Awọn eniyan Ọlọrun a wa bọ sinu wahala ati iporuuru ọkan ti woli naa pe ni akoko idamu Jakọbu. “Bayi ni Oluwa wi: A ti gbọ ohùn iwariri, ti ibẹru, ki i si i ṣe ti alaafia. . . . Gbogbo oju joro. O maṣe o! nitori ti ọjọ naa tobi, ti o fi jẹ wipe ko si eyi ti o dabi rẹ: ani akoko idamu Jakọbu ni; ṣugbọn a o gba a la kuro ninu rẹ.” Jeremaya 30:5—7.ANN 273.2

    Aṣalẹ iporuuru Jakọbu, nigba ti o jijakadi ninu adura fun idasilẹ kuro lọwọ Isọ (Jẹnẹsisi 32:24—30) ṣe afihan iriri awọn eniyan Ọlọrun ni akoko idamu. Nitori eke ti o ṣe lati gba ibukun ti baba rẹ fẹ ṣe fun Isọ, Jakobu sa asala fun ẹmi rẹ nigba ti bi arakunrin rẹ ti n leri iku dẹru ba a. Lẹyin ti o wa ni ilẹ ajeji fun ọpọlọpọ ọdun, o jade pẹlu aṣẹ Ọlọrun lati pada si ilẹ abinibi rẹ pẹlu awọn iyawo ati awọn ọmọ rẹ ati agbo ẹran rẹ. Nigba ti o de ibode ilẹ naa, ẹru baa pẹlu iroyin wipe Isọ n bọ wa pẹlu ẹgbẹ awọn jagunjagun, laiṣiyemeji o n bọwa gbẹsan ni. Awọn ẹgbẹ Jakọbu lainihamọra, lailaabo, dabi ẹni pe wọn fẹ ṣubu laini iranlọwọ ninu iwa ipa ati ipaniyan. Eyi ti o tun pakun ẹru ipaya ati ibẹru ni ẹru itiju, nitori ẹṣẹ ara rẹ ni o mu ewu yii wa. Ireti kan ṣoṣo ti o ni ni aanu Ọlọrun, aabo rẹ kan ṣoṣo nilati jẹ adura. Sibẹ ni ipa tirẹ, ko fi ohunkohun silẹ laiṣe lati tu arakunrin rẹ loju ati lati mu ewu ti n bọ kuro. Bẹẹ gẹgẹ ni o yẹ ki awọn atẹle Kristi, bi wọn ti n sun mọ akoko idamu, o ṣe ohun gbogbo ti o yẹ lati le jẹ ki awọn eniyan o ri wọn ni ọna ti o yẹ, lati mu ẹtanu kuro, ki wọn si mu ewu ti o fẹ wu ominira ẹri ọkan kuro.ANN 273.3

    Lẹyin ti o ran idile rẹ lọ ki wọn ma baa ri idamu rẹ, Jakọbu duro ni ohun nikan lati gbadura si Ọlọrun. O jẹwọ ẹṣẹ rẹ, o si fi imoore rẹ han fun aanu Ọlọrun si oun nigba ti o n fi irẹlẹ fi majẹmu ti Ọlọrun da pẹlu awọn Baba rẹ ati ileri ti O ṣe fun ninu iran aṣalẹ ni Bẹtẹli ati ni ilẹ ajeji bẹbẹ. Igba wahala ninu igbesi aye rẹ de, ohun gbogbo wa ninu ewu. Ninu okunkun nibi ti o danikan duro si, o tẹsiwaju lati gbadura o si n rẹ ara rẹ silẹ niwaju Ọlọrun. Lojiji ọwọ kan duro le ni ejika. O ro wipe ọta ni o fẹ gba ẹmi oun, pẹlu gbogbo agbara ibinujẹ ọkan o ba ẹni ti o wa kọlu yii jijakadi. Bi oju ti bẹrẹ sii mọ, ẹni ajeji yii lo agbara rẹ ti o ju ti eniyan lọ, nigba ti o fi ọwọ kan an, ọkunrin alagbara yii dabi arọ, o si ṣubu bi alainiranlọwọ to n bẹbẹ pẹlu ẹkun, si ọrùn olugbejako ti a ko mọ ibi ti o ti wa yii. Wayi, Jakọbu mọ wipe Angẹli majẹmu ni oun ti n ba jijakadi lati igba yii wa. Bi o tilẹ jẹ wipe o ti di amukun ti o si n jẹrora kikan kikan, ko fi erongba rẹ silẹ. O pẹ ti o ti n farada iporuuru ọkan, ibanujẹ ati idamu fun ẹṣẹ rẹ, bayi o nilati ni idaniloju wipe a ti dari ẹṣẹ oun ji. Olubẹwo lati ọrun wa ti fẹ maa lọ, ṣugbọn Jakọbu di mọ Ọ, o n bẹbẹ fun ibukun. Angẹli naa sọ pe, “Jẹ ki n maa lọ nitori ti ilẹ ti mọ,” ṣugbọn alagba naa sọ pe, “Emi ki yoo jẹ ki O lọ, ayafi bi Iwọ ba bukun fun mi.” Iru igboya wo, iru iduroṣinṣin ati iforiti wo ni a fihan nibi! Bi o ba ṣe wipe ifọnnu ikugbu ni eyi ni, oju ẹsẹ ni a ba pa Jakọbu run; ṣugbọn tirẹ jẹ idaniloju ẹni ti o jẹwọ ailera ati aiyẹ rẹ, sibẹ ti o gbẹkẹle aanu Ọlọrun ti n pa majẹmu mọ.ANN 273.4

    “O ba Angẹli jijakadi, o si bori.” Hosia 12:4. Nipasẹ irẹraẹni-silẹ, ironupiwada ati ijọwọ ara ẹni silẹ, eniyan ẹlẹṣẹ ti n baku yii ni iṣẹgun pẹlu Alagbara ọrun. O fi ọwọ rẹ ti o n gbọn di ileri Ọlọrun mu, Ọkan Ifẹ Ainipẹkun ko si le yipada kuro lọdọ ẹbẹ ẹlẹṣẹ. Gẹgẹ bi ẹri iṣẹgun rẹ, ati igbaniyanju fun awọn miran lati tẹle apẹẹrẹ rẹ, a yi orukọ rẹ pada kuro ni eyi ti o ṣe iranti fun ẹṣẹ rẹ, si eyi ti o ṣe iranti fun iṣẹgun rẹ. Wipe Jakọbu ṣẹgun pẹlu Ọlọrun jẹ idaniloju wipe yoo ṣẹgun pẹlu eniyan. Ko bẹru lati doju kọ ibinu ẹgbọn rẹ mọ, nitori pe Oluwa ni aabo rẹ.ANN 273.5

    Satani ti fi ẹsun kan Jakọbu niwaju awọn angẹli, o si n sọ wipe oun ni ẹtọ lati pa a run nitori ẹṣẹ rẹ, o mi si Isọ lati lọ pade rẹ; ni akoko ijakadi alagba naa ni aṣalẹ gigun naa, Satani ṣe akitiyan lati di ẹbi rẹ ru u lati le ko irẹwẹsi ba, ki o si jawọ kuro ni ọdọ Ọlọrun. Jakọbu fẹrẹ di alainireti tan, sugbọn o mọ wipe laisi iranlọwọ lati ọrun, oun yoo ṣegbe. O ti fi tọkantọkan yipada kuro ninu ẹṣẹ nla rẹ, o si bẹbẹ fun aanu Ọlọrun. Ko ni jẹ ki a yi oun pada kuro ninu erongba oun, ṣugbọn o di Angẹli naa mu ṣinṣin, o si bẹbẹ fun ẹdun ọkan rẹ pẹlu ẹkun irora atọkanwa titi ti o fi ṣẹgun.ANN 274.1

    Bi Satani ti mi si Isọ lati kọlu Jakọbu, bẹẹ gẹgẹ ni yoo ru awọn eniyan buburu soke lati pa awọn eniyan Ọlọrun run ni akoko idamu. Bi o ti fẹsun kan Jakọbu, bẹẹ gẹgẹ ni yoo ṣe fẹsun kan awọn eniyan Ọlọrun. O ri aye gẹgẹ bi ọmọ ijọba rẹ, ṣugbọn awọn ẹgbẹ kekere kan ti wọn n pa ofin Ọlọrun mọ n tako ijọba rẹ. Bi o ba le mu wọn kuro lori ilẹ, yoo ni iṣẹgun pipe. O ri wipe awọn angẹli mimọ n daabo bo wọn, o si mọ wipe a ti dari ẹṣẹ wọn ji, ṣugbọn ko mọ wipe a ti ṣe idajọ wọn ni ibi mimọ loke. O ni imọ pipe nipa ẹṣẹ ti o dan wọn wo lati da, yoo wa gbe wọn siwaju Ọlọrun pẹlu asọdun, yoo fi awọn eniyan wọnyi han bi awọn ti ko yẹ fun aanu Ọlọrun bii ti oun. O sọ wipe Oluwa ko le wuwa ododo nipa didari ẹṣẹ wọn ji nigba ti a wa pa oun ati awọn angẹli oun run. O ri wọn gẹgẹ bi ẹran ijẹ rẹ, o si beere ki a fi wọn fun oun lati pa wọn run.ANN 274.2

    Bi Satani ti n fẹsun kan awọn eniyan Ọlọrun nitori ẹṣẹ wọn, Oluwa a fi aaye gba a lati dan wọn wo de gongo. A o dan igboya wọn ninu Ọlọrun, igbagbọ ati iduroṣinṣin wọn wo kikankikan. Bi wọn ti wo ẹyin, ireti wọn tẹri nitori ninu gbogbo igbesi aye wọn iwọnba rere perete ni wọn ri. Wọn ni imọlara kikun nipa ailera ati aiyẹ wọn. Satani ṣe akitiyan lati dẹruba wọn pẹlu ero wipe ko si ireti fun wọn, wipe a ko ni fọ abawọn irira wọn kuro lae. O ni ireti lati pa igbagbọ wọn run ki wọn baa le jọwọ ara wọn fun idanwo ki o si mu wọn kuro ninu igbọran wọn si Ọlọrun.ANN 274.3

    Bi o tilẹ jẹ wipe awọn ọta a yi awọn eniyan Ọlọrun ka, ti wọn si pinu lati pa wọn run, sibẹ iporuuru ọkan ti wọn n jiya rẹ ki i ṣe ibẹru inunibini nitori otitọ wọn bẹru boya wọn koi ti i ronupiwada kuro ninu gbogbo ẹṣẹ wọn, ati pe nipasẹ aṣiṣe inu wọn, wọn le baku lati ri imuṣẹ ileri Olugbala: Emi “yoo pa ọ mọ kuro ninu wakati idanwo, eyi ti n bọwa sori aye.” Ifihan 3:10. Bi wọn ba le ri idaniloju idariji, wọn ko ni bẹru lati jiya tabi lati ku, ṣugbọn bi wọn ba jẹ alaiyẹ, ti wọn si padanu ẹmi wọn nitori abawọn iwa inu wọn, nigba naa ni a o kẹgan orukọ mimọ Ọlọrun.ANN 274.4

    Ni gbogbo ọna wọn n gbọ nipa pipete ọtẹ, wọn si n ri iṣọwọṣiṣẹ takuntakun iṣọtẹ, ifẹ gbigbona dide ninu wọn, ikaanu atọkanwa lati da iyapa nla yii duro ki a si fi opin si iwa buburu awọn eniyan buburu. Ṣugbọn nigba ti wọn n bẹbẹ pẹlu Ọlọrun lati dawọ iṣọtẹ duro, o jẹ pẹlu imọlara itiju nla wipe awọn funra wọn ko ni agbara mọ lati doju ija kọ igbi iwa buburu naa, ki wọn si da pada. Wọn ro wipe bi o ba ṣe wipe wọn ti n fi igba gbogbo lo gbogbo agbara wọn ninu iṣẹ Kristi ni, ti wọn n tẹsiwaju lati agbara de agbara, ogun Satani ki ba ti ni agbara ti ọ pọ lati ṣẹgun wọn.ANN 274.5

    Wọn jẹ ọkan wọn niya niwaju Ọlọrun, wọn n tọka si ironupiwada ti wọn ti ni fun ọpọlọpọ ẹṣẹ atẹyinwa, wọn si n bẹbẹ pẹlu ileri Olugbala: “Jẹ ki o di agbara Mi mu ki o le ba Mi laja; yoo si ba Mi laja.” Aisaya 27:5. Igbagbọ wọn ko baku nitori pe a ko tete dahun si adura wọn. Bi o tilẹ jẹ wipe wọn n jiya ipaya, ibẹru ati iporuuru ọkan, wọn ko dawọ ẹbẹ wọn duro. Wọn di ọwọ mọ okun Ọlọrun bi Jakọbu ti di Angẹli naa mu, iro ọkan wọn si ni: “Emi ki yoo jẹ ki O lọ ayafi bi Iwọ ba bukun fun mi.”ANN 274.6

    Bi o ba ṣe wipe Jakọbu ko yipada kuro ninu ẹṣẹ rẹ nipa fifi èrú gba ogun ibi ni, Ọlọrun i ba ma gbọ adura rẹ ki O si fi aanu pa ẹmi rẹ mọ. Bẹẹ gẹgẹ ni ni akoko idamu, bi awọn eniyan Ọlọrun ba ni ẹṣẹ ti wọn ko jẹwọ niwaju wọn, nigba ti ibẹru ati iporuuru ọkan ba n jẹ wọn niya, a o bori wọn; iporuuru ọkan a ge igbagbọ wọn kuro, wọn ko si ni ni igboya lati bẹbẹ fun idasilẹ lọdọ Ọlọrun. Ṣugbọn nigba ti wọn ni imọlara ti o jinlẹ nipa aṣiṣe wọn, wọn ko ni ẹṣẹ kankan ti wọn gbe pamọ lati fihan. Ẹṣẹ wọn ti ṣaaju wọn lọ si idajọ a si ti pa wọn rẹ, wọn ko si le ranti wọn.ANN 274.7

    Satani mu ki ọpọlọpọ o gbagbọ wipe Ọlọrun a fi oju fo aiṣootọ wọn ninu ohun kekere ile aye kọja, ṣugbọn Oluwa fihan ninu iṣesi Rẹ, pẹlu Jakọbu wipe Oun ko ni fọwọ si tabi farada iwa buburu. Gbogbo awọn ti wọn n tiraka lati ṣe awawi nipa ẹṣẹ wọn tabi lati bo wọn mọlẹ, ti wọn si jẹ ki a fi wọn silẹ ninu iwe ọrun, ni aijẹwọ, ti a ko si dari wọn ji, ni Satani a bori wọn. Bi ijẹwọ wọn ba ti ga to ati bi ipo ti wọn wa ba ti lọla to, bẹẹ ni iwa wọn a ṣe buru to niwaju Ọlọrun, bẹẹ gẹgẹ ni iṣẹgun ọta nla wọn a ti daju to. Awọn ti wọn n fa imurasilẹ fun ọjọ Ọlọrun sẹyin ko le ri i ni akoko idamu tabi ni akoko miran lẹyin rẹ. Ko si ireti fun iru awọn eniyan bawọnyi.ANN 275.1

    Awọn ti wọn pe ara wọn ni Kristẹni ti wọn de akoko rogbodiyan ikẹyin ẹlẹru yii laimurasilẹ jẹwọ ẹṣẹ wọn ninu ibẹru wọn pẹlu iporuuru ọkan, nigba ti inu awọn eniyan buburu n dun nitori iporuuru ọkan wọn. Awọn ijẹwọ yii jẹ nnkan naa pẹlu ti Isọ tabi ti Judasi. Awọn ti wọn ṣe wọn, kaanu fun abayọri irekọja, ki i si i ṣe ẹbi rẹ. Wọn ko ni ikaanu tootọ, ko si ikorira fun ẹṣẹ. Wọn jẹwọ ẹṣẹ wọn nitori ibẹru ijiya, ṣugbọn bi i ti Farao igbaani, wọn a pada sinu ìpe Ọrun nija wọn bi a ba mu idajọ kuro.ANN 275.2

    Itan Jakọbu tun jẹ idaniloju wipe Ọlọrun ko ni kọ awọn ti a tanjẹ, ti a danwo, ti a si ju sinu ẹṣẹ, ṣugbọn ti wọn pada si ọdọ Rẹ pẹlu ironupiwada tootọ silẹ. Nigba ti Satani n wọna lati pa ẹgbẹ yii run, Ọlọrun a ran awọn angẹli Rẹ lati tu wọn ninu ati lati daabo bo wọn ni akoko wahala. Awọn ikọlu Satani gbona wọn si daju, awọn ẹtan rẹ lagbara, ṣugbọn oju Oluwa wa lara awọn eniyan Rẹ, eti Rẹ si n gbọ igbe wọn. Ijiya wọn pọ, o dabi ẹnipe ina ileru fẹrẹ jo wọn run, ṣugbọn Ẹni ti n fọ wọn a mu wọn jade bi wura ti a danwo ninu ina. Ifẹ Ọlọrun fun awọn ọmọ Rẹ ni akoko idanwo nla yii nipọn, o si ṣe jẹjẹ bi ti akoko igbadun wọn; ṣugbọn o yẹ ki a ju wọn sinu ina ileru, a nilati mu ifarawe aye inu wọn kuro, ki aworan Kristi baa le farahan ni pipe.ANN 275.3

    Akoko wahala ati iporuuru ọkan ti o wa niwaju wa yoo nilo igbagbọ ti o le farada aarẹ, idaduro, ati ẹbi—igbagbọ ti ki yoo baku bi a ba tilẹ n dan an wo kikankikan. A fun gbogbo eniyan ni akoko oore ọfẹ lati mura silẹ fun akoko naa. Jakọbu ṣẹgun nitori pe o ni iforiti, o si ṣe ipinu. Iṣẹgun rẹ jẹ ẹri fun agbara adura awiiyannu. Gbogbo awọn ti wọn di ileri Ọlọrun mu gẹgẹ bi o ti ṣe, ti wọn si ṣe e tọkantọkan pẹlu iforiti bi o ti ṣe e, yoo ṣe aṣeyọri gẹgẹ bi o ti ṣe. Awọn ti wọn ko ṣetan lati sẹ ara wọn, lati kẹdun niwaju Ọlọrun, lati gba adura gigun latọkanwa fun ibukun Rẹ, ko ni ri gba. Jijijadu pẹlu Ọlọrun—awọn perete ni wọn mọ itumọ rẹ! Awọn ti wọn na ọkan wọn jade si Ọlọrun pẹlu ifẹ ọkan gbigbona titi ti gbogbo agbara fi na sita ti kere to. Nigba ti igbi iporuuru ọkan ti ẹnu ko le sọ ba ru kọja ẹni ti n bẹbẹ, iwọnba awọn melo ni wọn n fi igbagbọ ti ko baku dimọ ileri Ọlọrun.ANN 275.4

    Awọn ti wọn n lo igbagbọ kekere nisinsinyii wa ninu ewu nla lati ṣubu si abẹ agbara itanjẹ Satani ati aṣẹ ti n dari ẹri ọkan. Ani bi wọn tilẹ fi ara da idanwo naa, wọn yoo wa ninu idamu ati iporuuru ọkan ti o jinlẹ ni akoko idamu, nitori pe ki i ṣe iwa wọn ni lati gbẹkẹle Ọlọrun. Ẹkọ igbagbọ ti wọn kọ lati kọ ni a pọn dandan fun wọn lati kọ labẹ ooru gbigbona ti iporuuru ọkan.ANN 275.5

    Bayi a nilati so ara wa pọ mọ Ọlọrun nipa ṣiṣe ayẹwo awọn ileri Rẹ. Awọn angẹli ṣe akọsilẹ gbogbo adura otitọ ti o ti inu ọkan wa. A nilati yan lati kọ itẹra-ẹni-lọrun onimọ-ti-ara-ẹni-nikan silẹ ju lati kọ biba Ọlọrun sọrọ silẹ lọ. Aini ti o jinlẹ julọ, isẹra ẹni ti o ga julọ ti O fọwọ si, ṣi san ju ọrọ, ọla, irọrun, ati ibadọrẹ laisi rẹ lọ. A nilati wa akoko lati gbadura. Bi a ba jẹ ki ohun aye o gba ọkan wa, Oluwa le fun wa ni akoko nipa mimu oriṣa wura, ile tabi ilẹ ọlọra wa kuro.ANN 275.6

    A ko ni tan awọn ọdọ sinu ẹṣẹ bi wọn ko ba rin ni ọnakọna ayafi eyi ti wọn a tile beere ibukun Ọlọrun. Bi awọn iranṣẹ ti wọn ni ikilọ ẹlẹru ti o kẹyin si araye a ba gbadura fun ibukun Ọlọrun, ki i ṣe ni ọna tutu, aibikita, bi ọlẹ, ṣugbọn pẹlu itara ati ni igbagbọ, bi Jakọbu ti ṣe, wọn a ri ọpọlọpọ aaye nibi ti wọn a ti le sọ pe: “Mo ti ri Ọlọrun lojukoju, a si da ẹmi mi si.” Jẹnẹsisi 32:30. Ọrun a ri wọn gẹgẹ bi ọmọ alade ti o ni agbara lati ṣẹgun pẹlu Ọlọrun ati eniyan.ANN 276.1

    “Akoko idamu, iru eyi ti koi tii si ri,” yoo de sori wa laipẹ, a si nilo iriri ti a ko ni bayi, eyi ti ọpọlọpọ ṣe imẹlẹ lati ni. O saba maa n ṣẹlẹ wipe idamu maa n tobi nigba ti a ba n reti rẹ ju igba ti o da be bawa lọ, ṣugbọn ki i ṣe bii ti wahala ti o wa niwaju wa. Alaye ti o han kedere julọ ko le ṣe afihan bi iṣẹlẹ naa a ti tobi to. Ni akoko idanwo naa, gbogbo ọkan ni o nilati duro fun ara rẹ niwaju Ọlọrun. “Bi Noa, Daniẹli ati Jobu” ba wa ni ilẹ naa, “bi ẹmi Mi ti wa ni Oluwa Ọlọrun wi, wọn ki yoo le gba ọmọkunrin tabi ọmọbinrin la; ṣugbọn wọn a fi ododo wọn gba ọkan ara wọn la.” Isikiẹli 14:20.ANN 276.2

    Nisinsinyii, nigba ti Olu Alufa nla wa si n ṣe etutu fun wa, a nilati wa lati di pipe ninu Kristi. A ko le mu ki Kristi yọnda ara Rẹ fun agbara idanwo, ani bi o tilẹ jẹ ninu ero lasan. Satani n wa ibi ti o ti le ri aaye ninu ọkan eniyan nipa awọn ẹṣẹ ti a fẹran, eyi ti o n fun awọn idanwo rẹ lagbara. Kristi sọ nipa ara Rẹ: “Ọmọ alade aye yii wa, ko si ni ohun kan ninu Mi.” Johanu 14:30. Satani ko le ri ohun kan ti o le fun ni iṣẹgun ninu Ọmọ Ọlọrun. O pa ofin Baba Rẹ mọ, ko si si ẹṣẹ kan ninu Rẹ ti o le ran Satani lọwọ. Ipo ti ẹnikẹni ti yoo duro ni akoko idamu nilati wa niyii.ANN 276.3

    Ni akoko yii a nilati ya ara wa sọtọ kuro ninu ẹṣẹ nipa igbagbọ ninu ẹjẹ Kristi ti n wẹ ẹṣẹ nu. Olugbala wa ọwọn n pe wa lati so ara wa pọ mọ Oun, lati so ailera wa pọ mọ agbara Rẹ, aimọkan wa pọ mọ ọgbọn Rẹ, aiyẹ wa pọ mọ ikayẹ Rẹ. Ipese Ọlọrun jẹ ile ẹkọ nibi ti a nilati kọ ẹkọ ọkan tutu ati irẹlẹ Jesu. Oluwa n gbe afojusun tootọ wa siwaju wa, ki i si i ṣe ọna ti awa i ba yan, eyi ti o rọwa lọrun ti o si dun mọ wa. O wa lọwọ wa lati fi ọwọsowọpọ pẹlu awọn ọna ti Ọrun n lo ninu iṣẹ a ti yi iwa pada si ti apẹẹrẹ ọrun. Ko si ẹni ti o le kọ iṣẹ yii silẹ tabi ti o le fa a sẹyin laiko ewu nla ba ọkan ara rẹ.ANN 276.4

    Apostoli Johanu ninu iran gbọ ohun nla kan ni ọrun wipe: “Egbe ni fun awọn olugbe aye ati okun! nitori ti eṣu sọkalẹ tọ yin wa pẹlu ibinu nla, nitori ti o mọ wipe akoko kukuru ni oun ni.” Ifihan 12:12. Awọn iṣẹlẹ ti wọn fa igbe lati ọrun wa yii jẹ eyi ti o lẹru. Ibinu Satani n pọ si bi akoko rẹ ti n kere si, iṣẹ itanjẹ ati iparun rẹ yoo si de gongo ni akoko idamu.ANN 276.5

    Awọn iṣẹlẹ ẹlẹru ti wọn kọja oye eniyan yoo farahan loju ọrun laipẹ ni ẹri si agbara awọn ẹmi aimọ ti n ṣiṣẹ iyanu. Awọn ẹmi eṣu yoo jade lọ si ọdọ awọn ọba aye ati si gbogbo aye, lati dè wọn mọ inu ẹtan, wọn a si maa ti wọn lati darapọ mọ Satani ninu ijakadi rẹ ti o kẹyin pẹlu ijọba ọrun. Nipasẹ awọn aṣoju wọnyi, awọn alaṣẹ ati awọn ọmọ ilu papọ ni a o tanjẹ. Awọn eniyan a dide ti wọn pe ara wọn ni Kristi funra Rẹ, ti wọn a maa pe ara wọn ni orukọ, wọn a si maa gba ijọsin ti o yẹ fun Olurapada aye. Wọn a ṣe iṣẹ iyanu iwosan, wọn a si kede wipe wọn ni ifihan lati ọrun eyi ti o tako ẹri Iwe Mimọ.ANN 276.6

    Gẹgẹ bi iṣẹ rẹ ti o ga ju ninu iṣẹ itanjẹ, Satani funra rẹ yoo farahan bii Kristi. Ijọ ti n sọ fun igba pipẹ wipe oun n wọna fun wiwa Olugbala gẹgẹ bi imuṣẹ ireti rẹ. Bayi atannijẹ nla naa a mu ki o han wipe Kristi ti wa. Ni oriṣiriṣi ibi ni aye, Satani a fi ara rẹ han laarin awọn eniyan bi ẹda alagbara ti o n tàn, ti o jọ apejuwe Ọmọ Ọlọrun ti Johanu ṣe ninu Ifihan 1:13—15. Ogo ti o yika kọja ohunkohn ti oju eniyan tii ri ri lọ. Ariwo iṣẹgun n lọ ninu afẹfẹ: “Kristi ti de! Kristi ti de!” Awọn eniyan a dọbalẹ niANN 276.7

    ijọsin niwaju rẹ, nigba ti a gbe ọwọ rẹ soke a si bukun fun wọn bi Kristi ti ṣe bukun fun awọn ọmọ ẹyin Rẹ nigba ti O wa lori ilẹ aye. Ohùn rẹ fẹlẹ, o si rẹlẹ, sibẹ, o kun fun irọ. Pẹlu ohun irẹlẹ ati ikaanu o kọni ni diẹ lara awọn otitọ oloore ọfẹ ti Kristi fi kọni; o wo aisan awọn eniyan san, pẹlu iwa Kristi ti o gbe wọ, a sọ wipe oun ti yi ọjọ Isinmi pada si ọjọ Sọnde, a wa paṣẹ fun gbogbo eniyan lati bọwọ fun ọjọ ti oun ti bukun fun. A sọ wipe awọn ti wọn n tẹsiwaju lati maa pa ọjọ keje mọ n sọ ọrọ odi si orukọ oun nipa kikọ lati tẹti si awọn angẹli oun ti oun ran si wọn pẹlu imọlẹ ati otitọ. Eyi ni itanjẹ ti o lagbara ti o fẹrẹ ju gbogbo itanjẹ lọ. Bi awọn ara Samaria tí Simoni Magu tanjẹ, awọn eniyan, lati kekere titi de nla, tẹti si ìraniníye rẹ, wọn n wipe: “Agbara nla Ọlọrun” ni yii. Iṣe 8:10.ANN 276.8

    Ṣugbọn a ki yoo ṣi awọn eniyan Ọlọrun dari. Awọn ikọni kristi eke yii ko wa ni ibamu pẹlu Iwe Mimọ. Awọn ti n jọsin ẹranko naa ati aworan rẹ ni o ṣe ibukun fun, ẹgbẹ gan an pato ti Bibeli sọ wipe a o tu ibinu Ọlọrun laini abula si lori.ANN 277.1

    Siwaju si, a ko gba Satani laaye lati ṣe ayederu bi Kristi yoo ti wa. Olugbala ti ṣe ikilọ fun awọn eniyan Rẹ nipa itanjẹ lori koko ọrọ yii, O si ti sọ ọ ni kedere bi wiwa Oun lẹẹkeji yoo ti ri. “Kristi eke ati woli eke yoo dide, wọn yoo si fi iṣẹ ami ati iṣẹ iyanu nla han; yoo pọ to bẹẹ gẹẹ ni pe bi o ba ṣe e ṣe, wọn yoo tan awọn ayanfẹ paapa jẹ. . . . Nitori naa, bi wọn ba sọ fun yin, Kiyesi O wa ni aṣálẹ, ẹ maṣe lọ: kiyesi O wa ninu iyẹwu, ẹ maṣe gbagbọ. Nitori bi mọnamọna ti n jade wa lati ila oorun ti n tan ani titi de iwọ oorun, bẹẹ ni wiwa Ọmọ eniyan yoo ti ri.” Matiu 24:24—27, 31; 25:31; 1 Tẹsalonika 4:16, 17. Ko si aaye lati ṣe ayederu wiwa yii. Gbogbo aye ni yoo mọ—gbogbo aye ni yoo ri.ANN 277.2

    Kiki da awọn ti wọn jẹ akẹkọ Iwe Mimọ tootọ, ti wọn si ti gba ifẹ fun otitọ nikan ni a o daabo bo kuro ninu itanjẹ alagbara naa ti n ko araye nigbekun. Nipasẹ ẹri Bibeli, awọn wọnyi a da atannijẹ mọ ninu iboju rẹ. Gbogbo eniyan ni akoko idanwo yoo de ba. Nipa jijọ idanwo, a o fi Kristẹni ojulowo han. Ṣe awọn eniyan Ọlọrun fẹsẹ mulẹ daradara ninu ọrọ Rẹ bayii debi pe wọn ko ni gba ohun ti wọn ba ri gbọ bi? Ninu iru idanwo yii, ṣe wọn a di mọ Bibeli ani Bibeli nikan ṣoṣo? Bi o ba ṣe e ṣe Satani yoo di wọn lọwọ lati wa ni imurasilẹ lati le duro ni ọjọ naa. Yoo ṣe ohun gbogbo to bẹẹ gẹẹ lati le di wọn lọna, yoo fi ọrọ aye de wọn mọlẹ, yoo mu ki wọn o gbe ẹru wuwo ti n kaarẹ bani, ki ọkan wọn le kun fun wahala aye yii ti ọjọ naa a si de ba wọn bi olè.ANN 277.3

    Bi aṣẹ lati ọdọ oriṣiriṣi awọn alaṣẹ ẹsin Kristẹni, ni ilodi si awọn ti n pa ofin mọ, ti n jade lati maṣe daabo ijọba bo wọn, ki a si fi wọn silẹ fun awọn ti wọn ba fẹ pa wọn run, awọn eniyan Ọlọrun a sa kuro ninu awọn ilu nla ati awọn ileto, wọn a si parapọ ni ẹgbẹẹgbẹ, wọn a maa gbé nibi isọdahoro ti o pamọ. Ọpọ ni yoo ri ibi aabo ninu ibi kọlọfin oke. Bi awọn Kristẹni afonifoji Piedmont, wọn a fi ibi giga aye ṣe ibi aabo wọn, wọn a si dupe lọwọ Ọlọrun fun “ibi aabo apata.” Aisaya 33:16. Ṣugbọn ọpọlọpọ lati gbogbo orilẹ ede, ati laarin gbogbo eniyan, ati giga ati kukuru, ati ọlọrọ ati otoṣi, ati dudu ati funfun ni a o sọ sinu igbekun ti o buru jọjọ. Awọn ayanfẹ Ọlọrun a la ọjọ aarẹ kọja, ninu ẹwọn, ti a fi irin inu ọgba ẹwọn ka wọn mọ, ti a dajọ iku fun, ti a si fi awọn miran silẹ lati pebi ku ninu ihamọ ẹlẹgbin ti o ṣokunkun. Ko si eti eniyan ti o gbọ igbe wọn, ko si ọwọ eniyan ti o ṣetan lati ran wọn lọwọ.ANN 277.4

    Ṣe Oluwa a gbagbe awọn eniyan Rẹ ni wakati idanwo yii bi? Njẹ O gbagbe Noah nigba ti idajọ wa sori awọn olugbe aye ṣaaju ikun omi? Njẹ O gbagbe Lọti nigba ti ina wa lati ọrun lati pa awọn ilu nla ni pẹtẹlẹ run? Njẹ O gbagbe Josẹfu ti awọn abọriṣa yi kaakiri ni Ijibiti? Njẹ O gbagbe Elija nigba ti ẹjẹ Jesebeli dẹruba a pẹlu atubọtan awọn woli Baali? Njẹ O gbagbe Jeremaya ninu iwo ẹlẹgbin to ṣokunkun ninu ile tubu? Njẹ O gbagbe awọn akọni mẹta ninu ina ileru? tabi Daniẹli ninu iwo kiniun?ANN 277.5

    “Sioni wipe, Oluwa ti kọ mi silẹ, Oluwa mi si ti gbagbe mi. Njẹ obinrin ha le gbagbe ọmọ ọmu rẹ, ti ki yoo fi kaanu fun ọmọ inu rẹ? Sibẹ, wọn le gbagbe, ṣugbọn Emi ki yoo gbagbe rẹ. Kiyesi, Mo ti kọ ọ sinu atẹlẹwọ ọwọ Mi.” Aisaya 49:14—16. Oluwa awọn ọmọ ogun ti wipe: “Ẹni ti o ba fi ọwọ kan ọ fọwọ kan ẹyin oju Rẹ.” Sekaraya 2:8.ANN 277.6

    Bi o tilẹ jẹ wipe awọn ọta sọ wọn sinu tubu, sibẹ ogiri inu tubu ko le di ibasọrọ laarin ọkan wọn ati Kristi lọwọ. Ẹni ti O ri gbogbo ailera, ti O mọ gbogbo idanwo, ga ju gbogbo agbara aye lọ, awọn angẹli a si wa si ọdọ wọn ninu tubu ti wọn danikan wa, pẹlu imọlẹ ati alaafia lati ọrun. Ọgba ẹwọn yoo dabi aafin nitori pe awọn ọlọrọ ninu igbagbọ ni wọn n gbe nibẹ, ogiri ti o ṣokunkun a si mọlẹ pẹlu imọlẹ ọrun bi igba ti Pọlu ati Sila gbadura ti wọn n kọrin iyin ni oru ninu ile tubu ni Filipi.ANN 277.7

    Idajọ Ọlọrun a wa sori awọn ti wọn n wa ọna lati fiya jẹ ati lati pa awọn eniyan Rẹ run. Ifarada ọlọjọgbọọrọ Rẹ pẹlu awọn eniyan buburu ti kì wọn laya ninu ẹṣẹ, ṣugbọn ijiya wọn pẹlu daju o si lẹru nitori ti a fa a sẹyin. “Oluwa yoo dide gẹgẹ bi ti Oke Pẹrasimu yoo binu bii ti afonifoji Gibeoni, ki O le ṣe iṣẹ ajeji Rẹ; ki O si mu iṣẹ Rẹ wa si imuṣẹ, iṣẹ ajeji Rẹ.” Aisaya 28:21. Iṣẹ ijẹniniya jẹ iṣẹ ajeji si Ọlọrun alaanu wa. Oluwa jẹ “alaanu ati oloore ọfẹ, onipamọra ti o pọ ni oore ati otitọ, . . . ti n dari aiṣedeede ati irekọja ati ẹṣẹ ji.” Sibẹ ko ni “jẹki ẹlẹbi o lọ lọfẹ.” “Oluwa lọra lati binu, O pọ ni agbara, ko si ni da ẹlẹṣẹ silẹ lae.” Ẹksodu 34:6, 7; Nahumu 1:3. Pẹlu awọn ohun ẹru ni ododo yoo da aṣẹ ofin Rẹ ti a n tẹ loju lare. A le wo bi ijiya ti o n duro de awọn ẹlẹṣẹ yoo ti gbona to pẹlu bi Oluwa ti lọra lati ṣe idajọ. Orilẹ ede ti O ni ifarada fun ti ki yoo jẹ niya titi ti a fi kun odiwọn ẹṣẹ rẹ niwaju Ọlọrun, yoo mu ago ibinu laisi aanu nikẹyin.ANN 278.1

    Nigba ti Kristi ba ṣiwọ ibalaja ninu ibi mimọ loke, a o tu ibinu laisi abula ti a ṣeleri fun awọn ti wọn jọsin ẹranko naa ati aworan rẹ ti wọn si gba ami rẹ (Ifihan 14:9, 10) jade. Ijiya ti o wa sori Ijibiti nigba ti Ọlọrun fẹ da awọn ọmọ Israeli silẹ fẹ fi ara jọ awọn idajọ ti o lagbara julọ ti o tun pọ, eyi ti yoo wa si ori aye ni kete ṣaaju ki a to da awọn eniyan Ọlọrun silẹ. Onifihan sọ ni ṣiṣe alaye awọn ijiya ẹlẹru naa pe: “Egbò kikẹ ti o dibajẹ si da sori awọn eniyan ti wọn ni ami ẹranko naa, ati sori awọn ti wọn n jọsin aworan rẹ.” Òkun “dabi ẹjẹ oku eniyan: gbogbo ohun alaaye ti n bẹ ninu okun si ku.” “Odo ati orisun awọn omi . . . si di ẹjẹ.” Bi awọn ijiya wọnyi ti lagbara to, a si dá ododo Ọlọrun lare. Angẹli Ọlọrun wipe: “Olododo ni Iwọ, Oluwa . . . nitori pe Iwọ ṣe idajọ bayii. Nitori ti wọn ti ta ẹjẹ awọn eniyan mimọ ati ti awọn woli silẹ, Iwọ si fun wọn ni ẹjẹ mu; nitori pe wọn yẹ.” Ifihan 16:2—6. Nipa didajọ iku fun awọn eniyan Ọlọrun, wọn ti jẹbi ẹjẹ wọn lootọ afi bi ẹnipe wọn fi ọwọ wọn ta a silẹ. Ni ọna kan naa Kristi sọ pe awọn Ju ni akoko Rẹ jẹbi ẹjẹ awọn eniyan mimọ ti a ti ta silẹ lati akoko Abeli, nitori ti wọn ni iru ẹmi kan naa, wọn si n wa lati ṣe iru iṣẹ kan naa pẹlu awọn ti wọn pa awọn woli wọnyi.ANN 278.2

    Ninu ijiya ti o tẹle, a fun oorun ni agbara “lati fi ina jo awọn eniyan lara. Ooru nla si jo awọn eniyan lara.” Ẹsẹ 8, 9. Awọn woli ṣe apejuwe ipo aye ni akoko ẹlẹru yii: “Ilẹ naa n ṣọfọ; . . . nitori ti ikore ṣègbé. . . . Gbogbo igi oko rọ: nitori ti ayọ rọ kuro ni ọdọ awọn ọmọ eniyan. Eso n kẹ labẹ erupẹ ilẹ, a sọ àká di ahoro. . . . Ẹ wo bi awọn ẹranko ti n gbin! agbo ẹran n damu, nitori ti wọn ko ni eweko. . . . Awọn odo omi gbẹ, ina si ti jo papako ni aginju run.” “Orin tẹmpili yoo jẹ hihu ni ọjọ naa, ni Oluwa wi: oku pupọ ni yoo wa ni ibi gbogbo; wọn o maa ju wọn sode pẹlu idakẹjẹẹ.” Joeli 1:10—12; Amosi 8:3.ANN 278.3

    Awọn iyọnu yii ko kari aye, ki gbogbo awọn olugbe aye ma baa parun tan patapata. Sibẹ wọn a jẹ ijiya ti o lẹru julọ ti eniyan tii ri ri. Gbogbo idajọ ti wọn wa sori awọn eniyan, ṣaaju ki akoko oore ọfẹ to pari ni a fi aanu la. Ẹjẹ Kristi ti n ṣe ibalaja n daabo bo ẹlẹṣẹ lati maṣe gba ijiya ẹbi rẹ ni kikun; ṣugbọn ni idajọ ti o kẹyin, a o tu ibinu jade sita laisi aanu.ANN 278.4

    Ni ọjọ naa, ọpọlọpọ ni yoo fẹ lati ri idaabo bo aanu Ọlọrun ti wọn ti n gan fun igba pipẹ. “Kiyesi ọjọ naa n bọ, ni Oluwa wi, ti Emi yoo ran iyan si ilẹ naa, ki i ṣe iyan fun akara, tabi ongbe fun omi, ṣugbọn ti gbigbọ ọrọ Oluwa: wọn yoo si rin lati okun de okun, ati lati ariwa ani titi de ila oorun, wọn yoo sa sọtun sosi lati wa ọrọ Oluwa, wọn ki yoo si ri i.” Amosi 8: 11, 12.ANN 278.5

    Awọn eniyan Ọlọrun ki yoo bọyọ lọwọ ijiya, ṣugbọn nigba ti a n ṣe inunibini si wọn ti wọn si wa ninu idamu, nigba ti wọn n farada ijiya ati aini onjẹ, a ko ni fi wọn silẹ lati parun. Ọlọrun ti o pese fun Elija ko ni kọ ọkan ninu awọn ọmọ Rẹ ti n fi ara wọn rubọ silẹ. Ẹni ti O mọ iye irun ori wọn yoo pese fun wọn, ni akoko iyan a o tẹ wọn lọrun. Nigba ti awọn eniyan buburu n ku nitori ebi ati ajakalẹ arun, awọn angẹli a daabo bo awọn olododo, wọn a si pese fun aini wọn. Si ẹni ti n “rin ọna ododo” ni a ṣe ileri yii fun: “A o fun ni onjẹ; omi rẹ yoo si daju.” ” Nigba ti awọn otoṣi ati alaini ba n wa omi, ti ko si si, ti ahọn wọn baku fun ongbẹ, Emi Oluwa yoo gbọ wọn, Emi Ọlọrun Israeli ki yoo kọ wọn silẹ.” Aisaya 33:15, 16; 14:17.ANN 278.6

    “Bi igi ọpọtọ ki yoo tilẹ tanna, ti eso ko si ninu ajara; iṣẹ igi olifi yoo baku, oko ki yoo si mu onjẹ wa; a o ge agbo ẹran kuro ninu agbo, ọwọ ẹran ki yoo si si ni ibuso mọ;” sibẹ awọn ti wọn n bẹru rẹ “yoo yọ ninu Oluwa” wọn a si yọ ninu Ọlọrun igbala wọn. Habakuku 3:17, 18.ANN 279.1

    “Oluwa ni olusọ rẹ: Oluwa ni aabo ni ọwọ ọtun rẹ. Oorun ki yoo pa ọ ni igba ọsan, tabi oṣupa ni igba oru. Oluwa yoo pa ọ mọ kuro ninu ewu gbogbo: yoo pa ọkan rẹ mọ.” “Yoo gba ọ lọwọ ikẹkun pẹyẹpẹyẹ, ati lọwọ ajakalẹ arun buburu. Yoo da iyẹ Rẹ bo ọ, iwọ yoo si gbẹkẹle abẹ iyẹ apa Rẹ: otitọ Rẹ yoo jẹ asa ati aabo rẹ. Iwọ ki yoo bẹru ijamba ni igba oru; tabi fun ọfa ti n fo ni igba ọsan; tabi fun ajakalẹ arun ti n rin ninu okunkun; tabi fun iparun ti n panirun ni ọsan gangan. Ẹgbẹrun yoo ṣubu ni ẹgbẹ rẹ, ati ẹgbẹrun mẹwa ni ẹgbẹ ọtun rẹ; ṣugbọn ki yoo de ọdọ rẹ. Kikida oju rẹ ni iwọ yoo fi kiye si, ti iwọ yoo si fi ri èrè awọn ẹni buburu. Nitori ti iwọ ti fi Oluwa, Ẹni ti i ṣe aabo mi, ani Ẹni Giga julọ, ṣe ibugbe rẹ, ibikibi ki yoo ṣubu lu ọ, bẹẹ ni arunkarun kan ki yoo sunmọ ibugbe rẹ.” O. Dafidi 121:5—7; 91:3—10.ANN 279.2

    Sibẹ ni oju eniyan yoo dabi ẹnipe awọn eniyan Ọlọrun fẹ fi ẹjẹ wọn ṣe edidi fun ẹri wọn bi i ti awọn ajẹriku ṣaaju wọn. Awọn funra wọn bẹrẹ si nii bẹru wipe Oluwa ti fi wọn silẹ lati ṣubu ni ọwọ awọn ọta wọn. O jẹ akoko irora ti o lẹru. Lọsan ati loru, wọn n kigbe si Ọlọrun fun idasilẹ. Inu awọn eniyan buburu n dun, wọn n kigbe ifiniṣẹsin: “Nibo ni igbagbọ yin wa nisinsinyii? Kilo de ti Ọlọrun ko gba yin kuro lọwọ wa bi ẹyin ba jẹ eniyan Rẹ nitootọ?” Ṣugbọn awọn to n duro wọnyi ranti Jesu to n ku lori agbelebu Kalfari ti awọn olu alufa ati awọn alaṣẹ n kigbe pẹlu ẹgan: “O gba awọn miran la; ṣugbọn ko le gba ara Rẹ la. Bi O ba jẹ Ọba Isreali, jẹki O sọkalẹ lati ori agbelebu, awa yoo si gba a gbọ.” Matiu 27:42. Bi Jakọbu, gbogbo wọn ni wọn n ba Ọlọrun jijakadi. Oju wọn fi ijakadi inu wọn han. Oju gbogbo wọn joro. Sibẹ wọn ko ṣiwọ ẹbẹ atọkanwa.ANN 279.3

    Bi awọn eniyan ba le riran pẹlu oju ọrun, wọn a ri ẹgbẹ awọn angẹli ti wọn pọ ni agbara ti wọn duro yi awọn ti wọn pa ọrọ suuru Kristi mọ ka. Pẹlu ibakẹdun oniwajẹjẹ awọn angẹli wo iporuuru ọkan wọn, wọn si gbọ adura wọn. Wọn duro de ọrọ Adari wọn lati yọ wọn kuro ninu ewu ti wọn wa. Ṣugbọn wọn nilati duro fun igba diẹ si. Awọn eniyan Ọlọrun nilati mu ninu ago naa, ki a si ri wọn bọmi pẹlu itẹbọmi naa. Ifasẹyin gan, ti o ni wọn lara pupọpupọ, ni idahun ti o dara julọ fun adura wọn. Bi wọn ti n ṣe akitiyan lati duro pẹlu igbẹkẹle fun Oluwa lati ṣiṣẹ, wọn fi igbagbọ, ireti, ati suuru han eyi ti wọn ko fihan to ninu iriri ẹsin wọn. Sibẹ, nitori awọn ayanfẹ, a ge akoko idamu naa kuru. “Ṣe Ọlọrun ko ni gbẹsan nitori awọn ayanfẹ Rẹ, ti wọn n kigbe pe E lọsan ati loru? . . . Mo sọ fun yin yoo gbẹsan wọn kankan.” Luku 18:7, 8. Opin yoo yara de kankan ju bi awọn eniyan ti n reti rẹ lọ. A o ko alikama jọ ni ìtí lati ko wọn si inu aka Ọlọrun, a o si ko epo jọ bi igi idana fun ina iparun.ANN 279.4

    Awọn oluṣọna ọrun ti wọn jẹ olootọ si ojuṣe wọn tẹsiwaju lati maa ṣọna. Bi o tilẹ jẹ wipe a ti pa aṣẹ kan gboogi eyi ti o sọ akoko ti a o ṣe iku pa gbogbo awọn ti n pa ofin mọ, awọn ọta wọn ni ibomiran a fẹ ki ọjọ naa yara de kankan, ki akoko ti a yan o to de, wọn yoo gbiyanju lati gba ẹmi wọn. Ṣugbọn ko si ẹni ti o le la aarin awọn oluṣọna alagbara ti wọn yi awọn olootọ ka kọja. A kọ lu awọn miran bi wọn ti n salọ kuro ninu awọn ilu nla ati ileto, ṣugbọn ida ti a gbe soke si wọn da, o si jabọ bii koriko. Awọn angẹli gbeja awọn miran ni irisi bi awọn ologun.ANN 279.5

    Ni gbogbo igba, Ọlọrun n ṣiṣẹ nipasẹ awọn angẹli mimọ fun iranlọwọ ati igbala awọn eniyan Rẹ. Awọn ẹda ọrun n ko ipa takuntakun ninu ọrọ awọn eniyan. Wọn fi ara han pẹlu aṣọ ti n dan bi mọnamọna, wọn wa ni irisi eniyan gẹgẹ bi arinrinajo. Awọn angẹli farahan ni irisi eniyan si awọn eniyan Ọlọrun. Wọn a sinmi bi ẹni ti o rẹ labẹ igi ni ọsan. Wọn jẹ alejo ninu ile eniyan. Wọn ti ṣiṣẹ bi atọna fun arinrinajo ti ilẹ ṣu ba. Pẹlu ọwọ ara wọn, wọn tan ina sori pẹpẹ. Wọn ṣi ilẹkun ile tubu wọn si tu awọn iranṣẹ Oluwa silẹ. Wọn wọ aṣọ ọrun, wọn wa lati yi okuta kuro lori iboji Olugbala.ANN 279.6

    Ni irisi eniyan awọn angẹli saba maa n wa ninu apejọpọ awọn olododo, wọn si n ṣe ibẹwo si apejọpọ awọn ẹni buburu gẹgẹ bi wọn ti lọ si Sodomu, lati ṣe akọsilẹ iṣẹ wọn, lati mọ boya wọn ti la aala ifarada Ọlọrun kọja. Oluwa ni inu didun ninu aanu, nitori awọn perete ti wọn n sin In nitootọ, O fa ọwọ ijamba sẹyin, O si jẹ ki akoko alaafia awọn eniyan Rẹ o pọ si. Oye awọn ti n ṣẹ si Ọlọrun ko to nnkan rara wipe awọn olootọ perete ti wọn fẹran lati gan ati lati jẹ niya ni wọn n da ẹmi awọn funra wọn si.ANN 280.1

    Bi o tilẹ jẹ wipe awọn alaṣẹ aye yii ko mọ, sibẹ ni ọpọ igba níbi apero wọn, awọn angẹli n sọrọ nibẹ. Oju eniyan n wo wọn, eti eniyan n gbọ ipẹ wọn, ete eniyan ti tako àbá wọn ti o si kẹgan imọran wọn, ọwọ eniyan ba wọn pẹlu eebu ati abuku. Ninu gbọngan apero ati ile idajọ, awọn iranṣẹ ọrun wọnyi ti fihan wipe awọn ni oye kikun nipa itan eniyan, wọn ti fi ara wọn han wipe wọn le gbeja awọn ti a n fiya jẹ ju awọn olugbeja ti ẹnu wọn yọ julọ. Wọn ti ba erongba jẹ wọn si ti dawọ ibi duro, eyi ti i ba dawọ iṣẹ Ọlọrun duro ni ọna ti o ga, ti i ba tun fa ijiya fun awọn eniyan Rẹ. Ni akoko wahala ati idamu, “angẹli Oluwa yi awọn ti wọn bẹru Rẹ ka, o si gba wọn.” O. Dafidi 34:7.ANN 280.2

    Pẹlu ifẹ ọkan gbigbona, awọn eniyan Ọlọrun duro de ami Ọba wọn ti n bọ. Bi a ba ti n beere lọwọ aṣọna, “Bawo ni alẹ ti ri?” idahun naa laiṣeyemeji ni wipe, “‘Owurọ n bọ ati aṣalẹ pẹlu.’” Aisaya 21:11, 12. Imọlẹ n tan ninu awọsanma lori awọn oke. Laipẹ a o fi ogo Rẹ han. Oorun ododo yoo tan jade laipẹ. Owurọ ati aṣalẹ jumọ ku si dẹdẹ—ibẹrẹ ọjọ ailopin fun awọn olododo, ati ikorajọ aṣalẹ ailopin fun awọn eniyan buburu.ANN 280.3

    Bi awọn ti n jijadu ti n gbe ẹbẹ wọn wa siwaju Ọlọrun, aṣọ iboju ti o ya wọn ya aye airi fẹrẹ ẹ ka kuro. Awọn ọrun tan pẹlu yiyọ ọjọ ailopin, ati bi ìró orin awọn angẹli, ọrọ naa wa sinu eti wọn: “Ẹ duro ṣinṣin ninu igbọran yin. Iranlọwọ n bọ.” Kristi Aṣẹgun alagbara, na ade ologo ainipẹkun si awọn ọmọ ogun Rẹ ti aarẹ mu, ohùn Rẹ si jade wa lati inu ilẹkun ti a dọra ṣi silẹ: “Kiyẹsi, Emi wa pẹlu yin. Maṣe bẹru. Emi mọ gbogbo ibanujẹ yin; Mo ti ko ẹdun yin. Ki i ṣe ọta ti a koi ti i danwo ni ẹni ti ẹyin n ba jagun. Mo ti ja ija naa fun yin, ni orukọ Mi, ẹ ju aṣẹgun lọ.”ANN 280.4

    Olugbala ọwọn yoo ran iranlọwọ lọgan ti a ba nilo rẹ. A ya ọna ọrun si mimọ pẹlu ipa ẹsẹ Rẹ. Gbogbo ẹgun ti o gun wa lẹsẹ ti gun ẹsẹ Rẹ. Gbogbo agbelebu ti a pe wa lati gbe ni O ti gbe fun wa. Oluwa faaye gba idamu, lati pese ọkan silẹ fun alaafia. Akoko idamu jẹ akoko inira ẹlẹru fun awọn eniyan Ọlọrun; ṣugbọn o jẹ akoko ti o yẹ ki gbogbo onigbagbọ tootọ wọna fun, pẹlu igbagbọ o le ri ki oṣumare ileri o yi ọ ka.ANN 280.5

    “Awọn ẹni irapada Oluwa yoo pada, wọn yoo wa si Sioni pẹlu orin; ayọ ainipẹkun yoo wa ni ori wọn: wọn yoo ri idunnu ati ayọ gba; ikaanu ati ọfọ yoo fo lọ. Emi ani Emi ni Ẹni ti n tu yin ninu: tani iwọ ti iwọ yoo fi bẹru eniyan ti yoo ku, ati ọmọ eniyan ti a o ṣe bi koriko; ti iwọ si gbagbe Oluwa Ẹlẹda rẹ; . . . ti iwọ si n bẹru nigba gbogbo lojojumọ nitori irunu aninilara, bi ẹnipe o ṣetan lati parun? nibo ni irunu aninilara naa ha gbe wa? Onde ti a ti ṣi nipo yara ki a baa le tu silẹ, ati ki o ma baa ku sinu iho, tabi ki onjẹ rẹ ma baa tan. Ṣugbọn Emi ni Oluwa Ọlọrun rẹ, ti o pin okun niya, eyi ti igbi rẹ n ho: Oluwa awọn ọmọ ogun ni orukọ Rẹ. Emi si ti fi ọrọ Mi si ẹnu rẹ, Mo si ti fi ojiji ọwọ mi daabo bo ọ.” Aisaya 51:11—16.ANN 280.6

    “Nitori naa gbọ eyi na, iwọ ẹni ti a n pọn loju, ti o si mu amuyo, ṣugbọn ki i ṣe nipa waini: Bayi ni Oluwa rẹ Jehofa wi, ati Ọlọrun rẹ ti n gbeja eniyan Rẹ, Kiyesi, Emi ti gba ago iwariri kuro ni ọwọ rẹ, gẹdẹgẹdẹ ago irunu Mi; iwọ ki yoo si mu u mọ; ṣugbọn Emi yoo si fi si ọwọ awọn ti n pọn ọ loju; ti wọn ti wi fun ọkan rẹ pe, Wolẹ ki a ba le rekọja: ti iwọ si tẹ ara rẹ silẹ bi ilẹ, ati bi popo fun awọn ti wọn rekọja.” Ẹsẹ 21—23.ANN 280.7

    Oju Ọlọrun n wò de ọjọ iwaju, o n wo wahala ti awọn eniyan Rẹ yoo pade nigba ti agbara aye yoo doju kọ wọn. Bi onde ti a ṣi nipo, wọn a wa ninu ibẹru iku nitori ebi tabi iwa ipa. Ṣugbọn Ẹni Mimọ ti O pin Okun Pupa niya niwaju Israeli, yoo fi agbara nla Rẹ han, yoo si yi igbekun wọn pada. “Wọn yoo jẹ temi, ni Oluwa awọn ọmọ ogun wi, ni ọjọ naa ti Emi yoo ko ohun ọṣọ Mi jọ; Emi yoo da wọn si, bi eniyan ti n da ọmọ rẹ ti o n sin in si.” Malaki 3:17. Bi a ba ta ẹjẹ awọn ẹlẹri ododo Kristi silẹ ni akoko yii, ko ni jẹ eso ti a gbin lati mu ikore wa fun Ọlọrun, bi ẹjẹ awọn ajẹriku. Iṣegbọran wọn ko ni jẹ ẹri lati mu ki awọn miran o gbagbọ ninu otitọ; nitori awọn alaya lile ti bi igbi aanu sẹyin titi ti ko fi le wa mọ. Bi a ba wa fi awọn olododo silẹ lati ṣubu bi ẹran ijẹ ni ọwọ awọn ọta wọn, yoo jẹ iṣẹgun fun ọmọ alade okunkun. OniO. Dafidi naa sọ pe: “Ni akoko iyọnu yoo pa mi mọ ninu ibi aabo Rẹ: nibi ikọkọ ile Rẹ ni yoo pa mi mọ si.” O. Dafidi 27:5. Kristi ti sọrọ: “Ẹ wa ẹyin eniyan Mi, ẹ wọ inu iyẹwu yin lọ, ki ẹ si ti ilẹkun mọ ara yin: ẹ fi ara yin pamọ fun igba diẹ, titi ti ibinu yoo fi kọja. Nitori, kiyesi, Oluwa wá lati ibugbe Rẹ wa lati jẹ awọn olugbe aye niya fun aiṣedeede wọn.” Aisaya 26:20, 21. Igbasilẹ awọn ti wọn ti fi suuru duro de wiwa Rẹ ti a si ti kọ orukọ wọn sinu iwe iye yoo jẹ eyi ti o logo.ANN 281.1

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents