Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents
ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORI OGOJI—A GBA AWỌN ENIYAN ỌLỌRUN SILẸ

    Nigba ti a ba mu aabo ofin eniyan kuro lọdọ awọn ti wọn bọwọ fun ofin Ọlọrun, oriṣiriṣi ẹgbẹ ni yoo dide ni oriṣiriṣi orilẹ ede ti yoo pe fun iparun wọn. Bi akoko ti a ṣe ninu ofin ti n sunmọle, awọn eniyan yoo gbimọ pọ lati fa awọn ẹgbẹ ti a korira yii tu. A yoo pinu lati ṣe ikọlu gboogi ni aṣalẹ kan, eyi ti yoo pa ohun iyapa ti n ṣe ibawi yii lẹnumọ patapata.ANN 282.1

    Awọn eniyan Ọlọrun—awọn miran ninu ọgba ẹwọn, awọn miran fi ara pamọ nibi kọlọfin ninu igbo ati ni awọn oke—ṣi n bẹbẹ fun aabo Ọlọrun, nigba ti ẹgbẹ awọn ti o dihamọra wa ni ibi gbogbo, ti awọn angẹli eṣu n ti siwaju, n mura silẹ fun iṣẹ iku. Bayi ni akoko ti ohun gbogbo de gongo ni Ọlọrun Israeli yoo ṣiṣẹ fun igbala awọn ayanfẹ Rẹ. Oluwa wipe: “Ẹyin yoo ni orin kan gẹgẹ bi igba ti a n ṣe ajọ ni oru, ati inudidun, gẹgẹ bi igba ti eniyan n lọ . . . lati wa si oke Oluwa, si Alagbara Nla Israeli.ANN 282.2

    Oluwa yoo si jẹ ki a gbọ ohùn ologo Rẹ, yoo si fi isọkalẹ apa Rẹ han pẹlu irunu ibinu Rẹ, ati pẹlu ọwọ ina ajonirun, pẹlu ifọnka, iji, ati yinyin.” Aisaya 30:29, 30.ANN 282.3

    Pẹlu iro iṣẹgun, ifiniṣẹsin ati egun, ọgọọrọ awọn eniyan buburu fẹ kọlu awọn ti wọn wa ni ikawọ wọn, nigba ti okunkun dudu, ti o dudu ju okunkun alẹ lọ ṣubu sori ilẹ aye. Lẹyin eyi, oṣumare, ti o n tan pẹlu ogo lati itẹ Ọlọrun, la ọrun ja ti o si dabi ẹnipe o yi awọn ẹgbẹ ti n gbadura ka. Awọn ero ti n binu duro lọgan. Ariwo ẹgan wọn dakẹ. Wọn gbagbe awọn ti wọn n binu apaniyan si. Pẹlu ibẹru, wọn wo ami majẹmu Ọlọrun, wọn si fẹ lati ni aabo kuro lọwọ itansan agbara rẹ.ANN 282.4

    Awọn eniyan Ọlọrun gbọ ọrọ ti o ja geere ti o dabi orin wipe “Gbe oju soke,” ni gbigbe oju soke si ọrun, wọn ri oṣumare ileri. Ikuuku ibinu dudu ti o bo ofurufu fi aaye silẹ, bii Stefanu, wọn tẹ oju mọ ọrun, wọn si ri ogo Ọlọrun ti Ọmọ eniyan si joko lori itẹ Rẹ. Ni iri Rẹ ni Ọlọrun wọn ri ami irẹsilẹ Rẹ; lati ètè Rẹ wa wọn gbọ ibeere ti a beere niwaju Baba Rẹ ati awọn angẹli mimọ: “Emi fẹ ki awọn pẹlu, ti Iwọ ti fi fun Mi o wa pẹlu Mi nibi ti Emi gbe wa.” Johanu 17:24. Lẹẹkansi a gbọ ohun iṣẹgun bi iro orin ti n wipe: “Wọn wa! wọn wa! ni mimọ, ni ailewu ati ni ailabawọn. Wọn ti pa ọrọ suuru Mi mọ, wọn yoo rin laarin awọn angẹli;” ètè jijoro ti n gbọn ti awọn ti wọn duro ṣinṣin ninu igbagbọ si kigbe iṣẹgun.ANN 282.5

    Ni oruganjọ ni Ọlọrun fi agbara Rẹ han fun idasilẹ awọn eniyan Rẹ. Iṣẹ ami ati iṣẹ iyanu n ṣẹlẹ ni ṣisẹ n tẹle. Awọn ẹni ibi n wo iṣẹlẹ naa pẹlu ẹru ati iyanu, nigba ti awọn olododo n wo ami idasilẹ wọn pẹlu ayọ mimọ. O dabi ẹnipe gbogbo iṣẹda ya kuro ni ọna wọn. Iṣan omi ṣiwọ ṣiṣan. Ikuuku dudu n parapọ wọn si n kọlu ara wọn. Ni aarin ofurufu ti n binu, alafo kan wa ti o ni ogo ti a ko le fẹnu sọ, nibi ti ohùn Ọlọrun ti jade wa bi ìró ohùn ọpọ omi ti n wipe: “O pari.” Ifihan 16:17.ANN 282.6

    Ohùn naa mi ọrun ati aye. Ilẹ ríri ti o lagbara ṣẹlẹ, “iru eyi ti koi ti i si ri lati igba ti eniyan ti wa ni ori ilẹ aye, ilẹ riri naa lagbara o si pọ jọjọ.” Ẹsẹ 17, 18. O dabi ẹnipe ofurufu ṣi silẹ, o tun pade. Ogo lati itẹ Ọlọrun si tan jade wa. Awọn oke mì bii koriro ninu afẹfẹ, awọn apata si fọn kaakiri ilẹ. A gbọ ìró ìjì ti n bọ. Okun ru fun ibinu. A gbọ igbe ẹfufu lile bi ìró ohùn awọn ẹmi aimọ ti n lọ ṣe iṣẹ iparun. Gbogbo ilẹ aye mi, o si ru bi igbi omi okun. Ilẹ ya. O dabi ẹnipe ipilẹ rẹ n ṣubu. Awọn oke n tẹri. Awọn erekuṣu ti a n gbé poora. Awọn ibudokọ ọkọ oju omi ti wọn dabi Sodomu nitori iwa ibi tẹri wọ inu omi ti n binu. Babiloni nla naa wa si iranti niwaju Ọlọrun, “lati fun ni ago waini irunu ibinu Rẹ.” Awọn yinyin nla, ti wọn to bi “iwọn talẹnti kan” n ṣe iṣẹ iparun wọn. Ẹsẹ 19, 21. Awọn ilu agberaga di pẹtẹlẹ. Awọn aafin nla, nibi ti awọn eniyan nla aye fi ọrọ wọn ṣe ọṣọ si lati fi ogo fun ara wọn n wó lulẹ niṣoju wọn. Awọn ogiri ọgba ẹwọn ya lulẹ ti a si tu awọn eniyan Ọlọrun, ti a mu nigbekun nitori igbagbọ wọn silẹ.ANN 282.7

    Awọn iboji ṣi silẹ, “ọpọ awọn ti wọn sun sinu erupẹ ilẹ . . . ji dide, awọn kan si iye ainipẹkun, ati awọn kan si itiju ati ẹgan ayeraye.” Daniẹli 12:2. Gbogbo awọn ti wọn kú ninu igbagbọ iṣẹ iranṣẹ angẹli kẹta jade lati inu iboji pẹlu ara ti a ṣe logo, lati gbọ majẹmu alaafia ti Ọlọrun da pẹlu awọn ti wọn pa ofin Rẹ mọ. “Awọn pẹlu ti wọn gun ni ọkọ” (Ifihan 1:7), awọn ti wọn fi Kristi ṣẹsin ti wọn kẹgan Rẹ nigba ti O n ku ninu irora, ati awọn ti wọn fi ipa ṣe atako si otitọ Rẹ ati awọn eniyan Rẹ julọ, ni a ji dide lati ri ninu ogo Rẹ ati lati ri ọla ti a bu fun awọn olootọ ati olugbọran. Ikuuku nla bo oju awọsanma; sibẹ, oorun ntan sihinsọhun, o fi ara han bi oju igbẹsan Jehofa. Mọnamọna nla n kọ ni oju ọrun, wọn yi aye po pẹlu ọwọ ina. Loke awọn iro ara naa, awọn ohùn ẹlẹru n kede iparun awọn eniyan buburu. Ki i ṣe gbogbo eniyan ni wọn ni oye ohun ti wọn n sọ, ṣugbọn awọn ẹlẹkọ eke gbọ yekeyeke. Awọn ti wọn jẹ alaibikita, afọnnu, ati olugbejakoni, ti wọn n yọ ninu iwa ika si awọn eniyan ti n pa ofin Ọlọrun mọ, laipẹ yii, wa kun fun idamu ati iwariri ninu ibẹru. Iro igbe wọn kọja ohùn afẹfẹ. Awọn ẹmi aimọ gba Kristi ni Ọlọrun, wọn si wariri niwaju Rẹ, nigba ti awọn eniyan n bẹbẹ fun aanu ti wọn si n rakoro nitori ibẹru.ANN 283.1

    Awọn woli igbaani sọ bi wọn ti n woye ọjọ Oluwa ninu iran mimọ wipe: “Ẹ hu; nitori ọjọ Oluwa ku si dẹdẹ; yoo de bi iparun lati ọdọ Alagbara wa.” Aisaya 13:6. “Ẹ wọ inu apata lọ, e fi ara pamọ sinu erupẹ fun ẹru nitori ibẹru Oluwa, ati nitori ọjọ ogo ọla nla Rẹ. A o rẹ ìwò giga eniyan silẹ, a o si tẹ ori agberaga eniyan ba, Oluwa nikanṣoṣo ni a o gbe ga ni ọjọ naa. Nitori ọjọ Oluwa awọn ọmọ ogun yoo wa lori olukuluku ẹni ti o rera, ti o si gberaga, ati lori olukuluku ẹni ti a gbe soke, oun ni a o rẹ silẹ.” “Ni ọjọ naa eniyan yoo ju oriṣa fadaka, oriṣa wura rẹ, ti wọn ṣe olukuluku wọn funra wọn lati maa bọ, si ekute ati si adan; lati lọ sinu palapala apata, ati si oke apata sísán nitori ibẹru Oluwa, ati nitori ogo ọlanla Rẹ, nigba ti O ba dide lati mi ilẹ aye jigijigi.” Aisaya 2: 10—12, 20, 21.ANN 283.2

    Laarin apala kan ninu ofurufu, irawọ kan n tan eyi ti itansan rẹ tan ni ilọpo mẹrin ni afiwe pẹlu okunkun naa. O sọrọ ireti ati ayọ si awọn olootọ, ṣugbọn onroro ati ibinu si awọn ti wọn n ru ofin Ọlọrun. Awọn ti wọn fi ohun gbogbo silẹ nitori Kristi wa ninu aabo Kristi nisinsinyii, a pawọn mọ sinu ibi kọlọfin ogo Ọlọrun. A ti dan wọn wo niwaju araye ati awọn ti wọn gan otitọ, wọn si ti fi igbọran wọn han si Ẹni ti O ku fun wọn. Iyatọ ti o yanilẹnu de sori awọn ti wọn duro ṣinṣin ni oju iku. Lojiji a gba wọn silẹ kuro lọwọ okunkun ati iwa onroro nla awọn eniyan ti a sọ di ẹmi aimọ. Oju wọn ti o joro, ti o kun fun aniyan ti o si rù laipẹ yii wa n dan pẹlu iyanu, igbagbọ ati ifẹ. Ohun wọn dide ninu orin iṣẹgun: “Ọlọrun ni aabo ati agbara wa, lọwọ lọwọ iranlọwọ ni igba ipọnju. Nitori naa a ki yoo bẹru bi a tilẹ ṣi aye ni idi, ti a si ṣi awọn oke nla nipo lọ si inu okun; bi omi rẹ tilẹ n hó ti o si n ru, bi awọn oke tilẹ n mì nipa ọwọ bíbì rẹ.” O. Dafidi 46:1—3.ANN 283.3

    Nigba ti awọn ọrọ igbẹkẹle mimọ yii n goke lọ si ọdọ Ọlọrun, ikuuku awọsanma bi sẹyin, a ri awọn ọrun, eyi ti ogo wọn kọja afẹnusọ ni iyatọ si ofurufu dudu ti n binu ni ẹgbẹ mejeejii. Ogo ilu mimọ naa tan jade lati inu ilẹkun nla ti a rọra ṣi. Ọwọ kan si fi ara han ni oju ọrun ti o gbe okuta walaa meji ti a dipọ dani. Woli naa wipe: “Awọn ọrun yoo kede ododo Rẹ: nitori Ọlọrun funra Rẹ ni onidajọ.” O. Dafidi 50:6. Ofin mimọ naa, ododo Ọlọrun ti a kede ni Sinai gẹgẹ bi itọna fun gbigbe aye laarin ọwọ ina ati àrá, ni a wa fihan awọn eniyan gẹgẹ bi odiwọn fun idajọ. Ọwọ naa ṣi walaa naa, a ri awọn akọsilẹ Ofin Mẹwa, ti o dabi ẹnipe a fi kalamu ina kọ ọ. Ọrọ naa farahan ketekete debi pe gbogbo eniyan ni wọn le ka a. A ru iranti awọn eniyan soke, okunkun ìgba-ohun-asan-gbọ ati ẹkọ eke fẹ danu kuro ninu ọkan gbogbo, a si fi ọrọ mẹwa Ọlọrun, ti o wa lerefe, ti o si yeni yeke, ti o ni aṣẹ han gbogbo awọn olugbe aye.ANN 283.4

    Ko ṣe e ṣe lati ṣe alaye ibẹru ati ipaya awọn ti n tẹ ofin mimọ Ọlọrun loju. Oluwa fun wọn ni ofin Rẹ ki wọn le fi ṣe odiwọn iwa wọn ki wọn si mọ ibaku wọn nigba ti anfani si wa fun ironupiwada ati atunṣe; ṣugbọn lati le ri ojurere araye, wọn kọ awọn ilana rẹ silẹ, wọn si n kọ eniyan lati dẹṣẹ. Wọn ti ṣe akitiyan lati fi ipa mu eniyan lati ba ọjọ Isinmi Rẹ jẹ. Bayi ofin naa ti wọn gan wa n da wọn lẹbi. Pẹlu ifarahan ẹlẹru, wọn ri wipe wọn ko ni awawi. Wọn yan ẹni ti wọn yoo ṣe iranṣẹ fun ti wọn yoo si sin. “Nigba naa ni ẹyin o pada, ẹ yoo si mọ iyatọ laarin olododo ati eniyan buburu, laarin ẹni ti o sin Ọlọrun ati eni ti ko sin In.” Malaki 3:18.ANN 283.5

    Awọn ọta ofin Ọlọrun, lati ori awọn oniwaasu de ọdọ eyi ti o kere julọ laarin wọn, ni oye otitọ ati ojuṣe lọna akọtun. O ti pẹ ju fun wọn lati ri i wipe ọjọ Isinmi ofin kẹrin ni edidi Ọlọrun alaaye. O ti pẹ ju fun wọn lati ri ohun ti ọjọ isinmi eke wọn jẹ nitootọ ati lori ipilẹ oniyanrin ti wọn n kọle le. Wọn ri wipe wọn ti n ba Ọlọrun ja. Awọn ẹlẹko ẹsin ti dari awọn ọkan si iparun nigba ti wọn n sọ wipe wọn n dari wọn si ẹnu ọna Paradise. Ayafi bi o ba di igba ijiyin ikẹyin ni wọn a to mọ bi ojuṣe eniyan nibi iṣẹ mimọ ti tobi to ati bi atubọtan aiṣootọ ti lagbara to. Ni igba ainipẹkun ni a to le mọ bi ọkan kan ṣoṣo ti o sọnu ti loye lori to. Iparun ẹlẹru ni yoo jẹ ti awọn ti Ọlọrun yoo sọ fun wipe: Ẹ kuro lọdọ Mi, ẹyin iranṣẹ buburu. A gbọ ohun Ọlọrun lati ọrun ti o n kede ọjọ ati wakati wiwa Jesu, ti o si n ṣe majẹmu ainipẹkun fun awọn eniyan Rẹ. Bi ìró àrá ti o pariwo julọ, ọrọ Rẹ la aye ja. Israeli Ọlọrun duro, wọn n tẹti silẹ pẹlu oju wọn ti n woke. Ogo Rẹ tan imọlẹ si oju wọn, o n dan bi oju Mose ti ri nigba ti o sọkalẹ ti Sinai wa. Awọn ẹni buburu ko le wo wọn. Nigba ti a kede ibukun si ori awọn ti wọn bu ọla fun Ọlọrun nipa pipa ọjọ Isinmi mọ, a gbọ ariwo nla iṣẹgun.ANN 284.1

    Laipẹ ikuuku dudu kekere kan farahan ni iha ila oorun, ti o to idaji ọwọ eniyan. Ikuuku yii ni o yi Olugbala ka, eyi ti o farahan loke bi eyi ti okunkun yi ka. Awọn eniyan Ọlọrun mọ wipe eyi jẹ ami Ọmọ eniyan. Ni idakẹjẹ ọlọwọ wọn wo bi o ti n sunmọ aye, ti o n mọlẹ si ti ogo rẹ si n pọ si, titi ti o fi di ikuuku awọsanma funfun nla, isalẹ rẹ jẹ ogo bi ina ajonirun, ati loke rẹ oṣumare majẹmu. Jesu n gun ẹsun lọ bi aṣẹgun nla. Nisinsinyii, ki i ṣe “Ọkunrin Onirobinujẹ” lati mu ago kikoro itiju ati iparun, O wa, aṣẹgun ni ọrun ati aye, lati ṣe idajọ alaaye ati oku. “Olododo ati otitọ,” “ninu ododo ni O n ṣe idajọ ti o si n jagun.” “Awọn ẹgbẹ ogun ọrun” (Ifihan 19:11, 14) si tẹle E. Pẹlu orin ọrun, awọn angẹli mimọ, ti wọn pọ ni iye, ti a ko le ka, ba A kọwọ rin. Ofurufu dabi ẹnipe o kun fun awọn ẹni didan—”ẹgbẹẹgbẹrun lọna ẹgbẹẹgbẹrun, ati ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrun.” Ko si kalamu eniyan ti o le ṣe alaye iṣẹlẹ naa ko si oye eniyan ti o le ni oye pipe nipa ogo rẹ. “Ogo Rẹ bo awọn ọrun, ilẹ aye si kun fun iyin Rẹ. Itansan Rẹ si dabi imọlẹ.” Abakuku 3:3, 4. Bi ikuuku alaaye naa ti n sunmọ, gbogbo oju ri Ọmọ Alade iye. Ko si ade ẹgun ti o ba ori mimọ Rẹ jẹ nisinsinyii, sugbọn ade ogo ni o wa ni ori mimọ Rẹ. Irisi Rẹ tan ju itansan oorun ni ọsan gangan lọ. “O si ni orukọ kan ti a kọ si ara aṣọ Rẹ ati si ori itan Rẹ, Ọba awọn ọba, ati Oluwa awọn oluwa.” Ifihan 19:16.ANN 284.2

    “Gbogbo oju di jijoro” niwaju Rẹ, ibẹru ainireti ainipẹkun bọ lu awọn ti wọn kọ aanu Ọlọrun silẹ. “Ọkan yọ, orokun si kọlu ara wọn, . . . oju awọn ti wọn pejọ si ṣokunkun.” Jeremaya 30:6; Nahumu 2:10. Awọn olododo kigbe pẹlu iwariri: “Tani yoo le duro?” Awọn angẹli dakẹ orin, akoko idakẹjẹ ẹlẹru si wa. Nigba naa ni a gbọ ohùn Jesu ti n wipe: “Oore ọfẹ Mi to fun yin.” Oju awọn olododo mọlẹ, ayọ si kun gbogbo ọkan. Awọn angẹli gbe ohun wọn soke, wọn kọ orin si bi wọn ti n sunmọ aye.ANN 284.3

    Ọba awọn ọba sọkalẹ wa ninu ikuuku awọsanma, ti ọwọ ina tí n jo yii ka. Awọn ọrun ṣi bi iwe, ilẹ aye wa riri niwaju Rẹ, gbogbo oke ati erekuṣu ṣi kuro ni ipo wọn. “Ọlọrun wa yoo wa, ki yoo si dakẹ: ina yoo maa jo niwaju Rẹ, ẹfufu lile yoo maa ja yi I kaakiri. Yoo si ke si awọn ọrun lati oke wa, ati si aye, ki O baa le ṣe idajọ awọn eniyan Rẹ.” O. Dafidi 50:3, 4.ANN 284.4

    “Ati awọn ọba aye, ati awọn eniyan nla, ati awọn ọlọrọ, ati awọn olori ogun, ati awọn alagbara, ati gbogbo onde ati gbogbo ominira, fi ara wọn pamọ sinu iho ilẹ ati ninu apata awọn oke; wọn sọ fun oke ati apata, Wo lu wa, ki o si pawa mọ kuro ni oju Ẹni ti O joko lori itẹ, ati kuro lọwọ ibinu Ọdọ Aguntan: nitori ti ọjọ nla ibinu Rẹ de; tani yoo si le duro.” Ifihan 6:15—17.ANN 284.5

    Ifirẹrin ẹlẹya duro. Awọn ete ti n purọ dakẹ jẹẹ. Ikọlura ohun ija ogun, irọkẹkẹ ogun “pẹlu ariwo idarudapọ ati aṣọ ti a yi ninu ẹjẹ” (Aisaya 9:5), duro jẹ. Ko si ohun ti a gbọ mọ ayafi ohun adura ati ariwo ẹkun ati ọfọ. Awọn ti wọn n kẹgan laipẹ yii kigbe wipe: “Ọjọ nla ibinu Rẹ de, tani yoo le duro?” Awọn ẹni buburu gbadura ki a tẹwọnri sinu apata awọn oke dipo ki wọn pade oju Ẹni ti wọn kẹgan ti wọn si kọ silẹ.ANN 284.6

    Wọn mọ ohùn naa, ti o wọ eti awọn oku. Ọpọ igba ni ohùn ẹbẹ jẹjẹ naa n pe wọn wa si ironupiwada. Ọpọ igba ni a gbọ ninu ipẹ ọrẹ, arakunrin, Olurapada. Ko si ohùn ti o le kun fun idalẹbi, ti o wuwo nitori ikilọ ni gbangba, si awọn ti wọn kọ oore ọfẹ Rẹ silẹ bi ohùn naa ti o pẹ ti o ti n bẹbẹ wipe: “Ẹ yipada, ẹ yipada kuro ninu ọna buburu yin, nitori eeṣe ti ẹyin yoo fi ku?” Isikiẹli 33:11. Ah i ba jẹ ohùn ajeji! Jesu sọ wipe: “Emi ti pe, ẹyin si kọ; Mo ti na ọwọ Mi sita, ko si si ẹni ti o ka a si; ṣugbọn ẹyin sọ gbogbo imọran Mi di asan, ẹ ki yoo si tẹti si ibawi Mi.” Owe 1:24, 25. Ohùn naa sọ iranti ji eyi ti wọn ṣe akitiyan lasan lati parẹ—ikilọ ti a gan, ipe ti a kọ, anfani ti a ko kàsí.ANN 285.1

    Awọn kan wa ti wọn fi Kristi ṣẹsin ninu irẹsilẹ Rẹ. Pẹlu agbara ti n muni wariri wọn ranti ọrọ Ẹni ti n jiya, nigba ti olu alufa rọ Ọ, O sọ tọwọtọwọ wipe: “Lẹyin eyi, ẹyin yoo ri Ọmọ eniyan ti O joko ni ọwọ ọtun agbara, ti O n bọ ninu ikuuku awọsanma.” Matiu 26:64. Bayi wọn ri I ninu ogo Rẹ, wọn ko si tii ri I ki o joko ni ọwọ ọtun agbara.ANN 285.2

    Awọn ti wọn fi ṣẹsin nitori ti O pe ara Rẹ ni Ọmọ Ọlọrun ko le sọrọ mọ nisinsinyii. Ọba Hẹrọdu agberaga wa nibẹ, ẹni ti o fi ṣẹfẹ nitori oyè ọba Rẹ ti o si sọ fun awọn ọmọ ogun rẹ ti n ṣẹfẹ lati de ni ade ọba. Awọn eniyan ti wọn fi ọwọ àìlọwọ wọ Ọ ni aṣọ ọgbọ wa nibẹ, awọn ti wọn gbe ade ẹgun wọ ori mimọ Rẹ, ti wọn gbe ọpa aṣẹ le ọwọ Rẹ ti ko si janpata, ti wọn si tẹriba niwaju Rẹ ni ifiniṣẹsin. Awọn ti wọn lu U, ti wọn tutọ si Ọmọ Alalde iye lara wa gbe oju sa kuro ni bi O ti n wo wọn ti wọn si n wa lati sa kuro nibi ogo Rẹ ti n boni mọlẹ. Awọn ti wọn kan iṣo mọ ni ọwọ ati ẹsẹ, jagunjagun ti o fi ọkọ gun Un ni ẹgbẹ, kiyesi awọn ami wọnyi pẹlu ẹru ati ibọkanjẹ.ANN 285.3

    Pẹlu iranti yekeyeke awọn alufa ati alaṣẹ ranti awọn iṣẹlẹ Kalfari. Pẹlu ibẹru wọn ranti bi wọn ti sọ nigba ti wọn n mi ori wọn ni idunnu bi Satani, wipe: “O gba awọn miran la; ko le gba ara Rẹ la. Bi oun ba ni Ọba Isreali, jẹ ki O sọkalẹ wa lati ori agbelebu nisinsinyii, awa yoo si gba A gbọ. O gbẹkẹle Ọlọrun, jẹki O gba A silẹ nisinsinyii, bi yoo ba gba A.” Matiu 27:42, 43.ANN 285.4

    Wọn ranti daradara owe Olugbala nipa awọn oluṣọgba ti wọn kọ lati fun oluwa wọn ni eso ọgba ajara, ti wọn lo awọn iranṣẹ Rẹ nilokulo ti wọn si pa ọmọ rẹ. Wọn ranti pẹlu, ọrọ ti wọn funra wọn sọ: Oluwa ọgba ajara naa “yoo pa awọn ẹni buburu naa run nipakupa.” Ninu ẹṣẹ ati ijiya awọn alaiṣootọ naa, awọn alufa ati alagba ri iṣẹ ati iparun ti o tọ si wọn. Bayi wọn kigbe irora iku. Igbe ti o roke ju, “Kan An mọ agbelebu, kan An mọ agbelebu,” eyi ti o kun awọn popona Jerusalẹmu ni a gbọ ti n wi pẹlu ibẹru ati ainireti wipe “Oun ni Ọmọ Ọlọrun! Oun ni Mesaya tootọ!” Wọn wa ọna lati sa kuro niwaju Ọba awọn ọba. Ninu iho ilẹ ti awọn ohun tí a dá ti faya pẹrẹpẹrẹ, wọn tiraka, lasan lati farapamọ.ANN 285.5

    Ninu igbesi aye awọn ti wọn kọ otitọ silẹ, akoko wa ti ẹri ọkan n ṣiṣẹ, nigba ti wọn ranti igbe aye agabagebe, ti ọkan wọn si jiya nitori abamọ asan. Ṣugbọn kini awọn nnkan wọnyii jasi ni afiwe pẹlu ikaanu ọjọ naa nigbati, “ẹru yoo wa bi isọdahoro,” nigbati “iparun yoo wa bi iji lile”! Owe 1:27. Awọn ti i ba pa Kristi ati awọn eniyan olootọ Rẹ wa ri ogo ti o wa lori wọn. Ni aarin ibẹru wọn, wọn gbọ ohun awọn ẹni mimọ pẹlu orin ayọ ti n wi pe: “Kiyesii, Ọlọrun wa niyii; awa ti duro de E, Oun yoo si gba wa.” Aisaya 25:9.ANN 285.6

    Laarin aye ti n mi titi, kikọ mọnamọna, ati ìró àrá, ohùn Ọmọ Ọlọrun pe awọn ẹni mimọ ti wọn sun jade. O wo iboji awọn olododo, nigba naa ni, O gbe ọwọ Rẹ si ọrun, O kigbe wipe: “Ẹ dide, ẹ dide, ẹyin ti ẹ sun ninu erupẹ, ẹ dide soke!” La gbogbo igun ati ibu aye ja awọn oku yoo gbọ ohun naa, awọn ti wọn gbọ yoo si ye. Gbogbo aye kun fun ọpọ eniyan lati gbogbo orilẹ ede ati ẹya ati ede ati eniyan. Wọn jade wa lati inu ile tubu iku, a si gbe ogo ainipẹkun wọ wọn, wọn kigbe wipe: “Iku oro rẹ da? Isa oku, iṣẹgun rẹ da?” 1 Kọrintin 15:55. Awọn olododo ti wọn wa laaye ati awọn ẹni mimọ ti a ji dide pa ohun wọn pọ ni igbe nla ati idunnu iṣẹgun.ANN 285.7

    Gbogbo wọn jade wa lati inu iboji wọn pẹlu bi wọn ti ga to nigba ti wọn wọ inu iboji. Adamu, ẹni ti o duro laarin awọn ti a ji dide ga o si lọla ni ìrí ati ni giga, diẹ ni Ọmọ Ọlọrun fi ga ju u lọ. O yatọ patapata si awọn eniyan ti wọn wa lẹyin rẹ; ni abala yii kan ṣoṣo a fi ibajẹ nla ti o ba iran yii han. Ṣugbọn gbogbo wọn ni wọn jinde pẹlu awọ tutu ati agbara ayeraye ti ọdọ. Ni ibẹrẹ a da eniyan ni aworan Ọlọrun, ki i ṣe ni iwa nikan bikoṣe ni ìrí ati ìwò oju pẹlu. Ẹṣẹ ba aworan Ọlọrun jẹ, o si fẹrẹ pa a rẹ tan patapata, ṣugbọn Kristi wa lati da aworan Ọlọrun ti a padanu pada. Yoo yi ara kiku wa pada, yoo si ṣe e bi ara ologo Rẹ. Ara kiku ati idibajẹ ti ko ni ẹwa ti ẹṣẹ ti ko abawọn ba nigba kan ri a di pipe, yoo rẹwa, a si wa ni aiku. Gbogbo abawọn ati ibaku ni a fi silẹ ninu iboji. Nigba ti a ba da wọn pada si igi iye ni Edẹni ti wọn ti padanu fun igba pipẹ, awọn ti a ra pada a “dagba soke” (Malaki 4:2) de ìga kikun iran naa ni ogo igba iwaṣẹ. A o mu egun ẹṣẹ ti o kẹyin kuro, awọn olootọ Kristi a si fi ara han ninu “ẹwa Oluwa Ọlọrun wa,” ni iyè, ọkan ati ara wọn a fi aworan Oluwa han ni kikun. Ah! irapada iyanu! ti a ti n sọrọ rẹ fun igba pipẹ, ti a ti n reti rẹ fun igba pipẹ, ti a n ronu le lori pẹlu iwọna giga, ṣugbọn ti a ko ni oye kikun nipa rẹ.ANN 286.1

    A yi awọn olododo ti wọn wa laaye pada “lọgan, ni iṣẹju aaya.” A ṣe wọn logo pẹlu ohùn Ọlọrun; bayii a sọ wọn di aiku ati pẹlu awọn ẹni mimọ ti a ji dide, a gba wọn soke lati lọ pade Oluwa ninu afẹfẹ. Awọn angẹli “ko awọn ayanfẹ Rẹ jọ pọ lati origun mẹrẹẹrin afẹfẹ lati iha ọrun kan si ekeji.” Awọn angẹli mimọ gbe awọn ọmọ wẹwẹ lọ si apa iya wọn. Awọn ọrẹ ti iku ti pin niya fun igba pipẹ wa papọ, ti wọn ko si le pinya mọ, pẹlu orin ayọ wọn jijọ goke lọ si Ilu nla Ọlọrun.ANN 286.2

    Iyẹ wa ni ẹgbẹ mejeeji kẹkẹ ikuuku naa, labẹ rẹ si ni awọn kẹkẹ alaaye wa; bi ọkọ naa ti n lọ soke, awọn kẹkẹ naa n kigbe, “Mimọ, mimọ, mimọ, Oluwa Ọlọrun Alagbara.” Awọn ti a rapada si n kigbe, “Halleluya!” bi ọkọ naa ti n lọ si ọna Jerusalẹmu Tuntun.ANN 286.3

    Ki wọn to wọ Ilu nla Ọlọrun, Olugbala fun awọn atẹle Rẹ ni ohun iranti iṣẹgun, O si fun wọn ni ohun idanimọ bi ọba. Awọn ẹgbẹ ti n dan naa tò ni igun mẹrin ọgbọọgba yi Ọba wọn ka, Ẹni ti O ga soke ju awọn ẹni mimọ ati awọn angẹli lọ, Ẹni ti oju Rẹ n tan si wọn pẹlu ifẹ. Gbogbo ẹgbẹ ogun awọn ti a rapada ti a ko le ka tẹju mọ Ọ, gbogbo oju n wo ogo Ẹni ti a “ba irisi Rẹ jẹ ju ti ẹnikẹni lọ, ati iduro Rẹ ju ti ọmọ eniyan lọ.” Pẹlu ọwọ ọtun ara Rẹ, Jesu gbe ade ogo de ori gbogbo awọn aṣẹgun. Olukuluku ni o ni ade ti o ni “orukọ tuntun” rẹ (Ifihan 2:17), ati ọrọ ti a kọ si, “Mimọ si Oluwa.” A fun gbogbo wọn ni imọ ọpẹ aṣẹgun ati harpu ti n dan. Nigba naa, bi awọn adari angẹli ti tẹ ohun kan, gbogbo ọwọ lu harpu wọn pẹlu ọgbọn, ti o mu orin kikun, aladun wa. Idunnu ti a ko le fi ẹnu sọ kun gbogbo ọkan, olukuluku si gbe ohùn soke ni imoore pẹlu iyin: “Si Ẹni naa ti O fẹ wa, ti O fọ wa mọ kuro ninu ẹṣẹ wa pẹlu ẹjẹ ara Rẹ, ti O sọ wa di ọba ati alufa si Ọlọrun ati Baba Rẹ; ti Rẹ ni ogo ati agbara ijọba lae ati laelae.” Ifihan 1:5, 6.ANN 286.4

    Ilu Mimọ naa wa niwaju awọn ti a ra pada. Jesu ṣi ilẹkun nla pearli naa gbagada, ti awọn orilẹ ede ti wọn pa otitọ mọ si wọle. Nibẹ wọn ri paradise Ọlọrun, ile Adamu ni igba ti o wa ni ailẹṣẹ. Nigba naa ni ohùn naa, ti o dun ju orinkorin ti o tii wọ inu eti eniyan lọ wipe: “Ijakadi yin pari.” “Ẹ wa, ẹyin alabukun Baba Mi, ẹ jogun ijọba ti a ti pese silẹ fun yin lati ipilẹsẹ aye wa.”ANN 286.5

    Adura Olugbala fun awọn ọmọ ẹyin Rẹ wa wa si imuṣẹ: “Emi fẹ ki awọn pẹlu ti Iwọ ti fi fun Mi o wa pẹlu Mi nibi ti Emi gbe wa.” “Ni ailẹgan niwaju ogo Rẹ pẹlu ayọ nla” (Juda 24), Kristi fi awọn ti O fi ẹjẹ Rẹ ra han Baba, O wipe: “Emi niyii ati awọn ọmọ ti Iwọ ti fi fun Mi.” “Awọn ti Iwọ fi fun Mi, Emi pa wọn mọ.” Ah! iyanu ifẹ irapada! idunnu wakati naa nigba ti Baba ayeraye wo awọn ti a rapada, ti yoo ri aworan Rẹ, a ti le ibajẹ ẹṣẹ kuro, a si mu idiwọ kuro, ti iran eniyan si wa ni ibamu pẹlu Ọlọrun lẹẹkan si.ANN 286.6

    Pẹlu ifẹ ti a ko le fi ẹnu sọ, Jesu ki awọn olootọ wa sinu ayọ Oluwa wọn. Ayọ Olugbala wa ninu riri ọkan ti a gbala nipa ijiya ati irẹsilẹ Rẹ ni ijọba ogo. Awọn ti a rapada yoo jẹ alabapin ninu ayọ Rẹ, bi wọn ti n wo awọn ti a jere si ọdọ Kristi nipasẹ adura wọn, iṣẹ wọn, ati ifi-ara-ẹni-rubọ ifẹ wọn laarin awọn alabukun fun. Bi wọn ti to yi itẹ funfun nla naa ka, idunnu ti a ko le royin kun inu ọkan wọn, nigba ti wọn ri awọn ti a jere fun Kristi, ti wọn si ri ti awọn wọnyi jere awọn miran, ati awọn wọnyi awọn miran, ti gbogbo wọn wa ni ibi isinmi, nibẹ lati fi ade wọn lelẹ ni ẹsẹ Kristi ki wọn si yin In titi aye ainipẹkun.ANN 287.1

    Bi a ti n gba awọn ti a rapada wọle sinu Ilu Ọlọrun, ariwo ayọ ijọsin gba afẹfẹ kan. Awọn Adamu mejeeji fẹ pade. Ọmọ Ọlọrun duro O si na ọwọ Rẹ sita lati gba baba iran wa—ẹda ti O da, ti o ṣẹ si Ẹlẹda rẹ, ti Olugbala si gba ami ikanmọ-agbelebu si ara nitori ẹṣẹ rẹ. Bi Adamu ti ri ami iṣo, ko ṣubu si aya Oluwa rẹ, ṣugbọn ni irẹsilẹ o wolẹ si ẹsẹ Rẹ, o ke wipe: “Ọdọ Aguntan naa ti a pa ni o yẹ!” Pẹlu iṣe jẹjẹ, Olugbala gbe e dide O ni ki o wo Edẹni lẹẹkan si, ile nibi ti a ti le e jade fun ọjọ pipẹ.ANN 287.2

    Lẹyin igba ti a le kuro ni Edẹni, igbesi aye Adamu ninu aye kun fun ibanujẹ. Gbogbo ewe ti n ku, gbogbo ohun irubọ, gbogbo ibajẹ loju ẹda ti o rẹwa, gbogbo abawọn lori iwa mimọ eniyan, jẹ ohun ti n ran leti nipa ẹṣẹ ni akọtun. Irora ibanujẹ rẹ pọ jọjọ bi o ti n wo o ti ẹṣẹ n pọ si, ti a si kẹgan rẹ gẹgẹ bi okunfa ẹṣẹ ni idahun si awọn ikilọ rẹ. Pẹlu suuru onirẹlẹ, o fi ara da ijiya ẹṣẹ fun bi ẹgbẹrun ọdun kan. O yipada kuro ninu ẹṣẹ rẹ tọkantọkan o gbẹkẹle oore ọfẹ Olugbala, o si ku ninu ireti ajinde. Ọmọ Ọlọrun ra ibaku ati iṣubu eniyan pada, bayii, nipasẹ iṣẹ iwẹnumọ ẹṣẹ, a da Adamu pada sinu iṣakoso rẹ akọkọ.ANN 287.3

    Ayọ kun inu rẹ, bi o ti n wo awọn igi ti wọn jẹ idunnu rẹ nigba kan ri—awọn igi ti oun funra rẹ ko eso wọn jọ ni igba ailẹṣẹ ati ayọ rẹ. O ri awọn ẹka ti ọwọ ara rẹ tun ṣe, awọn ododo ti oun fi igba kan fẹran lati boju to. Iye rẹ mọ wipe otitọ ni iṣẹlẹ naa; o mọ wipe Edẹni ni a mu bọ sipo nitootọ, ṣugbọn ti o dara ju igba ti a le kuro ninu rẹ lọ. Olugbala mu lọ si ibi igi iye, O si ja eso ologo rẹ, O ni ki o jẹ ẹ. O wo ayika rẹ, o ri ọgọọrọ awọn idile rẹ ti a ra pada, ti wọn duro ni Paradise Ọlọrun. Nigba naa, o fi ade didan rẹ lelẹ lẹsẹ Jesu, o ṣubu si aya Rẹ, o dimọ Olurapada. O lu harpu wura rẹ, awọn orule ọrun si ho pẹlu orin iṣẹgun: “Ọdọ Aguntan naa yẹ, O yẹ, ti a pa ti O tun wa laaye lẹẹkan si.” Awọn idile Adamu gbe orin naa wọn si fi ade wọn lelẹ lẹsẹ Kristi bi wọn ti tẹriba niwaju Rẹ ni ijọsin.ANN 287.4

    Awọn angẹli ti wọn sọkun nigba ti Adamu ṣubu, ti wọn yọ nigba ti Jesu goke re ọrun lẹyin ajinde Rẹ, ti wọn ṣi iboji silẹ fun awọn ti yoo gbagbọ ninu orukọ Rẹ, ri ipade lẹẹkansi naa. Bayii wọn ri wipe iṣẹ irapada ti pari, wọn pa ohun wọn pọ ninu orin iyin.ANN 287.5

    Lori okun mimọ gaara niwaju itẹ naa, okun digi naa à fi bi eyi ti o dapọ mọ ina,—o n dan jọjọ fun ogo Ọlọrun,—ni awọn ẹgbẹ ti wọn ti “ni iṣẹgun lori ẹranko naa, ati lori aworan rẹ, ati lori ami rẹ, ati lori iye orukọ rẹ” duro si. Pẹlu Ọdọ Aguntan naa lori Oke Sioni,” ti Oun ti duru Ọlọrun,” awọn 144,000 ti a ra pada laarin awọn eniyan duro, a si gbọ bi iro ohun ọpọ omi, ati bi iro àrá nla, “ohùn duru awọn aluduru pẹlu duru wọn.” Wọn si kọ “orin tuntun” niwaju itẹ naa, orin ti ẹnikẹni ko le mọ ayafi awọn 144,000 ni wọn le kọ orin naa nitori orin iriri wọn ni—iriri ti ẹgbẹ kankan ko ni ri. “Awọn wọnyi ni wọn n tẹle Ọdọ Aguntan naa nibikibi ti O n lọ.” Awọn wọnyi ni a ra pada lati inu aye wa, lati aarin awọn alaaye, a ri wọn gẹgẹ bi “akọso eso si Ọlọrun ati si Ọdọ Aguntan.” Ifihan 15:2, 3;14:1—5. “Awọn wọnyi ni wọn jade lati inu idanwo nla wa;” wọn la akoko idamu, ti iru rẹ koi tii si ri lati igba ti awọn orilẹ ede ti wa kọja, wọn fi orí ti iporuuru akoko idamu Jakọbu, wọn ti duro laisi olubalaja titi ti Ọlọrun fi tu idajọ ikẹyin sita. Ṣugbọn a ti da wọn nide, nitori wọn ti “fọ aṣọ wọn, wọn ti sọ ọ di funfun ninu ẹjẹ Ọdọ Aguntan.” “Ko si eke ni ẹnu wọn: nitori ti wọn wa ni ailabuku” niwaju Ọlọrun. “Nitori naa wọn wa niwaju itẹ Ọlọrun, wọn si n sin In ni ọsan ni oru ninu tẹmpili Rẹ: Ẹni ti O joko lori itẹ naa yoo si maa gbe ni aarin wọn.” Wọn ti ri i ti iyan ati ajakalẹ arun pa aye run, ti oorun ni agbara lati jo awọn eniyan pẹlu ooru nla, ti awọn pẹlu fi ara da ijiya ebi ati oungbẹ. Ṣugbọn “ebi ki yoo pa wọn mọ bẹẹ ni ongbẹ ki yoo gbẹ wọn mọ, bẹẹ ni oorun ki yoo tan sori wọn, tabi ooru kankan. Nitori Ọdọ Aguntan naa ti O wa laarin itẹ naa yoo bọ wọn, yoo si mu wọn lọ si orisun omi iye: Ọlọrun yoo si nu omije gbogbo nu kuro ni oju wọn.” Ifihan 7:14—17.ANN 287.6

    Ni igba gbogbo a maa n kọ awọn ayanfẹ Olugbala lẹkọ, ti wọn si n gba ilana ati ẹkọ ni ile ẹkọ idanwo. Wọn rin ni ọna tooro lori ilẹ aye, a fọ wọn mọ ninu ina ipọnju. Nitori Jesu wọn fi ara da atako, ikorira, ibalorukọjẹ. Wọn tẹle E gba wahala gbigbona kọja, won fi ara da isẹra-ẹni, wọn si ni iriri ijakulẹ kikoro. Nipa iriri kikoro ara wọn, wọn mọ bi ẹṣẹ ti buru to, agbara rẹ, ẹbi rẹ, ati iparun rẹ, wọn si n fi ikorira wo o. Oye ẹbọ ayeraye ti a ṣe lati wo o san rẹ wọn silẹ ni oju ara wọn, o si fi ọpẹ ati iyin kun inu wọn eyi ti awọn ti ko ṣubu ri ko le mọ riri rẹ. Wọn fẹran pupọ nitori ti a ti dari ohun ti o pọ ji wọn. Nigba ti wọn ti jẹ alabapin ninu ijiya Kristi, a mu wọn peye lati jẹ alabapin pẹlu Rẹ ninu ogo Rẹ.ANN 288.1

    Awọn ajogun Ọlọrun wa lati inu yàrá ti ko funni ni irọrun, ile talaka, lati inu tubu, lati inu aṣalẹ, lati inu iho inu ilẹ, lati inu iho ilẹ nla lẹgbẹ okun. Lori ilẹ aye wọn jẹ “alaini, ẹni ti a n pọn loju, ẹni ti a n jẹ niya.” Ọpọlọpọ ni wọn lọ sinu iboji pẹlu ẹgan nitori ti wọn fi iduro ṣinṣin kọ lati gba itanjẹ Satani. Ile idajọ eniyan pe wọn ni ọdaran to buru julọ. Ṣugbọn nisinsinyii, “Ọlọrun funra Rẹ ni adajọ.” O. Dafidi 50:6. Bayii a yi ipinu aye pada. “O ko ibawi awọn eniyan Rẹ lọ.” Aisaya 25:8. “A yoo pe wọn ni Eniyan mimọ, Ẹni irapada Oluwa.” O ti pese “lati fun wọn ni ẹwa dipo eeru, ororo ayọ dipo ọfọ, aṣọ iyin dipo ẹmi ibanujẹ.” Aisaya 62:12; 61:3. Wọn ki i ṣe alaarẹ, ti a n pọn loju, ti a fọn kaakiri, ti a si n fiya jẹ mọ. Wọn yoo wa pẹlu Oluwa titi lae. Wọn duro niwaju itẹ naa, wọn wọ aṣọ ti o loye lori ju eyi ti ẹnikẹni ti a bu ọla fun julọ ninu aye wọ ri. Wọn de ade ti o logo ju eyi ti ọba aye kankan de ri lọ. Ọjọ irora ati ẹkun dopin titi lae. Ọba ogo ti nu omije nu kuro ninu oju gbogbo, gbogbo okunfa fun ibanujẹ ni a mu kuro. Bi wọn ti n mi imọ ọpe wọn, wọn kọ orin iyin, ti o dun ketekete ti o dun ti o si wa niṣọkan; gbogbo ohun gbe orin naa titi ti orin naa fi n ró ni gbogbo orule ọrun: “Ti Ọlọrun wa ti O joko lori itẹ ati ti Ọdọ Aguntan ni igbala.” Gbogbo awọn olugbe ọrun si dahun si iyin naa: “Amin: Ibukun, ati ogo ati ọgbọn, ati ọpẹ, ati iyin, ati agbara, ati ipa ni fun Ọlọrun wa titi lae lae.” Ifihan 7:10, 12.ANN 288.2

    A tilẹ le bẹrẹ sii ni oye koko ọrọ iyanu irapada ninu aye yii ni. Pẹlu oye kekere wa a le fi tọkantọkan ronu lori itiju ati ogo, iye ati iku, idajọ ati aanu, ti wọn pade lori agbelebu, sibẹ pẹlu ironu wa ti o ga julọ, a ko le ni oye kikun nipa itumọ rẹ. Oye wa nipa iwọn ati ibu, jinjin ati giga, ifẹ irapada ko le mọlẹ to. A ko le ni oye eto irapada tan patapata, ani nigbati awọn ti a ti rapada ba ri bi a ti ri wọn, ti wọn si mọ bi a ti mọ wọn; ṣugbọn titi ayeraye otitọ tuntun yoo maa fi ara han si oye ti o kun fun aanu, ti o si n yọ. Bi o tilẹ jẹ wipe ibanujẹ ati irora ati idanwo inu aye ti pari ti a si ti mu ohun ti n ṣe okunfa wọn kuro, awọn eniyan Ọlọrun, titi lae, yoo ni imọ ati oye ohun ti igbala wọn ná ni.ANN 288.3

    Agbelebu Kristi yoo jẹ imọ ati orin awọn ti a rapada titi aye ainipẹkun. Ninu Kristi ti a ṣe logo, wọn a ri Kristi ti a kan mọ agbelebu. Wọn ko ni gbagbe lae, wipe Ẹni ti agbara Rẹ da, ti O si n ṣe itọju awọn aye ti a ko le ka ninu oju ọrun ti o lọ ṣasu, Ayanfẹ Ọlọrun, Ọlanla ọrun, Ẹni ti awọn kerubu ati serafu didan ni inu didun si lati jọsin fun—rẹ ara Rẹ silẹ lati gbe eniyan ti o ṣubu soke; wipe O gbe ẹbi ati itiju ẹṣẹ, ati ifipamọ oju Baba Rẹ, titi ti iparun aye ti o sọnu fi ba A lọkan jẹ ti o si gba ẹmi Rẹ lori agbelebu Kalfari. Ẹlẹda gbogbo awọn aye, Ẹni ti n dari gbogbo atubọtan, le fi ogo Rẹ silẹ ki O si rẹ ara Rẹ silẹ nitori ifẹ fun eniyan yoo maa ru iyanu ati ijọsin gbogbo agbaala aye soke titi lae. Bi awọn orilẹ ede ti a gbala ba ṣe n wo Olurapada wọn, ti wọn si n ri ogo ainipẹkun Baba ti n tan lara Rẹ, bi wọn ti n wo itẹ naa, eyi ti o wa lati irandiran, ti wọn si mọ wipe ijọba Rẹ ki yoo lopin, wọn bu jade ninu orin ayọ: “Ọdọ Aguntan naa ti a pa yẹ, O yẹ! ti O fi ẹjẹ ara Rẹ ra wa pada si Ọlọrun.”ANN 288.4

    Ijinlẹ agbelebu ṣe alaye gbogbo ohun ijinlẹ miran. Ninu imọlẹ ti n tan lati Kalfari awọn iwa Ọlọrun ti wọn n fi ipaya ati ibẹru kun inu wa a wa rẹwa si a si wuni. Aanu, iṣe jẹjẹ, ifẹ obi ni a ri ti o dapọ mọ iwa mimọ, iṣotitọ ati agbara. Nigba ti a ba ri ọlanla itẹ Rẹ, ti o ga, ti a gbe soke, ti a ri iwa Rẹ ni ifarahan pẹlu oore ọfẹ, a yoo ni oye ju bi a ti ni tẹlẹ ri lọ, nipa itumọ oyè ọwọn ni, “Baba wa.”ANN 288.5

    A o ri wipe Ẹni ti ọgbọn Rẹ ko lopin ko le wa ọna miran fun igbala ju ki O fi Ọmọ Rẹ rubọ. Èrè ti O ri fun irubọ yii ni ayọ wipe aye kun fun awọn eniyan ti a rapada, ti wọn jẹ mimọ, alayọ ti wọn ko si le kú. Abayọri ijakadi Olugbala pẹlu agbara okunkun jẹ ayọ fun awọn ti a ra pada ti o n ró pada si ogo Ọlọrun titi aye ainipẹkum. Bẹẹ gẹgẹ ni ọkan niye lori to ti oye ti a san tẹ Baba lọrun; ti Kristi funra Rẹ, ni itẹlọrun nigba ti O ri eso irubọ nla Rẹ.ANN 289.1

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents