Loading...
Larger font
Smaller font
Copy
Print
Contents
ÀRÍYÀNJÍNYÀN ŃLÁ NAA - Contents
  • Results
  • Related
  • Featured
No results found for: "".
  • Weighted Relevancy
  • Content Sequence
  • Relevancy
  • Earliest First
  • Latest First
    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents

    ORI KẸTALA—NETHERLANDS ATI SCANDINAVIA

    Iwa onroro popu tete mu ifẹhonu ti o nipon wa ni Netherlands. Ni ọdẹgbẹrin (700) ọdun ṣaaju akoko Luther, awọn biṣọbu meji ti a ran gẹgẹ bi aṣoju ọba lọ si Romu yọ popu loye laibẹru nigba ti wọn mọ iru iwa ti wọn n wu ni “agbegbe mimọ” naa: Ọlọrun “ti pese fun ijọ, ayaba ati iyawo Rẹ, ipese ainipẹkun ti o ṣe pataki fun idile rẹ, pẹlu owo ori ti ko le ṣa tabi dibajẹ, O ti fun ni ade ati ọpa aṣẹ ainipẹkun; . . . ohun gbogbo ti o n ṣeni loore ni o gba gẹgẹ bi olè. O gbe ara rẹ kalẹ ninu tẹmpili Ọlọrun; dipo gẹgẹ bi oluṣọ aguntan, o di kọlọkọlọ fun agbo aguntan; . . . wa a fẹ ki a gbagbọ wipe iwọ ni biṣọbu ti o ga julọ, ṣugbọn o n wuwa gẹgẹ bi onroro. . . . Bi o tilẹ jẹ wipe o yẹ ki o wuwa bi iranṣẹ awọn iranṣẹ, bi o ti n pe ara rẹ, o n ṣe akitiyan lati jẹ oluwa awọn oluwa. . . . O sọ ofin Ọlọrun di asan. . . . Ẹmi Mimọ ni O n kọ ijọ ni gbogbo aye. . . . Ilu Ọlọrun wa, ọmọ ibi ti awa n ṣe, de gbogbo ọrun; o si tobi ju ilu ti awọn woli mimọ pe ni Babiloni, ti o n fi ara rẹ han bi ẹni mimọ, ti o fẹ ki ọrun o tẹwọ gba oun, ti o si n fọnnu wipe oun ni ọgbọn ayeraye; nikẹyin, laisi idi kankan fun, ti o n sọ wipe, ohun ko baku ri, bẹẹ ni ko le baku.”ANN 105.1

    Awọn miran dide lati ọdun de ọdun lati ṣe iru atako yii. Awọn olukọ akoko wọnyẹn, ti wọn la oriṣiriṣi ilẹ kọja, ti wọn n jẹ oriṣiriṣi orukọ, fi ara jọ awọn ajere ọkan ti Vadois, ti wọn tan imọ iyinrere ka ibi gbogbo, wọn de Netherlands. Awọn ikọni wọn yara tan kalẹ kankan. Wọn tumọ Bibeli awọn Waldens lẹsẹẹsẹ si ede Dutch. Wọn sọ wipe “anfani ti o pọ wa ninu rẹ; ko si ẹfẹ, itan arosọ, ọrọ asan, bikoṣe awọn ọrọ otitọ; lootọ a le tete ri awọn ohun ti wọn ni itumọ nihin lọhun, ṣugbọn eyi ti o ṣe pataki, ti o si dun julọ ninu awọn ohun ti o dara ti wọn si jẹ mimọ ni a le ri ninu rẹ.” Ohun ti awọn ọrẹ igbagbọ atijọ kọ silẹ niyi ni ọrundun kejila.ANN 105.2

    Awọn inunibini Romu wa bẹrẹ; ṣugbọn laarin ina ati ijiya awọn onigbagbọ tubọ n pọ si, wọn n fi iduroṣinṣin kede wipe Bibeli ni aṣẹ ti ko le baku ninu ẹsin, ati wipe “a ko gbọdọ fi ipa mu ẹnikẹni lati gbagbọ, ayafi nipa wiwaasu.”ANN 105.3

    Awọn ikọni Luther ri ilẹ ti o dara ni Netherlands, awọn eniyan olootọ ati olufọkansin si dide lati waasu iyinrere. Ọkan lara awọn agbegbe Holland ni Menno Simons ti jade wa. A kọ ni ilana Roman Katoliki, a si gbe ọwọ le lori gẹgẹ bi alufa, o jẹ alaimọkan patapata nipa Bibeli, ko si ni ka a nitori ki a ma baa tan an jẹ sinu ẹkọ odi. Nigba ti o ṣe iyemeji nipa ikọni wipe akara ati waini ounjẹ alẹ Oluwa jẹ ara ati ẹjẹ Oluwa gan an, o ri i gẹgẹ bi idanwo lati ọdọ Satani, o si wa ọna lati yọ ara rẹ kuro ninu rẹ pẹlu adura ati ijẹwọ ẹṣẹ, ṣugbọn lasan ni. O ro lati pa ẹri ọkan rẹ ti n da lẹbi lẹnu mọ nipa lilọ si ibi itẹ ifẹkufẹ ara ẹni lọrun lainiwọntuwọnsi, ṣugbọn eyi ko ṣiṣẹ. Lẹyin igba diẹ, a dari rẹ lati kọ Majẹmu Tuntun, eyi, pẹlu awọn iwe Luther mu ki o gba igbagbọ ti a fọ mọ. Laipẹ, o ri ti a bẹ ọkunrin kan lori ni ileto kan ti o wa lẹgbẹ rẹ nitori pe o tun itẹbọmi ṣe. Eyi mu ki o kọ ẹkọ Bibeli nipa ṣiṣe itẹbọmi fun ọmọ jojolo. Ko le ri ẹri kankan fun ninu Iwe Mimọ, ṣugbọn o ri wipe ironupiwada ati igbagbọ ni awọn ohun ti a nilo lati le ṣe itẹbọmi.ANN 105.4

    Menno kuro ninu ijọ Romu, o si fi ẹmi rẹ jin fun kikọni ni awọn otitọ ti o gba. Awọn ẹgbẹ onirokuro nipa ẹsin kan dide ni Germany ati Netherlands ti wọn kọ awọn ikọni kan ti ko bojumu ti wọn si le fa iṣọtẹ, wọn n fa idarudapọ ati ailétò, wọn si n da ija ati iṣọtẹ silẹ. Menno ri ohun ti awọn ẹgbẹ wọnyi yoo yọri si, o si ṣiṣẹ takuntakun lati tako awọn ẹkọ eke ati ète buburu awọn elerokero ẹsin wọnyi. Ọpọlọpọ awọn eniyan ni awọn elerokero yii ti ṣi lọna, ṣugbọn ti wọn kọ awọn ikọni buburu wọn silẹ; awọn ọmọọmọ awọn Kristẹni igba atijọ si wa nibẹ pẹlu, awọn eso ikọni awọn Waldens. Menno ṣiṣẹ laarin awọn wọnyi pẹlu itara nla o si ṣe aṣeyọri nla.ANN 105.5

    Fun ọdun marundinlogun, o rinrin ajo, pẹlu iyawo ati awọn ọmọ rẹ, o n fi ara da inira ati ijiya, o n wa ninu ewu ni ọpọ igba. O lọ si Netherlands ati iha ariwa Germany, o n ṣiṣẹ ni pataki julọ laarin awọn alaini, ṣugbọn ipa rẹ n pọ si. O ni ẹbun ọrọ sisọ, bi o tilẹ jẹ wipe ko kawe pupọ, o jẹ ẹni ti ko le yẹsẹ kuro ninu ohun ti o gbagbọ, o ni ẹmi irẹlẹ ati iwa apẹlẹ, o jẹ olootọ ati olufọkansin, o n fi awọn ohun ti o kọni han ninu igbesi aye rẹ, awọn eniyan si ni igbẹkẹle ninu rẹ. A fọn awọn atẹle rẹ kaakiri, a si fiya jẹ wọn. Wọn jiya pupọpupọ nitori ti a ko wọn pọ mọ awọn elerokero ẹsin ti Munsterites. Sibẹ ọpọ awọn eniyan ni wọn yipada nitori iṣẹ rẹ.ANN 105.6

    Ko si ibi ti a ti gba ikọni ti a tunṣe yii bii ni Netherlands. Orilẹ ede perete si ni awọn atẹle rẹ ti jiya inunibini bi i ti ibẹ. Charles V fi ofin de iṣẹ Atunṣe ni Germany, i ba si fi tayọtayọ dana sun gbogbo awọn atẹle rẹ bi ki i ba i ṣe awọn ijoye ti wọn duro gẹgẹ bi idiwọ fun iwa onroro rẹ. Agbara rẹ po gan ni Netherlands, aṣẹ inunibini si n tẹle ara wọn ni sisẹ n tẹle. Lati ka Bibeli, lati gbọ tabi lati waasu rẹ, tabi lati sọrọ nipa rẹ mu ijiya iku nipa idanasunni wa. Lati gba adura si Ọlọrun ni ikọọkọ, lati kọ lati tẹriba fun ere, tabi lati kọ O. Dafidi, tun fa ijiya iku. Ani a tun da awọn ti wọn ba kọ aṣiṣe wọn silẹ lẹbi, bi o ba jẹ ọkunrin, yoo ku nipa ida; bi o ba jẹ obinrin, a yoo sin in laaye. Ọpọ ni wọn ṣegbe labẹ ijọba Charles ati Philip II.ANN 106.1

    Ni akoko kan, a ko gbogbo idile kan wa siwaju igbimọ ti n ṣe igbẹjọ nipa ohun ti eniyan gbagbọ, a fi ẹsun kan wọn wipe wọn ko wa si mass mọ, wọn si n jọsin ninu ile. Nigba ti a beere lọwọ wọn nipa ohun ti wọn maa n ṣe ni ikọọkọ, ọmọkunrin wọn ti o kere julọ dahun wipe: “A maa n wolẹ, a si n gbadura ki Ọlọrun o lawa loye, ki O si dari ẹṣẹ wa jiwa; a maa n gbadura fun ọba wa, ki iṣakoso rẹ le ni alaafia ki aye rẹ si layo; a maa n gbadura fun awọn alaṣẹ wa ki Ọlọrun o pa wọn mọ.” Eyi fi ọwọ ba awọn adajọ diẹ lọkan, sibẹ wọn da baba ati ọkan ninu awọn ọmọ rẹ ni ẹjọ iku ina.ANN 106.2

    Ibinu awọn oninunibini ba igbagbọ awọn ajẹriku dọgba. Ki i ṣe awọn ọkunrin nikan bikoṣe ati awọn obinrin ẹlẹgẹ ati awọn ọdọmọbinrin pẹlu ni wọn fi igboya ti ko lẹgbẹ han. “Awọn iyawo a duro si ẹgbẹ igi ti a de ọkọ wọn mọ, nigba ti wọn ba n jẹ irora ina, wọn a sọ ọrọ itunu fun wọn, tabi ki wọn kọ O. Dafidi lati mu inu wọn dun.” “Awọn ọdọmọbinrin yoo dubulẹ sinu saare wọn laaye bi ẹni ti n wọ inu yara lati sun orun alẹ; tabi ki wọn lọ si ibi ibẹnilori ati inu ina, wọn a wọ aṣọ wọn ti o dara julọ, bi awọn ti n lọ si ibi igbeyawo wọn.”ANN 106.3

    Bii ti akoko ti ẹsin ibọriṣa fẹ pa iyinrere run, ẹjẹ awọn Kristẹni jẹ irugbin. Inunibini ṣiṣẹ lati jẹ ki iye awọn ajẹri fun otitọ o pọ si ni. Awọn ọba ti o dùn wọ inu eegun nitori ipinu awọn eniyan ti ko ṣe e bori jẹ ki iṣẹ buburu yii o tẹsiwaju lati ọdun de ọdun; ṣugbọn lasan ni. Labẹ William ti Orange, ẹni rere, idoju ijọba bolẹ fun Holland ni ominira lati jọsin Ọlọrun nikẹyin.ANN 106.4

    Ẹjẹ awọn ọmọ ẹyin ni o ṣe afihan itẹsiwaju iyinrere ni awọn oke Piedmont, ni pẹtẹlẹ France, ati ni eti bebe Holland. Ṣugbọn ni awọn orilẹ ede ti iha ariwa, o wọle pẹlu alaafia. Awọn ọmọ ile ẹkọ lati Wittenberg ti wọn n pada si ile wọn mu igbagbọ ti a tunṣe wa si Scandinavia. Awọn iwe Luther tun tan imọlẹ naa ka. Awọn eniyan lasan, alagidi ti iha ariwa yipada kuro ninu iwa ibajẹ, igberaga, ati igbagbọ asan Romu wọn si tẹwọ gba iwa mimọ, ainiwahala ati otitọ ti n funni ni iye ti Bibeli.ANN 106.5

    Tausen “Alatunse ti Denmark” jẹ ọmọ agbẹ. Ọdọmọkunrin naa tètè fi òye ti o ja fafa han; o poungbẹ fun ẹkọ; ṣugbọn ipo ti awọn obi rẹ wa ko jẹ ki o ṣe e ṣe fun lati ri eyi, nitori naa, o wọ ile awọn ajẹjẹ ẹsin lọ. Nibi, iwa mimọ igbesi aye rẹ, pẹlu imurasiṣe ati iṣotitọ rẹ mu ki awọn ọga rẹ o fẹran rẹ. Ayẹwo fihan wipe o ni ẹbun ti yoo jẹ ki o wulo fun ijọ ni ọjọ iwaju. A wa pinu lati ran an lọ kọ ẹkọ ni ọkan ninu awọn ile ẹkọ giga ti o wa ni Germany tabi Netherlands. A fun ọdọmọde akẹkọ yii ni anfani lati yan ile ẹkọ funra rẹ, ṣugbọn lori idi kan wipe ko gbọdọ lọ si Wittenberg. A ko gbọdọ jẹ ki majele ẹkọ odi o wu ọmọwe ijọ lewu. Bẹẹ ni awọn ajẹjẹ ẹsin wi.ANN 106.6

    Tausen lọ si Cologne, eyi ti o jẹ ọkan lara awọn ile iṣọ agbara ẹsin Romu nigba naa gẹgẹ bi o ti wa loni. Laipẹ, iṣọwọmọ Ọlọrun nipasẹ adura ati iṣaṣaro awọn olukọ nibi su. Laarin akoko kan naa ni o ri awọn iwe Luther. O ka wọn pẹlu iyalẹnu ati idunnu, o si fẹ lati jẹgbadun idanilẹkọ lọdọ Alatunṣe naa. Ṣugbọn lati ṣe eyi tumọ si wipe yoo ṣẹ ọga rẹ ni ile ajẹjẹ ẹsin, yoo si padanu iranlọwọ rẹ. O ṣe ipinu rẹ laipẹ, ki o to pẹ ju, o ti fi orukọ silẹ gẹgẹ bi akẹkọ ni Wittenberg.ANN 107.1

    Nigba ti o pada si Denmark, o lọ si yara ajẹjẹ ẹsin rẹ. Ko si ẹni ti o funra si wipe o ti gba ẹkọ Luther; ko fi aṣiri rẹ han, ṣugbọn o ṣa ipa, lairu ibẹru awọn akẹgbẹ rẹ soke, lati dari wọn si igbagbọ ati igbesi aye ti o mọ si. O ṣi Bibeli, o si ṣe alaye awọn itumọ rẹ ni tootọ, nikẹyin, o waasu Kristi si wọn gẹgẹ bi ododo ẹlẹṣẹ ati ireti kan ṣoṣo ti o ni fun igbala. Ibinu ọga rẹ, ẹni ti o ti ni ireti giga ninu rẹ gẹgẹ bi akikanju olugbeja Romu, pọ jọjọ. Loju ẹsẹ, a mu kuro ninu ile ẹsin rẹ lọ si ibomiran, a si ti i mọ yara rẹ pẹlu iṣọ ti o nipọn.ANN 107.2

    Si ibẹru awọn ẹlẹṣọ rẹ tuntun diẹ lara awọn ajẹjẹ ẹsin sọ wipe awọn ti yipada di ẹlẹsin Protestant. Lati oju irin yara rẹ, Tausen sọ imọ otitọ si awọn ẹlẹgbẹ rẹ. Bi o ba jẹ wipe awọn baba ti ilẹ Denmark wọnyẹn ni oye bi ijọ ti n ṣe si ẹkọ odi ni, a ba ma tun gbọ ohùn Tausen mọ lae; ṣugbọn dipo ki wọn ti i mọ inu saree kan labẹ ilẹ, wọn le e kuro ninu ile ẹsin wọn. Wọn wa di alailagbara ni akoko yii. Aṣẹ ọba ti a ṣẹṣẹ ṣe daabo bo awọn olukọ ikọni tuntun naa. Tausen bẹrẹ si ni i waasu. A ṣi awọn ile ijọsin silẹ fun, awọn eniyan si n rọ lọ lati gbọ ọ. Awọn miran pẹlu n waasu ọrọ Ọlọrun. A ṣe itumọ Majẹmu Tuntun si ede Denmark, a si pin in kaakiri. Akitiyan ti awọn ẹlẹsin popu n ṣe lati bi i lulẹ n ṣiṣẹ lati tan an kalẹ si ni, ko si pẹ pupọ ti Denmark tẹwọ gba igbagbọ ti a fọ mọ.ANN 107.3

    Ni Sweden bakan naa, awọn ọdọmọkunrin ti wọn ti mu lati inu kanga Wittenberg gbe omi iye lọ fun awọn ara ilu wọn. Meji ninu awọn adari iṣẹ Atunṣe ni ilẹ Sweden ni Olaf ati Laurentius Petri, ọmọ agbẹdẹ ti Orebro, ti wọn kẹkọ labẹ Luther ati Melancthon, wọn si fi tọkantọkan kọni ni otitọ ti wọn gba. Bii ti Alatunṣe nla naa, Olaf ru awọn eniyan soke pẹlu itara ati ẹbun isọrọ rẹ, nigba ti Laurentius, bi i ti Melancthon jẹ ọmọwe, ti o n ronu, ti o si ni iwa tutu. Awọn mejeeji jẹ olufọkansin tootọ, wọn ni imọ ti o ga nipa ẹkọ ọrọ Ọlọrun, wọn si ni igboya ti ko le yẹ ninu titan otitọ kalẹ. Atako awọn ẹlẹsin ijọ padi ko baku. Awọn alufa Katoliki ru awọn eniyan alaimọkan ti wọn gba ohun asan gbọ soke. Awọn ero saba maa n kọlu Olaf Petri, ni awọn akoko diẹ, pẹlu agbara ni o fi sa asala fun ẹmi rẹ. Ṣugbọn ọba fi oju rere wo awọn Alatunṣe wọnyi, o si daabo bo wọn.ANN 107.4

    Labẹ akoso ijọ Romu, awọn eniyan tẹri sinu aini ti inira si n lọ wọn mọlẹ. Wọn ko ni Iwe Mimọ; nitori ẹsin wọn ko kọja ami ati iṣẹ isin ti ko fun ọkan ni imọlẹ, wọn n pada sinu igbagbọ asan ati isin abọriṣa ti awọn baba wọn, ti ko gba Ọlọrun gbọ. Orilẹ ede naa pin si oriṣiriṣi ẹgbẹ ti wọn n ba ara wọn ja, ti ija aidẹyin wọn si pa kun ijiya gbogbo wọn. Ọba pinu lati ṣe iṣẹ atunṣe ninu ilu ati ijọ, o si tẹwọgba awọn oluranlọwọ ti wọn kun oju oṣuwọn wọnyi ninu ija rẹ lati tako Romu.ANN 107.5

    Niwaju ọba ati awọn eniyan pataki ni Sweden, Olaf Petri gbeja awọn ikọni ti a tunṣe pẹlu agbara nla ni atako si awọn aṣoju Romu. O sọ wipe a yoo gba awọn ikọni awọn Baba ijọ nigba ti wọn ba wa ni ibamu pẹlu Iwe Mimọ, wipe a ti fi awọn ikọni igbagbọ ti wọn ṣe pataki han ninu Bibeli ni ọna ti o han kedere ti o si yeni yekeyeke, ki gbogbo eniyan baa le ni oye rẹ. Kristi wipe, “Ikọni mi ki i ṣe temi, bikoṣe ti Ẹni ti o ran mi” (Johanu 7:16); Pọlu tun sọ wipe oun yoo di ẹni egun bi oun ba waasu iyinrere miran ju eyi ti oun ti gba lọ (Galatia 1:8). Alatunṣe naa wa sọ wipe, “Ki lo wa de ti awọn miran fi ro wipe wọn le gbe awọn ikọni kalẹ bi wọn ti fẹ, ti wọn si gbe wọn kalẹ gẹgẹ bi ohun ti a nilo fun igbala?” O fihan wipe awọn aṣẹ ijọ ko ni agbara bi wọn ba tako aṣẹ Ọlọrun, o si tẹle ẹkọ nla ti Protestant wipe “Bibeli, ani Bibeli nikan” ni aṣẹ fun igbagbọ ati iṣesi.ANN 107.6

    Bi o tilẹ jẹ wipe a ṣe ariyanjiyan yii ni ibi ti ko lokiki, o fihan wa “iru awọn eniyan ti wọn wa ninu ẹgbẹ ogun awọn Alatunṣe. Wọn ki i ṣe ẹni ti ko mọwe, onijagidijagan ẹsin, tabi alariwo—rara, ko ri bẹẹ; wọn ti kọ ẹkọ ọrọ Ọlọrun, wọn si mọ bi wọn ti le lo ohun ija ti a fifun wọn ninu ile ohun ija Bibeli daradara. Nipa imọ ẹkọ, wọn ju akẹgbẹ wọn lọ. Bi a ba fi akiyesi wa si awọn ibi titayọ bii Wittenberg ati Zurich, ati si awọn orukọ pataki bii Luther ati Melancthon, Zwingli ati Oecolampadius, a maa n ri wipe o tọna bi a ba sọ fun wa wipe awọn adari inu ẹgbẹ yii niwọnyi, a a si ro wipe wọn a ni agbara nla ati ọrọ pupọ; ṣugbọn awọn atẹle wọn ko ri bẹẹ. Amọ a yiju si ibi ija ti o farasin ni Sweden, ati orukọ ti ko lokiki bi i ti Olaf ati Laurentius Petri—lati ori awọn ọga titi de ori awọn ọmọ ẹyin—ki ni a ri? . . . “Awọn ọmọwe, ẹlẹkọ nipa ọrọ Ọlọrun, awọn ti wọn ti ni oye kikun nipa gbogbo ilana otitọ iyinrere, ti wọn n ri iṣẹgun lori awọn ọlọgbọn ẹwẹ ti ile ẹkọ ati ijoye Romu laijanpata.”ANN 108.1

    Nitori ariyanjiyan yii, ọba Sweden gba igbagbọ Protestant, laipẹ igbimọ orilẹ ede tẹwọ gba a pẹlu. Olaf Petri ti ṣe itumọ Majẹmu Tuntun si ede Sweden, nipa aṣẹ ọba, awọn arakunrin mejeeji naa si tumọ gbogbo Bibeli. Fun igba akọkọ, awọn eniyan Sweden gba ọrọ Ọlọrun ni ede abinibi wọn. Igbimọ orilẹ ede wa paṣẹ wipe ki gbogbo awọn alufa o ṣe alaye Iwe Mimọ, ki a si kọ awọn ọmọ ile iwe bi a ti n ka Bibeli.ANN 108.2

    Diẹdiẹ, ni ọna ti o si daju, imọlẹ alayọ ti iyinrere n gbá okunkun aimọkan ati igbagbọ asan lọ. Nigba ti o kuro ni abẹ inira Romu, orilẹ ede naa de ipo nla ati ipo agbara ti koi tii deri. Sweden di ọkan lara awọn ibi aabo fun ẹsin Protestant. Ọgọọrun ọdun lẹyin eyi, ni akoko ewu ti o buru julọ, orilẹ ede kekere ti ko lagbara tẹlẹ yii—ọkan ṣoṣo ni gbogbo Europe ti o gboya lati ṣe iranwọ—ni o wa gba Germany silẹ ninu wahala buburu ogun ti wọn ja fun ọgbọn ọdun. O dabi ẹnipe gbogbo iha ariwa Europe ti fẹ bọ si ọwọ iwa onroro Romu tan. Awọn ọmọ ogun Sweden ni wọn ran Germany lọwọ lati yi aṣeyọri awọn ẹlẹsin popu pada, lati gba ifarada fun awọn Protestant,—awọn atẹle Calvin, ati awọn atẹle Luther ,—ati lati da ominira ẹri ọkan pada sinu awọn orilẹ ede ti wọn ti gba iṣẹ Atunṣe.ANN 108.3

    Larger font
    Smaller font
    Copy
    Print
    Contents